Ohun Tó Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀
Ipa Tí Ọmọ Lè Ní Lórí Àjọṣe Ọkọ àti Aya
Charles: * “Inú èmi àti Mary dùn gan-an nígbà tá a bí ọmọbìnrin wa. Àmọ́ oṣù bíi mélòó kàn lẹ́yìn ìgbà tá a bí i ni mi ò fi lè sùn dáadáa. Ọ̀pọ̀ ètò la ti ṣe lórí ọ̀nà tá a máa gbà tọ́ ọ, àmọ́ nǹkan kò lọ bá a ṣe rò.”
Mary: “Láti ìgbà tá a ti bí ọmọ wa ni mi ò lè ṣe bó ṣe wù mí mọ́. Ohun tó gbàfiyèsí mi báyìí ni, bí mo ṣe máa rọ fídà tí ọmọ máa mu, bí mo ṣe máa pààrọ̀ ìtẹ́dìí rẹ̀ tàbí bí mo ṣe máa rẹ ọmọ lẹ́kún. Àyípadà tó bá ìgbésí ayé mi yìí lágbára jù. Oṣù bíi mélòó kan kọjá kí àjọṣe èmi àti ọkọ mi tó pa dà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀.”
Ọ̀PỌ̀ ló máa gbà pé, ọ̀kan lára ohun tó máa ń fúnni láyọ̀ jù lọ nígbèésí ayé ni téèyàn bá bímọ. Bíbélì pe àwọn ọmọ ní “èrè” látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. (Sáàmù 127:3) Àwọn tọkọtaya bíi Charles àti Mary tí wọ́n bímọ àkọ́bí tún gbà pé, ọmọ lè mú àwọn àyípadà tí èèyàn kò retí bá àjọṣe ọkọ àti aya. Bí àpẹẹrẹ, obìnrin kan tó bímọ àkọ́bí lè jẹ́ kí ọmọ náà gba àfiyèsí òun, kó sì máa yà á lẹ́nu bó ṣe máa ń wu òun láti ṣe ohun kan láti bójú tó ọmọ jòjòló náà. Ní ti ọkùnrin tí ìyàwó rẹ̀ bímọ àkọ́bí, ó lè jẹ́ ohun àgbàyanu fún un láti rí àjọṣe tímọ́tímọ́ tó wà láàárín ìyàwó rẹ̀ àti ọmọ tuntun náà, àmọ́ inú rẹ̀ tún lè má dùn sí bí ìyàwó rẹ̀ ṣe pa á tì lójijì.
Kódà, nígbà tí tọkọtaya bá bímọ àkọ́bí, ìyẹn lè ṣokùnfà oríṣiríṣi ìṣòro láàárín wọn. Nítorí ọ̀ràn ọmọ títọ́ tí wọ́n gbájú mọ́, àìbìkítà fún ẹnì kejì ẹni àtàwọn ìṣòro tí wọn kò yanjú á wá hàn kedere.
Kí ni tọkọtaya tí wọ́n bímọ àkọ́bí lè ṣe láti fara da wàhálà àwọn oṣù díẹ̀ tí ọmọ náà máa fi gba gbogbo àfiyèsí wọn lẹ́yìn tí wọ́n bí i? Kí ni tọkọtaya lè ṣe láti rí i pé ohunkóhun kò pa àjọṣe wọn lára? Kí ni wọ́n lè ṣe láti bójú tó èdèkòyédè tó bá wáyé lórí ọ̀ràn títọ́ ọmọ? Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ìṣòro yìí lọ́kọ̀ọ̀kan àti bí àwọn ìlànà Bíbélì ṣe lè ran tọkọtaya kan lọ́wọ́ láti kojú wọn.
ÌṢÒRO 1: Gbígbájúmọ́ ìtọ́jú ọmọ nìkan.
Ọmọ jòjòló máa ń gba gbogbo àkókò àti ìrònú ìyá rẹ̀. Inú ìyá yìí lè dùn bó ṣe ń ṣe gbogbo ohun tó yẹ kó ṣe láti bójú tó ọmọ rẹ̀. Àmọ́, ọkọ rẹ̀ lè máa rò pé, ìyàwó òun ti pa òun tì. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Manuel, tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Brazil, sọ pé: “Bí ìyàwó mi ṣe pa mí tì, tó sì wá gbájú mọ́ ọmọ wa nìkan ni àyípadà tó ṣòro jù lọ fún mi láti fara dà. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ àjọṣe wa ni ìyàwó mi gbájú mọ́, àmọ́ lójijì lo di pé ọ̀rọ̀ ọmọ wa nìkan ló wá gbájú mọ́.” Kí lo lè ṣe láti kojú ipò nǹkan tó dédé yí pa dà?
Ohun tó lè mú kéèyàn ṣàṣeyọrí: Jẹ́ onísùúrù.
Bíbélì sọ pé, “Ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra àti inú rere. Ìfẹ́ . . . kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan, a kì í tán an ní sùúrù.” (1 Kọ́ríńtì 13:4, 5) Nígbà tí tọkọtaya kan bá bímọ, báwo làwọn méjèèjì ṣe lè fi ìmọ̀ràn yìí sílò?
Ọkọ kan tó gbọ́n máa fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ ìyàwó òun tó bá túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ láti mọ ipá tí ọmọ bíbí máa ń ní lórí ìrònú àti ìrísí obìnrin. Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á jẹ́ kó mọ ìdí tí ìṣesí ìyàwó rẹ̀ fi máa ń yí pa dà láìrò tẹ́lẹ̀. * Lórílẹ̀-èdè Faransé, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Adam tó ní ọmọbìnrin ọmọ oṣù mọ́kànlá sọ pé: “Nígbà míì, ó máa ń ṣòro fún mi láti lóye ìṣesí ìyàwó mi tó máa ń yí pa dà, kì í sì í rọrùn fún mi láti ṣe sùúrù pẹ̀lú rẹ̀. Àmọ́, mo mọ̀ pé kò ní in lọ́kàn láti kó ìbànújẹ́ bá mi. Kàkà bẹ́ẹ̀, másùnmáwo tó bá a ló mú kó máa ṣe bẹ́ẹ̀.”
Nígbà míì, ṣé ìyàwó rẹ máa ń ṣì ọ́ lóye tó o bá fẹ́ ràn án lọ́wọ́? Tó bá jẹ bẹ́ẹ̀, má ṣe tètè bínú. (Oníwàásù 7:9) Kàkà bẹ́ẹ̀, ní sùúrù fún un, kó o sì ṣe ohun tó fẹ́, kì í ṣe ohun tí ìwọ fẹ́, ìyẹn kò sì ní jẹ́ kí inú bí ẹ.—Òwe 14:29.
Bákan náà, aya kan tó lóye yóò ran ọkọ rẹ̀ lọ́wọ́ láti bójú tó ojúṣe tí ọkọ rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà. Á kọ́ ọkọ rẹ̀ bó ṣe máa tọ́jú ọmọ, á ṣe sùúrù nígbà tó bá ń fi han ọkọ̀ rẹ̀ bó ṣe máa pààrọ̀ ìtẹ́dìí ọmọ tàbí bó ṣe máa ṣe oúnjẹ ọmọ sínú fídà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè má mọ nǹkan wọ̀nyí ṣe dáadáa níbẹ̀rẹ̀.
Ìyá kan tó ń jẹ́ Ellen, ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [26], rí i pé ó yẹ kí òun ṣe àwọn àtúnṣe kan sí ọ̀nà tóun ń gbà hùwà sí ọkọ òun. Ó sọ pé, “Mo ní láti mọ̀ pé èmi nìkan kọ́ ló ni ọmọ náà. Mo sì ní láti sọ fún ara mi pé, nígbà tí ọkọ mi bá ń ṣe ohun tí mo kọ ọ́ nípa bó ṣe máa tọ́jú ọmọ jòjòló náà, mi ò gbọ́dọ̀ máa ṣàríwísí lórí gbogbo ohun tó bá ń ṣe.”
GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Ìyàwó, bí ọkọ rẹ bá tọ́jú ọmọ yín lọ́nà tó yàtọ̀ sí bó o ṣe máa tọ́jú rẹ̀, má gbìyànjú láti bá a wí tàbí ṣe àtúnṣe iṣẹ́ náà fúnra rẹ. Gbóríyìn fún un lórí àwọn ohun tó ṣe dáadáa, tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọkàn rẹ̀ á balẹ̀, á sì jẹ́ kó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ọkọ, dín àkókò tí ò ń lò fún àwọn nǹkan tí kò ṣe pàtàkì kù, kí o bàa lè rí àkókò tó pọ̀ láti ran ìyàwó rẹ lọ́wọ́, pàápàá ní àwọn oṣù díẹ̀ lẹ́yìn tó bímọ.
ÌṢÒRO 2: Àjọṣe àárín ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ kò fí bẹ́ẹ̀ dán mọ́rán.
Ọ̀pọ̀ tọkọtaya tó bímọ àkọ́bí ni àjọṣe wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ dán mọ́rán nítorí àìlèsùn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan àti àwọn wàhálà tí wọ́n kò retí. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Vivianne láti ilẹ̀ Faransé tó ní ọmọ méjì, sọ pé: “Lákọ̀ọ́kọ́, ojúṣe mi gẹ́gẹ́ bí ìyá ni mo gbájú mọ́ mo sì fẹ́rẹ̀ẹ́ gbàgbé ojúṣe mi gẹ́gẹ́ bí aya.”
Bákan náà, ọkọ kan lè má mọ̀ pé àwọn àyípadà kan ti bá ìrònú àti ìrísí ìyàwó òun nígbà tó lóyún. Ọmọ tuntun lè gba okun àti àkókò tí ẹ ń lò tẹ́lẹ̀ fún ìbálòpọ̀ àti sísọ ẹ̀dùn ọkàn yín. Kí ni tọkọtaya kan lè ṣe tí ọmọ
wọn jòjòló tí wọ́n fẹ́ràn kò fi ní di ohun tó ba àjọṣe wọn jẹ́?Ohun tó lè mú kéèyàn ṣàṣeyọrí: Ẹ fi hàn pé ẹ ṣì nífẹ̀ẹ́ ara yín.
Nígbà tí Bíbélì ń ṣàlàyé ohun tí ìgbéyàwó jẹ́, ó ní: “Ìdí nìyẹn tí ọkùnrin yóò ṣe fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀ tí yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.” * (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Jèhófà Ọlọ́run ní in lọ́kàn pé kí àwọn ọmọ fi àwọn òbí wọn sílẹ̀ nígbà tó bá yá. Àmọ́ ṣá o, Ọlọ́run kò retí pé kí ọkọ àti aya fi ara wọn sílẹ̀, ó fẹ́ kí wọ́n jẹ́ ara kan jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn ni. (Mátíù 19:3-9) Báwo ni lílóye tí tọkọtaya kan tó bímọ àkọ́bí bá lóye kókó yìí ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ àwọn ohun tó yẹ kí wọ́n fi sí ipò àkọ́kọ́?
Obìnrin tó ń jẹ́ Vivianne tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níṣàájú sọ pé: “Mo ronú lórí ọ̀rọ̀ tó wà ní Jẹ́nẹ́sísì 2:24, ẹsẹ yẹn mú kí n mọ̀ pé ọkọ mi ni mo di ‘ara kan’ pẹ̀lú rẹ̀, kì í ṣe ọmọ mi. Mo rí i pé o yẹ kí n mú kí àjọṣe èmi àti ọkọ mi lágbára.” Ìyá kan tó ń jẹ́, Theresa, tó ní ọmọbìnrin ọmọ ọdún méjì sọ pé: “Tó bá ń ṣe mí bíi pé mo ti jìnnà sí ọkọ mi, mo tètè máa ń sapá láti rí i pé mo lo àkókò pẹ̀lú rẹ̀ lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan, bí àkókò náà tiẹ̀ kéré.”
