Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìgbà Wo Ni Wọ́n Pa Jerúsálẹ́mù Àtijọ́ Run?—Apá Kìíní

Ìgbà Wo Ni Wọ́n Pa Jerúsálẹ́mù Àtijọ́ Run?—Apá Kìíní

Ìgbà Wo Ni Wọ́n Pa Jerúsálẹ́mù Àtijọ́ Run?​—Apá Kìíní

Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Mọ̀ Nípa Rẹ̀; Àwọn Ẹ̀rí Tá A Rí

Àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ àkọ́kọ́ lára méjì irú rẹ̀ tó máa jáde tẹ̀ léra nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́, wọ́n máa dáhùn àwọn ìbéèrè nípa ọdún tí wọ́n pa Jerúsálẹ́mù àtijọ́ run. Àpilẹ̀kọ méjì yìí máa sọ àwọn ìdáhùn tí a ti ṣèwádìí wọ́n dáadáa tá a sì gbé karí Bíbélì, wọ́n á sì dáhùn àwọn ìbéèrè tó ti rú àwọn kan tó ń ka ìwé wa lójú.

“Gẹ́gẹ́ bí àwọn òpìtàn àti awalẹ̀pìtàn ṣe sọ, ọdún 586 tàbí 587 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run. * Kí nìdí tí ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi sọ pé ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni (Ṣ.S.K) ni? Kí lẹ rí tẹ́ ẹ fi sọ pé ọdún yìí ni?”

Ọ̀KAN lára àwọn tó máa ń ka ìwé wa ló béèrè ìbéèrè yìí. Àmọ́, kí nìdí tó fi yẹ ká mọ ọdún náà gan-an tí Nebukadinésárì Kejì Ọba Bábílónì pa ìlú Jerúsálẹ́mù run? Ìdí àkọ́kọ́ ni pé, ìṣẹ̀lẹ̀ náà jẹ́ ìyípadà pàtàkì kan nínú ìtàn àwọn èèyàn Ọlọ́run. Ọkùnrin òpìtàn kan sọ pé, ìṣẹ̀lẹ̀ yìí yọrí sí “àjálù kan, àjálù ńlá gbáà ni.” Ọdún náà ni wọ́n pa tẹ́ńpìlì kan run, èyí tó ti jẹ́ ojúkò ìjọsìn Ọlọ́run Olódùmarè fún ohun tó lé ní irínwó [400] ọdún. Onísáàmù kan nínú Bíbélì kédàárò pé: “Ọlọ́run . . . Wọ́n ti sọ tẹ́ńpìlì mímọ́ rẹ di ẹlẹ́gbin; wọ́n ti sọ Jerúsálẹ́mù di òkìtì àwókù.”—Sáàmù 79:1. *

Ìdí kejì ni pé, tó o bá mọ ọdún náà gan-an tí “àjálù ńlá” náà wáyé tó o sì mọ bí ìjọsìn tòótọ́ tí wọ́n mú pa dà bọ̀ sípò ní Jerúsálẹ́mù ṣe mú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kan ṣẹ, yóò mú kí ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run túbọ̀ lágbára sí i. Nítorí náà, kí nìdí tí ọdún tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé fi fi ogún ọdún yàtọ̀ sí ọdún tí ọ̀pọ̀ èèyàn sọ pé ó wáyé? Ní kúkúrú, ó jẹ́ nítorí ẹ̀rí tó wà nínú Bíbélì.

“Àádọ́rin Ọdún” Ti Ta Ni?

Ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú ìparun náà, wòlíì Júù náà, Jeremáyà, ti sọ ohun tí wọ́n máa fi dá àkókò tí Bíbélì sọ náà mọ̀. Ó kìlọ̀ fún “àwọn olugbe Jerusalemu” pé: “Gbogbo ilẹ yi yio si di iparun àti ahoro, orilẹ-ède wọnyi yio si sin ọba [Bábílónì] li adọrin ọdun.” (Jeremáyà 25:1, 2, 11, Bíbélì Mimọ) Nígbà tó yá, wòlíì náà fi kún un pé: “Nitori bayi li Oluwa wi pe, Lẹhin ti adọrin ọdun ba pari ni [Bábílónì], li emi o bẹ̀ yin wò, emi o si mu ọ̀rọ rere mi ṣẹ si nyin, ni mimu nyin pada si ibi yi.” (Jeremáyà 29:10) Báwo ni “adọrin ọdun” náà ti ṣe pàtàkì tó? Báwo sì ni sáà àkókò yẹn ṣe jẹ́ ká mọ ọdún tí wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run?

Kàkà kí ọ̀pọ̀ Bíbélì sọ pé àádọ́rin ọdún “ní Bábílónì,” ńṣe ni wọ́n sọ pé “fún Bábílónì.” (NIV) Nítorí náà, àwọn òpìtàn kan sọ pé Ilẹ̀ Ọba Bábílónì ni àádọ́rin ọdún náà wà fún. Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ìtàn ayé ṣe sọ, àwọn ará Bábílónì jọba lé ilẹ̀ Júdà àti Jerúsálẹ́mù àtijọ́ lórí fún nǹkan bí àádọ́rin ọdún, láti nǹkan bí ọdún 609 ṣáájú Sànmánì Kristẹni títí di ọdún 539 ṣáájú Sànmánì Kristẹni nígbà tí wọ́n ṣẹ́gun ìlú Bábílónì.

