Ǹjẹ́ Bíbélì Lòdì Sí Tẹ́tẹ́ Títa?
Ǹjẹ́ Bíbélì Lòdì Sí Tẹ́tẹ́ Títa?
ÀWỌN fíìmù àti eré orí tẹlifíṣọ̀n tó lókìkí sábà máa ń fi tẹ́tẹ́ títa hàn pé ó jẹ́ eré ọwọ́dilẹ̀ táwọn arẹwà, àwọn olówó àtàwọn ọ̀làjú máa ń ṣe nílé tẹ́tẹ́. Àmọ́, ìtàn àròsọ lásán làwọn tó ń wo irú àwọn eré bẹ́ẹ̀ kà wọ́n sí.
Àmọ́, ní ti tòótọ́, àwọn tó ń ta tẹ́tẹ́ fẹ́ràn tẹ́tẹ́ lọ́tìrì, tẹ́tẹ́ tí wọ́n máa ń ta nítorí eré ìdárayá àti tẹ́tẹ́ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì bí wọ́n ṣe fẹ́ràn tẹ́tẹ́ tí wọ́n ń ta láwọn ilé tẹ́tẹ́. Ìwé kan tó sọ̀rọ̀ nípa tẹ́tẹ́ ìyẹn, Internet Gambling sọ pé, tẹ́tẹ́ “jẹ́ ohun kan tó fẹ́rẹ̀ẹ́ kárí ayé tó ń fa ojú àwọn èèyàn mọ́ra tó sì ń gbèèràn bí iná ọyẹ́.” Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ti sọ tẹ́tẹ́ tí wọ́n ń fi káàdì ta di eré ìdárayá báyìí, ó sì wọ́pọ̀ lórí tẹlifíṣọ̀n àti Íńtánẹ́ẹ̀tì. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn kan ṣe sọ, àwọn tó mọ̀ nípa tẹ́tẹ́ sọ pé iye àwọn tó máa ń fi káàdì ta tẹ́tẹ́ ti pọ̀ ní ìlọ́po méjì láàárín ọdún kan ààbọ̀, ìyẹn lẹ́nu àìpẹ́ yìí.
Wọ́n ṣàlàyé pé tẹ́tẹ́ títa jẹ́ kíkó owó lé orí ohun kan téèyàn ò mọ̀ bóyá èèyàn máa jẹ tàbí kò ní jẹ. Ọ̀pọ̀ èèyàn sọ pé níwọ̀n bí owó náà bá sáà ti jẹ́ ti ẹni tó ń ta tẹ́tẹ́ náà, tí tẹ́tẹ́ títa kò sì di bárakú fún un, kò sí ohun tó burú nínú rẹ̀. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ ti Kátólíìkì, ìyẹn New Catholic Encyclopedia sọ pé, tẹ́tẹ́ “kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ àyàfi tí kò bá jẹ́ kéèyàn ṣe ojúṣe rẹ̀.” Àmọ́ kò sí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó ṣètìlẹ́yìn fún ohun tí wọ́n sọ yìí. Ojú wo ló yẹ kí Kristẹni kan fi wo ọ̀ràn yìí? Ṣé Bíbélì fara mọ́ tẹ́tẹ́ títa àbí ó lòdì sí i?
Lóòótọ́, Ìwé Mímọ́ kò sọ ohun kan tó ṣe tààràtà nípa tẹ́tẹ́ títa. Àmọ́, èyí kò túmọ̀sí pé kò sí ìtọ́sọ́nà kankan lórí ọ̀ràn yìí. Kàkà kí Bíbélì ṣe òfin nípa gbogbo nǹkan, ńṣe ló rọ̀ wá pé ká “máa bá a lọ ní ríróye ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́.” (Éfésù 5:17) Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀gbẹ́ni E. W. Bullinger tó ń ṣèwádìí nípa Bíbélì ti wí, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n túmọ̀ sí “róye,” túmọ̀ sí pé kéèyàn “lo ọpọlọ rẹ̀” láti fa àwọn kókó ẹ̀kọ́ yọ, ìyẹn ni “ìmọ̀ téèyàn máa ń ní nígbà tó bá ronú jinlẹ̀ lórí kókó kan.” Kristẹni kan lè róye ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́ lórí ọ̀ràn yìí nípa fífa kókó ọ̀rọ̀ yọ látinú Bíbélì kó sì ronú lórí àwọn ìlànà tó sọ nípa tẹ́tẹ́ títa. Bí o bá ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nínú ọ̀rọ̀ tá a fẹ́ jíròrò tẹ̀ lé e yìí, o lè bi ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ tẹ́tẹ́ títa bá àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí mu? Kí ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi hàn pé ó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run lórí ọ̀ràn yìí?’
