Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ni “Òpin” Náà?

Kí Ni “Òpin” Náà?

Kí Ni “Òpin” Náà?

“. . . nígbà náà ni òpin yóò sì dé.”—MÁTÍÙ 24:14.

LẸ́NU àìpẹ́ yìí, ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn èèyàn ń sọ nípa òpin ayé. Ìwé, sinimá àtàwọn ìwé ìròyìn, títí kan àwọn aláwàdà àtàwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì, ń lo oríṣiríṣi ọ̀nà láti ṣàlàyé bí ìparun ayé ṣe máa dé. Wọ́n ní ogun runlérùnnà máa mú ìparun bá ayé, pé àwọn òbìrìkìtì kan tí wọ́n ń pè ní steroid máa kọ lura, pé àwọn kòkòrò àrùn tó ń ṣekú pani máa gbayé kan, pé ojú ọjọ́ á máa yí pa dà lódìlódì tàbí pé ohun kan máa já lu ayé.

Èrò àwọn ẹlẹ́sìn náà yàtọ̀ síra lórí ọ̀ràn yìí, ọ̀pọ̀ wọn ló ń kọ́ni pé, “òpin” náà máa pa gbogbo ohun alààyè àti ilẹ̀ ayé run pátápátá. Nígbà tí ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn kan ń ṣàlàyé ìwé Mátíù 24:14, ó sọ ohun tó bani lẹ́rù yìí pé: “Ẹsẹ yìí jẹ́ ọ̀kan lára apá tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run . . . Ìran wa yìí dojú kọ ìparun yán-án-yán, àmọ́ àwọn èèyàn díẹ̀ ló rí àgbákò tó ń bọ̀ náà.”

Àwọn tó ní irú èrò yìí ti gbàgbé òtítọ́ kan tó ṣe pàtàkì pé, Jèhófà Ọlọ́run ti “fìdí [ilẹ̀ ayé] múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in, . . . kò wulẹ̀ dá a lásán, [àmọ́] ó ṣẹ̀dá rẹ̀ àní kí a lè máa gbé inú rẹ̀.” (Aísáyà 45:18) Nítorí náà, nígbà tí Jésù ń sọ nípa “òpin” náà, kò ní in lọ́kàn pé ayé yìí máa pa run, kò sì ní in lọ́kàn pé, ẹ̀dá èèyàn máa pa run. Ohun tó ní lọ́kàn ni pé, àwọn èèyàn burúkú ló máa pa run, ìyẹn àwọn tó kọ̀ jálẹ̀ láti máa gbé ìgbé ayé wọn lọ́nà tó bá àwọn ìlànà onífẹ̀ẹ́ ti Jèhófà mu.

Gbé àpèjúwe yìí yẹ̀ wò. Ká ní o ní ilé kan tó jojú ní gbèsè, tó o sì ní káwọn èèyàn máa gbé ibẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́. Àwọn kan lára àwọn tó gbé ibẹ̀ ń gbé lálàáfíà pẹ̀lú àwọn yòókù, wọ́n sì ń bójú tó ilé rẹ. Àmọ́, oníwàhálà làwọn yòókù, wọ́n máa ń bá ara wọn jà, wọ́n sì máa ń bú àwọn èèyàn rere tó ń gbe ibẹ̀. Àwọn oníwàhálà yìí ba àwọn ohun ìní rẹ jẹ́, nígbà tó o sì sọ fún wọn, ńṣe ni wọn ń bá ìwàkiwà wọn nìṣó.

Kí lo máa ṣe láti yanjú ọ̀ràn náà? Ṣé wàá wó ilé rẹ ni? Ó jọ pé o kò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé wàá lé àwọn èèyàn burúkú náà kúrò nílé rẹ tí wàá sì ṣàtúnṣe ohun tí wọ́n ti bà jẹ́.

