Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀yin Tọkọtaya, Ẹ Kọ́ Bí Ẹ Ṣe Jọ Máa Jẹ́ Ẹni Tẹ̀mí

Ẹ̀yin Tọkọtaya, Ẹ Kọ́ Bí Ẹ Ṣe Jọ Máa Jẹ́ Ẹni Tẹ̀mí

Ohun Tó Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀

Ẹ̀yin Tọkọtaya, Ẹ Kọ́ Bí Ẹ Ṣe Jọ Máa Jẹ́ Ẹni Tẹ̀mí

Frederick *: “Nígbà tá a kọ́kọ́ ṣe ìgbéyàwó, mo máa ń fi tipátipá mú ìyàwó mi pé kí á jọ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀. Mo máa ń rí sí i pé ó pọkàn pọ̀ nígbà tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́. Àmọ́ ìyàwó mi Leanne kì í jókòó jẹ́ẹ́. Tí mo bá sì béèrè ìbéèrè, bẹ́ẹ̀ ni tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́ ló máa ń dáhùn. Kì í dáhùn bí mo ṣe rò pé ó yẹ kó máa dáhùn nígbà tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”

Leanne: “Ọmọ ọdún méjìdínlógún ni mí nígbà tí mo fẹ́ Frederick ọkọ mi. A máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀ déédéé, àmọ́ Frederick máa ń lo àwọn àkókò yìí láti máa tọ́ka sí àwọn àṣìṣe mi àti bó ṣe yẹ kí n ṣàtúnṣe gẹ́gẹ́ bí aya. Èyí mú kí nǹkan sú mi gan-an, ó sì bà mí nínú jẹ́!”

KÍ LO rò pé ó fa ìṣòro tó wà láàárín Frederick àti Leanne ìyàwó rẹ̀? Èrò àwọn méjèèjì dáa. Àwọn méjèèjì nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Wọ́n sì rí i pé ó yẹ kí àwọn máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀. Àmọ́ ohun tó yẹ kó mú kí wọ́n wà níṣọ̀kan ló wá dàbí ohun tó fẹ́ da àárín wọn rú báyìí. Wọ́n máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀, àmọ́ àwọn méjèèjì kò tíì kọ́ láti jẹ́ ẹni tẹ̀mí.

Kí ló túmọ̀ sí láti jẹ́ ẹni tẹ̀mí? Kí nìdí tó fi yẹ kí tọkọtaya kọ́ láti jọ jẹ́ ẹni tẹ̀mí? Àwọn ìṣòro wo ni wọ́n lè ní bí wọ́n ṣe ń ṣe èyí, báwo sì ni wọ́n ṣe lè borí àwọn ìṣòro náà?

Kí Ló Túmọ̀ sí Láti Jẹ́ Ẹni Tẹ̀mí?

Ọ̀rọ̀ náà “ẹni tẹ̀mí” gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ ni pé, kéèyàn ní ìwà àti ìṣe tó fi hàn pé èèyàn mọyì àwọn ìlànà Ọlọ́run. (Júdà 18, 19) Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù tó jẹ́ ara àwọn tó kọ Bíbélì sọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìwà ẹni tẹ̀mí àti ẹni tí kì í ṣe ẹni tẹ̀mí. Ó sọ pé àwọn tí kì í ṣe ẹni tẹ̀mí máa ń ronú nípa ara wọn ju àwọn ẹlòmíì lọ. Dípò kí wọ́n máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run, ohun tó tọ́ lójú wọn ni wọ́n máa ń ṣe.—1 Kọ́ríńtì 2:14; Gálátíà 5:19, 20.

Àmọ́ àwọn ẹni tẹ̀mí yàtọ̀, nítorí pé wọ́n máa ń mọyì àwọn ìlànà Ọlọ́run. Wọ́n ka Jèhófà Ọlọ́run sí ọ̀rẹ́ wọn, wọ́n sì máa ń sapá láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ nínú ìwà wọn. (Éfésù 5:1) Nítorí náà, wọ́n máa ń fi ìfẹ́, inú rere àti ìwà pẹ̀lẹ́ hùwà sí àwọn èèyàn. (Ẹ́kísódù 34:6) Wọ́n tún máa ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run, kódà nígbà tí kò bá rọrùn fún wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀ pàápàá. (Sáàmù 15:1, 4) Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Darren tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Kánádà tí ó ti gbéyàwó fún ọdún márùndínlógójì [35] sọ pé, “Bí ọ̀rọ̀ náà ṣe yé mi ni pé, ẹni tẹ̀mí máa ń fìgbà gbogbo ronú lórí ipa tí ọ̀rọ̀ ẹnu àti ìṣe rẹ̀ máa ní lórí àjọṣe òun pẹ̀lú Ọlọ́run.” Jane ìyàwó rẹ̀ fi kún un pé: “Obìnrin tó jẹ́ ẹni tẹ̀mí lẹni tí á máa ṣiṣẹ́ kára lójoojúmọ́ láti máa fi èso ẹ̀mí Ọlọ́run ṣèwà hù.”—Gálátíà 5:22, 23.

