Ìhìn Rere fún Àwọn Òtòṣì
Ìhìn Rere fún Àwọn Òtòṣì
Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN fi dá wa lójú pé: “A kì yóò fi ìgbà gbogbo gbàgbé àwọn òtòṣì.” (Sáàmù 9:18) Bíbélì tún sọ nípa Ẹlẹ́dàá wa pé: “Ìwọ ṣí ọwọ́ rẹ, ìwọ sì ń tẹ́ ìfẹ́-ọkàn gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.” (Sáàmù 145:16) Ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ yìí kì í ṣe àlá tí kò lè ṣẹ. Ọlọ́run Olódùmarè lè ṣe ohun tó máa fòpin sí ipò òṣì. Kí ni àwọn òtòṣì ń fẹ́?
Ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà kan tó jẹ́ onímọ̀ nípa ọrọ̀ ajé sọ pé, ohun tó dára jù tí àwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ òtòṣì ń fẹ́ ni “aláṣẹ tó jẹ́ olóore.” Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé ẹnì kan tó lágbára tó sì jẹ́ aláàánú ló lè fòpin sí ipò òṣì. A tún lè fi kún un pé alákòóso kan tó lè fòpin sí ipò òṣì ayé gbọ́dọ̀ jẹ́ alákòóso gbogbo ayé, ìdí ni pé, ní báyìí àwọn orílẹ̀-èdè kan lọ́rọ̀ àwọn kan sì jẹ́ òtòṣì paraku. Yàtọ̀ síyẹn, alákòóso tó máa fòpin sí ipò òṣì gbọ́dọ̀ lágbára láti ṣe nǹkan kan sí ohun tó fa ipò òṣì, ìyẹn ìmọtara ẹni nìkan tó jẹ́ ìwà ẹ̀dá. Ibo la ti lè rí alákòóso tó lè ṣe nǹkan yìí?
Ọlọ́run rán Jésù láti kéde ìhìn rere fún àwọn òtòṣì. Nígbà tí Jésù dìde láti ka Ìwé Mímọ́ tó sọ nípa iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an, ó sọ pé: “Ẹ̀mí Jèhófà ń bẹ lára mi, nítorí tí ó fòróró yàn mí láti polongo ìhìn rere fún àwọn òtòṣì.”—Lúùkù 4:16-18.
Kí Ni Ìhìn Rere?
Ọlọ́run ti yan Jésù láti jẹ́ Ọba. Ìròyìn rere lèyí jẹ́. Jésù ni alákòóso tó dára jù lọ tó máa fòpin sí ipò òṣì nítorí pé (1) òun ló máa ṣàkóso gbogbo aráyé, ó sì ní agbára láti ṣe é, (2) ó fi ìyọ́nú hàn sí àwọn òtòṣì, ó sì kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti máa tọ́jú àwọn òtòṣì àti (3) pé ó lè mú ohun tó ń fa ipò òṣì kúrò, ìyẹn ìmọtara-ẹni-nìkan tí èèyàn jogún. Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ohun mẹ́ta tó jẹ́ ara ìhìn rere yìí.
1. Jésù ní àṣẹ lórí gbogbo orílẹ̀-èdè Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ nípa Jésù pé: “A sì fún un ní agbára ìṣàkóso . . . pé kí gbogbo àwọn ènìyàn, àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè àti àwọn èdè máa sin àní òun.” (Dáníẹ́lì 7:14) Wo bí àǹfààní náà ti máa pọ̀ tó tí ìjọba kan ṣoṣo bá ń ṣàkóso aráyé! Kò ní sí gbọ́nmi-si omi-ò-tó àti ìjà lórí àwọn ohun àmúṣọrọ̀ ilẹ̀ ayé mọ́. Gbogbo èèyàn ló máa jàǹfààní ọgbọọgba. Jésù fúnra rẹ̀ fi dá wa lójú pé òun máa di Alákòóso lórí ayé, òun sì lágbára láti ṣàkóso. Ó sọ pé: “Gbogbo ọlá àṣẹ ni a ti fi fún mi ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé.”—Mátíù 28:18.
2. Jésù fi ìyọ́nú hàn sí àwọn òtòṣì Jálẹ̀ gbogbo iṣẹ́ ìwàásù Jésù lórí ilẹ̀ ayé, ó fi ìyọ́nú hàn sí àwọn òtòṣì. Bí àpẹẹrẹ, obìnrin kan tó ti fi gbogbo ohun ìní rẹ̀ tọ́jú àìsàn tó ń ṣe é fọwọ́ kan aṣọ Jésù, ó retí pé òun á rí ìwòsàn. Obìnrin yìí ti jìyà lọ́wọ́ àìsàn ìsun ẹ̀jẹ̀ fún ọdún méjìlá, ó sì dájú pé àìsàn yìí ti ṣàkóbá fún ìlera rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Òfin ti sọ, ẹnikẹ́ni tí obìnrin yìí bá fọwọ́ kàn yóò di aláìmọ́. Àmọ́ Jésù fi àánú hàn sí i. Jésù sọ pé: “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá. Máa lọ ní àlàáfíà, kí o sì ní ìlera kúrò lọ́wọ́ àìsàn burúkú tí ń ṣe ọ́.”—Máàkù 5:25-34.
Ẹ̀kọ́ Jésù lágbára láti yí ọkàn àwọn èèyàn pa dà kí àwọn náà lè máa fi ìyọ́nú hàn sí àwọn èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, ṣàgbéyẹ̀wò ìdáhùn tí Jésù fún ọkùnrin kan tó fẹ́ mọ bí òun ṣe lè ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Ọkùnrin yìí mọ̀ pé Ọlọ́run ń fẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wa, àmọ́, ó béèrè lọ́wọ́ Jésù pé: “Ní ti gidi ta ni aládùúgbò mi?”
Jésù fi àkàwé kan dá a lóhùn, àkàwé náà sì gbajúmọ̀ gan-an, ó jẹ́ nípa ọkùnrin kan tó ń rìnrìn-àjò láti Jerúsálẹ́mù lọ sí Jẹ́ríkò, tí àwọn ọlọ́ṣà dá lọ́nà, tí wọ́n fi í sílẹ̀ “láìkú tán.” Àlùfáà kan tó ń gba ojú ọ̀nà náà sọ̀kalẹ̀ lọ́ rí i, àmọ́ ó gba ẹ̀gbẹ́ òdìkejì kọjá lọ. Ọmọ Léfì kan Lúùkù 10:25-37.
tóun náà gba ibẹ̀ rí i, àmọ́ òun náà fi í sílẹ̀. “Ṣùgbọ́n ará Samáríà kan tí ó ń rin ìrìn àjò gba ojú ọ̀nà náà ṣàdédé bá a pàdé, bí ó sì ti rí i, àánú ṣe é.” O wẹ ojú ọgbẹ́ ọkùnrin náà, ó gbé e lọ sí ilé èrò, ó sì sanwó fún olùtọ́jú ilé èrò náà pé kó bá òun tọ́jú rẹ̀. Jésù béèrè pé: “Ta ni . . . ó ṣe ara rẹ̀ ní aládùúgbò fún ọkùnrin tí ó bọ́ sí àárín àwọn ọlọ́ṣà?” Ọkùnrin náà dáhùn pé: “Ẹni tí ó hùwà sí i tàánú-tàánú.” Nígbà náà ni Jésù sọ pé: “Kí ìwọ alára sì máa ṣe bákan náà.”—Àwọn tó ń di Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́ irú àwọn ẹ̀kọ́ tí Jésù fi kọ́ni yìí, wọ́n sì yí èrò wọn pa dà kí wọ́n lè máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, nínu ìwé náà, Women in Soviet Prisons, tí òǹkọ̀wé kan lórílẹ̀-èdè Latvia kọ, ó sọ nípa àìsàn tó ṣe òun nígbà tí òun wà nínú àgọ́ Potma lọ́dún 1965 sí 1967, níbi tí wọ́n ti ń fìyà jẹ àwọn ọ̀daràn. Ó sọ pé: “Ní gbogbo àkókò tí àìsàn náà fi ṣe mí [àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà] jẹ́ àwọn nọ́ọ̀sì tó ń ṣiṣẹ́ kára. Wọ́n tọ́jú mi ju bí mo ṣe rò lọ.” Ó fi kún un pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kà á sí ojúṣe wọn láti ran gbogbo èèyàn lọ́wọ́, láìwo ẹ̀sìn tàbí orílẹ̀-èdè tí ẹni náà ti wá.”
Nígbà tí ipò ọrọ̀ ajé sọ àwọn kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìlú Ancón, lórílẹ̀-èdè Ecuador, di aláìníṣẹ́ tí owó kò sì wọlé fún wọn mọ́, àwọn Ẹlẹ́rìí yòókù nínú ìjọ wọn pinnu pé àwọn máa kówó jọ fún wọn. Wọ́n se oúnjẹ, wọ́n sì ń tà á fún àwọn apẹja tí wọ́n ń pa dà bọ̀ láti ibi tí wọ́n ti lọ pẹja lóru (àwòrán lápá ọ̀tún). Gbogbo ará ìjọ náà fọwọ́sowọ́pọ̀, títí kan àwọn ọmọdé. Wọ́n máa ń bẹ̀rẹ̀ oúnjẹ sísè ní aago kan òru kí oúnjẹ lè ti wà nílẹ̀ nígbà tí ọkọ̀ àwọn apẹja bá fi máa dé ní aago mẹ́rin ìdájí. Àwọn Ẹlẹ́rìí náà pín owó tí wọ́n kó jọ náà fún àwọn tó wà nípò àìní gẹ́gẹ́ bí iye tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn nílò.
Irú àwọn ìrírí yìí fi hàn pé àpẹẹrẹ àti ẹ̀kọ́ Jésù ní agbára láti yí ìwà àwọn èèyàn pa dà kí wọ́n lè máa ran àwọn èèyàn tí wọ́n jẹ́ aláìní lọ́wọ́.
3. Agbára tí Jésù ní láti yí ìwà ẹ̀dá pa dà Gbogbo èèyàn ló mọ̀ pé ìwà ẹ̀dá ni kéèyàn jẹ́ onímọtara ẹni nìkan. Bíbélì pè é ní ẹ̀ṣẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pàápàá sọ pé: “Mo wá rí òfin yìí nínú ọ̀ràn tèmi: pé nígbà tí mo bá fẹ́ láti ṣe ohun tí ó tọ́, ohun tí ó burú a máa wà pẹ̀lú mi.” Ó fi kún un pé: “Ta ni yóò gbà mí lọ́wọ́ ara tí ń kú ikú yìí? Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi Olúwa.” (Róòmù 7:21-25) Ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ níbí yìí ni bí Ọlọ́run yóò ṣe tipasẹ̀ Jésù gba àwọn olùjọ́sìn tòótọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí a jogún, èyí tí ìmọtara ẹni nìkan tó ń fa ipò òṣì jẹ́ ọ̀kan lára rẹ̀. Báwo ló ṣe máa ṣe é?
Lẹ́yìn tí Jésù ṣe ìrìbọmi, Jòhánù Oníbatisí sọ nípa Jésù, ó ní: “Wò ó, Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run, tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ!” (Jòhánù 1:29) Láìpẹ́, àwọn èèyàn tó ti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún ló máa kún inú ayé, wọ́n á tún bọ́ lọ́wọ́ ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan. (Aísáyà 11:9) Nígbà yẹn, Jésù á ti mú ohun tó fa ipò òṣì kúrò.
Ẹ wo bó ti ń múnú ẹni dùn tó láti máa fojú inú wo ìgbà tí gbogbo èèyàn yóò ní ohun tí wọ́n fẹ́! Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Wọn yóò sì jókòó ní ti tòótọ́, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì.” (Míkà 4:4) Àwọn ọ̀rọ̀ yìí ṣàpèjúwe ìgbà tí gbogbo èèyàn máa ní iṣẹ́ tó tẹ́ni lọ́rùn àti ààbò tó dájú, tí wọ́n á sì láǹfààní láti gbádùn ayé kan tí kò tí ní sí ipò òṣì, èyí yóò sì mú ìyìn bá Jèhófà.