Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìgbà Wo Ni Wọ́n Pa Jerúsálẹ́mù Àtijọ́ Run?—Apá Kejì

Ìgbà Wo Ni Wọ́n Pa Jerúsálẹ́mù Àtijọ́ Run?—Apá Kejì

Ìgbà Wo Ni Wọ́n Pa Jerúsálẹ́mù Àtijọ́ Run?​—Apá Kejì

Àwọn Ẹ̀rí Tá A Rí Nínú Àwọn Wàláà Alámọ̀

Àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ìkejì lára àpilẹ̀kọ tó jáde tẹ̀ léra nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́, wọ́n dáhùn àwọn ìbéèrè tó jinlẹ̀ nípa ìgbà tí wọ́n kọ́kọ́ pa Jerúsálẹ́mù àtijọ́ run. Àpilẹ̀kọ méjì yìí sọ àwọn ìdáhùn tí a ti ṣèwádìí wọ́n dáadáa tá a sì gbé karí Bíbélì, wọ́n sì dáhùn àwọn ìbéèrè tó ti rú àwọn kan tó ń ka ìwé wa lójú.

Apá Kìíní Gbé Àwọn Kókó Yìí Jáde:

▪ Àwọn òpìtàn ayé máa ń sọ pé ọdún 587 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run.

▪ Ìṣirò àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì fi hàn pé ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run.

▪ Àwọn òpìtàn ayé gbé èrò wọn ka ìwé àwọn òpìtàn ayé àtijọ́ àti àkọsílẹ̀ Ptolemy.

▪ Àwọn àṣìṣe ńlá wà nínú àwọn ìwé táwọn òpìtàn ayé àtijọ́ kọ, wọn kì í sì í fìgbà gbogbo bá àwọn àkọsílẹ̀ inú àwọn wàláà alámọ̀ mu. *

BÍBÉLÌ sọ pé àwọn Júù tí wọ́n kó lẹ́rú máa wà nígbèkùn Bábílónì “titi adọrin ọdun yio fi pé,” láti “mu ọ̀rọ Oluwa ṣẹ lati ẹnu Jeremiah.” Ìgbà wo ni Bábílónì dá wọn sílẹ̀? Ó jẹ́ ní “ọdún kini [ìgbà ìṣàkóso] Kirusi, ọba Persia.” (2 Kíróníkà 36:21, 22, Bibeli Mimọ) Ìtàn inú Bíbélì àti èyí tí kì í ṣe ti Bíbélì jẹ́rìí sí i pé ìgbèkùn àwọn Júù ní Bábílónì dópin lẹ́yìn tí Kírúsì ṣẹ́gun Bábílónì, tó sì dá àwọn Júù sílẹ̀, wọ́n sì pa dà sí Jerúsálẹ́mù lọ́dún 537 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Nítorí pé Bíbélì sọ kedere pé àádọ́rin [70] ọdún ni àwọn Júù fi wà ní ìgbèkùn, wọ́n ti gbọ́dọ̀ wà ní ìgbèkùn náà láti ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni.

Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ jù lọ ọ̀mọ̀wé sọ pé ọdún 587 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni Jerúsálẹ́mù pa run. Èyí á mú kí ọdún tí wọ́n fi wà nígbèkùn náà jẹ́ àádọ́ta [50] ọdún péré. Kí nìdí tí wọ́n fi rò bẹ́ẹ̀? Wọ́n mú ìṣirò wọn látinú àwọn àkọsílẹ̀ wàláà àtijọ́ tó sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa Nebukadinésárì Kejì àtàwọn tó jọba tẹ̀ lé e.1 Àwọn tó gbé láyé nígbà tí Jerúsálẹ́mù pa run tàbí kété lẹ́yìn ìgbà yẹn ló kọ ọ̀pọ̀ lára àwọn àkọsílẹ̀ yìí. Àmọ́, ǹjẹ́ ìṣirò tó sọ pé ọdún 587 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run ṣeé gbára lé? Ẹ̀rí wo la nínú àwọn àkọsílẹ̀ náà?

Láti dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, ṣàgbéyẹ̀wò oríṣi àkọsílẹ̀ mẹ́ta táwọn ọ̀mọ̀wé sábà máa ń lò: (1) Àwọn wàláà tí wọ́n kọ ìtàn Bábílónì sí, (2) àwọn wàláà tí wọ́n fi ṣàkọsílẹ̀ ọrọ̀ ajé, àti (3) àwọn wàláà tó ní àkọsílẹ̀ nípa àwọn nǹkan tó wà ní ojú ọ̀run.

Àwọn wàláà tí wọ́n kọ ìtàn Bábílónì sí.

Kí ni wọ́n jẹ́? Àwọn wàláà tí wọ́n kọ ìtàn Bábílónì sí jẹ́ ọ̀wọ́ àwọn wàláà tí wọ́n fi ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì tó wáyé ní Bábílónì.2

Kí ni àwọn ọ̀mọ̀wé sọ? Ọ̀gbẹ́ni R. H. Sack, tó jẹ́ òléwájú nínú ìmọ̀ nípa àwọn àkọsílẹ̀ wàláà sọ pé àwọn wàláà tí wọ́n kọ ìtàn Bábílónì sí kò ní àkọsílẹ̀ gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì. * Ó sọ pé àwọn òpìtàn ní láti lọ wo “àwọn àkọsílẹ̀ míì . . . kí wọ́n tó lè mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an.”

Kí ni àwọn àkọsílẹ̀ náà sọ? Àwọn àlàfo kan wà nínú ìtàn tó wà nínú àwọn wàláà tí wọ́n kọ ìtàn Bábílónì sí.3 (Wo  àpótí tó wà nísàlẹ̀ yìí.) Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu kéèyàn béèrè pé, Ṣé ó yẹ kéèyàn gbára lé ìpinnu tí wọ́n ṣe látinú irú àkọsílẹ̀ tí kò pé yìí?

Àwọn wàláà tí wọ́n fi ṣàkọsílẹ̀ ọrọ̀ ajé.

