Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà
Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà
Ọ̀DỌ́BÌNRIN kan fi ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn tí àwọn òbí rẹ̀ kọ́ ọ láti kékeré sílẹ̀, àmọ́ nígbà tó yá, ó pa dà sídìí ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn náà, kí nìdí tó fi pa dà? Ẹ gbọ́ ohun tó sọ.
“Ní báyìí, ìgbésí ayé mi ti dára gan-an.”—LISA ANDRÉ
ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1986
ORÍLẸ̀-ÈDÈ: LUXEMBOURG
IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: ỌMỌ ONÍNÀÁKÚNÀÁ
ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Ìlú Bertrange ni mo dàgbà sí, ìlú kékeré yìí mọ́ tónítóní, ó ní ààbò, ó sì jẹ́ ìlú ọlọ́rọ̀, ó wà ní ìtòsí ìlú Luxembourg. Èmi ni àbíkẹ́yìn nínú àwa ọmọ márùn-ún tí àwọn òbí wa bí. Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn òbí mi, wọ́n sì gbìyànjú láti kọ́ èmi àtàwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin àti obìnrin ní ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Kristẹni.
Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyè méjì gan-an nípa ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ni. Mi ò kọ́kọ́ ka iyè méjì tí mo ní yìí sí, àmọ́ díẹ̀díẹ̀ ni ìgbàgbọ́ mi bẹ̀rẹ̀ sí í yìnrìn. Àwọn òbí mi ṣe gbogbo nǹkan tí wọ́n lè ṣe láti tọ́ mi sọ́nà tó tọ́, síbẹ̀ mi ò gba ìrànlọ́wọ́ náà. Ni mo bá bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ tí kò bọ̀wọ̀ fún àṣẹ, mi ò sì jẹ́ kí àwọn òbí mi mọ̀. Ó jọ pé àwọn ọmọ wọ̀nyí lómìnira láti ṣe ohun tó wù wọ́n, irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sì wu èmi náà. A máa ń lọ sí oríṣiríṣi ibi àríyá, a máa ń ṣe ìṣekúṣe, a máa ń lo oògùn olóró, a sì máa ń mu ọtí àmujù. Inú mi kọ́kọ́ ń dùn pé mo wà láàárín àwọn tó jọ pé wọ́n ń jayé orí wọn.
Àmọ́ kí n sọ tòótọ́, mi ò láyọ̀. Ìgbésí ayé mi kò dára rárá, kò sí ìkankan nínú àwa tá a jọ ń ṣọ̀rẹ́ tí ó máa ń ronú jinlẹ̀. Dípò kí n máa láyọ̀, ńṣe ni ìwà ìrẹ́jẹ tó wà káàkiri ayé tún ń kó ìdààmú ọkàn bá mi. Bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ńṣe ni ìdààmú ọkàn mi túbọ̀ ń pọ̀ sí i.
BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún, lọ́jọ́ kan ìdààmú ọkàn bá mi gan-an. Nígbà tí màmá mi róye pé mi ò láyọ̀, ó rọ̀ mí pé kí n pa dà kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó gbà mí níyànjú pé kí n ṣàyẹ̀wò ohun tó kọ́ni, kí n sì wá pinnu bóyá màá fẹ́ máa gbé ìgbésí ayé mi ní ìbámu pẹ̀lú ohun tó sọ tàbí mi ò ní fẹ́ bẹ́ẹ̀. Ọ̀rọ̀ tó ṣe ṣàkó tó sì wọni lọ́kàn tá a jọ sọ yẹn mú kí n yí èrò mi pa dà. Mo gbà pé kí ẹ̀gbọ́n mi obìnrin tó ń jẹ́ Caroline àti Akif ọkọ rẹ̀ kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kì í ṣe inú ẹ̀sìn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ọkọ ẹ̀gbọ́n mi yìí dàgbà sí, ìgbà tó ti dàgbà ló ṣẹ̀ṣẹ̀ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Èrò mi ni pé nítorí ìgbésí ayé tí Akif ti gbé sẹ́yìn, ìyẹn á jẹ́ kó ṣeé ṣe
fún mi láti bá a sọ ohun tó wà lọ́kàn mi fàlàlà, nítorí ẹni tí màá lè bá sọ̀rọ̀ fàlàlà ni mo fẹ́.Mo mọ̀ pé ìgbésí ayé tí mò ń gbé kò yẹ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ nígbà tí mo kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ìwà yẹn, èrò mi ni pé ọ̀rọ̀ ìgbésí ayé mi kò kan ẹnì kankan. Àmọ́ ohun tí mo kọ́ nínú Bíbélì jẹ́ kí n mọ̀ pé, ìwà mi kò múnú Jèhófà dùn. (Sáàmù 78:40, 41; Òwe 27:11) Mo tún wá rí i pé, ìgbésí ayé tí mo gbé kó ìbànújẹ́ bá àwọn míì náà.
