Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àsọtẹ́lẹ̀ 4. Kò Sí Ìfẹ́ Nínú Ìdílé Mọ́

Àsọtẹ́lẹ̀ 4. Kò Sí Ìfẹ́ Nínú Ìdílé Mọ́

Àsọtẹ́lẹ̀ 4. Kò Sí Ìfẹ́ Nínú Ìdílé Mọ́

‘Àwọn èèyàn kì yóò ní ìfẹ́ tó yẹ fún àwọn ìdílé wọn.’—2 TÍMÓTÌ 3:1-3, God’s Word Bible

● Obìnrin kan tó ń jẹ́ Chris jẹ́ òṣìṣẹ́ àwùjọ tó ń ṣèrànwọ́ fún àwọn tí wọ́n hùwà ipá sí nínú ilé ní North Wales. Ọ̀gbẹ́ni Chris sọ pé, “Mo rántí ọmọbìnrin kan tó wọlé wá, wọ́n ti lù ú nílùkulù débi pé, mi ò dá a mọ̀ mọ́. Ẹ̀dùn ọkàn àwọn obìnrin míì pọ̀ débi pé, wọn kò ní lè gbójú sókè wo ìwọ tó ò ń bá wọn sọ̀rọ̀.”

KÍ NI Ẹ̀RÍ FI HÀN? Ní orílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Áfíríkà, nǹkan bí obìnrin kan nínú mẹ́ta ni wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe láti kékeré. Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní orílẹ̀-èdè yìí kan náà, ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ ìdajì àwọn ọkùnrin tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ló gbà pé kò burú láti lu ìyàwó wọn. Àmọ́, kì í ṣe àwọn obìnrin nìkan ni wọ́n ń hùwà ipá sí nínú ilé. Bí àpẹẹrẹ, ní orílẹ̀-èdè Kánádà nǹkan bí ọkùnrin mẹ́ta nínú mẹ́wàá ni ìyàwó wọ́n ti lù nílùkulù tàbí hùwà ìkà sí.

ÀTAKÒ TÁWỌN ÈÈYÀN Ń ṢE Ó ti pẹ́ tí ìwà ipá ti ń ṣẹlẹ̀ nínú ilé. Àmọ́ ìyàtọ̀ tó wà níbẹ̀ lóde òní ni pé, wọ́n ń jẹ́ káwọn èèyàn gbọ́ nípa rẹ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.

ṢÉ ÀTAKÒ YÌÍ LẸ́SẸ̀ NÍLẸ̀? Wọ́n ń jẹ́ káwọn èèyàn gbọ́ gan-an nípa ìwà ipá inú ilé láti ohun tó lé lógún ọdún sí àkókò yìí. Àmọ́, ṣé bí wọ́n ṣe ń kéde ìṣòro yìí fáyé gbọ́ ti jẹ́ kí ìwà ipá inú ilé dín kù? Rárá o. Ńṣe ni àìsí ìfẹ́ nínú ìdílé túbọ̀ ń pọ̀ sí i.

KÍ NI ÈRÒ RẸ? Ṣé ohun tó wà nínú ìwé 2 Tímótì 3:1-3 ló ń ṣẹ? Ṣé òótọ́ ni pé ọ̀pọ̀ èèyàn kò ní ìfẹ́ tó yẹ fún àwọn ìdílé wọn?

Àsọtẹ́lẹ̀ karùn-ún tó ń ṣẹ lákòókò yìí kan ayé tó jẹ́ ilé wa. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 7]

“Wọ́n sọ pé, ìwà ipá inú ilé jẹ́ ìwà ọ̀daràn tí wọn kì í sọ síta láwùjọ wa lónìí. Ìwádìí fi hàn pé ó máa ń tó ìgbà márùndínlógójì [35] ni ọkọ kan máa ń hùwà ìkà sí ìyàwó rẹ̀ kí obìnrin náà tó sọ fún ọlọ́pàá.”​—AGBỌ̀RỌ̀SỌ ÀWÙJỌ TÓ Ń ṢÈRÀNWỌ́ FÚN ÀWỌN TÍ WỌ́N HÙWÀ IPÁ SÍ NÍNÚ ILÉ NÍLẸ̀ WALES.