Kí ni wọ́n jẹ́? Ọ̀pọ̀ jù lọ wàláà tí wọ́n fi ṣàkọsílẹ̀ ọrọ̀ ajé nígbà ìṣàkóso Ilẹ̀ Ọba Bábílónì Ẹlẹ́ẹ̀kejì jẹ́ rìsíìtì tó bófin mu. Wọ́n máa ń kọ ọjọ́, oṣù àti ọdún tí ọba tó wà lórí ìtẹ́ ń ṣàkóso sínú àwọn wàláà náà. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n fi wàláà kan ṣe rìsíìtì ọjà ní “Nísàn 27, ọdún kọkànlá ìgbà ìjọba Nebukadinésárì [tí wọ́n mọ̀ sí Nebukadinésárì Kejì], ọba Bábílónì.”4

Nígbà tí ọba kan bá kú tàbí nígbà tí wọ́n bá mú un kúrò lórí ìtẹ́, tí ọba tuntun sì gorí ìtẹ́, àwọn oṣù tó ṣẹ́ kù nínú ọdún tí ọba àtijọ́ kúrò ni wọ́n kà sí ọdún tí ọba tuntun gorí ìtẹ́. *5 Kí á sọ ọ́ lọ́nà míì, gẹ́gẹ́ bí kàlẹ́ńdà Bábílónì ṣe sọ, ọdún tí ọba kan kúrò lórí ìtẹ́ ni ọba míì máa ń bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso. Bó ṣe yẹ kó rí ni pé àwọn wàláà tí wọ́n fi ṣàkọsílẹ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọdún tí ọba tuntun bọ́ sípò yẹ kó ní déètì àwọn oṣù tó tẹ̀ lé oṣù tí ọba ti tẹ́lẹ̀ parí ìjọba rẹ̀.

Kí ni àwọn ọ̀mọ̀wé sọ? Ọ̀gbẹ́ni R. H. Sack ṣàyẹ̀wò ọ̀pọ̀ wàláà tí wọ́n fi ṣàkọsílẹ̀ ọrọ̀ ajé ní ìgbà ìṣàkóso Ilẹ̀ Ọba Bábílónì Ẹlẹ́ẹ̀kejì. Lọ́dún 1972, Ọ̀gbẹ́ni Sack sọ pé àwọn wàláà tó ní àwọn ọ̀rọ̀ tí ẹnikẹ́ni kò tíì sọ nǹkan kan nípa rẹ̀ wà ní ìkáwọ́ òun, Ibi Ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ló ni ín, àwọn wàláà náà sì fi hàn pé “irọ́ pátápátá” ni èrò tó wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀ nípa àkókò tí ìṣàkóso ti ọwọ́ Nebukadinésárì Kejì bọ́ sí ọwọ́ ọmọkùnrin rẹ̀ Amel-Marduk (tí wọ́n tún mọ̀ sí Evil-merodach).6 Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Ọ̀gbẹ́ni Sack ti mọ̀ pé àwọn wàláà sọ pé Nebukadinésárì Kejì ló ṣì ń jọba ní oṣù kẹfà ọdún tó gbẹ̀yìn nínú ọdún tó fi jọba (ìyẹn ọdún kẹtàlélógójì [43] ìgbà ìjọba rẹ̀). Àmọ́, àwọn wàláà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ ọ̀rọ̀ inú wọn, tó ní àkọsílẹ̀ ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọdún tí Amel-Marduk tó jọba tẹ̀ lé bàbá rẹ̀ gorí ìtẹ́ sọ pé, oṣù kẹrin àti oṣù karùn-ún ọdún kan náà yẹn ni ọmọ náà jọba.7 Ó ṣe kedere pé ìtakora wà nínú ohun tí wọ́n sọ náà.

Kí ni àwọn àkọsílẹ̀ sọ? Àwọn ìtakora míì tún wà nínú àkókò tí wọ́n sọ pé ìṣàkóso ti ọwọ́ ọba kan bọ́ sí ọwọ́ ọba mìíràn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn àkọsílẹ̀ sọ pé ní ọdún tó kẹ́yìn ìgbà ìjọba Nebukadinésárì Kejì, ó ṣì ń ṣàkóso ní oṣù kẹwàá ọdún náà, ìyẹn jẹ́ oṣù kẹfà lẹ́yìn tí ẹni tí wọ́n gbà pé ó gbapò rẹ̀ ti ń jọba.8 Ìtakora tó jọ irú èyí tún wà nínú àkókò tí ìṣàkóso ti ọwọ́ Amel-Marduk bọ́ sí ọwọ́ Neriglissar, tó gbapò rẹ̀.9

Kí nìdí tí àwọn ìtakora yìí fi yẹ fún àfiyèsí? Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ní ìbẹ̀rẹ̀, àwọn àlàfo tó wà nínú ìtàn tó wà nínú àwọn wàláà tí wọ́n kọ ìtàn Bábílónì sí fi hàn pé a lè má mọ bí àwọn ọba náà ṣe ṣàkóso ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé.10 Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí àwọn ọba míì ti ṣàkóso ṣáájú tàbí lẹ́yìn àwọn ọba yìí? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, a máa ní láti fi àwọn ọdún míì kún àkókò ìṣàkóso Ilẹ̀ Ọba Bábílónì Ẹlẹ́ẹ̀kejì nìyẹn. Nítorí náà, àwọn wàláà tí wọ́n kọ ìtàn Bábílónì sí àti àwọn wàláà tí wọ́n fi ṣàkọsílẹ̀ ọrọ̀ ajé kò ní ẹ̀rí tí ó tó láti fi hàn pé ọdún 587 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run. *

Àwọn wàláà tó ní àkọsílẹ̀ nípa àwọn nǹkan tó wà ní ojú ọ̀run.

Kí ni wọ́n jẹ́? Wọ́n jẹ́ àwọn wàláà tí wọ́n fi ṣàlàyé ibi tí oòrùn, òṣùpá, àwọn pílánẹ́ẹ̀tì àti ìràwọ̀ wà sí ara wọn, tí wọ́n sì tún ní ìtàn nípa ọdún tí ọba kan ní pàtó fi jọba. Bí àpẹẹrẹ, àkọ́sílẹ̀ nípa àwọn nǹkan ojú ọ̀run tó wà nínú àwòrán ojú ìwé yìí ṣàfihàn ìgbà tí ọ̀sán dòru ní oṣù kìíní ọdún kìíní ìgbà ìjọba Mukin-zeri Ọba.11

Kí ni àwọn ọ̀mọ̀wé sọ? Àwọn ọ̀mọ̀wé gbà pé àwọn ará Bábílónì ti ṣe àwọn àtẹ ìsọfúnni nípa àwọn nǹkan ojú ọ̀run láti fi ṣírò ìgbà tó ṣeé ṣe jù lọ kí ọ̀sán dòru.12

Àmọ́, ǹjẹ́ àwọn ará Bábílónì lè ṣírò rẹ̀ pa dà sẹ́yìn láti mọ àwọn ìgbà tí ọ̀sán dòru láwọn ìgbà tó ti kọjá sẹ́yìn? Ọ̀jọ̀gbọ́n John Steele sọ pé, “Nígbà tí wọ́n ń ṣe àtẹ ìsọfúnni náà, ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti lo ọgbọ́n tí wọ́n fi ń ṣírò ìgbà tí ọ̀sán máa dòru láti fi ka àwọn ọjọ́ náà pa dà sẹ́yìn tí wọ́n fi mọ díẹ̀ lára àwọn ìgbà àkọ́kọ́ tí ọ̀sán dòru láwọn ìgbà tó ti kọjá sẹ́yìn.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.)13 Ọ̀jọ̀gbọ́n David Brown, gbà pé àwọn ìgbà tí ọ̀sán máa dòru tí wọ́n ti ṣàkọsílẹ̀ wọn kété kí wọ́n tó ṣẹlẹ̀ wà nínú àtẹ ìsọfúnni nípa àwọn nǹkan ojú ọ̀run. Ó sọ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé “àwọn akọ̀wé òfin ni wọ́n ṣe ìṣírò yẹn pa dà sẹ́yìn ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin ṣáájú Sànmánì Kristẹni tàbí àwọn ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn láti fi mọ díẹ̀ lára àwọn ìgbà tí ọ̀sán dòru.”14 Tó bá jẹ́ pé wọ́n ka àwọn ìgbà tí ọ̀sán dòru náà pa dà sẹ́yìn ni, ṣé ó yẹ kéèyàn gbára lé wọn pátápátá láìsí ẹ̀rí míì tó tì wọ́n lẹ́yìn?

Ká tiẹ̀ sọ pé ọ̀sán dòru ní ọjọ́ kan pàtó, ṣe ìyẹn túmọ̀ sí pé nǹkan míì tí ẹni tó kọ wàláà náà sọ pé ó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn jóòótọ́? Ó lè máà rí bẹ́ẹ̀. Ọ̀mọ̀wé R. J. van der Spek sọ pé: “Àwọn awòràwọ̀ ló ṣe àwọn àkọsílẹ̀ náà, wọn kì í ṣe òpìtàn.” Ó ní, àwọn apá tí wọ́n kọ ìtàn sí nínú àwọn wàláà náà jẹ́ “ohun tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀,” ó sì sọ pé èèyàn gbọ́dọ̀ “ṣọ́ra tó bá fẹ́ lo” irú àwọn ìtàn bẹ́ẹ̀.15

Kí ni àwọn àkọsílẹ̀ sọ? Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò wàláà tí wọ́n pè ní VAT 4956. Ìlà àkọ́kọ́ nínú wàláà yìí sọ pé: “Ọdún kẹtàdínlógójì [37] ìjọba Nebukadinésárì ọba Bábílónì.”16 Lẹ́yìn náà, ó ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ibi tí òṣùpá àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì wà sí ibi tí oríṣiríṣi àwọn ìràwọ̀ àtàwọn àgbájọ ìràwọ̀ wà. Ó tún ní àkọ́sílẹ̀ nípa ìgbà kan ṣoṣo tí ọ̀sán dòru. Àwọn ọ̀mọ̀wé sọ pé gbogbo nǹkan wọ̀nyí ṣẹlẹ̀ ní ọdún 568 tàbí 567 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, èyí á wá jẹ́ ọdún kejìdínlógún ìgbà ìjọba Nebukadinésárì Kejì, ìyẹn ìgbà tí wọ́n sọ pé ó pa Jerúsálẹ́mù run ní ọdún 587 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Àmọ́, ṣé ọdún 568 tàbí 567 ṣáájú Sànmánì Kristẹni nìkan ni àkọsílẹ̀ nípa àwọn nǹkan ojú ọ̀run yìí tọ́ka sí pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé?

Wàláà náà sọ nípa ọ̀sán tó dòru tí wọ́n ṣírò pé ó ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù kẹta ti kàlẹ́ńdà Bábílónì, ìyẹn oṣù Simanu. Òótọ́ ni pé ọ̀sán dòru ní July 4, ọdún 568 ṣáájú Sànmánì Kristẹni (ìyẹn nínú kàlẹ́ńdà Julian) tó ṣe déédéé pẹ̀lú ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù kẹta ti kàlẹ́ńdà Bábílónì. Àmọ́, ní ogún ọdún ṣáájú ìgbà yẹn, ọ̀sán tún dòru ní July 15, ọdún 588 ṣáájú Sànmánì Kristẹni.17

Bí ọdún 588 ṣáájú Sànmánì Kristẹni bá jẹ́ ọdún kẹtàdínlógójì [37] ìgbà ìṣàkóso Nebukadinésárì Kejì, nígbà náà, ọdún kejìdínlógún ìgbà ìjọba rẹ̀ yóò jẹ́ ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ìyẹn ọdún tí àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì fi hàn pé wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run! (Wo  àkọsílẹ̀ ìgbà táwọn nǹkan ṣẹlẹ̀, èyí tó wà lójú ìwé yìí.) Àmọ́, ǹjẹ́ wàláà VAT 4956 fúnni ní ẹ̀rí síwájú sí i pé ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run?