Òótọ́ ni pé, kò yẹ kó dìgbà téèyàn ṣègbéyàwó kó tó máa hùwà tó fi hàn pé òun mọyì àwọn ìlànà Ọlọ́run. Kódà, Bíbélì sọ pé ojúṣe ẹnì kọ̀ọ̀kan ló jẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run kó sì máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀.—Ìṣe 17:26, 27.

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí Tọkọtaya Kọ́ Bí Wọ́n Ṣé Jọ Máa Jẹ́ Ẹni Tẹ̀mí?

Kí wá nìdí tó fi yẹ kí tọkọtaya sapá láti jọ jẹ́ ẹni tẹ̀mí? Gbé àpèjúwe yìí yẹ̀ wò, àwọn méjì pawọ́ pọ̀, wọ́n fẹ́ dáko sórí ilẹ̀ kan ṣoṣo, wọ́n sì fẹ́ gbin ewébẹ̀ sórí ilẹ̀ náà. Ọ̀kan lára wọn ní káwọn fún irúgbìn sóko náà ní àkókò kan pàtó nínú ọdún, àmọ́ ẹnì kejì sọ pé rárá kò tí ì yá. Ọ̀kan fẹ́ lo irú oríṣi ajílẹ̀ kan, àmọ́ ẹnì kejì kọ̀ jálẹ̀ pé ewébẹ̀ náà kò nílò ajílẹ̀ rárá. Ọ̀kan fẹ́ràn láti máa ṣiṣẹ́ àṣekára nínú oko náà lójoojúmọ́. Àmọ́ ẹnì kejì fẹ́ràn láti jókòó, kó sì máa wòran dípò kó ṣiṣẹ́. Nínú àpèjúwe yìí, òótọ́ ni pé oko yìí lè ṣe dáadáa dé ìwọ̀n àyè kan, àmọ́ á ṣe dáadáa jù bẹ́ẹ̀ lọ ká ní àwọn méjèèjì fìmọ̀ ṣọ̀kan lórí ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe, tí wọ́n sì jọ ṣe é kí ọwọ́ wọn lè tẹ ohun tí wọ́n fẹ́.

Nínú àpèjúwe yìí, tọkọtaya ló dàbí àwọn méjì tí wọ́n jọ dáko. Bí ọ̀kan lára wọn bá jẹ́ ẹni tẹ̀mí, ìyẹn lè mú kí àjọṣe wọn dára. (1 Pétérù 3:1, 2) Àmọ́, ẹ wo bó ṣe máa túbọ̀ dára tó nígbà tí àwọn méjèèjì bá gbà láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run nínú ìgbésí ayé wọn tí wọ́n sì ń sapá láti ran ara wọn lọ́wọ́ bí wọ́n ṣe ń sin Ọlọ́run! Sólómọ́nì Ọba sọ pé, “Ẹni méjì sàn ju ẹnì kan.” Kí nìdí? Ìdí ni pé: “Wọ́n ní ẹ̀san rere fún iṣẹ́ àṣekára wọn. Nítorí bí ọ̀kan nínú wọn bá ṣubú, èkejì lè gbé alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ dìde.”—Oníwàásù 4:9, 10.

Ó dájú pé wàá fẹ́ kí ìwọ àti ẹnì kejì rẹ jẹ́ ẹni tẹ̀mí. Kí ire oko tó lè ṣe dáadáa, yàtọ̀ sí ríronú ohun téèyàn fẹ́ ṣe sí oko náà, èèyàn tún ní láti ṣe ohun náà. Ṣàgbéyẹ̀wò ìṣòro méjì tó o lè ní àti bó o ṣe lè borí wọn.

ÌṢÒRO 1: Kò sí àyè rárá. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Sue tó ṣẹ̀ṣẹ̀ lọ sí ilé ọkọ sọ pé, “Aago méje ìrọ̀lẹ́ ni ọkọ mi máa ń wá gbé mi ní ibi iṣẹ́. Tá a bá délé, iṣẹ́ ilé wà tá a máa ṣe. Kò rọrùn rárá, nítorí pé lọ́kàn wa lọ́hùn-ún, a mọ̀ pé ó yẹ ká wá àyè láti máa kẹ́kọ̀ọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pa pọ̀, àmọ́ ara wa ń fẹ́ ìsinmi.”