Ohun tí Jèhófà máa ṣe nìyẹn. Ó mí sí onísáàmù yìí láti kọ̀wé pé: “Àwọn aṣebi ni a óò ké kúrò, ṣùgbọ́n àwọn tí ó ní ìrètí nínú Jèhófà ni yóò ni ilẹ̀ ayé. Àti pé ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́; dájúdájú, ìwọ yóò sì fiyè sí ipò rẹ̀, òun kì yóò sì sí. Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—Sáàmù 37:9-11.

Àpọ́sítélì Pétérù náà sọ̀rọ̀ lórí kókó yìí. Lábẹ́ ìdarí ẹ̀mí mímọ́, ó sọ pé: “Àwọn ọ̀run wà láti ìgbà láéláé àti ilẹ̀ ayé kan tí ó dúró digbí-digbí láti inú omi àti ní àárín omi nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; àti nípasẹ̀ ohun wọnnì, ayé ìgbà yẹn jìyà ìparun nígbà tí a fi àkúnya omi bò ó mọ́lẹ̀.” (2 Pétérù 3:5, 6) Ìkún Omi ọjọ́ Nóà ni àpọ́sítélì yìí ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run ló pa run, àmọ́ ilẹ̀ ayé kò pa run. Àkúnya Omi tó kárí ayé yìí jẹ́ “àpẹẹrẹ kan . . . fún àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run nípa àwọn ohun tí ń bọ̀.”—2 Pétérù 2:6.

Pétérù wá fi kún un pé: “Àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé tí ó wà nísinsìnyí ni a tò jọ pa mọ́ fún iná.” Tá a bá ní ká dúró sí ibẹ̀ yẹn, a lè ṣi ọ̀rọ̀ náà lóye pátápátá. Àmọ́ kíyè sí i pé ẹsẹ náà ń bá a nìṣó pé: “Àti ti ìparun àwọn ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run.” Kì í ṣe ilẹ̀ ayé ló máa pa run bí kò ṣe àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run. Kí ló wá máa tẹ̀ lé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí? Pétérù sọ pé: “Ṣùgbọ́n ọ̀run tuntun [Ìjọba Ọlọ́run tí Mèsáyà máa ṣàkóso] àti ilẹ̀ ayé tuntun [àwùjọ ẹ̀dá èèyàn olódodo] wà tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀, nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.”—2 Pétérù 3:7, 13.

Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tún fi hàn pé àkókò tí “òpin” náà máa dé ti sún mọ́lé. Ka Mátíù 24:3-14 àti 2 Tímótì 3:1-5 láti rí àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí. *

Ǹjẹ́ kò yà ẹ́ lẹ́nu pé, àwọn èèyàn kò lóye Mátíù 24:14, ẹsẹ Bíbélì tí ọmọdé pàápàá lè lóye? Ìdí wà tí ọ̀ràn fi rí bẹ́ẹ̀. Sátánì ti fọ́ èrò inú àwọn èèyàn lójú, kí wọ́n má bàa lóye òtítọ́ ṣíṣeyebíye tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (2 Kọ́ríńtì 4:4) Bákan náà, Ọlọ́run ti fi àwọn nǹkan tó fẹ́ ṣe pa mọ́ fún àwọn agbéraga, ó sì ti ṣí wọn payá fún àwọn onírẹ̀lẹ̀. Gbọ́ ohun tí Jésù sọ lórí èyí, ó ní: “Mo yìn ọ́ ní gbangba, Baba, Olúwa ọ̀run àti ilẹ̀ ayé, nítorí pé ìwọ ti fi nǹkan wọ̀nyí pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n àti àwọn amòye, o sì ti ṣí wọn payá fún àwọn ìkókó.” (Mátíù 11:25) Ẹ ò rí i bó ti jẹ́ ohun iyì tó pé, a wà lára àwọn onírẹ̀lẹ̀ èèyàn tó lóye ohun tí Ìjọba Ọlọ́run jẹ́, tá a sì tún wà lára àwọn tó lè máa retí ìbùkún tó máa mú wá fún àwọn tó tì í lẹ́yìn!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka orí 9 ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ìjọba náà máa fi “òpin” sí gbogbo ìwà ibi tó wà lórí ilẹ̀ ayé