Yàtọ̀ sí ìgbà tí ọ̀sán dòru tí wọ́n ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ sórí wàláà yìí, ó tún ní àkọsílẹ̀ ìgbà mẹ́tàlá tí wọ́n ṣàkíyèsí òṣùpá àti ìgbà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tí wọ́n ṣàkíyèsí pílánẹ́ẹ̀tì. Ìwọ̀nyí ṣàlàyé bí òṣùpá tàbí àwọn pílánẹ́ẹ̀tì ṣe wà sí àwọn ìràwọ̀ kan tàbí àwọn àgbájọ ìràwọ̀.18 Wọ́n tún pín àkókò tó wà láàárín ìgbà tí oòrùn ń yọ àti ìgbà tó ń wọ̀ sí ọ̀nà mẹ́jọ, bákan náà, wọ́n pín àkókò tó wà láàárín ìgbà tí òṣùpá ń yọ àti ìgbà tó ń wọ̀ sí ọ̀nà mẹ́jọ.18a

Nítorí pé àkókò tí òṣùpá máa ń yọ àti ìgbà tó máa ń wọ kì í yẹ̀, àwọn tó ń ṣèwádìí ti fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ ìgbà mẹ́tàlá tí wọ́n ṣàkíyèsí òṣùpá, èyí tó wà lórí wàláà VAT 4956. Kọ̀ǹpútà ni wọ́n fi ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ náà, kọ̀ǹpútà náà lè fi ibi tí àwọn nǹkan ojú ọ̀run wà ní ọjọ́ kan pàtó ní ìgbà tó ti kọjá hàn.19 Kí ni àyẹ̀wò wọn fi hàn? Nínú àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe lórí àkọsílẹ̀ náà, kì í ṣe gbogbo ìgbà mẹ́tàlá tí wọ́n ṣàkíyèsí òṣùpá ló bá ibi tí òṣùpá wà ní ọdún 568 tàbí 567 ṣáájú Sànmánì Kristẹni mu, àmọ́, gbogbo ìgbà mẹ́tàlá náà ló bá ibi tí òṣùpá wà ní ogún ọdún sẹ́yìn mu, ìyẹn ọdún 588 tàbí 587 ṣáájú Sànmánì Kristẹni.

Àkọsílẹ̀ tó wà láwọn ojú ìwé yìí ṣàfihàn ọ̀kan lára àwọn ibi tí òṣùpá wà, èyí tó bá ti ọdún 588 ṣáájú Sànmánì Kristẹni mú gan-an ju ti ọdún 568 ṣáájú Sànmánì Kristẹni lọ. Ìlà kẹta nínú wàláà náà sọ pé, òṣùpá wà ní ipò kan pàtó ní “alẹ́ ọjọ́ 9 [Nisanu].” Àmọ́ àwọn ọ̀mọ̀wé tí wọ́n kọ́kọ́ sọ pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé ní ọdún 568 ṣáájú Sànmánì Kristẹni (astronomical -567) gbà pé “Nisanu 8,” ọdún 568 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni òṣùpá wà ní ipò yẹn, “kì í ṣe Nisanu 9.” Láti lè tì í lẹ́yìn pé wàláà sọ pé ọdún 568 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni ohun náà ṣẹlẹ̀, wọ́n sọ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni akọ̀wé ṣèèṣì kọ “9” dípò “8.”20 Àmọ́ ní ìlà kẹta lórí wàláà náà, ibi tí òṣùpá wà bá ibi tí òṣùpá wà gan-gan ní Nisanu 9 ọdún 588 ṣáájú Sànmánì Kristẹni mu.21

Ó ṣe kedere pé, ọ̀pọ̀ lára ohun tó wà nínú wàláà VAT 4956 nípa àwọn nǹkan ojú ọ̀run bá ọdún 588 ṣáájú Sànmánì Kristẹni mu, ó sì fi hàn pé ó jẹ́ ọdún kẹtàdínlógójì [37] ìgbà ìṣàkóso Nebukadinésárì Kejì. Nítorí náà, èyí jẹ́rìí sí i pé ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ.

Kí Nìdí Tá A Fi Fọkàn Tán Bíbélì?

Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ọ̀pọ̀ jù lọ òpìtàn gbà pé ọdún 587 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run. Àmọ́, Jeremáyà àti Dáníẹ́lì tí wọ́n wà lára àwọn tó kọ Bíbélì sọ kedere pé, àádọ́rin [70] ọdún ni àwọn Júù fi wà nígbèkùn, kì í ṣe [50] àádọ́ta ọdún. (Jeremáyà 25:1, 2, 11; 29:10; Dáníẹ́lì 9:2) Àwọn ọ̀rọ̀ yẹn fẹ̀rí tó lágbára hàn pé ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí tí a gbé yẹ̀ wò lókè ti fi hàn, àwọn ẹ̀rí kan tó yàtọ̀ sí ti inú Bíbélì ti ọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn.

Àwọn ọ̀mọ̀wé ti sọ léraléra pé Bíbélì kò ṣeé gbára lé. Àmọ́, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ àwárí, ẹ̀rí máa ń fi hàn pé àkọ́sílẹ̀ inú Bíbélì jóòótọ́. * Àwọn tí wọ́n fọkàn tán Bíbélì ní ìdí pàtàkì tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀. Ìdí náà ni pé, wọ́n gbà pé ohun tí Bíbélì sọ nípa ìtàn, ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti àsọtẹ́lẹ̀ jóòótọ́. Ẹ̀rí yìí ló mú kí wọ́n gba ohun tí Bíbélì sọ pé Ọlọ́run ló mí sí Bíbélì. (2 Tímótì 3:16) O ò ṣe ṣèwádìí kó o lè rí ẹ̀rí yìí fúnra rẹ? Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, o lè wá rí i pé òótọ́ ni.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Àkíyèsí: Kò sí ọ̀kan lára àwọn ọ̀mọ̀wé tá a lo ọ̀rọ̀ wọn nínú àpilẹ̀kọ yìí tó gbà pé ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run.

