Ó Rántí Pé “Ekuru Ni Wá”
Sún Mọ́ Ọlọ́run
Ó Rántí Pé “Ekuru Ni Wá”
“MI Ò gbà pé Jèhófà lè dárí jì mí, èrò mi ni pé títí ayé mi ni màá fi máa gbé ẹrù tó wúwo yìí kiri.” Ohun tí obìnrin kan tó jẹ́ Kristẹni sọ nípa àṣìṣe tó ti ṣe sẹ́yìn nìyẹn. Lóòótọ́, ẹ̀rí ọkàn tó ń dáni lẹ́bi dà bí ẹrù tó wúwo téèyàn ń gbé kiri. Àmọ́, Bíbélì fúnni ní ìtùnú tó lè mú kí ẹ̀dùn ọkàn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pì wà dà dín kù. Ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀rọ̀ Dáfídì tó wà ní Sáàmù 103:8-14.
Dáfídì mọ̀ pé “Jèhófà jẹ́ aláàánú” kì í sì í “wá àléébù” lára wa “ṣáá nígbà gbogbo.” (Ẹsẹ 8-10) Nígbà tí Ọlọ́run bá rí ìdí tó fi yẹ kóun fi àánú hàn, ó máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́pọ̀ jaburata. Dáfídì tó jẹ́ akéwì tó dáńtọ́ lo àfiwé mẹ́ta láti fi ṣàpèjúwe bí àánú Ọlọ́run sí wa ti pọ̀ tó.
“Bí ọ̀run ti ga ju ilẹ̀ ayé, bẹ́ẹ̀ ni inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ ga lọ́lá sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.” (Ẹsẹ 11) Nígbà tá a bá wo ojú ọ̀run lálẹ́, òye wa kò lè gbé bí ojú ọ̀run tó kún fún ìràwọ̀ ṣe jìnnà tó sí ilẹ̀ ayé. Dáfídì ń tipa báyìí fi yé wa bí àánú Jèhófà ṣe pọ̀ tó, èyí jẹ́ ká rí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí Ọlọ́run ní sí wa. Ọ̀mọ̀wé kan sọ pé, àánú yìí wà fún “àwọn tí ó bẹ̀rù” Ọlọ́run, ìyẹn àwọn tó ní “ìrẹ̀lẹ̀ àti ọ̀wọ̀ àtọkànwá fún àṣẹ rẹ̀.”
“Bí yíyọ oòrùn ti jìnnà réré sí wíwọ̀ oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú àwọn ìrélànàkọjá wa jìnnà réré sí wa.” (Ẹsẹ 12) Àwọn Bíbélì míì túmọ̀ apá yìí sí, “bí ìlà oòrùn ṣe jìnnà sí ìwọ oòrùn.” Báwo nìyẹn ṣe jìnnà tó? Ibi tó o bá lè fojú inú wò ó pé ó dé ní. Ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé: “Fò lọ dé ibi tí ojú inú bá lè gbé ọ dé, tí o bá gba inú òfúrufú lọ sí apá ìlà oòrùn, ńṣe ni wàá túbọ̀ máa jìnnà sí ìwọ̀ oòrùn.” Ohun tí Dáfídì ń sọ fún wa níbí yìí ni pé, nígbà tí Ọlọ́run bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, ó máa mú wọn jìnnà rere kúrò lọ́dọ̀ wa.
“Bí baba ti ń fi àánú hàn sí àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ń fi àánú hàn sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.” (Ẹsẹ 13) Dáfídì tóun fúnra rẹ̀ jẹ́ bàbá mọ bí ọ̀ràn ṣe máa ń rí lára bàbá onífẹ̀ẹ́. Irú bàbá bẹ́ẹ̀ máa ń fi ìfẹ́ hàn sí àwọn ọmọ rẹ̀, pàápàá nígbà tí wọ́n bá wà nínú ìrora. Dáfídì mú un dá wa lójú pé Bàbá wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ máa ń fi àánú hàn sí àwọn ọmọ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé, pàápàá nígbà tí wọ́n bá ti ronú pìwà dà, tí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá sì ń mú kí ọkàn wọn ní “ìròbìnújẹ́ tí ó sì wó palẹ̀.”—Sáàmù 51:17.
Bá a ti gbé àfiwé mẹ́tà yìí yẹ̀ wò, Dáfídì jẹ́ ká mọ ohun tó mú kí Jèhófà máa fi àánú hàn sí àwa èèyàn aláìpé, ó ní: “Òun fúnra rẹ̀ mọ ẹ̀dá wa, ó rántí pé ekuru ni wá.” (Ẹsẹ 14) Jèhófà mọ̀ pé ẹ̀dá tóun fi erùpẹ̀ dá ni wá, a ní àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ, ó sì ní ibi tí agbára wa mọ. Jèhófà gba ipò ẹ̀ṣẹ̀ tí a wà rò, ó “ṣe tán láti dárí jini,” ìyẹn tá a bá fi hàn pé a ti ronú pìwà dà látọkànwá.—Sáàmù 86:5.
Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ nípa àánú Jèhófà wọ̀ ẹ́ lọ́kàn? Obìnrin tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Bíbélì sọ nípa bí Ọlọ́run ṣe múra tán láti dárí jini, ohun tó kọ́ wọ̀ ọ́ lọ́kàn, ó sì sọ pé: “Mo ti wá mọ̀ pé mo lè sún mọ́ Jèhófà, ńṣe ló dà bíi pé ẹrù tó wúwo kan ti kúrò lórí mi.” * O ò ṣe kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa àánú Ọlọ́run àti bí o ṣe lè rí i gbà? Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ló máa dà bíi pé ẹrù tó wúwo kan ti kúrò lórí ìwọ náà.
Bíbélì kíkà tá a dábàá fún August:
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ Ka orí 26, nínú ìwé Sún Mọ́ Jèhófà, àkòrí rẹ̀ sọ pé “Ọlọ́run Tó ‘Ṣe Tán Láti Dárí Jini.’” Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ìwé yìí.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 13]
“Mo ti wá mọ̀ pé mo lè sún mọ́ Jèhófà, ńṣe ló dà bíi pé ẹrù tó wúwo kan ti kúrò lórí mi”