Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ẹnì Kan Ló Wà Nídìí Gbogbo Ìwà Ibi Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Yìí?

Ṣé Ẹnì Kan Ló Wà Nídìí Gbogbo Ìwà Ibi Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Yìí?

Ṣé Ẹnì Kan Ló Wà Nídìí Gbogbo Ìwà Ibi Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Yìí?

“ÈMI àti Èṣù bọ ara wa lọ́wọ́.” Olórí àwọn ọmọ ogun àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tí wọ́n lọ sí orílẹ̀-èdè Rùwáńdà ló sọ ọ̀rọ̀ yìí, nígbà tó ń sọ nípa bí wọn kò ṣe lè dáwọ́ ìpakúpa tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1994 ní ilẹ̀ náà dúró. Nígbà tí ẹlòmíì ń sọ nípa ìpakúpa tó burú jáì tó ṣẹlẹ̀ lákòókò náà, ó sọ pé: “Bí ẹnì kan bá sọ pé Sátánì kò sí, kó ká lọ sí orílẹ̀-èdè Rùwáńdà nídìí kòtò gìrìwò kan tí wọ́n sin àìmọye òkú sí.” Ṣé iṣẹ́ Èṣù làwọn ìwà ibi yìí lóòótọ́?

Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò gbà pé ańgẹ́lì búburú kan tí èèyàn kò lè rí ló wà nídìí ìwà ìkà tó burú jáì tó ń ṣẹlẹ̀ yìí. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé, ìmọtara-ẹni-nìkan tí èèyàn ní ló fa ìwà ibi tó ń ṣẹlẹ̀. Àwọn kan sọ pé, àwùjọ àwọn ọlọ́rọ̀ àtàwọn alágbára kan tó wà káàkiri ayé, ló ń dọ́gbọ́n darí àwọn èèyàn lábẹ́lẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún kí wọ́n bàa lè máa ṣàkóso ayé. Àmọ́, àwọn kan sọ pé, àwọn ìjọba orílẹ̀-èdè àtàwọn aláṣẹ ló jẹ̀bi àìṣẹ̀tọ́ àti ìjìyà tó ń ṣẹlẹ̀ yìí.

Kí ni èrò rẹ? Kí ló fà á tí ìwà ibi, ìwà òǹrorò, ìwà ìkà tó burú jáì àti ìjìyà fi wà káàkiri ayé lónìí láìka gbogbo bí wọ́n ṣe gbìyànjú láti ṣẹ́pá rẹ̀ sí? Kí nìdí táwọn èèyàn fi ń hùwà tó lè ṣekú pa wọ́n, tí wọ́n sì kọ etí dídi sí ìkìlọ̀ tó ń wá léraléra? Ṣé ẹnì kan ló wà nídìí gbogbo ìwà ibi yìí? Ta ló ń ṣàkóso ayé yìí? Ìdáhùn ìbéèrè yìí lè yà ẹ́ lẹ́nu.