Ewu Tó Wà Nínú Wíwá Oríire
Nítorí pé tẹ́tẹ́ jẹ́ kíkó owó lé orí ohun kan téèyàn ò mọ̀ bóyá èèyàn máa jẹ tàbí kò ní jẹ, àwọn èèyàn gbà pé oríire, ìyẹn agbára abàmì kan tí wọ́n sọ pé ó ń darí nǹkan, ló ń mú káwọn èèyàn jẹ, pàápàá nígbà tí wọ́n bá ti kó owó sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tó ń ta tẹ́tẹ́ máa
ń mú nọ́ńbà oríire fún tẹ́tẹ́ lọ́tìrì, nítorí ìgbàgbọ́ nínú ohun asán, àwọn tó ń ta ayò àwọn ará Ṣáínà, ìyẹn mah-jongg kò fẹ́ kéèyàn máa sọ̀rọ̀ sórí ọmọ ayò kí wọ́n tó tá a, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò fẹ́ kéèyàn fi ẹnu fẹ́ atẹ́gùn sórí ọmọ ayò náà kí wọ́n tó ta á. Kí nìdí? Ìdí ni pé, àwọn atatẹ́tẹ́ gbà gbọ́ pé oríire lè mú kí ẹni náà jẹ.Ṣé kò léwu téèyàn bá gbẹ́kẹ̀ lé oríire? Àwọn kan lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ rò pé kò léwu. Wọ́n gbà gbọ́ pé oríire lè mú kí àwọn ní aásìkí. Kí ni èrò Jèhófà lórí ọ̀ràn náà? Ọlọ́run tipasẹ̀ wòlíì Aísáyà sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin jẹ́ àwọn tí ń fi Jèhófà sílẹ̀, àwọn tí ń gbàgbé òkè ńlá mímọ́ mi, àwọn tí ń tẹ́ tábìlì fún ọlọ́run Oríire, àti àwọn tí ń bu àdàlù wáìnì kún dẹ́nu fún ọlọ́run Ìpín.” (Aísáyà 65:11) Lójú Ọlọ́run, ìgbàgbọ́ nínú oríire jẹ́ oríṣi ìbọ̀rìṣà kan, kò sì bá ìjọsìn tòótọ́ mu. Ó jẹ́ níní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú agbára kan dípò kéèyàn ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run tòótọ́. Kò sí ìdí kankan láti gbà pé Ọlọ́run ti yí èrò rẹ̀ pa dà.
Bí Wọ́n Ṣe Máa Ń Jẹ Owó
Bóyá wọ́n ra tíkẹ́ẹ̀tì lọ́tìrì ni o tàbí wọ́n kó owó lé ohun kan tí wọ́n fẹ́ jẹ látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì, bóyá wọ́n ta tẹ́tẹ́ tí wọ́n máa ń ta nítorí eré ìdárayá ni o tàbí wọ́n ta tẹ́tẹ́ nílé tẹ́tẹ́, àwọn atatẹ́tẹ́ kì í sábà bìkítà nípa ibi tí owó tí wọ́n fẹ́ jẹ náà ti wá. Tẹ́tẹ́ títa yàtọ̀ sí okòwò tó tọ́ tàbí ọjà téèyàn rà kó lè jèrè, ìdí ni pé, owó táwọn kan pàdánù ni atatẹ́tẹ́ fẹ́ jẹ. * Ibùdó Ìtọ́jú Àwọn Tí Àṣà Burúkú Ti Di Bárakú fún, Tí Wọ́n Tún Ń Rí sí Ìlera Ọpọlọ nílẹ̀ Kánádà sọ pé: “Bí ẹnì kan bá di olówó tabua nídìí tẹ́tẹ́ títa, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ti pàdánù owó wọn!” Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló lè ran Kristẹni kan lọ́wọ́ láti lóye èrò Ọlọ́run lórí ọ̀ràn yìí?