Àmọ́, Bíbélì fi hàn pé àádọ́rin ọdún náà jẹ́ àkókò ìjìyà tó múná látọwọ́ Ọlọ́run, ìyẹn ìyà tó fi jẹ àwọn èèyàn Júdà àti Jerúsálẹ́mù tí wọ́n ti dá májẹ̀mú pé àwọn á máa ṣègbọràn sí Ọlọ́run. (Ẹ́kísódù 19:3-6) Nígbà tí wọ́n kọ̀ láti yí pa dà kúrò ní ọ̀nà búburú wọn, Ọlọ́run sọ pé: “Èmi yóò ránṣẹ́ sí Nebukadirésárì ọba Bábílónì  . . . láti gbéjà ko ilẹ̀ yìí, àti láti gbéjà ko àwọn olùgbé rẹ̀ àti láti gbéjà ko gbogbo orílẹ̀-èdè wọ̀nyí tí ó yí i ká.” (Jeremáyà 25:4, 5, 8, 9) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nítòsí pẹ̀lú yóò rí ìbínú Bábílónì, síbẹ̀ Jeremáyà sọ pé ìparun Jerúsálẹ́mù àti ìgbèkùn àádọ́rin ọdún jẹ́ “ìyà  . . . àwọn ènìyàn mi” nítorí Jerúsálẹ́mù ti “dá ẹ̀ṣẹ̀ paraku.”—Ìdárò 1:8; 3:42; 4:6.

Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, àádọ́rin ọdún náà jẹ́ sáà ìjìyà mímúná fún Júdà, Ọlọ́run sì lo àwọn ará Bábílónì gẹ́gẹ́ bí ohun èlò láti fi ìyà tó múná jẹ wọ́n. Síbẹ̀, Ọlọ́run sọ fún àwọn Júù pé: “Lẹhin ti adọrin ọdun ba pari . . . emi o si mu . . . nyin pada si ibi yi,” ìyẹn sí ilẹ̀ Júdà àti Jerúsálẹ́mù.—Jeremáyà 29:10, Bibeli Mimọ.

Ìgbà Wo Ni “Àádọ́rin Ọdún Náà” Bẹ̀rẹ̀?

Òpìtàn kan tí Ọlọrun mí sí tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ẹ́sírà, tó gbé láyé lẹ́yìn ìgbà tí àádọ́rin ọdún inú àsọtẹ́lẹ̀ Jeremáyà ti parí, sọ nípa Ọba Nebukadinésárì pé: “Awọn ti o ṣiku lọwọ idà li o kó lọ si [Bábílónì]; nibiti nwọn jẹ́ iranṣẹ fun u, ati fun awọn ọmọ rẹ̀ titi di ijọba awọn ara Persia: Láti mu ọ̀rọ Oluwa ṣẹ lati ẹnu Jeremiah wá, titi ilẹ̀ na yio fi san ọdun isimi rẹ̀; ani ni gbogbo ọjọ idahoro on nṣe isimi titi adọrin ọdun fi pé.”—2 Kíróníkà 36:20, 21, Bibeli Mimọ.

Nítorí náà, àádọ́rin ọdún yóò jẹ́ àkókò tí ilẹ̀ Júdà àti Jerúsálẹ́mù yóò ní “isimi.” Ìyẹn ni pé wọn kò ní dá oko sórí ilẹ̀ náà, wọn kò ní gbin irúgbìn kankan, wọn kò sì ní rẹ́ ọwọ́ àwọn àjàrà ibẹ̀. (Léfítíkù 25:1-5) Nítorí àìgbọràn àwọn èèyàn Ọlọ́run, tó ṣeé ṣe kí ó kan ṣíṣàì pa àwọn Sábáàtì mọ́, Ọlọ́run sọ pé wọn kò ní ṣiṣẹ́ lórí ilẹ̀ náà, yóò sì wà ní ahoro fún àádọ́rin ọdún.—Léfítíkù 26:27, 32-35, 42, 43.

Ìgbà wo ni ilẹ̀ Júdà di ahoro tí wọn kò sì ṣiṣẹ́ lórí rẹ̀? Ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn ará Bábílónì gbéjà ko Jerúsálẹ́mù, èyí sì jẹ́ ní àwọn ọdún tó yàtọ̀ síra, Nebukadinésárì ló sì ṣáájú ogun náà nígbà méjèèjì. Ìgbà wo ni àádọ́rin ọdún náà bẹ̀rẹ̀? Ó dájú pé kì í ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí Nebukadinésárì gbógun ti Jerúsálẹ́mù ló bẹ̀rẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Nebukadinésárì mú ọ̀pọ̀ lẹ́rú láti Jerúsálẹ́mù lọ sí Bábílónì nígbà yẹn, ó fi àwọn kan sílẹ̀ ní ilẹ̀ náà. Bákan náà, kò tíì pa ìlú náà run. Lẹ́yìn àwọn ọdún mélòó kan tí wọ́n ti kó àwọn kan lọ, àwọn tó ṣẹ́ kù sí Júdà, ìyẹn “ìsọ̀rí àwọn ẹni rírẹlẹ̀ lára àwọn ènìyàn” náà ṣì ń gbé ilẹ̀ náà. (2 Àwọn Ọba 24:8-17) Àmọ́ lẹ́yìn ìgbà ìyẹn, gbogbo nǹkan yí pa dà pátápátá.

