Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jésù—Ibo Ló Ti Wá?

Jésù—Ibo Ló Ti Wá?

“[Pílátù] tún wọ ààfin gómìnà, ó sì wí fún Jésù pé: ‘Ibo ni o ti wá?’ Ṣùgbọ́n Jésù kò fún un ní ìdáhùn kankan.”—JÒHÁNÙ 19:9.

PỌ́ŃTÙ PÍLÁTÙ tó jẹ́ gómìnà tó ń ṣojú fún Róòmù béèrè ìbéèrè yẹn nígbà tí wọ́n ń bá Jésù ṣe ẹjọ́ tó lè yọrí sí ikú rẹ̀. * Pílátù mọ ibi tí Jésù ti wá ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. (Lúùkù 23:6, 7) Ó tún mọ̀ pé Jésù kì í ṣe èèyàn kan lásán. Ṣé Pílátù ń ṣe kàyéfì bóyá Jésù ti wà láàyè nígbà kan rí ni? Ṣé kèfèrí alákòóso yìí fẹ́ mọ òtítọ́ nípa ọ̀rọ̀ yìí kí ó sì ṣe nǹkankan ni? Ohun yòówù kó jẹ́, Jésù kò dáhùn, kò sì pẹ́ tó fi hàn kedere pé ọ̀ràn ìlú ló jẹ Pílátù lógún ju òtítọ́ àti ìdájọ́ òdodo lọ.—Mátíù 27:11-26.

Ó dùn mọ́ni pé àwọn tí wọ́n fẹ́ láti mọ ibi tí Jésù ti wá lóòótọ́ lè mọ̀ ọ́n pẹ̀lú ìrọ̀rùn. Bíbélì jẹ́ ká mọ ibi tí Jésù Kristi ti wá gangan. Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ohun tó tẹ̀ lé e yìí.

Ibi tí wọ́n bí i sí

Ìṣirò òde òní fi hàn pé ní ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà ìwọ́wé ọdún tí wọ́n ń pè ní ọdún 2 ṣáájú Sànmánì Kristẹni nísinsìnyí ni wọ́n bí Jésù sí abúlé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti ìlú Jùdíà ní ipò rírẹlẹ̀ kan. Àṣẹ tí Késárì Ọ̀gọ́sítọ́sì pa pé káwọn èèyàn lọ forúkọ sílẹ̀, ló mú kí Màríà, ìyá Jésù, tí “ó ti sún mọ́ àkókò àtibímọ,” bá Jósẹ́fù ọkọ rẹ̀ lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, tó jẹ́ ìlú àwọn baba ńlá Jósẹ́fù. Nígbà tí wọn kò rí ibi tí wọ́n lè dé sí nínú abúlé tó kún fọ́fọ́ fún èrò yìí, tọkọtaya náà ní láti dé sí ilé ẹran, níbi tí wọ́n bí Jésù sí, wọ́n sì tẹ́ ẹ sí ibùjẹ ẹran.—Lúùkù 2:1-7.

Ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún ṣáájú, Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ ibi tí wọ́n máa bí Jésù sí, ó ní: “Ìwọ, Bẹ́tílẹ́hẹ́mù Éfúrátà, ẹni tí ó kéré jù láti wà lára àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún Júdà, inú rẹ ni ẹni tí yóò di olùṣàkóso Ísírẹ́lì yóò ti jáde tọ̀ mí wá.” * (Míkà 5:2) Bẹ́tílẹ́hẹ́mù kéré gan-an débi pé wọn kò kà á mọ́ ara àwọn ìlú ńlá tó wà ní ilẹ̀ Júdà. Síbẹ̀, abúlé kékeré yìí máa ní ògo tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Bẹ́tílẹ́hẹ́mù yìí ni Mèsáyà tàbí Kristi tí Bíbélì ṣèlérí yóò ti jáde wá.—Mátíù 2:3-6; Jòhánù 7:40-42.