Tó o bá jẹ́ ọkọ, kí lo lè ṣe láti mú kí àjọṣe ìwọ àti aya rẹ lágbára? Sọ fún ìyàwó rẹ pé o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Jẹ́ kó hàn nínú ìwà rẹ pé òótọ́ lo nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Sapá gidigidi láti fi ìyàwó rẹ lọ́kàn balẹ̀. Ìyá kan tó ń jẹ́ Sarah, tó jẹ́ ẹni ọgbọ̀n ọdún, sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé oyún lè ti yí ara ìyàwó kan pa dà, síbẹ̀ ìyàwó ṣì máa ń fẹ́ kí ọkọ òun fi hàn pé òun ṣì wúlò àti pé ó ṣì nífẹ̀ẹ́ òun.” Bàbá kan tó ń jẹ́ Alan tó ń gbé ní Jámánì tó ní ọmọkùnrin méjì rí i pé ó yẹ kí òun jẹ́ ẹni tó ṣe é fọ̀rọ̀ lọ̀. Ó sọ pé: “Mo máa ń tu ìyàwó mi nínú nígbà tí inú rẹ̀ bá bà jẹ́.”
Òótọ́ ni pé bí tọkọtaya kan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ, ìyẹn máa ń dí ìbálòpọ̀ lọ́wọ́. Nítorí náà, ó yẹ kí tọkọtaya jíròrò ohun tí kálukú wọ́n fẹ́. Bíbélì sọ pé ìyípadà tí tọkọtaya kan bá ṣe lórí ọ̀ràn ìbálòpọ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ “àjọgbà.” (1 Kọ́ríńtì 7:1-5) Ìyẹn gba pé kí àwọn méjèèjì jọ sọ̀rọ̀. O lè má rọrùn fún ẹ láti bá ọkọ tàbí aya rẹ sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀, èyí lè jẹ́ nítorí bí wọ́n ṣe tọ́ ẹ dàgbà tàbí àṣà ìbílẹ̀ yín. Àmọ́ irú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì bí tọkọtaya ti ń mọ iṣẹ́ wọn síwájú sí i gẹ́gẹ́ bí òbí. Jẹ́ agbatẹnirò, onísùúrù àti olóòótọ́. (1 Kọ́ríńtì 10:24) Ìwọ àti ẹnì kejì rẹ yóò tipa bẹ́ẹ̀ yẹra fún èdèkòyédè, ẹ ó sì mú kí ìfẹ́ tẹ́ ẹ ní sí ara yín jinlẹ̀ sí i.—1 Pétérù 3:7, 8.
Tọkọtaya kan tún lè mú ìfẹ́ tí wọ́n ní sí ara wọn jinlẹ̀ sí i nípa fífi hàn pé àwọn mọrírì ẹnì kejì àwọn. Ọkọ tó lóye mọ̀ pé ọ̀pọ̀ iṣẹ́ tí obìnrin tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ ń ṣe ni èèyàn kò lè rí. Vivianne sọ pé: “Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ kan bá fi máa ṣú, ńṣe ló máa ń ṣe mí bíi pé mi ò ṣe nǹkan kan látàárọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ńṣe ni ọwọ́ mi dí tí mò ń tọ́jú ọmọ mi!” Bí ọwọ́ obìnrin Òwe 17:17.