Nítorí pé àwọn Júù ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Bábílónì, èyí mú kí àwọn ará Bábílónì pa dà wá sí Jerúsálẹ́mù. (2 Àwọn Ọba 24:20; 25:8-10) Wọ́n pa ìlú náà run yán-án-yán-án, títí kan tẹ́ńpìlì rẹ̀ mímọ́, wọ́n sì kó ọ̀pọ̀ lára àwọn olùgbé ilẹ̀ náà lẹ́rú lọ sí Bábílónì. Láàárín oṣù méjì, “gbogbo àwọn ènìyàn náà [ìyẹn àwọn tó ṣẹ́kù sí ìlú náà] láti ẹni kékeré dé ẹni ńlá, àti àwọn olórí ẹgbẹ́ ológun dìde, wọ́n sì wá sí Íjíbítì; nítorí tí àyà ń fò wọ́n nítorí àwọn ará [Bábílónì].” (2 Àwọn Ọba 25:25, 26) Ní oṣù keje ti àwọn Júù, ìyẹn oṣù Tíṣírì (September/October) ọdún yẹn ni a tó lè sọ pé ilẹ̀ tó ti di ahoro tí wọn kò sì lè ṣiṣẹ́ lórí rẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìsinmi rẹ̀, ìyẹn Sábáàtì. Ọlọ́run tipasẹ̀ Jeremáyà sọ fún àwọn Júù tó wá ibi ìsádi lọ sí Íjíbítì pé: “Ẹ̀yin fúnra yín ti rí gbogbo ìyọnu àjálù tí mo mú wá sórí Jerúsálẹ́mù àti sórí gbogbo àwọn ìlú ńlá Júdà, sì kíyè sí i, ibi ìparundahoro ni wọ́n ní òní yìí, kò sì sí olùgbé kankan nínú wọn.” (Jeremáyà 44:1, 2) Nítorí náà, a lè sọ pé àkókò tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé ni àádọ́rin ọdún náà bẹ̀rẹ̀. Ọdún wo sì ni? Láti dáhùn ìbéèrè yìí, ó yẹ ká mọ ìgbà tí àkókò náà parí.

Ìgbà Wo Ni “Àádọ́rin Ọdún Náà” Parí?

Wòlíì Dáníẹ́lì tó gbé ayé títí dìgbà “ijọba awọn ara Persia” wà ní Bábílónì nígbà yẹn, ó sì ṣírò ìgbà tí àádọ́rin ọdún náà máa parí. Ó sọ pé: “Emi Daniẹli fiyesi lati inu iwe, iye ọdun, nipa eyi tí ọ̀rọ Oluwa tọ Jeremiah, woli wá, pé àdọrin ọdun li on o mu pé lori idahoro Jerusalemu.”—Dáníẹ́lì 9:1, 2, Bibeli Mimọ.

Ẹ́sírà ronú lórí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Jeremáyà, ó sì sọ pé “adọrin ọdun” náà máa dópin nígbà tí “Oluwa ru ẹmi Kirusi, ọba soke, ti o si ṣe ikede.” (2 Kíróníkà 36:21, 22, Bibeli Mimọ) Ìgbà wo ni wọ́n dá àwọn Júù sílẹ̀? “Ọdún kìíní Kírúsì ọba Páṣíà” ni àṣẹ náà jáde pé kí wọ́n kúrò ní ìgbèkùn. (Wo àpótí náà  “Ọdún Pàtàkì Kan Nínú Ìtàn.”) Nípa báyìí, nígbà tó fi máa di ìgbà ìwọ́wé ọdún 537 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn Júù ti pa dà sí Jerúsálẹ́mù láti mú ìjọsìn tòótọ́ pa dà bọ̀ sípò.—Ẹ́sírà 1:1-5; 2:1; 3:1-5.

Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú ìṣírò ọjọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì, àádọ́rin ọdún jẹ́ sáà àkókò kan tó parí lọ́dún 537 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Tí a bá ka àádọ́rin ọdún pa dà sẹ́yìn, ọdún tí àádọ́rin náà bẹ̀rẹ̀ yóò jẹ́ ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni.

Àmọ́, tí ẹ̀rí látinú Ìwé Mímọ́ bá fi hàn kedere pé ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni Jerúsálẹ́mù pa run, kí nìdí tí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé fi sọ pé ọdún 587 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni? Ìdí ni pé láti ibi méjì ni wọ́n ti mú ìsọfúnni wọn, ìyẹn látinú ìwé àwọn òpìtàn ayé àtijọ́ pẹ̀lú àkọsílẹ̀ Ptolemy. Ṣé àwọn ìwé yìí ṣeé gbára lé ju Bíbélì lọ ni? Ẹ jẹ́ ká wò ó.

Báwo Ni Ìwé Àwọn Òpìtàn Ayé Àtijọ́ Ṣe Péye Tó?

Àwọn òpìtàn tí wọ́n gbé láyé kété lẹ́yìn ìgbà tí Jerúsálẹ́mù pa run fúnni ní ìsọfúnni tó ta ko ara wọn nípa àwọn ọba tó ṣàkóso Ilẹ̀ Ọba Bábílónì Ẹlẹ́ẹ̀kejì. * (Wo àpótí náà,  “Àwọn Ọba Tó Ṣàkóso Ilẹ̀ Ọba Bábílónì Ẹlẹ́ẹ̀kejì.”) Ọdún tí àwọn òpìtàn náà ṣírò pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé àti bí wọ́n ṣe ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra kò bá èyí tí Bíbélì sọ mú. Àmọ́, báwo ni àwọn ìwé àwọn òpìtàn yìí ti ṣeé gbára lé tó?

Ọ̀kan lára àwọn òpìtàn tó gbé láyé kété lẹ́yìn ìgbà ìṣàkóso Ilẹ̀ Ọba Bábílónì Ẹlẹ́ẹ̀kejì ni Berossus, “àlùfáà Bélì” ti Bábílónì. Ìwé tó kọ́kọ́ kọ, ìyẹn Babyloniaca, ní nǹkan bí ọdún 281 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ti bà jẹ́, kìkì ohun tó wà nínú àjákù rẹ̀ ni wọ́n kọ sínú àwọn ìwé táwọn òpìtàn míì kọ. Ọ̀gbẹ́ni Berossus sọ pé òun lo “àwọn ìwé tí wọ́n fara balẹ̀ tọ́jú tó wà ní Bábílónì.”1 Ǹjẹ́ òpìtàn tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ péye ni Berossus? Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan.

Berossus sọ pé Senakéríbù Ọba Ásíríà ló jọba tẹ̀ lé “ẹ̀gbọ́n [rẹ̀] ọkùnrin,” àti “lẹ́yìn tirẹ̀, ọmọ rẹ̀ [Esarihádónì jọba fún] ọdún mẹ́jọ; àti lẹ́yìn náà Sammuges [Shamash-shuma-ukin] jọba fún ọdún mọ́kànlélógún.” (Ìdìpọ̀ Kẹta, 2.1, 4) Àmọ́, àwọn àkọsílẹ̀ ìtàn Bábílónì tí wọ́n ti kọ tipẹ́ ṣáájú ìgbà Berossus sọ pé Senakéríbù jọba tẹ̀ lé bàbá rẹ̀ Ságónì Kejì, kì í ṣe tẹ̀ lé ẹ̀gbọ́n rẹ̀; Esarihádónì jọba fún ọdún méjìlá, kì í ṣe ọdún mẹ́jọ; àti pé Shamash-shuma-ukin jọba fún ogún ọdún, kì í ṣe ọdún mọ́kànlélógún. Nígbà tí ọ̀mọ̀wé R. J. van der Spek ń sọ nípa bí Berossus ṣe lọ wo àwọn wàláà tí wọ́n kọ ìtàn Bábílónì sí, ó ní: “Èyí kò dí i lọ́wọ́ láti ṣe àfikún tìrẹ àti ìtumọ̀ tirẹ̀.”2

Ojú wo ni àwọn ọ̀mọ̀wé yòókù fi ń wo Berossus? Ọ̀gbẹ́ni S. M. Burstein tó ti fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn ìwé Berossus sọ pé, “Nígbà kan rí ni wọ́n ti sábà máa ń wò ó bí òpìtàn.” Àmọ́, ibi tó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí ni pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n kà á sí òpìtàn lóòótọ́, àwọn ìwé rẹ̀ kò jọ ti òpìtàn rárá. Àní tá a bá wo àjákù ìwé Babyloniaca, àwọn àṣìṣe kan wà níbẹ̀ tó yani lẹ́nu, wọ́n sì jẹ́ àwọn àṣìṣe kéékèèké tí kò yẹ kó ṣẹlẹ̀ . . . Kò yẹ ká bá irú àṣìṣe bẹ́ẹ̀ nínú ìwé ẹni tó jẹ́ òpìtàn, àmọ́ ìdí tí Berossus fi ṣe ìwé náà kì í ṣe nítorí ìtàn.”3

Pẹ̀lú gbogbo àlàyé tá a ti ṣe yìí, kí lèrò rẹ? Ṣé ó yẹ ká gbà pé ìṣirò ọjọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí Berossus ṣe tọ̀nà délẹ̀délẹ̀? Àwọn òpìtàn ayé àtijọ́ ńkọ́, àwọn tó jẹ́ pé èyí tó pọ̀ jù lára ìṣirò ọjọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí wọ́n ṣe ni wọ́n mú látinú àwọn ìwé Berossus? Ǹjẹ́ àwọn ìtàn tí wọ́n kọ ṣeé gbára lé?

Àkọsílẹ̀ Ptolemy

Ìwé Ọba tí Claudius Ptolemy, tó jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà ọgọ́rùn-ún ọdún kejì Sànmánì Kristẹni (S.K.) kọ ni wọ́n tún ń lò láti fi ti èrò náà lẹ́yìn pé ọdún 587 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni ìlú Jerúsálẹ́mù pa run. Inú àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn ọba tí Ptolemy kọ ni wọ́n ti rí ìṣirò àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ ìtàn àtijọ́, títí kan ìgbà ìṣàkóso Ilẹ̀ Ọba Bábílónì Ẹlẹ́ẹ̀kejì.