^ Wọn kì í ka ọdún tí ọba tuntun gorí ìtẹ́ mọ́ ọdún tí ọba náà bá fi ṣàkóso, ńṣe ni wọ́n ka àwọn oṣù náà sí èyí tó ṣẹ́ kù nínú ọdún títí wọ́n fi máa fàṣẹ yan ọba tuntun sorí ìtẹ̀.

^ Àwọn wàláà tí wọ́n fi ṣàkọsílẹ̀ ọrọ̀ ajé wà fún gbogbo àwọn ọdún tí wọ́n sọ pé àwọn ọba Ilẹ̀ Ọba Bábílónì Ẹlẹ́ẹ̀kejì fi ṣàkóso. Nígbà tí wọ́n ṣe àròpọ̀ gbogbo iye ọdún tí àwọn ọba wọ̀nyí fi ṣàkóso, tí wọ́n wá kà á pa dà sẹ́yìn látọ̀dọ̀ Nábónídọ́sì tó ṣàkóso kẹ́yìn ní Ilẹ̀ Ọba Bábílónì Ẹlẹ́ẹ̀kejì, ọdún tí wọ́n sọ pé wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run yóò wá bọ́ sí ọdún 587 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Àmọ́ ohun tí wọ́n sọ yìí máa jóòótọ́ kìkì tí àwọn ọba náà bá jẹ tẹ̀ lé ara wọn ní ọdún kan náà láìsí àlàfo kankan láàárín wọn.

^ Wàá rí àwọn àpẹẹrẹ tó o bá ka orí 4 àti 5 nínú ìwé The Bible—God’s Word or Man’s? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Àpótí/Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 23]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

 ÀWỌN WÀLÁÀ TÍ WỌ́N KỌ ÌTÀN BÁBÍLÓNÌ SÍ—ÌTÀN TÓ NÍ ÀLÀFO NÍNÚ

Nǹkan bí ọdún méjìdínláàádọ́rùn-ún [88] ni wọ́n sọ pé Ilẹ̀ Ọba Bábílónì Ẹlẹ́ẹ̀kejì fi wà, àmọ́ kìkì ìtàn ọdún márùndínlógójì [35] lára ọdún yẹn ló wà nínú wàláà tí wọ́n kọ ìtàn Bábílónì sí.

ỌDÚN TÍ KÒ SÍ ÀKỌSÍLẸ̀ ÌTÀN

ỌDÚN TÍ ÀKỌSÍLẸ̀ ÌTÀN WÀ

BM 21901 BM 21946 BM 35382

ÌGBÀ ÌṢÀKÓSO ILẸ̀ ỌBA BÁBÍLÓNÌ ẸLẸ́Ẹ̀KEJÌ ÀWỌN ARÁ PÁṢÍÀ

Nabopolásárì Nebukadinésárì Kejì Amel-Marduk Nábónídọ́sì

Neriglissar Labashi-Marduk

BM 25127 BM 22047 BM 25124

[Àwọn Credit Line]

BM 21901 àti BM 35382: Fọ́tò nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda British Museum; BM 21946: Copyright British Museum; BM 22047, 25124, 25127: © The Trustees of the British Museum

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

ÀKỌSÍLẸ̀ NÍPA ÀWỌN NǸKAN OJÚ Ọ̀RUN TÓ WÀ NÍNÚ WÀLÁÀ BM 32238

Wàláà yìí ní àkọsílẹ̀ àwọn ìgbà tí ọ̀sán dòru, àmọ́ ẹ̀yìn nǹkan bí irínwó [400] ọdún tí ọ̀sán kan dòru ni wọ́n ṣẹ̀sẹ̀ wá ṣàkójọ àwọn ìgbà tó ti kọjá tí ọ̀sán dòru sínú wàláà yìí. Nígbà tó jẹ́ pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyẹn kò ṣojú òǹkọ̀wé náà, ó ṣeé ṣe kó ti lo ìṣirò láti pinnu àwọn ìgbà tó ti kọjá tí ọ̀sán dòru. Irú àwọn àkọsílẹ̀ tó fi ìṣirò ṣe yìí lè má ṣeé gbára lé, tó bá di ọ̀ràn ìtàn àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀, àyàfi tí ẹ̀rí mìíràn bá wà tó ti ọ̀rọ̀ òǹkọ̀wé náà lẹ́yìn.

[Credit Line]

© Ìyọ̀ǹda The Trustees of the British Museum

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwéé 26, 27]

KÍ NI WÀLÁÀ VAT 4956 SỌ GAN-AN?

Kí nìdí tó fi fa àríyànjiyàn? Ìlà kẹta lórí wàláà yìí sọ pé “ní alẹ́ ọjọ́ kẹsàn-án” oṣù kìíní (Nisanu tàbí Nísàn), “òṣùpá wà ní ìgbọ̀nwọ́ kan níwájú ìràwọ̀ tó ń jẹ́ ß Virginis.” Àmọ́, Ọ̀gbẹ́ni Neugebauer àti Ọ̀gbẹ́ni Weidner kọ̀wé lọ́dún 1915 nípa ọdún 568 ṣáájú Sànmánì Kristẹni (láti fi hàn pé ọdún 587 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni Jerúsálẹ́mù pa run) pé “Nísàn 8 ni òṣùpá dúró ní ìgbọ̀nwọ́ kan níwájú ìràwọ̀ yìí, kì í ṣe ní Nísàn 9.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.) Àmọ́, àyẹ̀wò fi hàn pé ibi tí àkọsílẹ̀ sọ pé òṣùpá wà bá ibi tí òṣùpá wà ní Nísàn 9, ọdún 588 ṣáájú Sànmánì Kristẹni mu gan-an, èyí sì tọ́ka sí i pé ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ló tọ̀nà.

Ṣé “9” ni àbí “8”?

(1) Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú àwòrán níbí yìí, wàá rí àmì tí àwọn ará Ákádì ń lò fún nọ́ńbà 9.

(2) Nígbà tí ọ̀gbẹ́ni Neugebauer àti ọ̀gbẹ́ni Weidner ń ṣe ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ inú wàláà yìí, wọ́n yí “9” pa dà sí “8.”

(3) Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé nìkan ló fi hàn pé “9” ló wà nínú wàláà tí wọ́n túmọ̀ ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ sí èdè míì.