Ojútùú: Mú ara rẹ bá ipò tó o wà mu kó o sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀. Sue sọ pé: “Èmi àti ọkọ mi pinnu láti máa tètè jí ní àárọ̀ kùtùkùtù ká lè jọ jíròrò apá kan nínú Bíbélì ká tó lọ sí ibi iṣẹ́. Ọkọ mi tún máa ń bá mi ṣe àwọn iṣẹ́ ilé kan, èyí sì máa ń jẹ́ kí n rí àkókò tí mo máa lò pẹ̀lú rẹ̀.” Àǹfààní wo ni wọ́n rí látinú ìsapá tí wọ́n ṣe yìí? Ed ọkọ Sue sọ pé: “Mo ti rí i pé, láti ìgbà tí èmi àti Sue ti ń jíròrò ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pa pọ̀ déédéé, ó ti mú kó rọrùn fún wa láti máa yanjú àwọn ìṣòro wa, ó sì tún mú kí á dín àníyàn wa kù.”

Yàtọ̀ sí bíbá ara yín sọ̀rọ̀, ó tún ṣe pàtàkì láti máa lo àkókò díẹ̀ lójoojúmọ́ láti máa gbàdúrà pa pọ̀. Ìrànlọ́wọ́ wo ni ìyẹn lè ṣe? Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ryan tó ti ṣe ìgbéyàwó lọ́dún mẹ́rìndínlógún sẹ́yìn sọ pé: “Lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn, àjọṣe àárín èmi àti ìyàwó mi kò dán mọ́rán. Àmọ́ a wá àkókò láti jọ máa gbàdúrà pa pọ̀ ní alaalẹ́, a máa ń fi àkókò yìí sọ ẹ̀dùn ọkàn wa fún Ọlọ́run. Mo rí i pé gbígbàdúrà pa pọ̀ ti ràn wá lọ́wọ́ láti yanjú àwọn ìṣòro wa, a sì wá pa dà láyọ̀.”

GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Ẹ ya àkókò díẹ̀ sọ́tọ̀ ní òpin ọjọ́ kọ̀ọ̀kan láti fi sọ àwọn nǹkan dáadáa tó ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀yín méjèèjì, tí ẹ lè torí rẹ̀ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run. Ẹ tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣòro tẹ́ ẹ ní, ní pàtàkì èyí tẹ́ ẹ fẹ́ kí Ọlọ́run ràn yín lọ́wọ́ láti borí. Àkíyèsí: Ẹ má ṣe lo àkókò yìí láti máa ka àwọn àṣìṣe ọkọ tàbí aya yín. Kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà tẹ́ ẹ bá ń gbàdúrà pa pọ̀, kìkì ohun tó yẹ kí ẹ̀yín méjèèjì jọ ṣàtúnṣe rẹ̀ ni kẹ́ ẹ mẹ́nu kàn. Tó bá sì di ọjọ́ kejì, ẹ ṣiṣẹ́ lórí ohun tí ẹ gbàdúrà nípa rẹ̀.

ÌṢÒRO 2: A kò lẹ́bùn kan náà. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Tony sọ pé: “Kì í yá mi lára láti gbé ìwé kí n jókòó kí n sì máa kà á.” Ìyàwó rẹ̀ tó ń jẹ́ Natalie, sọ pé: “Mó fẹ́ràn láti máa kàwé, mó sì fẹ́ràn kí n máa sọ ohun tí mo kà fún àwọn èèyàn. Nígbà míì, mo máa ń kíyè sí pé ẹ̀rù máa ń ba ọkọ mi láti bá mi sọ̀rọ̀ nígbà tá a bá ń jíròrò Bíbélì.”

Ojútùú: Jẹ́ olùrànlọ́wọ́, má ṣe jẹ́ abánidíje tàbí alárìíwísí. Máa gbóríyìn fún ẹnì kejì rẹ kó o sì máa fún un ní ìṣírí lórí àwọn ìsapá rẹ̀. Tony sọ pé: “Bí ìyàwó mi ṣe máa ń fi ìtara jíròrò Bíbélì máa ń súni nígbà míì, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kó nira fún mi tẹ́lẹ̀ láti máa jíròrò ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pẹ̀lú rẹ̀. Àmọ́, Natalie ìyàwó mi ràn mí lọ́wọ́ gan-an ni. Ní báyìí, a ti jọ ń jíròrò ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, mo sì ti wá rí i pé kò sídìí láti máa bẹ̀rù. Mo máa ń gbádùn ìjíròrò ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pẹ̀lú rẹ̀. Èyí ti mú kí ara túbọ̀ tù wá, a sì ń gbé ní àlàáfíà.”

