Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Àwọn wo ni “àwọn tí ó jẹ́ ti agbo ilé Késárì” tí wọ́n sọ pé kí Pọ́ọ̀lù bá àwọn kí àwọn Kristẹni tó wà ní ìlú Fílípì?
▪ Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé láti Róòmù sí ìjọ Fílípì ní nǹkan bí ọdún 60 sí 61 Sànmánì Kristẹni. Olú Ọba Nérò ni Késárì náà tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn. Àmọ́, àwọn wo nínú agbo ilé Nérò ló lè ní kí Pọ́ọ̀lù máa bá àwọn kí àwọn Kristẹni tó wa ní ìlú Fílípì?—Fílípì 4:22.
Kò tọ̀nà láti rò pé àwọn mọ̀lẹ́bí olú ọba nìkan ni gbólóhùn náà “agbo ilé Késárì” ń tọ́ka sí. Kàkà bẹ́ẹ̀, gbogbo àwọn èèyàn tó ń ṣiṣẹ́ fún olú ọba ni ọ̀rọ̀ náà ń tọ́ka sí, ìyẹn àwọn ẹrú àti òmìnira tí wọ́n wà ní Róòmù àti agbègbè rẹ̀. Nítorí náà, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ìránṣẹ́ ọba wà lára “agbo ilé Késárì.” Wọ́n máa ń ṣe onírúurú iṣẹ́ tó jẹ mọ́ iṣẹ́ àbójútó àti iṣẹ́ nínú àwọn ààfin olú ọba àti nínú àwọn ilé àti ilẹ̀ rẹ̀. Àwọn ìránṣẹ́ kan tiẹ̀ ń ṣiṣẹ́ àbójútó nínú àkóso ìjọba.
Ẹ̀rí fi hàn pé àwọn kan lára àwọn ìránṣẹ́ olú ọba tó wà ní Róòmù di Kristẹni. A kò mọ̀ bóyá ìyẹn jẹ́ àbájáde iṣẹ́ ìwàásù tí Pọ́ọ̀lù ṣe ní Róòmù. Èyí tó wù tí ì báà jẹ́, àwọn èèyàn náà nífẹ̀ẹ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ sí ìjọ tó wà ní ìlú Fílípì. Níwọ̀n bí ìlú Fílípì ti jẹ́ ìlú tó wà lábẹ́ àkóso Róòmù, tí ọ̀pọ̀ ọmọ ogun àtàwọn ìránṣẹ́ ọba tí wọ́n ti fẹ̀yìn tì sì ń gbé níbẹ̀, ó ṣeé ṣe kí àwọn Kristẹni kan ní ìlú Fílípì yìí jẹ́ ọ̀rẹ́ àwọn ará Róòmù, àwọn ará Róòmù yìí ló ní kí Pọ́ọ̀lù máa bá àwọn kí àwọn Kristẹni tó wà ní ìlú Fílípì.
Kí ni ètò ṣíṣú opó tí Òfin Mósè sọ nípa rẹ̀?
▪ Ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́, bí ọkùnrin kan bá kú láìní ọmọ, wọ́n retí pé kí arákùnrin rẹ̀ ṣú aya rẹ̀ lópó kó bàa lè bímọ kí ìdílé ọkùnrin tó kú náà má bàa pa run. (Jẹ́nẹ́sísì 38:8) Nígbà tó yá, wọ́n fi ètò yìí kún Òfin Mósè, wọ́n sì mọ̀ ọ́n sí ètò ṣíṣú opó. (Diutarónómì 25:5, 6) Ohun tí Bóásì ṣe tó wà nínú ìwé Rúùtù, fi hàn pé ọkùnrin kan tó jẹ́ mọ̀lẹ́bí ẹni tó kú náà lè ṣú aya rẹ̀ lópó tí ẹni tó kú náà kò bá ní arákùnrin mọ́.—Rúùtù 1:3, 4; 2:19, 20; 4:1-6.
Ohun tí àwọn Sadusí sọ gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Máàkù 12:20-22 fi hàn pé wọ́n ń tẹ̀ lé àṣà yìí ní ọjọ́ Jésù. Òpìtàn Júù ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, tó ń jẹ́ Flavius Josephus sọ pé, kì í ṣe pé ètò yìí kò jẹ́ kí orúkọ ìdílé pa rẹ́ nìkan ni, àmọ́ kò tún jẹ́ kí dúkìá ìdílé náà bọ́ sọ́wọ́ ẹlòmíì, èyí sì mú kí opó náà rí ohun táá máa fi gbọ́ bùkátà ara rẹ̀. Nígbà yẹn, ìyàwó kò ní ẹ̀tọ́ láti jogún ọkọ rẹ̀. Àmọ́, ọmọ tí opó náà bá bí fún arákùnrin ẹni tó kú náà ló máa jogún ẹni tó kú náà.
Òfin náà gba mọ̀lẹ́bí kan láyè láti kọ̀ pé òun kò ṣú opó. Àmọ́ ohun ìtìjú ni wọ́n kà á sí tí ẹnì kan bá kọ̀ láti “gbé agbo ilé arákùnrin rẹ̀ ró.”—Diutarónómì 25:7-10; Rúùtù 4:7, 8.