Ọ̀gbẹ́ni Ptolemy ṣe àkọsílẹ̀ náà ní nǹkan bí ẹgbẹ̀ta [600] ọdún lẹ́yìn tí ìṣàkóso Ilẹ̀ Ọba Bábílónì Ẹlẹ́ẹ̀kejì parí. Nítorí náà, báwo ló ṣe mọ ìgbà tí ọba àkọ́kọ́ tó wà nínu àkọsílẹ̀ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í jọba? Ptolemy ṣàlàyé pé àwọn lo ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà tó ní í ṣe pẹ̀lú òṣùpá láti fi mọ ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó sọ pé, “a ṣè ìṣirò láti mọ ìgbà ìbẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso Nabonásárì,” tó jẹ́ ọba àkọ́kọ́ lórí àkọ́sílẹ̀ rẹ̀.4 Ọ̀gbẹ́ni Christopher Walker tó ń ṣiṣẹ́ ní Ilé Ìkó-ohun-ìṣẹ̀ǹbáyé sí nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ pé àkọ́sílẹ̀ Ptolemy jẹ́ “ohun kan tó hùmọ̀ fún àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ojú sánmà láti máa fi ṣírò àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀” àmọ́ “kò ṣe é fún àwọn òpìtàn láti fi mọ àkókò pàtó náà tí àwọn ọba gorí ìtẹ́ àti ìgbà tí wọ́n kú.”5

Leo Depuydt tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn alátìlẹyìn gidi fún Ptolemy sọ pé, “Ó ti pẹ́ táwọn èèyàn ti mọ̀ pé àkọsílẹ̀ Ptolemy ṣeé gbára lé gan-an tó bá kan ọ̀ràn ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà, àmọ́ ìyẹn kò túmọ̀ sí pé àkọsílẹ̀ náà ṣeé gbára lé tó bá kan ọ̀ràn ìtàn.” Ọ̀jọ̀gbọ́n Depuydt fi kún un pé: “Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ti ṣàkóso ṣáájú [tó fi mọ́ àwọn ọba tó ṣàkóso ní Ilẹ̀ Ọba Bábílónì Ẹlẹ́ẹ̀kejì], a ní láti fi àkọ́sílẹ̀ Ptolemy wéra pẹ̀lú àkọsílẹ̀ wàláà tó sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ìṣàkóso ọba kọ̀ọ̀kan.”6

“Àkọsílẹ̀ wàláà” wo ló mú kó ṣeé ṣe fún wa láti mọ̀ bóyá ìtàn tó wà nínú àkọsílẹ̀ Ptolemy ṣeé gbára lé? Ara rẹ̀ ni àwọn wàláà tí wọ́n kọ ìtàn Bábílónì sí, àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn ọba àti wàláà tí wọ́n fi ṣàkọsílẹ̀ ọrọ̀ ajé, èyí táwọn akọ̀wé tó gbé láyé ní ìgbà ìṣàkóso Ilẹ̀ Ọba Bábílónì Ẹlẹ́ẹ̀kejì kọ.7

Báwo la ṣe fi àkọsílẹ̀ Ptolemy wéra pẹ̀lú àkọsílẹ̀ wàláà náà? Àpótí náà,  “Ǹjẹ́ Àkọsílẹ̀ Ptolemy Bá Àwọn Wàláà Ayé Àtijọ́ Mu?” (wo ìsàlẹ̀), fi apá kan àkọ́sílẹ̀ Ptolemy hàn, ó sì fi wéra pẹ̀lú àkọsílẹ̀ wàláà ayé àtijọ́. Kíyè sí i pé orúkọ ọba mẹ́rin ni Ptolemy tò sí ẹ̀yìn orúkọ ọba Kandalánù kó tó kan ọba Nábónídọ́sì, tí gbogbo wọ́n jẹ́ ọba Bábílónì. Àmọ́, Àkọsílẹ̀ Ọba Uruk tó jẹ́ ara àkọsílẹ̀ wàláà ayé àtijọ́ sọ pé ọba méje ló jẹ lẹ́yìn ọba Kandalánù kó tó wá kan ọba Nábónídọ́sì. Ṣé nítorí pé àkókó kúkúrú ni àwọn ọba tí kò mẹ́nu kàn náà fi ṣàkóso, tí àkóso wọn kò sì já mọ́ nǹkan kan ni kò ṣe sọ̀rọ̀ nípa wọn ni? Gẹ́gẹ́ bí wàláà tí wọ́n fi ṣàkọsílẹ̀ ọrọ̀ ajé ṣe sọ, ọ̀kan lára wọn ṣàkóso fún ọdún méje.8

Ẹ̀rí tó dájú látinú àkọsílẹ̀ wàláà wà pé ṣáájú ìgbà ìjọba Nabopolásárì (ọba àkọ́kọ́ lára àwọn ọba tó jẹ nígbà ìṣàkóso Ilẹ̀ Ọba Bábílónì Ẹlẹ́ẹ̀kejì), ọba mìíràn (Ashur-etel-ilani) wà tó ṣàkóso fún ọdún mẹ́rin ní Bábílónì. Ó tún ṣẹlẹ̀ pé, ó ju ọdún kan lọ tí kò fi sí ọba kankan ní ilẹ̀ náà.9 Àmọ́, àkọ́sílẹ̀ Ptolemy kò mẹ́nu kan gbogbo nǹkan yìí.