(4) Kódà nínú ìtumọ̀ tí wọ́n ṣe sí èdè Jámánì, “8” ni wọ́n fi síbẹ̀.

(5) Lọ́dún 1988, ọ̀gbẹ́ni Sachs àti ọ̀gbẹ́ni Hunger tẹ àwọn ọ̀rọ̀ inú wàláà náà jáde bó ṣe wà níbẹ̀, pẹ̀lú “9.”

(6) Àmọ́, nínú ìtumọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n ṣe, wọ́n kọ ọ́ pé, “9” jẹ́ “àṣìṣe,” àmọ́ “8 ló tọ̀nà.”

[Credit Line]

bpk / Vorderasiatisches Museum, SMB / Olaf M. Teßmer

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 28]

Àfikún Àlàyé Lórí Àpilẹ̀kọ náà, “Ìgbà Wo Ni Wọ́n Pa Jerúsálẹ́mù Àtijọ́ Run?—Apá Kejì”

1. Oríṣiríṣi àmì ni wọ́n fi kọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú wàláà yìí. Bí wọ́n ṣe máa ń ṣe é ni pé, òǹkọ̀wé máa ń fi kálàmù mú oríṣiríṣi àmì tá a sì wá tẹ̀ ẹ́ mọ́ ojú wàláà alámọ̀ tí kò tíì gbẹ láti fi kọ ọ̀rọ̀.

2. Ìwé tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn wàláà, ìyẹn Assyrian and Babylonian Chronicles, látọwọ́ A. K. Grayson, ó tẹ̀ ẹ́ ní ọdún 1975, ó tún un tẹ̀ ní ọdún 2000, ojú ìwé 8.

3. Ìgbà ìṣàkóso Ilẹ̀ Ọba Bábílónì Ẹlẹ́ẹ̀kejì bẹ̀rẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún keje ṣáájú Sànmánì Kristẹni nígbà tí àwọn ọba Kálídíà ń ṣàkóso Ilẹ̀ Ọba Bábílónì. Ọba àkọ́kọ́ ni Nabopolásárì, tó jẹ́ bàbá Nebukadinésárì Kejì. Àkókò náà dópin nígbà tí Kírúsì Ọba Páṣíà ṣẹ́gun ọba tó kẹ́yìn, ìyẹn Nábónídọ́sì, ní ọdún 539 ṣáájú Sànmánì Kristẹni.

4. Ìwé Neo-Babylonian Business and Administrative Documents, látọwọ́ Ellen Whitley Moore, ó tẹ̀ ẹ́ ní ọdún 1935, ojú ìwé 33.

5. Ìwé Archimedes, Volume 4, New Studies in the History and Philosophy of Science and Technology, “Observations and Predictions of Eclipse Times by Early Astronomers,” látọwọ́ John M. Steele, ó tẹ̀ ẹ́ ní ọdún 2000, ojú ìwé 36.

6. Ìwé Amel-Marduk 562-560 B.C.—A Study Based on Cuneiform, Old Testament, Greek, Latin and Rabbinical Sources. With Plates, Látọwọ́ Ronald H. Sack, ó tẹ̀ ẹ́ ní ọdún 1972, ojú ìwé 3.

7. Àwọn wàláà tí wọ́n pè ní BM 80920 àti BM 58872 tí wọ́n ti wà láti oṣù kẹrin àti ìkarùn-ún ọdún tí ọba Evil-merodach gorí ìtẹ́. Sack sọ̀rọ̀ nípa wọn nínú ìwé tó tẹ̀, ìyẹn ìwé Amel-Marduk 562-560 B.C.—A Study Based on Cuneiform, Old Testament, Greek, Latin and Rabbinical Sources. With Plates, ojú ìwé 3, 90, 106.

8. Àwọn wàláà tí wọ́n kó wá sí Ibi Ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì (BM 55806) ti wà láti oṣù kẹwàá, ọdún kẹtàlélógójì [43] ìgbà ìjọba náà.

9. Àwọn wàláà tí wọ́n pè ní BM 75106 àti BM 61325 ti wà láti oṣù keje àti ìkẹwàá ọdún tí wọ́n sọ pé ó jẹ́ ọdún (kejì) tó kẹ́yìn ìgbà tí ọba Evil-merodach fi jọba. Àmọ́ wàláà BM 75489 ti wà láti oṣù kejì ọdún tí ẹni tó gbapò rẹ̀, ìyẹn Neriglissar gorí ìtẹ́.—Ìwé Catalogue of the Babylonian Tablets in the British Museum, Volume VIII, (Tablets From Sippar 3) látọwọ́ Erle Leichty, J. J. Finkelstein, àti C.B.F. Walker, wọ́n tẹ̀ ẹ́ ní ọdún 1988, ojú ìwé 25 àti 35.

Ìwé Catalogue of the Babylonian Tablets in the British Museum, Volume VII, (Tablets From Sippar 2) látọwọ́ Erle Leichty àti A. K. Grayson, wọ́n tẹ̀ ẹ́ ní ọdún 1987, ojú ìwé 36.

Ìwé Neriglissar—King of Babylon, látọwọ́ Ronald H. Sack, ó tẹ̀ ẹ́ ní ọdún 1994, ojú ìwé 232. Oṣù tó wà lórí wàláà náà ni Ajaru (oṣù kejì).

10. Ṣàgbéyẹ̀wò àpẹẹrẹ Neriglissar. Àkọlé kan sọ pé ó jẹ́ “ọmọ Bêl-shum-ishkun,” tó jẹ́ “ọba Bábílónì.” (ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.) Àkọlé míì pe Bêl-shum-ishkun ní “ọmọ ọba tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n.” Ọ̀rọ̀ náà, rubû, tó túmọ̀ sí “ọmọ ọba,” jẹ́ orúkọ oyè tó tún túmọ̀ sí “ọba, alákòóso.” Bí ìtakora ṣe wà nínú ìgbà tí wọ́n sọ pé Neriglissar jọba àti ìgbà ìjọba Amel-Marduk tó ti jọba ṣáájú rẹ̀, ǹjẹ́ ó lè jẹ́ pé Bêl-shum-ishkun, “ọba Bábílónì” ti jọba fún àkókò kan lẹ́yìn Amel-Marduk kí ó tó kan Neriglissar? Ọ̀jọ̀gbọ́n R. P. Dougherty gbà pé “ẹ̀rí pé Neriglissar wá láti ìdílé ọlọ́lá ni a kò lè kó dà nù.”—Ìwé Nabonidus and Belshazzar—A Study of the Closing Events of the Neo-Babylonian Empire, látọwọ́ Raymond P. Dougherty, ó tẹ̀ ẹ́ ní ọdún 1929, ojú ìwé 61.