Ọ̀pọ̀ tọkọtaya ló rí i pé àárín wọn túbọ̀ ń dára sí i nígbà tí wọ́n ya àkókò sọ́tọ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti fi ka Bíbélì kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Àmọ́ ṣá o, àkíyèsí kan rèé: Tẹ́ ẹ bá kẹ́kọ̀ọ́ ohun kan, ńṣe ni kó o sọ bí ìwọ ṣe lè fi ohun náà sílò nígbèésí ayé rẹ, kì í ṣe bí ẹnì kejì rẹ ṣe lè fi í sílò. (Gálátíà 6:4) Àkókò mìíràn ni kẹ́ ẹ máa jíròrò àwọn èdèkòyédè tẹ́ ẹ ní, kì í ṣe àkókò tí ẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́. Kí nìdí?

Àpèjúwe kan rèé: Tí ìwọ àti ìdílé rẹ bá ń jẹun, ṣe àkókò yẹn ni wàá máa tọ́jú egbò tó ti kẹ̀? Kò dájú pé wàá ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí pé tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá jẹ́ kí oúnjẹ náà sú wọn. Jésù fi kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run àti ṣíṣe ìfẹ́ rẹ̀ wé oúnjẹ jíjẹ. (Mátíù 4:4; Jòhánù 4:34) Tó bá jẹ́ pé gbogbo ìgbà tẹ́ ẹ bá ṣí Bíbélì lo máa ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tí kò dáa tí ẹnì kejì rẹ ṣe, wàá mú kí kíkẹ́kọ̀ọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sú u. Òótọ́ ni pé, ó yẹ kẹ́ ẹ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣòro tẹ́ ẹ ní. Àmọ́ àkókò tẹ́ ẹ yà sọ́tọ̀ fún irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ni kẹ́ ẹ jíròrò wọn.—Òwe 10:19; 15:23.

GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Ṣàkọsílẹ̀ ìwà méjì tàbí mẹ́ta tí ẹnì kejì rẹ ní tó o mọyì gan-an. Nígbà míì tẹ́ ẹ bá jíròrò ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó jẹ mọ́ àwọn ìwà náà, jẹ́ kí ẹnì kejì rẹ mọ bó o ṣe mọyì àwọn ìwà náà tó.

Ohun Tó O Bá Gbìn Lo Máa Ká

Tí ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ bá sapá láti ní àwọn ìwà àti ìṣe tó fi hàn pé ẹ mọyì àwọn ìlànà Ọlọ́run, ẹ óò túbọ̀ ní àlàáfíà àti ìbàlẹ̀ ọkàn nínú ìgbéyàwó yín. Kódà, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi dá wá lójú pé, “ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni yóò ká.”—Gálátíà 6:7.

Frederick àti Leanne, tá a fa ọ̀rọ̀ wọn yọ ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí rí i pé òtítọ́ ni ìlànà Bíbélì yìí. Ní báyìí, ó ti tó ọdún márùndínláàádọ́ta [45] tí wọ́n ti ṣègbéyàwó, wọ́n sì ti jàǹfààní tó pọ̀ látinú bí wọ́n ṣe ń ran ara wọn lọ́wọ́ láti jẹ́ ẹni tẹ̀mí. Frederick sọ pé: “Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, mo máa ń fẹ̀sùn kan ìyàwó mi pé kì í bá mi sọ̀rọ̀ dáadáa. Àmọ́ nígbà tó yá, mo rí i pé ó yẹ kí n ṣe nǹkan kan nípa ọ̀rọ̀ náà.” Leanne sọ pé: “Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà Ọlọ́run ni ohun tó ràn wá lọ́wọ́ láwọn àkókò líle koko yẹn. Ní gbogbo àwọn ọdún yẹn, a máa ń kẹ́kọ̀ọ́ pa pọ̀ a sì máa ń gbàdúrà pa pọ̀ déédéé. Bí mo ti ń rí i pé Frederick ń sapá láti máa hùwà tó yẹ Kristẹni, èyí mú kó rọrùn fún mi láti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.”

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ A ti yí àwọn orúkọ náà pa dà.

BI ARA RẸ PÉ . . .

▪ Ìgbà wo ni èmi àti ọkọ tàbí aya mi gbàdúrà pa pọ̀ kẹ́yìn?

▪ Kí ni mo lè ṣe tó máa fún ẹnì kejì mi ní ìṣírí tí á fi máa sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ nígbà tá a bá ń sọ̀rọ̀ Ọlọ́run?