kan bá tiẹ̀ dí, ó yẹ kí olóye obìnrin ṣọ́ra kó má ṣe fojú kéré ohun tí ọkọ rẹ̀ ń ṣe láti mú kí ìdílé wọn tẹ̀ síwájú.—GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Ìyá, tó bá ṣeé ṣe sùn díẹ̀ nígbà tí ọmọ rẹ̀ bá ń sùn lọ́wọ́. Wàá tipa báyìí “sọ agbára rẹ dọ̀tun,” wàá sì ní okun sí i láti bójú tó àjọṣe àárín ìwọ àti ọkọ rẹ. Bàbá, tó bá ṣeé ṣe dìde ní òru kó o fún ọmọ lóúnjẹ tàbí kó o pààrọ̀ ìtẹ́dìí rẹ̀ kí ìyàwó rẹ lè sinmi. Máa kọ ọ̀rọ̀ tó fi hàn pé o ṣì nífẹ̀ẹ́ aya rẹ sínú ìwé, kí o sì fi sílẹ̀ fún un, máa tẹ ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí i lórí fóònù tàbí kó o máa bá a sọ̀rọ̀ lórí fóònù. Kí ẹ sì máa wá àyè láti bá ara yín sọ̀rọ̀. Ẹ sọ̀rọ̀ nípa ẹnì kọ̀ọ̀kan yín, kì í ṣe nípa ọmọ yín nìkan. Mú kí ìdè ọ̀rẹ́ tó wà láàárín ìwọ àti ẹnì kejì rẹ lágbára, tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ó lè bójú tó àwọn ìṣòro tó wà nínú títọ́ ọmọ.
ÌṢÒRO 3: Èdèkòyédè nípa títọ́ ọmọ.
Bí wọ́n ṣe tọ́ ọkọ tàbí aya kan dàgbà lè mú kí ó máa bá ẹnì kejì rẹ̀ ṣe àríyànjiyàn. Ìyá kan tó ń jẹ́ Asami àti ọkọ rẹ̀ tó ń jẹ́ Katsuro, tí wọ́n jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Japan ní irú ìṣòrò yìí. Asami sọ pé: “Lójú tèmi, ọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ ni ọkọ mi fi ń mú ọmọbìnrin wa, àmọ́ ọkọ mi ní tiẹ̀ rò pé mo ti lé koko mọ́ ọmọ wa jù.” Kí lẹ lè ṣe tí ẹ kò fi ní máa ta ko ara yín?
Ohun tó lè mú kéèyàn ṣàṣeyọrí: Máa bá ẹnì kejì rẹ sọ̀rọ̀, kí ẹ sì máa ran ara yín lọ́wọ́.
Sólómọ́nì ọlọ́gbọ́n Ọba sọ pé: “Nípasẹ̀ ìkùgbù, kìkì ìjàkadì ni ẹnì kan ń dá sílẹ̀, ṣùgbọ́n ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn tí ń fikùn lukùn.” (Òwe 13:10) Báwo lóhun tó o mọ̀ nípa ọ̀nà tí ẹnì kejì rẹ fẹ́ gbà tọ́ ọmọ ṣe pọ̀ tó? Tó o bá dúró títí dìgbà tí ẹ bímọ kẹ́ ẹ tó jíròrò ọ̀nà tẹ́ ẹ máa gbà tọ́ ọmọ yín, ẹ óò rí i pé àríyànjiyàn ni ẹ óò máa ṣe dípò kí ẹ yanjú ìṣòro náà.
Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìdáhùn wo ni ẹ ti fohùn ṣọ̀kan lé lórí nípa àwọn ìbéèrè yìí: “Kí la máa fi kọ́ ọmọ wa nípa bó ṣe yẹ kéèyàn máa jẹun àti nípa oorun sísùn? Ṣé gbogbo ìgbà la ó máa gbé ọmọ wa tó bá ń ké nígbà tó bá fẹ́ sùn? Kí ló yẹ ká ṣe bí ọmọ wa kò bá tètè ṣe ohun tá a kọ́ ọ pé kó ṣe tó bá fẹ́ yàgbẹ́?” Ó dájú pé, ohun tí ẹ máa fohùn ṣọ̀kan lé lórí máa yàtọ̀ sí ti àwọn tọkọtaya yòókù. Bàbá kan tó ń jẹ́ Ethan tó ní ọmọ méjì sọ pé: “Ó yẹ kí ẹ jọ sọ̀rọ̀ náà parí síbì kan, kí ohùn yín lè ṣọ̀kan. Èyí á jẹ́ kí ẹ lè jọ bójú tó ohun tí ọmọ yín nílò.”
GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Ronú nípa àwọn ọ̀nà tí àwọn òbí rẹ gbà tọ́ ẹ. Pinnu èyí tó o fẹ́ tẹ̀ lé nínú àwọn ọ̀nà náà nígbà tó o bá ń tọ ọmọ rẹ. Bákan náà, pinnu àwọn ọ̀nà tí o kò fẹ́ tẹ̀ lé nínú àwọn ọ̀nà náà, tí wọ́n bá wà. Bá ọkọ tàbí aya rẹ jíròrò èrò rẹ lórí ọ̀ràn náà.
Ọmọ Lè Nípa Rere Lórí Àjọṣe Ọkọ àti Aya
Bó ṣe máa gba àkókò àti sùúrù kó tó di pé ọ̀rẹ́ tuntun méjì mọwọ́ ara wọn, kí wọ́n sì máa ṣe nǹkan pa pọ̀, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe máa gba àkókò kí tọkọtaya kan tó bímọ àkọ́bí tó lè mọ iṣẹ́ ọmọ títọ́ ṣe dáadáa. Àmọ́ tó bá yá, ẹ ó mọ iṣẹ́ náà ṣe.
Ọmọ títọ́ yóò fi hàn bí ìfẹ́ tó o ní sí ọkọ tàbí aya rẹ ṣe jinlẹ̀ tó, á sì mú àwọn àyípadà kan tó máa wà títí lọ bá àjọṣe ìwọ àti ẹnì kejì rẹ. Àmọ́ ṣá o, yóò tún fún ọ láǹfààní láti ní àwọn ànímọ́ tó ṣeyebíye. Tó o bá lo àwọn ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tó wà nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ rẹ yóò dà bíi ti bàbá kan tó ń jẹ́ Kenneth. Ó sọ pé: “Títọ́ ọmọ ti ní ipa rere lórí èmi àti ìyàwó mi. A kò mọ ti ara wa nìkan mọ́, á sì ti ní ìfẹ́ àti òye tó pọ̀ sí i.” Irú àwọn àyípadà yìí dára láàárín ọkọ àti aya.
^ A ti yí àwọn orúkọ tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí pa dà.
^ Ìdààmú ọkàn máa ń bá ọ̀pọ̀ àwọn ìyá láwọn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bímọ. Àìsàn kan tó lágbára tí wọ́n ń pè ní àbísínwín máa ń bá àwọn kan fínra. Fún ìsọfúnni síwájú sí i nípa béèyàn ṣe lè mọ̀ bí àìlera yìí bá ń ṣe ẹnì kan àti béèyàn ṣe lè fara dà á, ka àwọn àpilẹ̀kọ yìí lédè Gẹ̀ẹ́sì, ìyẹn Awake! ti July 22, 2002, tí àkòrí rẹ̀ sọ pé, “I Won My Battle With Postpartum Depression,” àti Awake! ti June 8, 2003, tí àkòrí rẹ̀ sọ pé, “Understanding Postpartum Depression.” Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é. O lè rí àwọn àpilẹ̀kọ́ yìí kà lórí ìkànnì wa www.watchtower.org.
^ Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìwádìí kan ti wí, ọ̀rọ̀ ìṣe èdè Hébérù tí wọ́n túmọ̀ sí “fà mọ́” ní Jẹ́nẹ́sísì 2:24 ní ìtumọ̀ ‘fífi ìfẹ́ àti ìdúróṣinṣin dìrọ̀ mọ́ ẹnì kan.’
BI ARA RẸ PÉ . . .
-
Ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá, kí ni mo ṣe láti fi han ẹnì kejì mi pé mo mọyì ohun tó ń ṣe fún ìdílé wa?
-
Ǹjẹ́ mo máa ń wá àyè láti bá ẹnì kejì mi sọ̀rọ̀ tí kò jẹ mọ́ ọ̀ràn títọ́ ọmọ, ìgbà wo ni mo sì ṣe bẹ́ẹ̀ kẹ́yìn?