11. Ìwé Astronomical Diaries and Related Texts From Babylonia, Volume V, Hermann Hunger ló ṣàtúnṣe rẹ̀, tó sì tẹ̀ ẹ́ ní ọdún 2001, ojú ìwé 2 sí 3.

12. Ìwé Journal of Cuneiform Studies, Volume 2, No. 4, 1948, “A Classification of the Babylonian Astronomical Tablets of the Seleucid Period,” látọwọ́ A. Sachs, ojú ìwé 282 sí 283.

13. Ìwé Astronomical Diaries and Related Texts From Babylonia, Volume V, ojú ìwé 391.

14. Ìwé Mesopotamian Planetary Astronomy-Astrology, látọwọ́ David Brown, ó tẹ̀ ẹ́ ní ọdún 2000, ojú ìwé 164, 201 sí 202.

15. Ìwé Bibliotheca Orientalis, L N° 1/2, Januari-Maart, 1993, “The Astronomical Diaries as a Source for Achaemenid and Seleucid History,” látọwọ́ R. J. van der Spek, ojú ìwé 94 àti 102.

16. Astronomical Diaries and Related Texts From Babylonia, Volume I, látọwọ́ Abraham J. Sachs, tí Hermann Hunger ṣàtúnṣe rẹ̀ tó sì parí rẹ̀, ó tẹ̀ ẹ́ ní ọdún 1988, ojú ìwé 47.

17. Ìwé Babylonian Eclipse Observations From 750 BC to 1 BC, látọwọ́ Peter J. Huber àti Salvo De Meis, wọ́n tẹ̀ ẹ́ ní ọdún 2004, ojú ìwé 186. Wàláà VAT 4956 sọ nípa ọ̀sán tó dòru, àyẹ̀wò sì fi hàn pé ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù kẹta lórí kàlẹ́ńdà Bábílónì ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé, tó fi hàn pé oṣù Simanu ti bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ṣáájú ìgbà yẹn. Bí ọ̀sán tó dòru yìí bá bọ́ sí July 15, ọdún 588 ṣáájú Sànmánì Kristẹni lórí kàlẹ́ńdà Julian, ìyẹn kàlẹ́ńdà òde òní, á jẹ́ pé ọjọ́ kìíní Simanu yóò bọ́ sí June 30 tàbí July 1, ọdún 588 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Nítorí náà, oṣù Nisanu tó jẹ́ oṣù àkọ́kọ́ lórí kàlẹ́ńdà Bábílónì ti bẹ̀rẹ̀ ọdún tuntun lóṣù méjì sẹ́yìn, èyí tó jẹ́ May 2 tàbí 3 lórí kàlẹ́ńdà òde òní. Bó ṣe yẹ kó rí ni pé oṣù April 3 tàbí 4 ló yẹ kí ọdún tí ọ̀sán dòru yìí bẹ̀rẹ̀, àmọ́ ìlà kẹfà nínú wàláà VAT 4956 sọ pé wọ́n fi oṣù kan kún un lẹ́yìn oṣù kejìlá tó kẹ́yìn (ìyẹn Addaru) nínú ọdún náà. (Wàláà náà sọ pé: “ọjọ́ kẹjọ oṣù XII2 [oṣù kẹtàlá].”) Nítorí náà, èyí mú kí ọdún tuntun náà má bẹ̀rẹ̀ títí ó fi di May 2 tàbí 3. Nípa báyìí, ọdún tí ọ̀sán dòru náà, ìyẹn ọdún 588 ṣáájú Sànmánì Kristẹni bá àkókò tó wà lórí wàláà náà mu gẹ́lẹ́.

18. Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn Berichte über die Verhandlungen der Königl. Sächsischen Gesellschaft der Wissenschaften zu Leipzig (Reports Regarding the Discussions of the Royal Saxonian Society of Sciences at Leipzig); Volume 67; May 1, 1915; nínú àpilẹ̀kọ náà, “Ein astronomischer Beobachtungstext aus dem 37. Jahre Nebukadnezars II” (An Astronomical Observer’s Text of the 37th Year Nebuchadnezzar II), látọwọ́ Paul V. Neugebauer àti Ernst F. Weidner, wọ́n sọ ní ojú ìwé 67 sí 76 pé, ìgbà mẹ́tàlá wà tí wọ́n ṣàkíyèsí òṣùpá tí wọ́n sì sọ bí wọ́n ṣe wà sí àwọn ìràwọ̀ kan tàbí àwọn àgbájọ ìràwọ̀. Wọ́n tún ṣàkọsílẹ̀ ìgbà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tí wọ́n ṣàkíyèsí àwọn pílánẹ́ẹ̀tì. (Ojú ìwé 72 sí 76) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àmì tí wọ́n fi ṣàpẹẹrẹ òṣùpá nínú wàláà náà ṣe kedere, tí kò sì ní ìtumọ̀ méjì, àwọn àmì kan tó ṣàpẹẹrẹ orúkọ àwọn pílánẹ́ẹ̀tì àti ibi tí wọ́n wà lójú ọ̀run kò ṣe kedere. (Mesopotamian Planetary Astronomy—Astrology, láti ọwọ́ David Brown, ó tẹ̀ ẹ́ ní ọdún 2000, ojú ìwé 53 sí 57) Nítorí pé àwọn àmì náà kò ṣe kedere, èyí lè mú kí wọ́n túmọ̀ àmì tó ṣàpẹẹrẹ àwọn pílánẹ́ẹ̀tì náà sí oríṣiríṣi ọ̀nà. Nítorí pé àmì tó ṣàpẹẹrẹ òṣùpá ṣe kedere, ó ṣeé ṣe láti fi àmì yìí mọ ibi tí àwọn nǹkan ojú ọ̀run wà sí ibi tí òṣùpá wà gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wàláà VAT 4956 ṣe fi hàn, ó sì ṣeé ṣe láti mọ ìgbà tí wọ́n wà níbẹ̀.