Kí nìdí tí Ptolemy kò fi mẹ́nu kan àwọn ọba kan? Ẹ̀rí fi hàn pé kò kà wọ́n mọ́ ara àwọn ọba Bábílónì tí ipò ọba tọ́ sí.10 Bí àpẹẹrẹ, kò fi Labashi-Marduk, tó jọba nígbà ìṣàkóso Ilẹ̀ Ọba Bábílónì Ẹlẹ́ẹ̀kejì sínú àkọ́sílẹ̀ rẹ̀. Àmọ́, gẹ́gẹ́ bí àkọ́sílẹ̀ wàláà ṣe sọ, àwọn ọba tí Ptolemy kò fi sínú àkọsílẹ̀ rẹ̀ jẹ́ àwọn ọba tí wọ́n jọba ní Bábílónì lóòótọ́.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ka àkọsílẹ̀ Ptolemy sí èyí tó péye. Àmọ́, bí kò ṣe mẹ́nu kan àwọn nǹkan pàtàkì yìí, ṣé ó yẹ ká lo àkọsílẹ̀ rẹ̀ láti ṣe ìṣirò ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ pàtó kan nínú ìtàn?

Èrò Wa Nípa Àwọn Ẹ̀rí Tá A Rí

Àkópọ̀ ohun tá a ti ń sọ bọ̀ ni pé: Bíbélì sọ ni kedere pé àádọ́rin ọdún ni àwọn Júù fi wà ní ìgbèkùn. Ẹ̀rí tó dájú wà pé ọdún 537 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni àwọn Júù tó wà nígbèkùn pa dà lọ sí ìlú ìbílẹ̀ wọn, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ọ̀mọ̀wé ló sì fara mọ ẹ̀rí náà. Tá a bá ka àádọ́rin ọdún pa dà sẹ́yìn láti ọdún 537 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, á mú wa dé ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ìyẹn ìgbà tí wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òpìtàn ayé àtijọ́ àti àkọsílẹ̀ Ptolemy kò fara mọ́ ọdún yìí, àwọn ìbéèrè tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ wà tó múni gbà pé ìwé táwọn èèyàn yìí kọ kò lè jóòótọ́. Ká sòótọ́, ẹ̀rí tí àwọn òpìtàn ayé àtijọ́ àti Ptolemy fúnni kò tó láti fi hàn pé ọjọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì kò jóòótọ́.

Àmọ́, àwọn ìbéèrè míì ṣì wà. Yàtọ̀ sí ẹ̀rí tó wà nínú Bíbélì, ṣé kò sí ẹ̀rí mìíràn nínú ìtàn tó ti Bíbélì lẹ́yìn pé ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run? Ẹ̀rí wo ló wà nínú ọ̀pọ̀ wàláà tó ní àkọsílẹ̀ àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀, èyí tí àwọn tí ọ̀ràn ṣojú wọn láyé àtijọ́ kọ? A óò jíròrò àwọn ìbéèrè yìí nínú ìtẹ̀jáde wa tó ń bọ̀.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Ọdún méjèèjì yìí ló wà nínú àwọn ìwé ìtàn. Kí ọ̀rọ̀ yìí má bàa lọ́jú pọ̀, ọdún 587 ṣáájú Sànmánì Kristẹni la máa lò nínu àpilẹ̀kọ yìí.

^ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe Bíbélì kan tó ṣeé gbára lé, orúkọ rẹ̀ ni Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. Àmọ́, tó bá jẹ́ pé o kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, o lè lo àwọn Bíbélì míì nígbà tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a lo àwọn Bíbélì kan táwọn èèyàn máa ń lò dáadáa.

^ Ilẹ̀ Ọba Bábílónì Ẹlẹ́ẹ̀kejì bẹ̀rẹ̀ nígbà tí bàbá Nebukadinésárì, ìyẹn Nabopolásárì jọba, ó sì parí nígbà ìṣàkóso Nábónídọ́sì. Àkókò yìí ṣe pàtàkì gan-an fún àwọn ọ̀mọ̀wé, nítorí pé èyí tó pọ̀ jù lára àádọ́rín ọdún tí Jerúsálẹ́mù fi wà ní ahoro ló bọ́ sí sáà àkókò náà.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

 ỌDÚN PÀTÀKÌ KAN NÍNÚ ÌTÀN

Àwọn ẹ̀rí tó wà nísàlẹ̀ yìí la fi ṣèṣirò tá a fi mọ̀ pé ọdún 539 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni Kírúsì Kejì ṣẹ́gun Bábílónì:

Àwọn ìtàn àtijọ́ àti àwọn àkọsílẹ̀ wàláà: Ọ̀gbẹ́ni Diodorus ti erékùṣù Sicily (nǹkan bí ọdún 80 sí 20 ṣáájú Sànmánì Kristẹni) sọ pé Kírúsì di ọba Páṣíà ní “ìbẹ̀rẹ̀ ọdún karùnléláàádọ́ta ti Olympiad.” (Historical Library, Book IX, 21) Ọdún yẹn ni ọdún 560 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì náà, Herodotus (nǹkan bí ọdún 485 sí 425 ṣáájú Sànmánì Kristẹni) sọ pé wọ́n pa Kírúsì “lẹ́yìn ọdún kọkàndínlọ́gbọ̀n tó ti ń ṣàkóso,” èyí á mú kí ìgbà tó kú bọ́ sí ọgbọ̀n [30] ọdún ìṣàkóso rẹ̀, ìyẹn ọdún 530 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. (Histories, Book I, Clio, 214) Àwọn àkọsílẹ̀ wàláà fi hàn pé ṣáájú kí Kírúsì tó kú, ó ṣàkóso Bábílónì fún ọdún mẹ́sàn-án. Nítorí náà, ọdún mẹ́sàn-án ṣáájú ikú rẹ̀, ní ọdún 530 ṣáájú Sànmánì Kristẹni mú wa pa dà sí ọdún 539 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ìyẹn ọdún tí Kírúsì ṣẹ́gun Bábílónì.

Àkọsílẹ̀ wàláà fi hàn pé òótọ́ ni: Wàláà alámọ̀ ti Bábílónì tí wọ́n fi òṣùpá ṣèṣirò àkókò inú rẹ̀ (BM 33066) jẹ́rìí sí i pé Kírúsì kú ní ọdún 530 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àṣìṣe kan wà nínú wàláà yìí nípa ibi tí àwọn nǹkan tó wà lójú sánmà wà, ó sọ nípa ìgbà méjì tí ọ̀sán dòru, èyí tí wàláà náà sọ pé ó ṣẹlẹ̀ ní ọdún keje ìgbà ìjọba Kanbáísísì Kejì, tó jẹ́ ọmọkùnrin Kírúsì tó jọba tẹ̀ lé bàbá rẹ̀. Wọ́n sọ pé ìgbà méjì tí ọ̀sán dòru ní Bábílónì ni July 16, ọdún 523 ṣáájú Sànmánì Kristẹni àti ní January 10, ọdún 522 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, èyí tó fi hàn pé ìgbà ìrúwé ọdún 523 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni ìbẹ̀rẹ̀ ọdún keje ìgbà ìjọba Kanbáísísì. Ìyẹn yóò sì mú kí ọdún àkọ́kọ́ ìgbà ìjọba rẹ̀ jẹ́ ọdún 529 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Nítorí náà, ọdún tí Kírúsì lò kẹ́yìn láyé ní láti jẹ́ ọdún 530 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, èyí sì mú kí ọdún 539 ṣáájú Sànmánì Kristẹni jẹ́ ọdún àkọ́kọ́ ìgbà ìṣàkóso rẹ̀ lórí Bábílónì.

[Credit Line]

Wàláà: © The Trustees of the British Museum

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 31]

ÀKÓPỌ̀ ṢÓKÍ

▪ Àwọn òpìtàn ayé máa ń sọ pé ọdún 587 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run.

▪ Ìṣirò àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì fi hàn pé ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run.

▪ Àwọn òpìtàn ayé gbé èrò wọn ka kìkì àwọn ìwé àwọn òpìtàn ayé àtijọ́ àti àkọsílẹ̀ Ptolemy.

▪ Àwọn àṣìṣe ńlá wà nínú àwọn ìwé táwọn òpìtàn ayé àtijọ́ kọ, bákan náà, wọn kì í fìgbà gbogbo bá àwọn àkọsílẹ̀ inú àwọn wàláà alámọ̀ mu.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Àfikún Àlàyé

1. Ìwé Babyloniaca, (Chaldaeorum Historiae) Book One, 1.1.

2. Ìwé Studies in Ancient Near Eastern World View and Society, ojú ìwé 295.

3. Ìwé The Babyloniaca of Berossus, ojú ìwé 8.

4. Ìwé Almagest, III, 7, èyí tí G. J. Toomer ṣètumọ̀ rẹ̀, tí ó wà nínú ìwé Ptolemy’s Almagest, tí wọ́n tẹ̀ jáde ní ọdún 1998, ojú ìwé 166. Ọ̀gbẹ́ni Ptolemy mọ̀ pé àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà ará Bábílónì fi ìmọ̀ ìṣirò “ṣírò” àkókò tí ọ̀sán dòru ní ìgbà tó ti kọjá àti ti ọjọ́ iwájú, nítorí wọ́n mọ̀ pé ọdún méjìdínlógún síra wọn ni ọ̀sán máa ń dòru.—Almagest, IV, 2.

5. Ìwé Mesopotamia and Iran in the Persian Period, ojú ìwé 17-18.

6. Ìwé Journal of Cuneiform Studies, Ìdìpọ̀ 47, 1995, ojú ìwé 106-107.

7. Wàláà jẹ́ ohun alámọ̀ kan tí akọ̀wé fi kálàmù ẹlẹ́nu ṣóṣóró kọ oríṣiríṣi ọ̀rọ̀ sí.

8. Ọdún méje ni Ọba Sin-sharra-ishkun fi ṣàkóso, ọba yìí ní wàláà mẹ́tàdínlọ́gọ́ta tí wọ́n fi ṣàkọsílẹ̀ ọrọ̀ ajé, àkọsílẹ̀ tó wà lórí wàláà náà jẹ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé láti ìgbà tí ó gorí ìtẹ́ títí ọdún méje fi parí. Wo Journal of Cuneiform Studies, Ìdìpọ̀ 35, 1983, ojú ìwé 54-59.

