Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Kí nìdí tí àwọn tó ń pààrọ̀ owó fi wà nínú tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù?
▪ Nígbà tó kù díẹ̀ kí Jésù kú, ó sọ̀rọ̀ nípa ìwà ìrẹ́jẹ tó bùáyà tó ń ṣẹlẹ̀ nínú tẹ́ńpìlì. Bíbélì ròyìn pé: “Jésù . . . lé gbogbo àwọn tí ń tà, tí wọ́n sì ń rà nínú tẹ́ńpìlì síta, ó sì sojú tábìlì àwọn olùpààrọ̀ owó dé àti bẹ́ǹṣì àwọn tí ń ta àdàbà. Ó sì wí fún wọn pé: “A ti kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ilé mi ni a óò máa pè ní ilé àdúrà,’ ṣùgbọ́n ẹ ń sọ ọ́ di hòrò àwọn ọlọ́ṣà.’”—Mátíù 21:12, 13.
Ní ọ̀gọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe Júù máa ń rìnrìn àjò láti ọ̀pọ̀ ilẹ̀ àti ìlú ńlá wá sí tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì máa ń mú ẹyọ owó tí wọ́n ń ná ní ìlú wọn dání. Ṣùgbọ́n, irú owó kan wà tí wọ́n fẹ́ kí wọ́n máa fi san owó orí ọdọọdún ní tẹ́ńpìlì, kí wọ́n máa fi ra ẹran ìrúbọ, kí wọ́n sì máa fi ṣe ọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe. Nítorí náà, àwọn tó ń pààrọ̀ owó máa ń gba iye owó kan tí wọ́n bá ti bá àwọn èèyàn pààrọ̀ owó ìlú wọn sí irú owó tí wọ́n ń ná ní tẹ́ńpìlì náà. Bí àwọn àjọyọ̀ àwọn Júù bá ti ń sún mọ́lé, àwọn tó ń pààrọ̀ owó máa ń gbé káńtà ọjà wọn sínú tẹ́ńpìlì ní Àgbàlá àwọn Kèfèrí.
Bí Jésù ṣe bá àwọn tó ń pààrọ̀ owó wí pé wọ́n ti sọ tẹ́ńpìlì di “hòrò àwọn ọlọ́ṣà” fi hàn kedere pé iye tí wọ́n ń gbà lọ́wọ́ àwọn tó fẹ́ pààrọ̀ owó ti pọ̀ jù.
Kí nìdí tí igi ólífì fi wúlò gan-an ní àkókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì?
▪ Igi ólífì àti ọgbà àjàrà wà lára ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa fún àwọn èèyàn òun tí wọ́n bá jẹ́ olóòótọ́ sí òun. (Diutarónómì 6:10, 11) Títí dòní yìí, igi ólífì ṣì wúlò gan-an fún àwọn èèyàn ní àwọn ilẹ̀ ibi tí igi náà wà. Igi náà kì í gba ìtọ́jú tó pọ̀, ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún ló sì fi máa ń so èso. Àní igi náà lè mú èso tó pọ̀ jáde lórí ilẹ̀ olókùúta, ó sì lè dàgbà ní ilẹ̀ tí kì í fi bẹ́ẹ̀ sí omi pàápàá. Tí wọ́n bá gé igi náà tàbí tó bá wó ṣubú, gbòǹgbò rẹ̀ lè yọ ẹ̀tun tó máa di àwọn ẹ̀ka ńlá.
Ní àkókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, wọ́n máa ń fi èèpo àti ewé igi ólífì ṣe oògùn ibà. Oje tó ń jáde látara àwọn ẹ̀ka tọ́jọ́ rẹ̀ ti pẹ́ tó sì ní òórùn dídùn ni wọ́n fi máa ń ṣe lọ́fíńdà. Àmọ́, ohun pàtàkì tí igi náà wà fún ni oúnjẹ, ìyẹn àwọn èso rẹ̀, pàápàá jù lọ, òróró rẹ̀. Kìkìdá òróró ni ìdajì èso ólífì tó bá ti pọ́n.
Igi ólífì kan tó ṣe dáadáa lè mú ohun tí ó tó gálọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún òróró jáde lọ́dún, ìyẹn nǹkan bíi lítà mẹ́tàdínlọ́gọ́ta [57]. Wọ́n tún máa ń lo òróró ólífì fún epo àtùpà, wọ́n ń lo òróró ólífì fún ayẹyẹ àti ìjọsìn, wọ́n fi ń pa ara àti irun, wọ́n sì máa ń fi pa ojú ọgbẹ́ àti ara tó bó.—Ẹ́kísódù 27:20; Léfítíkù 2:1-7; 8:1-12; Rúùtù 3:3; Lúùkù 10:33, 34.