Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ni Ọlọ́run Ní Lọ́kàn fún Ilẹ̀ Ayé?

Kí Ni Ọlọ́run Ní Lọ́kàn fún Ilẹ̀ Ayé?

Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Kí Ni Ọlọ́run Ní Lọ́kàn fún Ilẹ̀ Ayé?

Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a béèrè àwọn ìbéèrè tó o ti lè máa ṣe kàyéfì nípa wọn, a sì tún sọ ibi tó o ti lè rí ìdáhùn wọn kà nínú Bíbélì rẹ. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti bá ẹ sọ̀rọ̀ lórí ohun tí àwọn ìdáhùn náà jẹ́.

1. Kí ni Ọlọ́run ní lọ́kàn fún ilẹ̀ ayé?

Ilẹ̀ ayé jẹ́ ilé ẹ̀dá èèyàn. Lẹ́yìn tí Ọlọ́run ti dá àwọn áńgẹ́lì láti máa gbé ní ọ̀run, ó dá ẹ̀dá èèyàn láti máa gbádùn ilẹ̀ ayé. (Jóòbù 38:4, 7) Ìdí nìyẹn tí Jèhófà ṣe fi ọkùnrin àkọ́kọ́ sínú ọgbà ẹlẹ́wà kan tó ń jẹ́ Édẹ́nì, ó sì fún òun àtàwọn ọmọ rẹ̀ tó máa bí nírètí láti gbádùn ìwàláàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé.—Jẹ́nẹ́sísì 2:15-17; ka Sáàmù 115:16.

Apá kékeré ni ọgbà Édẹ́nì jẹ́ lórí ilẹ̀ ayé. Ọlọ́run fẹ́ kí Ádámù àti Éfà tí wọ́n jẹ́ tọkọtaya àkọ́kọ́ bímọ. Bí àwọn èèyàn bá sì ṣe ń pọ̀ sí i, Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n máa bójú tó ayé, kí wọ́n sì sọ ayé di Párádísè. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Ayé kò ní pa run láé.—Ka Sáàmù 104:5.

2. Kí nìdí tí ayé kò fi jẹ́ Párádísè nísinsìnyí?

Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, nítorí náà Ọlọ́run lé wọn jáde kúrò nínú ọgbà Édẹ́nì. Wọ́n pàdánù Párádísè, kò sì tíì sí ẹ̀dá èèyàn kankan tó lè sọ ayé di Párádísè pa dà. Bíbélì sọ pé: “Ilẹ̀ ayé ni a ti fi lé ọwọ́ ẹni burúkú.”—Jóòbù 9:24; ka Jẹ́nẹ́sísì 3:23, 24.

Àmọ́ ṣá o, Jèhófà kò gbàgbé ohun tó ní lọ́kàn ní ìbẹ̀rẹ̀ fún aráyé, ó sì dájú pé Ọlọ́run kò lè ṣe àṣetì. (Aísáyà 45:18) Ó máa mú kí ẹ̀dá èèyàn pa dà sí bó ṣe fẹ́ kí wọ́n wà.—Ka Sáàmù 37:11.

3. Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa dá àlàáfíà pa dà sórí ilẹ̀ ayé?

Kí aráyé tó lè máa gbádùn àlàáfíà, Ọlọ́run ní láti kọ́kọ́ mú àwọn ẹni burúkú kúrò. Nínú ogun Amágẹ́dọ́nì, àwọn áńgẹ́lì Ọlọ́run yóò pa gbogbo àwọn ọ̀tá Ọlọ́run run. Sátánì á ṣẹ̀wọ̀n fún ẹgbẹ̀rún ọdún, àmọ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run yóò yè bọ́ láti gbádùn ètò àwọn nǹkan tuntun lórí ilẹ̀ ayé.—Ka Ìṣípayá 16:14, 16; 20:1-3; 21:3, 4.

4. Ìgbà wo ni ìjìyà máa dópin?

Ní ẹgbẹ̀rún ọdún náà, Jésù máa ṣàkóso gbogbo ayé láti ọ̀run, á sì sọ ayé di Párádísè pa dà. Ó tún máa pa ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run rẹ́. Jésù á sì tipa bẹ́ẹ̀ fòpin sí àìsàn, ọjọ́ ogbó àti ikú.—Ka Aísáyà 11:9; 25:8; 33:24; 35:1.

Ìgbà wo ni Ọlọ́run máa fòpin sí ìwà ibi lórí ilẹ̀ ayé? Jésù sọ àwọn “àmì” kan tó máa fi hàn pé àkókò náà ti sún mọ́lé. Ipò tí ayé wà báyìí ń mú káwọn èèyàn máa bẹ̀rù pé àwọn máa pa run, èyí sì fi hàn pé à ń gbé ní àkókò “ìparí ètò àwọn nǹkan.”—Ka Mátíù 24:3, 7-14, 21, 22; 2 Tímótì 3:1-5.

5. Àwọn wo ló máa gbé nínú Párádísè tó ń bọ̀ náà?

Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn, kí wọ́n sì máa kọ́ wọn ní àwọn ọ̀nà tí Ọlọ́run ń gbà fi ìfẹ́ hàn. (Mátíù 28:19, 20) Kárí ayé, Jèhófà ń múra ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn sílẹ̀ kí wọ́n lè gbé nínú ètò àwọn nǹkan tuntun lórí ilẹ̀ ayé. (Sefanáyà 2:3) Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn èèyàn ń kẹ́kọ̀ọ́ bí wọ́n ṣe lè jẹ́ ọkọ àti bàbá rere àti bí wọ́n ṣe lè jẹ́ aya àti ìyá rere. Àwọn ọmọ àtàwọn òbí ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìdí tó fi yẹ kí wọ́n gbà gbọ́ pé ọjọ́ ọ̀la máa dára.—Ka Míkà 4:1-4.

Ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, wàá rí àwọn èèyàn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, tí wọ́n sì fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ bí wọ́n ṣe lè ṣe ohun tí ó wu Ọlọ́run.—Ka Hébérù 10:24, 25.

Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka orí 3 ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.