Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wọ́n Fi Ẹ̀sùn Èké Kàn Án!

Wọ́n Fi Ẹ̀sùn Èké Kàn Án!

Abala Àwọn Ọ̀dọ́

Wọ́n Fi Ẹ̀sùn Èké Kàn Án!

JÓSẸ́FÙ—APÁ KEJÌ

Ohun tó o máa ṣe: Ibi tí kò sí ariwo ni kó o ti ṣe ìdánrawò yìí. Bó o bá ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí, máa fojú inú wò ó bíi pé o wà níbi tọ́rọ̀ náà ti ń ṣẹlẹ̀, jẹ́ kó dà bíi pé ò ń gbọ́ bí àwọn èèyàn náà ṣe ń sọ̀rọ̀. Ronú nípa bí ohun tó ò ń kà yẹn ṣe máa rí lára àwọn èèyàn wọ̀nyẹn. Kó o sì máa fojú inú wò ó bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.

Àwọn tá a sọ̀rọ̀ nípa wọn: Jósẹ́fù, Pọ́tífárì àti ìyàwó rẹ̀

Àkópọ̀: Wọ́n fi Jósẹ́fù sínú ẹ̀wọ̀n láìṣẹ̀ láìrò, àmọ́ Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ̀.

1 KA ÌTÀN NÁÀ DÁADÁA.—KA JẸ́NẸ́SÍSÌ 39:7, 10-23.

Kí lo kíyè sí nínú ohùn ìyàwó Pọ́tífárì bó ṣe ń fi ẹ̀sùn èké kan Jósẹ́fù?

․․․․․

Fojú inú wo ọgbà ẹ̀wọ̀n náà kí o sì ṣàlàyé bó ṣe rí.

․․․․․

Àwọn nǹkan wo ni wọ́n ṣe fún Jósẹ́fù nígbà tí ó kọ́kọ́ dé ẹ̀wọ̀n? (Ojútùú: Ka Sáàmù 105:17, 18.)

․․․․․

2 ṢÈWÁDÌÍ KÓ O SÌ RONÚ JINLẸ̀.

Ká ní ìgbàgbọ́ Jósẹ́fù kò lágbára ni, èrò tí kò dára wo ni Jósẹ́fù ì bá ní nígbà tó wà lẹ́wọ̀n? (Ojútùú: Ka Jóòbù 30:20, 21.)

․․․․․

Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Jósẹ́fù kò sọ pé Jèhófà ló ń fi ìyà jẹ òun? (Ojútùú: Ka Jẹ́nẹ́sísì 40:8; 41:15, 16.)

․․․․․

Àwọn ohun wo lo rò pé ó ran Jósẹ́fù lọ́wọ́ láti fara dà á nígbà tí wọ́n fi í sẹ́wọ̀n láìṣẹ̀ láìrò? (Ojútùú: Ka Míkà 7:7; Lúùkù 14:11; Jákọ́bù 1:4 kí o sì ronú lé wọn lórí.)

․․․․․

Kí ni Jósẹ́fù kọ́ nígbà tó wà lẹ́wọ̀n, báwo sì ni ohun tó kọ́ náà ṣe ṣe é láǹfààní nígbà tó yá? (Ojútùú: Ka Jẹ́nẹ́sísì 39:21-23; 41:38-43.)

․․․․․

3 MÁA FOHUN TÓ O KỌ́ ṢÈWÀ HÙ. ṢÀKỌSÍLẸ̀ Ẹ̀KỌ́ TÓ O KỌ́ NÍPA . . . 

Àǹfààní tí àwọn tó ní ìfaradà máa ń jẹ.

․․․․․

Ohun tó o lè rí kọ́ nígbà tó o bá wà nínú ìṣòro.

․․․․․

Ìrànlọ́wọ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà nígbà àdánwò.

․․․․․

ÀWỌN OHUN MÍÌ TÓ O LÈ FI ṢÈWÀ HÙ.

Ǹjẹ́ ó ti ṣẹlẹ̀ sí ọ rí pé o wà nínú ìṣòro tí kò sì sí ẹni tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́? Nígbà tó o wà nínú àdánwò náà, báwo ni Jèhófà ṣe ràn ẹ́ lọ́wọ́? (Ojútùú: Ka 1 Kọ́ríńtì 10:13 kí o sì ronú lórí rẹ̀.)

․․․․․

4 KÍ LÓ WÚ Ẹ LÓRÍ JÙ LỌ NÍNÚ ÌTÀN YÌÍ, KÍ SÌ NÌDÍ?

․․․․․

Kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa bíbélì, lórí ìkànnì wa www.watchtower.org àti www.pr418.com