5 Gbogbo Ìjọsìn Tó Wá Látọkàn Ni Ọlọ́run Tẹ́wọ́ Gbà—Ṣé Òótọ́ Ni?
5 Gbogbo Ìjọsìn Tó Wá Látọkàn Ni Ọlọ́run Tẹ́wọ́ Gbà—Ṣé Òótọ́ Ni?
Ohun táwọn èèyàn ń sọ: “Bí èèyàn ṣe lè gba oríṣiríṣi ọ̀nà dé ibì kan, bẹ́ẹ̀ náà ni èèyàn lè gba oríṣiríṣi ọ̀nà jọ́sìn Ọlọ́run. Ó kù sọ́wọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kàn láti gba ọ̀nà tó bá fẹ́ láti jọ́sìn Ọlọ́run.”
Ohun tí Bíbélì kọ́ni: A gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ nínú ìjọsìn wa, kí á má ṣe jẹ́ ẹni tí ń fojú ṣe tí kò fọkàn ṣe àti alágàbàgebè. Jésù sọ fún àwọn aṣáájú ìsìn ìgbà ayé rẹ̀ nípa ìdí tí Ọlọ́run kò fi tẹ́wọ́ gbà wọ́n, ó ní: “Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ lọ́nà tí ó ṣe wẹ́kú nípa ẹ̀yin alágàbàgebè, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Àwọn ènìyàn yìí ń fi ètè wọn bọlá fún mi, ṣùgbọ́n ọkàn-àyà wọn jìnnà réré sí mi.’” (Máàkù 7:6) Síbẹ̀, fífi òótọ́ ọkàn jọ́sìn Ọlọ́run nìkan kọ́ ló máa mú kí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa.
Jésù mú kí èyí ṣe kedere nígbà tó sọ olórí àléébù tó wà nínú ìjọsìn àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn àti ti àwọn ọmọlẹ́yìn wọn. Ó lo ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wọn, ó ní: “Lásán ni wọ́n ń jọ́sìn mi, nítorí pé wọ́n ń fi àwọn àṣẹ ènìyàn kọ́ni gẹ́gẹ́ bí ẹ̀kọ́.” (Máàkù 7:7) Ìjọsìn wọn jẹ́ “lásán” tàbí aláìwúlò, nítorí pé wọ́n kọ́ni pé ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ ẹ̀sìn wọn ṣe pàtàkì ju ohun tí Ọlọ́run fẹ́.
Bíbélì kò sọ pé ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni èèyàn lè gbà jọ́sìn Ọlọ́run, kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ pé ọ̀nà kan ṣoṣo ló wà. Mátíù 7:13, 14 sọ pé: “Ẹ gba ẹnubodè tóóró wọlé; nítorí fífẹ̀ àti aláyè gbígbòòrò ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìparun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ni àwọn tí ń gbà á wọlé; nígbà tí ó jẹ́ pé, tóóró ni ẹnubodè náà, híhá sì ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìyè, díẹ̀ sì ni àwọn tí ń rí i.”
Bí mímọ òtítọ́ ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́: Fojú inú wo bó ṣe máa rí lára rẹ ká ní o ti ṣe ìdánrawò fún ọ̀pọ̀ oṣù kí o bàa lè lọ sá eré ẹlẹ́mìí ẹṣin, ká wá sọ pé o sá eré náà parí àmọ́ wọ́n ní o kò lè gba ẹ̀bùn nítorí pé o ti rú ọ̀kan lára òfin eré náà tí o kò mọ̀ tẹ́lẹ̀. Ó máa dùn ẹ́ gan-an pé gbogbo ìsapá rẹ ti já sófo. Ṣé ohun kan tó jọ èyí lè ṣẹlẹ̀ sí wa nínú ìjọsìn wa sí Ọlọ́run?
Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi ìjọsìn wa wé ìdíje àwọn eléré ìdárayá, ó ní: “Jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí ẹnì kan bá díje nínú àwọn eré pàápàá, a kì í dé e ládé láìjẹ́ pé ó díje ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà àfilélẹ̀.” (2 Tímótì 2:5) A máa rí ojú rere Ọlọ́run tí a bá ń jọ́sìn rẹ̀ “ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà àfilélẹ̀,” ìyẹn ní ọ̀nà tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà. Bí a bá yan ọ̀nà tó bá ṣáà ti wù wá láti jọ́sìn Ọlọ́run, ìjọsìn wa kò lè ṣètẹ́wọ́gbà bó ṣe jẹ́ pé sárésáré kan kò lè sáré gba ibi tó bá ṣáà ti wù ú, kí ó sì rí ẹ̀bùn gbà.
Kí a tó lè ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, ìjọsìn wa kò gbọ́dọ̀ fára mọ́ irọ́ nípa Ọlọ́run. Jésù sọ pé: “Àwọn olùjọsìn tòótọ́ yóò máa jọ́sìn Baba ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” (Jòhánù 4:23) Inú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni a ti máa ń kọ́ ọ̀nà tòótọ́ tí a lè gbà jọ́sìn rẹ̀.—Jòhánù 17:17. *
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ Fún ìsọfúnni síwájú sí i nípa ìjọsìn tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà, ka orí 15 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 8]
Ṣé gbogbo ẹ̀sìn ló ń kọ́ àwọn èèyàn láti máa jọ́sìn Ọlọ́run ní ọ̀nà tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà?