Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Báwo làwọn orúkọ tí wọ́n fi òǹtẹ̀ lù sárá amọ̀ láyé ìgbàanì ṣe bá àwọn orúkọ tó wà nínú Bíbélì mu?
▪ Nígbà àtijọ́, àwọn tó ń bójú tó àwọn àkọ́sílẹ̀ ìjọba máa ń ká àwọn àkọ́sílẹ̀ náà pa pọ̀, wọ́n á fi okùn dì í, wọ́n á wá fi ègé amọ̀ tútù sórí ibi tí wọ́n ti dì í, wọ́n á sì fi òǹtẹ̀ lu amọ̀ náà. Wọ́n máa ń fi òǹtẹ̀ náà lu ara amọ̀ láti sàmì sára àwọn àkọsílẹ̀, láti ṣe ẹ̀rí àti láti fi hàn pé àwọn àkọsílẹ̀ náà jẹ́ ojúlówó.
Nígbà míì, wọ́n máa ń fi òǹtẹ̀ lu àwọn òrùka àmì, wọ́n sì kà wọ́n sí ohun iyebíye. (Jẹ́nẹ́sísì 38:18; Ẹ́sítérì 8:8; Jeremáyà 32:44) Orúkọ oníǹkan, orúkọ oyè rẹ̀ àti orúkọ bàbá rẹ̀ ló sábà máa ń wà lára òǹtẹ̀ náà.
Àwọn tó ń ṣèwádìí ti rí ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn òǹtẹ̀ tí wọ́n ń pè ní bulla. Àwọn kan nínu wọn ní orúkọ àwọn èèyàn inú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, àwọn awalẹ̀pìtàn ti rí àwọn òǹtẹ̀ tí wọ́n lù sára nǹkan, èyí tí wọ́n gbà pé wọ́n jẹ́ òǹtẹ̀ àwọn ọba Júdà méjì. Ọ̀kan lára ọ̀rọ̀ òǹtẹ̀ náà kà pé: “Ó jẹ́ ti Áhásì [ọmọkùnrin] Yéhótámù [Jótámù] Ọba Júdà.” Ọ̀rọ̀ inú òǹtẹ̀ míì kà pé: “Ó jẹ́ ti Hesekáyà [ọmọkùnrin] Áhásì, Ọba Júdà.” (2 Àwọn Ọba 16:1, 20) Áhásì àti Hesekáyà jọba ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹjọ ṣáájú Sànmánì Kristẹni.
Àwọn ọ̀mọ̀wé ti ṣàyẹ̀wò àwọn bulla míì tí wọ́n fi òǹtẹ̀ lù, wọ́n sì gbà pé àwọn èèyàn inú Bíbélì ló ni àwọn òǹtẹ̀ náà. A mẹ́nu kan àwọn kan lára wọn nínú ìwé tí Jeremáyà kọ, irú bíi Bárúkù (akọ̀wé Jeremáyà), Gemaráyà (“ọmọkùnrin Ṣáfánì”), Jéráméélì (“ọmọkùnrin ọba”), Júkálì (“ọmọkùnrin Ṣelemáyà”), àti Seráyà (arákùnrin Bárúkù).—Jeremáyà 32:12; 36:4, 10, 26; 38:1; 51:59.
Báwo ni wọ́n ṣe ń ka wákàtí ọjọ́ nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì?
▪ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù lo àwọn ọ̀rọ̀ bí “òwúrọ̀,” “ọ̀sán gangan,” “ọjọ́kanrí,” àti “ìrọ̀lẹ́.” (Jẹ́nẹ́sísì 24:11; Diutarónómì 28:29; 1 Àwọn Ọba 18:26) Ìṣọ́ mẹ́ta ni àwọn Hébérù pín òru sí, ìṣọ́ kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ nǹkan bíi wákàtí mẹ́rin, àmọ́ nígbà tó yá wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìṣọ́ mẹ́rin, ìyẹn ọ̀nà tí àwọn ará Gíríìsì àtàwọn ará Róòmù pín òru sí. Ó dájú pé ìṣọ́ mẹ́rin tí wọ́n pín òru sí yẹn ni Jésù ń sọ nígbà tó sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí ẹ kò mọ ìgbà tí ọ̀gá ilé náà ń bọ̀, yálà nígbà tí alẹ́ ti lẹ́ tàbí ní ọ̀gànjọ́ òru tàbí ìgbà kíkọ àkùkọ tàbí ní kùtùkùtù òwúrọ̀.” (Máàkù 13:35) Ìṣọ́ kìíní, ìyẹn “nígbà tí alẹ́ ti lẹ́” bẹ̀rẹ̀ láti ìrọ̀lẹ́ sí aago mẹ́sàn-án alẹ́. Ìṣọ́ kejì parí ní aago méjìlá òru, ìṣọ́ kẹta, ìyẹn “ìgbà kíkọ àkùkọ,” parí ní nǹkan bí aago mẹ́ta òru. Ìṣọ́ kẹrin, ìyẹn “ní kùtùkùtù òwúrọ̀” parí nígbà tí ilẹ̀ bá mọ́. “Ìṣọ́ kẹrin òru” ni Jésù rìn lórí omi Òkun Gálílì.—Mátíù 14:23-26.
Nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì, ọ̀rọ̀ náà “wákàtí” jẹ́ ìdá kan nínú ìdá méjìlá ojúmọ́ ọjọ́ kan, ìyẹn láti ìgbà tí ilẹ̀ bá mọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ nígbà tí oòrùn bá wọ̀. (Jòhánù 11:9) Ní Ísírẹ́lì, ojú ọjọ́ ló máa ń pinnu ìgbà tí oòrùn máa ń yọ àti ìgbà tó máa n wọ̀, nítorí náà, ńṣe ni wọ́n máa ń fojú bu àkókò tí nǹkan ṣẹlẹ̀, irú bíi “nǹkan bí wákàtí kẹfà.”—Ìṣe 10:9.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Amọ̀ tó ní òǹtẹ̀ orúkọ Hesekáyà àti ti Áhásì (níwájú) àti èyí tó lè jẹ́ ti Bárúkù (lẹ́yìn)
[Àwọn Credit Line]
Ẹ̀yìn: Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Israel Museum, Jerusalem
Iwájú: www.BibleLandPictures.com/Alamy
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ohun tí wọ́n ń fi ka wákàtí ọjọ́ nígbà tí oòrùn bá yọ, ìgbà ìjọba Róòmù (ọdún 27 ṣáájú sànmánì kristẹni sí ọdún 476 Sànmánì Kristẹni)
[Credit Line]
© Gerard Degeorge/The Bridgeman Art Library International