Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ìwàláàyè Títí Láé Nínú Párádísè Máa Súni?

Ǹjẹ́ Ìwàláàyè Títí Láé Nínú Párádísè Máa Súni?

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . .

Ǹjẹ́ Ìwàláàyè Títí Láé Nínú Párádísè Máa Súni?

▪ Bíbélì jẹ́ ká ní ìrètí pé a lè gbé títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. (Sáàmù 37:29; Lúùkù 23:43) Ǹjẹ́ gbígbé títí láé ní àyíká tó dára jù lọ lè súni?

Ìbéèrè yìí ṣe pàtàkì. Àwọn olùṣèwádìí ti rí i pé tí nǹkan bá súni lọ́nà tó pọ̀ jù, ó lè mú kéèyàn máa ṣàníyàn, kí èèyàn ní ìbànújẹ́ ọkàn, ó sì lè mú kéèyàn máa ṣe ohun tó lè gba ẹ̀mí ẹni. Nǹkan máa ń sú àwọn èèyàn tí kò rí ìdí tí èèyàn fi wà láàyè tàbí àwọn tí kò gbádùn ohun tí wọ́n ń ṣe lójoojúmọ́. Ṣé àwọn èèyàn tó máa wà nínú Párádísè máa rí ohun gidi tí wọ́n máa fi ìgbésí ayé wọn ṣe? Ṣé ohun tí wọ́n á máa ṣe lójoojúmọ́ máa sú wọn?

Lákọ̀ọ́kọ́, ẹ má gbàgbé pé Jèhófà Ọlọ́run tó ni Bíbélì ló ṣèlérí ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòhánù 3:16; 2 Tímótì 3:16) Ìfẹ́ sì ni ànímọ́ Ọlọ́run tó ṣe kókó jù lọ. (1 Jòhánù 4:8) Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ó sì fún wa ní gbogbo ohun tí à ń gbádùn báyìí.—Jákọ́bù 1:17.

Ẹlẹ́dàá wa mọ̀ pé, a nílò iṣẹ́ tó nítumọ̀ kí á bàa lè láyọ̀. (Sáàmù 139:14-16; Oníwàásù 3:12) Nínú Párádísè, àwọn èèyàn kò ní dà bí ẹ̀rọ tí kò mọ̀ ju pé kó ṣiṣẹ́. Iṣẹ́ tí wọ́n á máa ṣe yóò ṣe àwọn fúnra wọn àtàwọn èèyàn wọn láǹfààní. (Aísáyà 65:22-24) Tó o bá ní iṣẹ́ kan tó gbádùn mọ́ni, tó sì gba àkókò àti ìsapá, ṣé ìgbésí ayé á sú ẹ?

Bákan náà, ẹ má gbàgbé pé ó lójú àwọn èèyàn tí Jèhófà Ọlọ́run máa gbà láyè láti máa gbé Párádísè. Àwọn èèyàn tó tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù Ọmọ rẹ̀ nìkan ló ṣèlérí ìyè àìnípẹ̀kun fún. (Jòhánù 17:3) Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ìdùnnú rẹ̀ ni láti máa ṣe ìfẹ́ Baba rẹ̀. Ó fi ọ̀rọ̀ àti àpẹẹrẹ rẹ̀ kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé ayọ̀ pípẹ́ títí máa ń wá látinú fífúnni ju látinú rírígbà lọ. (Ìṣe 20:35) Nínú Párádísè tó ń bọ̀, àṣẹ méjì tó ṣe pàtàkì jù lọ ni á máa darí ìgbé ayé gbogbo èèyàn, ìyẹn ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti ìfẹ́ fún ọmọnìkejì ẹni. (Mátíù 22:36-40) Wo bó ṣe máa rí lára rẹ tó o bá wà láàárín àwọn tí kò mọ tara wọn, tí wọ́n fẹ́ràn rẹ, tí wọ́n sì tún fẹ́ràn iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe! Ṣé o rò pé nǹkan máa sú ẹ tó o bá wà láàárín irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀?

Àwọn nǹkan wo ni èèyàn tún máa gbádùn nínú Párádísè? Ojoojúmọ́ ni a ó máa láǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ ohun tuntun nípa Ẹlẹ́dàá wa. Òótọ́ ni pé, àwọn olùṣèwádìí ti ṣe ọ̀pọ̀ àwárí tó gbàfiyèsí nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà dá. (Róòmù 1:20) Àmọ́, ìwọ̀nba táṣẹ́rẹ́ ni gbogbo ohun tí èèyàn mọ̀ nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà dá. Ní ẹgbẹ̀rún ọdún mélòó kan sẹ́yìn, Jóòbù ọkùnrin olóòótọ́ náà ronú lórí ohun tó mọ̀ nípa àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá, ohun tó sọ ṣì jẹ́ òótọ́. Jóòbù sọ pé: “Ìwọ̀nyí jẹ́ bèbè àwọn ọ̀nà [Ọlọ́run], àhegbọ́ mà ni ohun tí a sì gbọ́ nípa rẹ̀! Ṣùgbọ́n nípa ààrá agbára ńlá rẹ̀, ta ní lè lóye rẹ̀?”—Jóòbù 26:14.

Kò sí bá a ṣe pẹ́ láyé tó, a kò lè mọ ohun gbogbo nípa Jèhófà Ọlọ́run àtàwọn nǹkan tó dá. Bíbélì sọ pé Ọlọ́run ti fi ìfẹ́ láti wà láàyè títí láé sínú ọkàn wa. Àmọ́, ó tún sọ pé a ò lè “rídìí iṣẹ́ tí Ọlọ́run tòótọ́ ti ṣe láé láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin.” (Oníwàásù 3:10, 11) Ǹjẹ́ o rò pé ó máa sú ẹ tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ ohun tuntun nípa Ẹlẹ́dàá rẹ?

Ní báyìí pàápàá, ekukáká ni nǹkan fi ń sú àwọn tí ọwọ́ wọ́n dí lẹ́nu iṣẹ́ tó ń ṣe àwọn èèyàn láǹfààní tó sì ń fi ìyìn fún Ọlọ́run. Ó dájú pé, tí a bá jẹ́ kí ọwọ́ wá dí lẹ́nu irú iṣẹ́ yìí, nǹkan kò ní sú wa, àní títí láé.

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 27]

Ayé: Image Science and Analysis Laboratory, NASA-Johnson Space Center; Ìṣùpọ̀ ìràwọ̀: The Hubble Heritage Team (AURA/STScI/NASA)