Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àkókò Tí Kò Yẹ Ká Sùn

Àkókò Tí Kò Yẹ Ká Sùn

Kọ́ Ọmọ Rẹ

Àkókò Tí Kò Yẹ Ká Sùn

Ó DÁJÚ pé o mọ̀ pé kò yẹ kéèyàn máa sùn nígbà tí èèyàn bá wà ní ilé ẹ̀kọ́. Àwọn kan máa ń sùn ní kíláàsì lákòókò tí olùkọ́ ń kọ́ wọn lọ́wọ́, àmọ́ kò yẹ kéèyàn sùn téèyàn bá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́. Ó ṣeé ṣe kí o tún máa lọ sí ìpàdé níbi tó o ti lè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Kí lo rò pé o lè ṣe tí o kò fi ní máa sùn nígbà tí o bá ń kẹ́kọ̀ọ́? * Ohun kan ni pé, kí o tètè máa sùn lálẹ́. Ó tún dára tó o bà lè wáyè sun oorun ráńpẹ́ ní ọ̀sán. Jẹ́ ká wo ohun tá a lè rí kọ́ látinú nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀dọ́ tó sùn lálẹ́ ọjọ́ kan lákòókò tí kò yẹ kó sùn, nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ àsọyé. Ka ohun tó wà nínú ìwé Ìṣe inú Bíbélì orí 20, ẹsẹ 7 sí 12, kó o lè rí ohun tó ṣẹlẹ̀.

Ó ti tó ọjọ́ mélòó kan tí Pọ́ọ̀lù ti wà lọ́dọ̀ àwọn ará ìjọ tó wà ní ìlú Tíróásì, etí òkun ni ìlú yìí wà. Bíbélì sọ pé, Pọ́ọ̀lù máa wọ ọkọ̀ ojú omi kúrò níbẹ̀ “ní ọjọ́ kejì.” Nítorí náà, ó “fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ gùn títí di ọ̀gànjọ́ òru.” Bíbélì sọ pé: “Ọ̀dọ́kùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Yútíkọ́sì, tí ó jókòó sójú fèrèsé, ni oorun àsùnwọra gbé lọ bí Pọ́ọ̀lù ti ń bá ọ̀rọ̀ nìṣó.” Kí ló wá ṣẹlẹ̀?

Yútíkọ́sì já bọ́ “láti àjà kẹta” ojú fèrèsé ilé náà. Pọ́ọ̀lù àtàwọn míì yára sáré lórí àtẹ̀gùn ilé náà wá sílẹ̀. Àmọ́ Yútíkọ́sì ti kú! Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo bí inú wọn ṣe bà jẹ́ tó?— Bíbélì sọ pé Pọ́ọ̀lù gbé Yútíkọ́sì sí ọwọ́ rẹ̀, ó sì gbá a mọ́ra. Lẹ́yìn náà Pọ́ọ̀lù fi ayọ̀ ké jáde pé: ‘Ẹ má ṣe ìyọnu, ara rẹ̀ ti pa dà bọ̀ sípò!’ Ọlọ́run ti jí Yútíkọ́sì dìde!

Kí la lè rí kọ́ nípa Ọlọ́run látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Yútíkọ́sì yìí?— Ohun kan ni pé, Bàbá wa ọ̀run Jèhófà lè jí òkú dìde títí kan àwọn ọmọdé. Jèhófà mọ gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ, ó sì nífẹ̀ẹ́ rẹ, àní ju àwọn òbí rẹ lọ. Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó kọ́ wa nípa irú ẹni tí Bàbá rẹ̀ jẹ́ nípasẹ̀ ìwà tó hù sí àwọn ọmọdé, ìyẹn bó ṣe gbé wọn sí ọwọ́ tó sì gbàdúrà fún wọn. Ó tún jí àwọn ọmọdé dìde títí kan ọmọbìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìlá.

Báwo ni mímọ̀ tó o mọ̀ pé Bàbá rẹ ọ̀run nífẹ̀ẹ́ rẹ ṣe rí lára rẹ?— Bẹ́ẹ̀ ni, ó ń mú kí àwa náà túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì ń mú ká fẹ́ láti ṣe ìgbọ́ràn sí ohun tó sọ. Ǹjẹ́ o mọ bí a ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀?— Ọ̀nà kan ni pé kí á sọ ọ́ jáde pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Jésù sọ pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ Baba.” Àmọ́ ṣá o, yàtọ̀ sí pé Jésù sọ pé òun nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ó tún fi hàn nínú ìwà rẹ̀ pé lóòótọ́ ni òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.

Jésù ṣègbọràn sí Ọlọ́run. Jésù sọ pé: “Nígbà gbogbo ni mo ń ṣe ohun tí ó wù ú.” Tí àwa náà bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa wu Jèhófà àti Jésù Ọmọ rẹ̀, a óò máa sapá láti rí i pé a kò sùn lákòókò tí kò yẹ ká sùn.

Kà á nínú Bíbélì rẹ

Ìṣe 20:7-12

Lúùkù 8:49-56

Jòhánù 8:29; 14:31

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Tó bá jẹ́ ọmọdé lò ń ka ìwé yìí fún, má gbàgbé láti dánu dúró níbi tó o bá ti rí àmì dáàṣì (—), kó o sì jẹ́ kí ọmọ náà sọ èrò rẹ̀.