18a. Ìgbà tá a sọ yìí jẹ́ ìdíwọ̀n àkókò bí àpẹẹrẹ, ìdíwọ̀n ìgbà tí oòrùn wọ̀ sí ìgbà tí òṣùpá wọ̀ ní ọjọ́ àkọ́kọ́ nínú oṣù àti ìgbà méjì míì nínu oṣù kan náà. Àwọn ọ̀mọ̀wé ti ń lo ìdíwọ̀n àkókò yìí láti lè mọ ìgbà táwọn nǹkan ojú ọ̀run máa yọ ní apá ibì kan pàtó. (“The Earliest Datable Observation of the Aurora Borealis,” by F. R. Stephenson and David M. Willis, in Under One Sky—Astronomy and Mathematics in the Ancient Near East, John M. Steele àti Annette Imhausen ló ṣàtúnṣe rẹ̀, wọ́n tẹ̀ ẹ́ ní ọdún 2002, ojú ìwé 420 sí 428) Kí àwọn tó ń ṣàkíyèsí àwọn nǹkan ojú ọ̀run nígbà àtijọ́ tó lè díwọ̀n àkókò yìí, wọ́n nílò oríṣi àwọn aago kan. Irú àwọn ìdíwọ̀n bẹ́ẹ̀ kò ṣeé gbára lé. (Archimedes, Volume 4, New Studies in the History and Philosophy of Science and Technology, “Observations and Predictions of Eclipse Times by Early Astronomers,” látọwọ́ John M. Steele, ó tẹ̀ ẹ́ ní ọdún 2000, ojú ìwé 65 sí 66) Àmọ́ ṣá o, ìdíwọ̀n tí wọ́n ṣe nípa ibi tí òṣùpá sí àwọn nǹkan ojú ọ̀run yòókù ṣeé gbára lé gan-an.

19. Kọ̀ǹpútà ni wọ́n fi ṣe àlàyé àwọn nǹkan ojú ọ̀run tá a sọ yìí, orúkọ ètò orí kọ̀ǹpútà tí wọ́n lò náà ni TheSky6™. Ní àfikún sí i, wọ́n tún mú àlàyé yìí sunwọ̀n sí i nípasẹ̀ ètò kọ̀ǹpútà tó gbòòrò tí wọ́n kò sanwó fún, tí wọ́n pè ní Cartes du Ciel/Sky Charts (CDC) àti ohun èlò tí àwọn Ọmọ Ogun Ojú Omi Amẹ́ríkà fi ń ṣírò ọjọ́. Nítorí pé àwọn àmì tó ṣàpẹẹrẹ ibi tí ọ̀pọ̀ pílánẹ́ẹ̀tì wà kò ṣe kedere, èyí lè mú kí wọ́n túmọ̀ àmì náà sí oríṣiríṣi ọ̀nà, nítorí náà, nínú ìwádìí yìí, wọn kò lo àmì tí kò ṣe kedere yìí láti pinnu ọdún tí àkọsílẹ̀ wàláà náà tọ́ka sí.

20. Ìròyìn Berichte über die Verhandlungen der Königl. Sächsischen Gesellschaft der Wissenschaften zu Leipzig (Reports Regarding the Discussions of the Royal Saxonian Society of Sciences at Leipzig); Volume 67; May 1, 1915; “Ein astronomischer Beobachtungstext aus dem 37. Jahre Nebukadnezars II, (-567/66)” (An Astronomical Observer’s Text of the 37th Year Nebuchadnezzar II), látọwọ́ Paul V. Neugebauer and Ernst F. Weidner, ojú ìwé 41.

21. Ìlà kẹta nínú wàláà VAT 4956 sọ pé: “Òṣùpá wà ní ìgbọ̀nwọ́ kan [tàbí ní ìwọ̀n 2°] níwájú ìràwọ̀ ß Virginis.” Ìwádìí tí wọ́n ṣe tá a sọ níṣàájú fi hàn pé ní Nisanu 9, òṣùpá wà ní ìwọ̀n 2°04’ níwájú ìràwọ̀ ß Virginis àti ní ìwọ̀n 0° nísàlẹ̀ rẹ̀. Wọ́n sọ pé ó bá a mu gẹ́lẹ́.

[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 25]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

 WÀLÁÀ VAT 4956 TỌ́KA SÍ ỌDÚN TÍ WỌ́N PA JERÚSÁLẸ́MÙ RUN​—ṢÉ ỌDÚN 587 ṢÁÁJÚ SÀNMÁNÌ KRISTẸNI NI ÀBÍ ỌDÚN 607 ṢÁÁJÚ SÀNMÁNÌ KRISTẸNI?

◼ Wàláà yìí ṣàlàyé ibi tí òṣùpá, àwọn pílánẹ́ẹ̀tì àti àwọn ìràwọ̀ wà àti ìgbà kan tí ọ̀sán dòru, àwọn nǹkan yìí ṣẹlẹ̀ ní ọdún kẹtàdínlógójì [37] ìgbà ìṣàkóso Ọba Nebukadinésárì Kejì.

◼ Nebukadinésárì Kejì pa Jerúsálẹ́mù run ní ọdún kejìdínlógún [18] ìgbà ìṣàkóso rẹ̀.—Jeremáyà 32:1.

Bí ọdún kẹtàdínlógójì [37] ìgbà

ìṣàkóso Ọba Nebukadinésárì Kejì

bá jẹ́ ọdún 568 ṣáájú Sànmánì

Kristẹni, á jẹ́ pé ọdún 587 ṣáájú

Sànmánì Kristẹni ló pa

587 ← ← Jerúsálