Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ọlọ́run Ní Ètò Kan Tó Gbé Kalẹ̀?

Ǹjẹ́ Ọlọ́run Ní Ètò Kan Tó Gbé Kalẹ̀?

Ǹjẹ́ Ọlọ́run Ní Ètò Kan Tó Gbé Kalẹ̀?

GBOGBO ohun tí Ọlọ́run dá ló wà létòlétò, yálà àwọn ohun tí a lè fojú rí tàbí èyí tí a kò lè fojú rí. Bíbélì fi hàn pé àwọn áńgẹ́lì pàápàá wà létòlétò lọ́run, wọ́n ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Nínú ìran kan, wòlíì Dáníẹ́lì rí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn áńgẹ́lì nínú àgbàlá Ọlọ́run lọ́run, ó sọ pé: “Ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún ń ṣe ìránṣẹ́ fún un, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lọ́nà ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá sì ń dúró níwájú rẹ̀ gangan.” (Dáníẹ́lì 7:9, 10) Ẹ wo ètò tí ó ti ní láti wà, kó tó lè ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn áńgẹ́lì, tí iye wọn ju mílíọ̀nù lọ́nà ọgọ́rùn-ún lọ, láti máa ṣe ohun tí Ọlọ́run pa láṣẹ pé kí wọ́n ṣe fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé!—Sáàmù 91:11.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá jẹ́ Ẹni tó ṣètò àwọn nǹkan lọ́nà tí kò lẹ́gbẹ́, kò to òfin jọ rẹpẹtẹ láti ni wá lára. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ Ọlọ́run aláyọ̀ tó nífẹ̀ẹ́, tó sì ń bójú tó gbogbo ohun tí ó dá. (1 Tímótì 1:11; 1 Pétérù 5:7) A rí ẹ̀rí èyí nínú ọ̀nà tó gbà bójú tó orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ àtàwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní.

Bí Ọlọ́run Ṣe Ṣètò Ìjọsìn Orílẹ̀-Èdè Ísírẹ́lì Àtijọ́

Jèhófà Ọlọ́run lo Mósè láti ṣètò bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì á ṣe máa ṣe ìjọsìn tòótọ́. Ṣàgbéyẹ̀wò bí wọ́n ṣe ṣètò ibùdó wọn nígbà tí wọ́n wà ní aginjù Sínáì. Ó dájú pé nǹkan kò ní wà létòlétò ká ní wọ́n ní kí ìdílé kọ̀ọ̀kan pàgọ́ wọn síbi tí wọ́n fẹ́. Jèhófà fún orílẹ̀-èdè náà ní ìsọfúnni pàtó nípa ibi tí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan máa pabùdó wọn sí. (Númérì 2:1-34) Òfin Mósè tún ní àwọn ìlànà tó ṣe pàtó nípa ìlera àti ìmọ́tótó, bí àpẹẹrẹ, ó sọ bí wọ́n ṣe máa palẹ̀ ìgbọ̀nsẹ̀ mọ́.—Diutarónómì 23:12, 13.

Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì dé Ilẹ̀ Ìlérí, ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni wọ́n gbà wà létòlétò. Wọ́n pín orílẹ̀-èdè náà sí ẹ̀yà méjìlá, ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan sì ní ilẹ̀ tó jẹ́ ìpín tirẹ̀. Òfin tí Jèhófà fún orílẹ̀-èdè náà nípasẹ̀ Mósè kárí gbogbo apá ìgbésí ayé àwọn èèyàn náà, ó kan ọ̀ràn ìjọsìn, ìgbéyàwó, ìdílé, ẹ̀kọ́ ìwé, okòwò, oúnjẹ, iṣẹ́ àgbẹ̀, bí wọ́n ṣe ń sin ẹran àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. * Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òfin kan ṣe pàtó tí wọ́n sì ní kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé, gbogbo wọn ń fi hàn pé Jèhófà bìkítà fún àwọn èèyàn rẹ̀, wọ́n sì ń fi kún ayọ̀ wọn. Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tẹ̀ lé gbogbo ètò onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà ṣe yìí, wọ́n rí ojú rere rẹ̀ lọ́nà àkànṣe.—Sáàmù 147:19, 20.

Òótọ́ ni pé Mósè mọ béèyàn ṣe ń ṣe aṣáájú, àmọ́ ìyẹn kọ́ ló máa pinnu bóyá yóò ṣe àṣeyọrí tàbí kò ní ṣe àṣeyọrí, ṣùgbọ́n ṣíṣe àṣeyọrí rẹ̀ wà lọ́wọ́ bó bá ṣe ń tẹ̀ lé ètò tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, báwo ni Mósè ṣe mọ ọ̀nà tí wọ́n máa gbà nínú aginjù? Jèhófà ló fọ̀nà hàn wọ́n, ó lo ọwọ̀n àwọ̀ sánmà ní ọ̀sán, ó sì lo ọwọ̀n iná ní òru láti fi darí wọn. (Ẹ́kísódù 13:21, 22) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà lo àwọn èèyàn, òun fúnra rẹ̀ ló mú kí àwọn èèyàn rẹ̀ wà létòlétò, tó sì ń darí wọn. Ohun kan náà ló ṣe ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní.

Bí Ọlọ́run Ṣe Ṣètò Ìjọsìn Àwọn Kristẹni Àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀

Iṣẹ́ ìwàásù táwọn àpọ́sítélì àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn fi ìtara ṣe ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní mú kí wọ́n dá àwọn ìjọ Kristẹni sílẹ̀ níbi tó pọ̀ ní ilẹ̀ Éṣíà àti ilẹ̀ Yúróòpù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìjọ wọ̀nyí wà káàkiri, gbogbo wọn ló wà ní ìṣọ̀kan, wọ́n kò dáwà. Gbogbo wọn ló wà létòlétò, tí wọ́n sì ń jàǹfààní bí àwọn àpọ́sítélì ṣe ń fìfẹ́ bójú tó wọn. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù yan Títù láti lọ sí Kírétè “kó lè mú kí gbogbo nǹkan wà létòlétò níbẹ̀.” (Títù 1:5, The Jerusalem Bible) Pọ́ọ̀lù sì kọ̀wé sí ìjọ Kọ́ríńtì pé àwọn arákùnrin kan ní “ẹ̀bùn láti darí ètò iṣẹ́ ìjọ,” tàbí àwọn arákùnrin kan “mọ bí wọ́n ṣe ń ṣètò nǹkan.” (1 Kọ́ríńtì 12:28, Ìròyìn Ayọ̀; The Bible in Contemporary Language) Àmọ́, ta lẹni tó ń mú káwọn nǹkan wà létòlétò? Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ̀ pé, “Ọlọ́run [ló] pa ara pọ̀ ṣọ̀kan,” tàbí “ṣètò” ìjọ.—1 Kọ́ríńtì 12:24; Ìròyìn Ayọ̀.

Àwọn tó jẹ́ alábòójútó nínu ìjọ Kristẹni kì í jẹ ọ̀gá lórí àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, “ alábàáṣiṣẹ́pọ̀” ni wọ́n jẹ́, tí wọ́n ń tẹ̀ lé ohun tí ẹ̀mí Ọlọ́run darí wọ́n pé kí wọ́n ṣe, wọ́n sì ní láti jẹ́ “àpẹẹrẹ fún agbo.” (2 Kọ́ríńtì 1:24; 1 Pétérù 5:2, 3) Jésù Kristi tó ti jíǹde ni “orí ìjọ,” kì í ṣe èèyàn kan tàbí àwùjọ èèyàn aláìpé.—Éfésù 5:23.

Nígbà tí ìjọ tó wà ní Kọ́ríńtì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe nǹkan lọ́nà tó yàtọ̀ sí ti àwọn ìjọ yòókù, Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kínla? Ṣé láti ọ̀dọ̀ yín ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti jáde wá ni, tàbí ọ̀dọ̀ yín nìkan ni ó dé?” (1 Kọ́ríńtì 14:36) Pọ́ọ̀lù lo ìbéèrè mọ̀ọ́nú yìí láti tọ́ ìrònú wọn sọ́nà àti láti jẹ́ kí wọ́n lóye pé wọn kò gbọ́dọ̀ máa ṣe nǹkan tó yàtọ̀ sí táwọn yòókù. Àwọn ìjọ náà gbèrú, wọ́n sì ń ṣe dáadáa nígbà tí wọ́n tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà tí wọ́n gbà látọ̀dọ̀ àwọn àpọ́sítélì.—Ìṣe 16:4, 5.

Ọlọ́run Fi Ìfẹ́ Rẹ̀ Hàn

Òde òní ń kọ́? Àwọn kan lè máà fẹ́ dara pọ̀ mọ́ ètò ẹ̀sìn kan. Àmọ́ Bíbélì fi ẹ̀rí hàn pé ìgbà gbogbo ni Ọlọ́run máa ń lo ètò tó gbé kalẹ̀ láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. Ó ṣètò bí àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ á ṣe jọ́sìn rẹ̀ àti bí àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ á ṣe jọ́sìn rẹ̀.

Nítorí náà, ṣé kò bọ́gbọ́n mu láti rò pé Jèhófà Ọlọ́run ṣì ń darí àwọn èèyàn rẹ̀ bó ṣe ṣe nígbà àtijọ́? Ó dájú pé bí Ọlọ́run ṣe ṣètò àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ tó sì mú kí wọ́n wà níṣọ̀kan fi hàn pé, ó ń fìfẹ́ bójú tó wọn. Lónìí, Jèhófà ń lo ètò tó gbé kalẹ̀ láti mú ohun tó ní lọ́kàn fún aráyé ṣẹ. Báwo lèèyàn ṣe lè dá ètò Ọlọ́run mọ̀? Jẹ́ ká wo àwọn ohun téèyàn lè fi dá a mọ̀.

Bí a ṣe ṣètò àwọn Kristẹni tòótọ́ láti ṣe iṣẹ́ kan. (Mátíù 24:14; 1 Tímótì 2:3, 4) Jésù pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti wàásù ìhìn rere Ìjọba náà fún gbogbo orílẹ̀-èdè, àmọ́ èyí kò lè ṣeé ṣe tí kò bá sí ètò kan tó kárí ayé tó ń darí bí wọ́n ṣe máa ṣe iṣẹ́ náà. Àkàwé kan rèé: Ìwọ nìkan lè se oúnjẹ fún ẹnì kan ṣoṣo, àmọ́ tó o bá fẹ́ se oúnjẹ ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn, tàbí ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn ń kọ́? Wàá kó àwọn èèyàn kan jọ, wàá sì ṣètò bí wọ́n ṣe máa ṣiṣẹ́ náà. Bákan náà, àwọn Kristẹni tòótọ́ ń ṣiṣẹ́ ní “ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́,” tàbí ní “ìfọwọ́sowọ́pọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn [Ọlọ́run]” láti lè ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wọn lọ́wọ́ ní àṣeyanjú. (Sefanáyà 3:9; Byington) Ǹjẹ́ iṣẹ́ kan tí àwọn èèyàn onírúuru ẹ̀yà àti èdè máa ṣe ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè lè kẹ́sẹ járí tí kò bá sí ètò kan tó mú kí wọ́n wà níṣọ̀kan? Kò lè kẹ́sẹ járí.

Bí a ṣe ṣètò àwọn Kristẹni tòótọ́ láti ran ara wọn lọ́wọ́ àti láti fún ara wọn ní ìṣírí. Ẹnì kan tó ń dá gun òkè lè gun òkè èyíkéyìí tó bá fẹ́, láìsí pé ó ń dúró de àwọn kan. Àmọ́ tí jàǹbá bá ṣẹlẹ̀ sí i tàbí tí ó kó sínú ìṣòro, inú ewu ńlá ló máa wà, nítorí kò ní sí ẹni tó máa ràn án lọ́wọ́. Nítorí náà, kò bọ́gbọ́n mu kéèyàn ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ láti máa dá ṣe nǹkan. (Òwe 18:1) Kí àwọn Kristẹni tó lè ṣe iṣẹ́ tí Jésù gbé lé wọn lọ́wọ́, wọ́n ní láti ran ara wọn lọ́wọ́ kí wọ́n sì ti ara wọn lẹ́yìn. (Mátíù 28:19, 20) Ìjọ Kristẹni ń pèsè ìtọ́ni, ìdálẹ́kọ̀ọ́ àti ìṣírí látinú Bíbélì ká lè máa jọ́sìn Ọlọ́run nìṣó. Ibo lèèyàn ti lè gba ìtọ́ni nípa ọ̀nà Jèhófà tí kò bá sí àwọn ìpàdé Kristẹni tá a ṣètò níbi tí a ti ń gba ìtọ́ni, tí a sì ti ń jọ́sìn?—Hébérù 10:24, 25.

Bí a ṣe ṣètò àwọn Kristẹni tòótọ́ láti sin Ọlọ́run ní ìṣọ̀kan. Bí àwọn àgùntàn Jésù ṣe ‘ń fetí sí ohùn rẹ̀,’ wọ́n di ‘agbo kan,’ ó sì ń darí wọn. (Jòhánù 10:16) Wọn kò wà káàkiri nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì àti àwọn àwùjọ tó ń ṣe ohun tó wù wọ́n, ohun tí wọ́n sì gbà gbọ́ kò pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, gbogbo wọn ń “sọ̀rọ̀ ní ìfohùnṣọ̀kan.” (1 Kọ́ríńtì 1:10) Láti máa gbé ní ìṣọ̀kan a ní láti wà létòlétò, kí èyí tó lè ṣeé ṣe, ètò kan ní láti wà tí á máa darí àwọn nǹkan. Ẹgbẹ́ ará tó wà níṣọ̀kan ló lè rí ìbùkún Ọlọ́run gbà.—Sáàmù 133:1, 3.

Ìfẹ́ tòótọ́ fún Ọlọ́run àti òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló mú kí ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn wá sínú ètò kan tó ń ṣe ohun tá a ti sọ yìí àtàwọn ohun míì tí Bíbélì sọ. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé wà létòlétò àti ní ìṣọ̀kan, wọ́n sì ń sapá láti máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Ìlérí Ọlọ́run dá wọn lójú, ó ní: “Èmi yóò máa gbé láàárín wọn, èmi yóò sì máa rìn láàárín wọn, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn, wọn yóò sì jẹ́ ènìyàn mi.” (2 Kọ́ríńtì 6:16) Ìbùkún àgbàyanu yìí lè jẹ́ tìrẹ tó o bá ń jọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run nínú ètò rẹ̀.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Wo ìwé náà, Insight on the Scriptures, Apá Kejì, ojú ìwé 214 sí 220. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣètò ibùdó wọn dáadáa

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14, 15]

Ètò ní láti wà ká tó lè ṣe iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé

Ìwàásù ilé-dé-ilé

Ìrànwọ́ nígbà àjálù

Àwọn àpéjọ

Kíkọ́ ibi ìjọsìn