Kí Ló Lè Mú Kí Ìdílé Rẹ Jẹ́ Aláyọ̀?
Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Kí Ló Lè Mú Kí Ìdílé Rẹ Jẹ́ Aláyọ̀?
Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a béèrè àwọn ìbéèrè tó o ti lè máa ṣe kàyéfì nípa wọn, a sì tún sọ ibi tó o ti lè rí ìdáhùn wọn kà nínú Bíbélì rẹ. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti bá ẹ sọ̀rọ̀ lórí ohun tí àwọn ìdáhùn náà jẹ́.
1. Kí nìdí tí ìgbéyàwó tó bá òfin mu fi ṣe pàtàkì kí ìdílé tó lè jẹ́ aláyọ̀?
Jèhófà Ọlọ́run aláyọ̀ ló dá ìgbéyàwó sílẹ̀. Ìgbéyàwó tó bófin mu ṣe pàtàkì kí ìdílé tó lè jẹ́ aláyọ̀, nítorí pé yàtọ̀ sí pé ó máa jẹ́ kí àjọṣe tó dára wà láàárín tọkọtaya, ó tún máa jẹ́ kí wọ́n lè fi ìfọ̀kànbalẹ̀ tọ́ àwọn ọmọ wọn. Kí ni èrò Ọlọ́run nípa ìgbéyàwó? Ó fẹ́ kí tọkọtaya jọ wà títí láé, kí wọ́n sì fi orúkọ ìgbéyàwó wọn sílẹ̀ lọ́dọ̀ ìjọba. (Lúùkù 2:1-5) Ọlọ́run fẹ́ kí tọkọtaya jẹ́ olóòótọ́ sí ara wọn. (Hébérù 13:4) Jèhófà fàyè gba àwọn Kristẹni tó jẹ́ tọkọtaya láti kọ ara wọn sílẹ̀ kí wọ́n sì fẹ́ ẹlòmíì bí ọ̀kan lára wọn bá ṣe panṣágà.—Ka Mátíù 19:3-6, 9.
2. Báwo ló ṣe yẹ kí tọkọtaya máa ṣe sí ara wọn?
Jèhófà ṣẹ̀dá ọkùnrin àti obìnrin pé kí wọ́n máa ran ara wọn lọ́wọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 2:18) Ọkọ ni olórí ìdílé, ó sì yẹ kó mú ipò iwájú láti gbọ́ bùkátà ìdílé rẹ̀, kó sì tún kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run. Ó yẹ kó ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún aya rẹ̀, kó sì fi ara rẹ̀ jìn fún un. Tọkọtaya ní láti nífẹ̀ẹ́ ara wọn kí wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún ara wọn. Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé, ọkọ àti ìyàwó ló jẹ́ aláìpé, kí ìdílé tó lè jẹ́ aláyọ̀, wọ́n ní láti kọ́ bí èèyàn ṣe ń dárí jini.—Ka Éfésù 4:31, 32; 5:22-25, 33; 1 Pétérù 3:7.
3. Ṣé ó yẹ kó o fi ọkọ tàbí aya rẹ sílẹ̀ nítorí pé ìgbéyàwó yín kò fún ẹ láyọ̀?
Bí ìṣòro bá wà láàárín ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ, ẹ sapá láti máa fìfẹ́ hàn sí ara yín. (1 Kọ́ríńtì 13:4, 5) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò sọ pé, kí tọkọtaya fi ara wọn sílẹ̀ nítorí àwọn ìṣòro tí wọ́n bá ní. Àmọ́ ṣá o, nínú àwọn ipò tó le koko, Kristẹni kan lè pinnu bóyá ó bọ́gbọ́n mu kí òun fi ẹnì kejì òun sílẹ̀ fúngbà kan ná nítorí ìṣòro tàbí kí òun má ṣe bẹ́ẹ̀.—Ka 1 Kọ́ríńtì 7:10-13.
4. Ẹ̀yin ọmọ, kí ni Ọlọ́run fẹ́ fún yín?
Jèhófà fẹ́ kẹ́ ẹ láyọ̀. Ó fún yín ní ìmọ̀ràn tó dára jù lọ nípa bí ẹ ṣe lè gbádùn ìgbà ọ̀dọ́ yín. Ó fẹ́ kẹ́ ẹ jàǹfààní látinú ọgbọ́n àti ìrírí táwọn òbí yín ní. (Kólósè 3:20) Inú Jèhófà máa ń dùn tí ẹ bá ṣe gbogbo ohun tí ẹ lè ṣe láti fi ìyìn fún un.—Ka Oníwàásù 11:9–12:1; Mátíù 19:13-15; 21:15, 16.
5. Ẹ̀yin òbí, kí làwọn ọmọ yín nílò kí wọ́n lè láyọ̀?
Ẹ ní láti ṣiṣẹ́ kára láti pèsè oúnjẹ, ibùgbé àti aṣọ fún àwọn ọmọ yín. (1 Tímótì 5:8) Àmọ́ kí àwọn ọmọ yín tó lè ní ayọ̀, ẹ tún ní láti kọ́ wọn láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀. (Éfésù 6:4) Àpẹẹrẹ tẹ́ ẹ fi lélẹ̀ nípa bí ìfẹ́ tí ẹ̀yin fúnra yín ní fún Ọlọ́run ṣe jinlẹ̀ tó máa ní ipa rere lórí àwọn ọmọ yín. Tí àwọn ìmọ̀ràn tí ẹ̀ ń fún àwọn ọmọ yín bá jẹ́ látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí á ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní èrò tó dáa.—Ka Diutarónómì 6:4-7; Òwe 22:6.
Ó máa ṣe àwọn ọmọ yín láǹfààní tẹ́ ẹ bá ń fún wọn níṣìírí tẹ́ ẹ sì ń gbóríyìn fún wọn. Wọ́n tún nílò ìtọ́sọ́nà àti ìbáwí. Àwọn nǹkan yìí máa dáàbò bò wọ́n kúrò lọ́wọ́ ìwà tó lè mú kí wọ́n pàdánù ayọ̀ wọn. (Òwe 22:15) Àmọ́ ṣá o, kò yẹ kí ẹ bá wọn wí lọ́nà líle koko tàbí lọ́nà rírorò.—Ka Kólósè 3:21.
Onírúurú ìwé làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣe láti ran àwọn òbí àtàwọn ọmọ wọn lọ́wọ́. Àwọn ìwé náà sì dá lórí Bíbélì.—Ka Sáàmù 19:7, 11.
Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka orí 14 nínú ìwé yìí, Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.