Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?
Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?
“Ìhìn rere ìjọba yìí . . . ”—MÁTÍÙ 24:14.
NÍNÚ ìwàásù Jésù Lórí Òkè èyí táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa, ó gba àdúrà kan tó jẹ́ àwòkọ́ṣe, nínú àdúrà náà, ó bẹ Ọlọ́run pé: “Kí ìjọba rẹ dé.” Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ti há àdúrà yìí sórí, tí wọ́n sì ń gba àdúrà náà lágbà-tún-gbà. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan sọ pé, àdúrà yìí ni “olórí àdúrà táwọn Kristẹni máa ń gbà nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ìjọsìn.” Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gba àdúrà yìí lágbà-tún-gbà ni kò mọ ohun tí Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ tàbí ohun tó máa ṣe nígbà tó bá dé.—Mátíù 6:9, 10.
Kò yà wá lẹ́nu pé ọ̀rọ̀ rí bẹ́ẹ̀. Nítorí pé, àwọn aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣì ń kọ́ni láwọn ẹ̀kọ́ tó ta kora, tó ń ṣini lọ́nà, wọ́n sì máa ń ṣe àwọn àlàyé tí kò yéni nípa ohun tí Ìjọba Ọlọ́run jẹ́. Ẹnì kan kọ̀wé pé, Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ “ohun àrà ọ̀tọ̀ kan, . . . bí ẹnì kan ṣe sún mọ́ Ọlọ́run tó . . . , èrò tí àwọn èèyàn lọ́kùnrin lóbìnrin máa ń ní pé àwọn ti rí ìgbàlà lọ́dọ̀ Ọlọ́run.” Ẹlòmíì sọ pé, ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ni “ìtọ́ni nípa ṣọ́ọ̀ṣì.” Ìwé ẹ̀kọ́ ìsìn Kátólíìkì tó ń jẹ́, Catechism of the Catholic Church sì sọ pé: “Ìjọba Ọlọ́run ni òdodo àti àlàáfíà àti ìdùnnú nínú Ẹ̀mí Mímọ́.”
Wàá rí àlàyé tó yéni yékéyéké lójú ìwé 2 ìwé ìròyìn yìí. Ó kà pé: “Ìjọba Ọlọ́run tó ti ń ṣàkóso ní ọ̀run, yóò fòpin sí gbogbo ìwà ibi, á sì sọ ilẹ̀ ayé di Párádísè.” Ẹ jẹ́ ká wo bí Bíbélì ṣe ti ọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn.
Àwọn Tó Máa Ṣàkóso Gbogbo Ayé Lọ́jọ́ Iwájú
Ìjọba jẹ́ àkóso kan tí ọba kan ń ṣàkóso lé lórí. Jésù Kristi tó ti jíǹde ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run. Ìran tí Ọlọ́run fi han wòlíì Dáníẹ́lì jẹ́ ká mọ bí Ọlọ́run ṣe gbé Jésù gorí ìtẹ́ ní ọ̀run, Dáníẹ́lì sọ pé: “Mo rí i nínú ìran òru, sì wò ó! ó ṣẹlẹ̀ pé ẹnì kan bí ọmọ ènìyàn [Jésù] ń bọ̀ pẹ̀lú àwọsánmà ọ̀run; ó sì wọlé wá sọ́dọ̀ Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé [Jèhófà Ọlọ́run], wọ́n mú un wá, àní sún mọ́ iwájú Ẹni náà. A sì fún un ní agbára ìṣàkóso àti iyì àti ìjọba, pé kí gbogbo àwọn ènìyàn, àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè àti àwọn èdè máa sin àní òun. Agbára ìṣàkóso rẹ̀ jẹ́ agbára ìṣàkóso tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin tí kì yóò kọjá lọ, ìjọba rẹ̀ sì jẹ́ èyí tí a kì yóò run.”—Dáníẹ́lì 7:13, 14.