Bí mo ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo wá rí àwọn ìdí tó bọ́gbọ́n mu tó fi yẹ́ kí n gbà pé Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, mo kẹ́kọ̀ọ́ ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nínú Bíbélì, tí gbogbo wọn sì ṣẹ láìkù síbì kan. Gbogbo nǹkan tí mo mọ̀ yìí jẹ́ kí n ṣàtúnṣe sí iyè méjì tí mo ní tẹ́lẹ̀.
Ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, èmi àtàwọn òbí mi lọ kí ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin tó ń ṣe iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè Jámánì. Orí mi wú nígbà tí mo rí bí ayọ̀ ẹ̀gbọ́n mi ṣe pọ̀ tó. Irú ayọ̀ tí mò ń fẹ́ gan-an nìyẹn! Inú mi tún dùn láti rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yòókù tó wà níbẹ̀ táwọn náà yọ̀ǹda ara wọn. Wọ́n yàtọ̀ pátápátá sí àwọn tá a jọ ń kóra wa kiri tẹ́lẹ̀ tó jẹ́ pé wọn kò mọ̀ ju fàájì lọ. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìgbà yẹn, mo gbàdúrà àtọkànwá sí Jèhófà, mo sì fi dá a lójú pé màá fi ìgbésí ayé mi jọ́sìn rẹ̀. Nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19], mo ṣe ìrìbọmi, mo sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ: Ní báyìí, ìgbésí ayé mi ti dára gan-an. Mò ń láyọ̀ bí mo ṣe ń fi Bíbélì kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, tí mò ń ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ̀ nípa Jèhófà àtàwọn ìlérí rẹ̀ fún ọjọ́ ọ̀la. Àwọn ìdílé mi pàápàá ti jàǹfààní, nítorí pé ọ̀rọ̀ mi kò tún kó ìdààmú ọkàn bá wọn mọ́.
Mo mọ̀ pé ohun tí mo ṣe sẹ́yìn kò dára, àmọ́ mi ò kì í fẹ́ máa ronú lórí àwọn nǹkan náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìdáríjì Jèhófà àti ìfẹ́ tó ní fún mi ni mò ń ronú lé lórí. Mo gbà pẹ̀lú ohun tó wà nínú ìwé Òwe 10:22 tó sọ pé: “Ìbùkún Jèhófà—èyíinì ni ohun tí ń sọni di ọlọ́rọ̀, kì í sì í fi ìrora kún un.”
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 12]
“A máa ń lọ sí oríṣiríṣi ibi àríyá, a máa ń ṣé ìṣekúṣe, a máa ń lo oògùn olóró, a sì máa ń mu ọtí àmujù”
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 13]
“Mo mọ̀ pé ohun tí mo ṣe sẹ́yìn kò dára, àmọ́ mi ò kì í fẹ́ máa ronú lórí àwọn nǹkan náà”