Òfin Kẹwàá tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ pé: “Ojú rẹ kò gbọ́dọ̀ wọ aya ọmọnìkejì rẹ, tàbí ẹrúkùnrin rẹ̀ tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀ tàbí akọ màlúù rẹ̀ tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ tàbí ohunkóhun tí ó jẹ́ ti ọmọnìkejì rẹ.” (Ẹ́kísódù 20:17) Ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ló jẹ́ tí èèyàn bá jẹ́ kí ojú òun wọ ohun ìní àti owó ọmọnìkejì ẹni, wọ́n sì kà á mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ jíjẹ́ kí ojú èèyàn wọ aya ọmọnìkejì ẹni. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tún òfin yìí sọ fún àwọn Kristẹni pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣojúkòkòrò.” (Róòmù 7:7) Ṣé Kristẹni kan lè jẹ̀bi ojúkòkòrò, tó bá ń fẹ́ kí ohun tí ẹnì kan pàdánù di tòun?
Ọ̀gbẹ́ni J. Phillip Vogel tó jẹ́ akọ̀ròyìn sọ pé: “Bóyá [ọ̀pọ̀ onítẹ́tẹ́] gbà tàbí wọn kò gbà, kí wọ́n tó dáwọ́ lé tẹ́tẹ́ tí wọ́n fẹ́ ta, ó máa ń ṣe wọ́n bíi pé àwọn fi owó tó wà lọ́wọ́ àwọn jẹ owó ńlá, bí owó tó wà lọ́wọ́ wọn kò bá tiẹ̀ tó nǹkan pàápàá.” Èrò àwọn tó ń ta tẹ́tẹ́ yìí ni pé, kí àwọn di ọlọ́rọ̀ láìṣe iṣẹ́ rárá. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, èrò yẹn ta ko ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé kí Kristẹni kan “ṣe iṣẹ́ àṣekára, kí ó máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe ohun tí ó jẹ́ iṣẹ́ rere, kí ó lè ní nǹkan láti pín fún ẹni tí ó wà nínú àìní.” (Éfésù 4:28) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pàápàá tẹnu mọ́ ọn pé: “Bí ẹnikẹ́ni kò bá fẹ́ ṣiṣẹ́, kí ó má ṣe jẹun.” Ó tún sọ pé: “Kí wọ́n máa jẹ oúnjẹ tí àwọn fúnra wọn ṣiṣẹ́ fún.” (2 Tẹsalóníkà 3:10, 12) Àmọ́, ṣé a lè sọ pé tẹ́tẹ́ títa jẹ́ iṣẹ́ rere?
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé tẹ́tẹ́ títa lè gba pé kéèyàn máa fi ọpọlọ ṣèṣirò, èèyàn jẹ owó téèyàn bá rí níbẹ̀ ni, kì í ṣe pé èèyàn ṣiṣẹ́ fún owó náà, kì í sì í ṣe owó tí èèyàn gbà nítorí iṣẹ́ tó ṣe. Nínú tẹ́tẹ́ títa, orí bóyá èèyàn á jẹ tàbí kò ní jẹ ló máa ń wà lọ́kàn ẹni lẹ́yìn téèyàn bá ti kówó sílẹ̀, atatẹ́tẹ́ sì máa ń rò pé ìrètí wà pé, bópẹ́ bóyá nǹkan á dáa. Kà sòótọ́, ìfà ni atatẹ́tẹ́ ń wá. Àmọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gba àwọn Kristẹni níyànjú láti máa fọwọ́ ara wọn ṣiṣẹ́ rere láti rí owó. Ọlọ́gbọ́n Ọba Sólómọ́nì sọ pé: “Fún ènìyàn, kò sí ohun tí ó sàn ju pé kí ó máa jẹ kí ó sì máa mu ní tòótọ́, kí ó sì jẹ́ kí ọkàn òun rí ohun rere nítorí iṣẹ́ àṣekára rẹ̀.” Ó tún sọ síwájú sí i pé: “Ọwọ́ Ọlọ́run tòótọ́ ni èyí ti wá.” (Oníwàásù 2:24) Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kò gbé ìrètí wọn ka àlá ọ̀sán gangan tàbí ọ̀nà ẹ̀bùrú, àmọ́ ojú Ọlọ́run ni wọ́n ń wò fún ayọ̀ àti ìbùkún wọn.
“Ìdẹkùn” Téèyàn Gbọ́dọ̀ Yẹra Fún
Bí atatẹ́tẹ́ kan bá tiẹ̀ sapá tó sì jẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú rẹ̀ á máa dùn lákòókò náà, kò yẹ kó gbàgbé àkóbá ọlọ́jọ́ pípẹ́ tí tẹ́tẹ́ títa máa ń fà báni. Ìwé Òwe 20:21 sọ pé, “Ogún ni a ń fi ìwọra kó jọ lákọ̀ọ́kọ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ ọ̀la rẹ̀ kì yóò ní ìbùkún.” Ọ̀pọ̀ àwọn tó jẹ tẹ́tẹ́ lọ́tìrì àtàwọn tó ń ta oríṣi tẹ́tẹ́ míì ti kábàámọ̀ nígbà tí wọ́n rí i pé owó tí wọ́n jẹ kò mú kí wọ́n láyọ̀. Ẹ ò rí i pé ó dára gan-an ká fetí sí ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé ká má ṣe gbé ìrètí wa lé “ọrọ̀ àìdánilójú, bí kò ṣe lé Ọlọ́run, ẹni tí ń pèsè ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀ jaburata fún ìgbádùn wa.”—1 Tímótì 6:17.
Yàtọ̀ sí pé atatẹ́tẹ́ lè jẹ tàbí kó pàdánù, ewu ńlá tún wà nídìí tẹ́tẹ́ títa. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Àwọn tí ó pinnu láti di ọlọ́rọ̀ máa ń ṣubú sínú ìdẹwò àti ìdẹkùn àti ọ̀pọ̀ ìfẹ́-ọkàn tí í ṣe ti òpònú, tí ó sì ń ṣeni lọ́ṣẹ́, èyí tí ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé.” (1 Tímótì 6:9) Àwọn èèyàn máa ń ṣe ìdẹkùn lọ́nà tó lè gbá ẹranko kan mú ṣinṣin. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n kàn fẹ́ ta tẹ́tẹ́ fúngbà díẹ̀ nígbà tí wọ́n kó owó kékeré lé e, àmọ́ tí wọn kò sì lè jáwọ́ nínú rẹ̀ mọ́ nítorí tẹ́tẹ́ títa ti dẹkùn mú wọn. Èyí sì ti ba iṣẹ́ ìgbésí ayé àwọn kan jẹ́, ó ti mú kí àárín àwọn tó fẹ́ràn ara wọn dàrú, ó sì ti mú kí ìdílé tú ká.
Lẹ́yìn tá a ti ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀pọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó jẹ́ ká mọ ojú tó yẹ ká máa fi wo tẹ́tẹ́, ǹjẹ́ o rí ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́ lórí ọ̀rọ̀ yìí? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni pé: “Ẹ sì jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí, ṣùgbọ́n ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín padà, kí ẹ lè ṣàwárí fúnra yín ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.” (Róòmù 12:2) Ìfẹ́ Ọlọ́run ló yẹ kó máa darí ìgbésí ayé Kristẹni kì í ṣe èrò ọ̀pọ̀ èèyàn. Nítorí pé Jèhófà jẹ́ “Ọlọ́run aláyọ̀,” ó fẹ́ ká gbádùn ìgbésí ayé wa, àmọ́ kò fẹ́ kí á kábàámọ̀ tó máa ń gbẹ̀yìn ọ̀rọ̀ àwọn tó kó sí ìdẹkùn tẹ́tẹ́ títa.—1 Tímótì 1:11.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ Ìwé ìròyìn Jí! October 8, 2000, lédè Gẹ̀ẹ́sì, ojú ìwé 25 sí 27 ṣàlàyé ìyàtọ̀ tó wà láàárín fífi owó dókòwò àti títa tẹ́tẹ́. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 14]
Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa ń ṣe iṣẹ́ rere láti rí owó
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 13]
Ìdùnnú Tó Máa Ń Wà Nínú Jíjẹ́ Tẹ́tẹ́
Ṣé tẹ́tẹ́ títa lè mọ́ èèyàn lára táá sì wá di bárakú? Lẹ́yìn àyẹ̀wò tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Hans Breiter ṣe lórí bí ọ̀ràn ṣe máa ń rí lára àwọn atatẹ́tẹ́ nígbà tí wọ́n bá jẹ tàbí tí wọ́n bá pàdánù, ó sọ pé, “owó tí wọ́n máa ń jẹ nídìí tẹ́tẹ́ má ń mú kí ọpọlọ wọn máa ṣe bíi ti àwọn tí kokéènì ti di bárakú fún.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Owó ta ni àwọn atatẹ́tẹ́ ń retí láti jẹ?