Ìwé Dáníẹ́lì tún jẹ́ ká mọ̀ pé, Ọlọ́run máa fìdí Ìjọba náà múlẹ̀, pé ó máa fòpin sí gbogbo ìṣàkóso èèyàn àti pé, ìjọba náà kò ní bọ́ sọ́wọ́ ẹlòmíì. Ìwé Dáníẹ́lì orí kejì ṣàlàyé àlá tí Ọlọ́run jẹ́ kí ọba Bábílónì lá, nínú èyí tó ti rí ère ńlá kan, tó ṣàpẹẹrẹ bí àwọn ìjọba alágbára tó ń ṣàkóso ayé á ṣe máa gba ìjọba lọ́wọ́ ara wọn. Wòlíì Dáníẹ́lì sọ ìtumọ̀ àlá náà. Ó sọ pé, “ní apá ìgbẹ̀yìn ọjọ́,” “Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn. Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Dáníẹ́lì 2:28, 44.
Ọba Ìjọba Ọlọ́run kò ní dá ṣàkóso. Nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù lórí ilẹ̀ ayé, ó fi dá àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ lójú pé, àwọn àtàwọn olóòótọ́ míì máa ní àjíǹde sí ọ̀run, wọ́n sì máa jókòó sórí ìtẹ́. (Lúùkù 22:28-30) Kì í ṣe ìtẹ́ gidi ni Jésù ní lọ́kàn, nítorí nínú ohun tó sọ, ọ̀run ni Ìjọba yẹn máa wà. Bíbélì ṣàlàyé pé àwọn tó máa bá Jésù ṣàkóso máa wá látinú “gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àti àwọn ènìyàn àti orílẹ̀-èdè.” Wọ́n máa jẹ́ “ìjọba kan àti àlùfáà fún Ọlọ́run wa, wọn yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀ ayé lórí.”—Ìṣípayá 5:9, 10.
Ìdí Tí Ìhìn Nípa Ìjọba Ọlọ́run fi Jẹ́ Ìhìn Rere
Kíyè sí i pé, Kristi Jésù gba àṣẹ láti ṣàkóso gbogbo “àwọn ènìyàn, àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè àti àwọn èdè,” àwọn tó ń bá Jésù ṣàkóso náà sì máa “ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀ ayé lórí.” Àwọn wo ló máa jẹ́ ọmọ abẹ́ Ìjọba yìí? Àwọn ni àwọn tó gbọ́ ìhìn rere tí à ń wàásù lónìí, tí wọ́n sì ń fi ohun tí wọ́n gbọ́ sílò. Àwọn òkú tó máa jíǹde sórí ilẹ̀ ayé àtàwọn tó máa láǹfààní láti wà láàyè títí láyé tún wà lára àwọn ọmọ abẹ́ ìjọba náà.
Kedere ni Bíbélì sọ àwọn ìbùkún tí àwọn èèyàn náà máa gbádùn lábẹ́ Ìjọba náà. Díẹ̀ nìyí lára wọn:
“Ó mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé. Ó ṣẹ́ ọrun sí wẹ́wẹ́, ó sì ké ọ̀kọ̀ sí wẹ́wẹ́; ó sun àwọn kẹ̀kẹ́ nínú iná.”—Sáàmù 46:9.
“Dájúdájú, wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn. Wọn kì yóò kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé; wọn kì yóò gbìn fún ẹlòmíràn jẹ.”—Aísáyà 65:21, 22.
“[Ọlọ́run] yóò . . . nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:3, 4.
“Ní àkókò yẹn, ojú àwọn afọ́jú yóò là, etí àwọn adití pàápàá yóò sì ṣí. Ní àkókò yẹn, ẹni tí ó yarọ yóò gun òkè gan-an gẹ́gẹ́ bí akọ àgbọ̀nrín ti ń ṣe, ahọ́n ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀ yóò sì fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ ké jáde.”—Aísáyà 35:5, 6.
“Wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn [Jésù], wọn yóò sì jáde wá, àwọn tí wọ́n ṣe ohun rere sí àjíǹde ìyè.”—Jòhánù 5:28, 29.
“Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—Sáàmù 37:11.
Ẹ ò rí i pé ìhìn rere lèyí jẹ́ lóòótọ́! Síwájú sí i, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó ti ní ìmúṣẹ fi hàn pé Ìjọba náà máa tó bẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso òdodo lé ilẹ̀ ayé lórí.