9. Wàláà tí wọ́n fi ṣàkọsílẹ̀ ọrọ̀ ajé, ìyẹn C.B.M. 2152 ti wà láti ọdún kẹrin ìjọba Ashur-etel-ilani. (Wo ìwé Legal and Commercial Transactions Dated in the Assyrian, Neo-Babylonian and Persian Periods—Chiefly From Nippur, tí A.T. Clay ṣe, 1908, ojú ìwé 74.) Bákan náà, ìwé Harran Inscriptions of Nabonidus, (H1B), Ìdìpọ̀ Kìíní, ìlà 30, to orúkọ Nabonídọ́sì ṣáájú orúkọ Nabopolásárì. (Anatolian Studies, Ìdìpọ̀ Kẹjọ 1958, ojú ìwé 35, 47.) Tí o bá fẹ́ mọ ìgbà tí kò sí ọba, wo wàláà Chronicle 2, ìlà 14, ti àkọsílẹ̀ Assyrian and Babylonian Chronicles, ojú ìwé 87-88.

10. Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé àwọn ọba Bábílónì nìkan ni Ptolemy ṣàkọsílẹ̀ orúkọ wọn, kò sì mẹ́nu kan àwọn ọba kan nítorí pé “Ọba Asíríà” ni wọ́n ń pè wọ́n. Àmọ́ gẹ́gẹ́ bó o ṣe máa rí i nínú àpótí tó wà ní ojú ìwé 30, àwọn ọba mélòó kan tó wà nínú àkọsílẹ̀ Ptolemy tún ní orúkọ oyè náà, “Ọba Asíríà.” Wàláà tí wọ́n fi ṣàkọsílẹ̀ ọrọ̀ ajé, àwọn wàláà tí wọ́n fi kọ lẹ́tà àtàwọn àkọlé kan fi hàn kedere pé àwọn ọba Ashur-etel-ilani, Sin-shumu-lishir àti Sin-sharra-ishkun jọba lórí Bábílónì.

[Àtẹ Ìsọfúnnni/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

 (Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

ÀWỌN ỌBA TÓ ṢÀKÓSO ILẸ̀ ỌBA BÁBÍLÓNÌ ẸLẸ́Ẹ̀KEJÌ

Bí ọ̀rọ̀ àwọn òpìtàn wọ̀nyí bá ṣeé gbára lé, kì nìdí tí ohùn wọn kò fi ṣọ̀kan?

BEROS- POLYHIS- JOSE- PTOL-

SUS TOR PHUS EMY

n. * 350-270 105-? 37-?100 n. 100-170

Ṣ.S.K. Ṣ.S.K. S.K. S.K.

Àwọn Ọba

Nabopo

lásárì 21 20 — 21

Nebukadi

nésári II 43 43 43 43

Amel-

Marduk 2 12 18 2

Neri

glissar 4 4 40 4

Labashi-

Marduk oṣù 9 — oṣù 9 —

Nábóní

dọ́sì 17 17 17 17

Ìgbà ìṣàkóso ọba kọ̀ọ̀kan (ọdún ni a fi kà á) bí àwọn òpìtàn ayé àtijọ́ ṣe sọ

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ n. túmọ̀ sí “nǹkan bí”

[Credit Line]

 Fọ́tò nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda British Museum

[Àtẹ Ìsọfúnnni/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

ǸJẸ́ ÀKỌSÍLẸ̀ PTOLEMY BÁ ÀWỌN WÀLÁÀ AYÉ ÀTIJỌ́ MU?

Ptolemy kò mẹ́nu kan àwọn ọba kan nínú àkọsílẹ̀ rẹ̀. Kí nìdí?

ÀKỌSÍLẸ̀ PTOLEMY

Nabonásárì

Nabu-nadin-zeri (Nadinu)

Mukin-zeri àti Pul

Ululayu (Ṣálímánésà Kárùn-ún)

“Ọba Ásíríà”

Merodaki-báládánì

Ságónì Kejì “Ọba Ásíríà”

Ìgbà Àkọ́kọ́ Tí Kò Sí Ọba

Bel-ibni

Ashur-nadin-shumi

Nergal-ushezib

Mushezib-Marduk

Ìgbà Kejì Tí Kò Sí Ọba ÀKỌSÍLẸ̀ ỌBA URUK

Esarihádónì “Ọba Ásíríà” BÓ ṢE WÀ NÍNÚ

Shamash-shuma-ukin WÀLÁÀ AYÉ ÀTIJỌ́

Kandalánù Kandalánù

Sin-shumu-lishir

Sin-sharra-ishkun

Nabopolásárì Nabopolásárì

Nebukadinésárì Nebukadinésárì

Amel-Marduk Amel-Marduk

Neriglissar Neriglissar

Labashi-Marduk

Nábónídọ́sì Nábónídọ́sì

Kírúsì

Kanbáísísì

[Àwòrán]

Àwọn wàláà tí wọ́n kọ ìtàn Bábílónì sí jẹ́ ara àkọsílẹ̀ wàláà tó jẹ́ ká mọ̀ bóyá àkọsílẹ̀ Ptolemy ṣeé gbára lé

[Credit Line]

Fọ́tò nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda British Museum

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 31]

Fọ́tò nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda British Museum