Ibi tí wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà

Lẹ́yìn tí Jésù àtàwọn òbí rẹ̀ ti gbé nílẹ̀ Íjíbítì fúngbà díẹ̀, wọ́n ṣí wá sí Násárétì, ìlú ńlá kan nílẹ̀ Gálílì tó wà ní nǹkan bíi kìlómítà mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún [96] ní àríwá ìlú Jerúsálẹ́mù. Ní àkókò yẹn, Jésù kò tíì tó ọmọ ọdún mẹ́ta. Àgbègbè yìí jẹ́ ibi tó lẹ́wà gan-an, tí àwọn àgbẹ̀, olùṣọ́ àgùntàn àti àwọn apẹja ti máa ń ṣe iṣẹ́ wọn. Ibi yìí ni Jésù dàgbà sí nínú ìdílé ńlá kan tí kì í ṣe ìdílé olówó.—Mátíù 13:55, 56.

Ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún ṣáájú ìgbà yẹn, Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé Mèsáyà yóò jẹ́ “ará Násárétì.” Mátíù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ ìwé Ìhìn Rere sọ pé, Jésù àtàwọn òbí rẹ̀ wá gbé ní “Násárétì, kí a bàa lè mú ohun tí a sọ nípasẹ̀ àwọn wòlíì ṣẹ pé: ‘A ó pè é ní ará Násárétì.’” (Mátíù 2:19-23) Ó jọ pé ìtumọ̀ orúkọ náà, “ará Násárétì” tan mọ́ ọ̀rọ̀ Hébérù náà “èéhù.” Ó hàn kedere pé àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà tó pe Mèsáyà ní “èéhù kan” tí yóò yọ látara Jésè ni Mátíù ń tọ́ka sí, èyí tó túmọ̀ sí pé Mèsáyà yóò jẹ́ àtọmọdọ́mọ Jésè, bàbá Dáfídì Ọba. (Aísáyà 11:1) Lóòótọ́, àtọmọdọ́mọ Jésè ni Jésù nípasẹ̀ Dáfídì.—Mátíù 1:6, 16; Lúùkù 3:23, 31, 32.

Ibi tó ti wá gangan

Bíbélì kọ́ wa pé Jésù ti wà láàyè tipẹ́tipẹ́ kí wọ́n tó bí i sí ilé ẹran yẹn ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Àsọtẹ́lẹ̀ Míkà tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níṣàájú ń bá a lọ pé, “Orírun [Ẹni yìí] jẹ́ láti àwọn àkókò ìjímìjí, láti àwọn ọjọ́ tí ó jẹ́ àkókò tí ó lọ kánrin.” (Míkà 5:2) Jésù ni àkọ́bí Ọmọ Ọlọ́run, ẹ̀dá ẹ̀mí ni lọ́run tẹ́lẹ̀ kí wọ́n tó bí i sórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn. Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé: “Èmi sọ kalẹ̀ wá láti ọ̀run.” (Jòhánù 6:38; 8:23) Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀?

Jèhófà * Ọlọ́run tipasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ ṣe iṣẹ́ ìyanu kan, ó mú ìwàláàyè Ọmọ rẹ̀ ní ọ̀run, ó sì fi sí inú Màríà tó jẹ́ wúńdíá Júù kan kí ó bàa lè bí i gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn pípé. Irú iṣẹ́ ìyanu yìí kò ṣòro fún Ọlọ́run Olódùmarè. Gẹ́gẹ́ bí áńgẹ́lì tó ṣàlàyé ọ̀rọ̀ náà fún Màríà ti wí, “lọ́dọ̀ Ọlọ́run kò sí ìpolongo kankan tí yóò jẹ́ aláìṣeéṣe.”—Lúùkù 1:30-35, 37.

Yàtọ̀ sí pé Bíbélì sọ fún wa nípa ibi tí Jésù ti wá, ó tún sọ àwọn nǹkan míì fún wa nípa rẹ̀. Àwọn ìwé Ìhìn Rere náà, Mátíù, Máàkù, Lúùkù àti Jòhánù sọ ohun púpọ̀ fún wa nípa bí Jésù ṣe gbé ìgbé ayé rẹ̀.

^ Fún ìsọfúnni síwájú sí i nípa bí wọ́n ṣe mú Jésù tí wọ́n sì ṣẹjọ́ rẹ̀, ka àpilẹ̀kọ náà, “Ìgbẹ́jọ́ Tó Burú Jù Lọ Láyé,” lójú ìwé 18 sí 22 nínú ìwé ìròyìn yìí.

^ Ẹ̀rí fi hàn pé Éfúrátà (tàbí Éfúrátì) ni orúkọ tí wọ́n ń pe Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tẹ́lẹ̀ rí.—Jẹ́nẹ́sísì 35:19.

^ Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ.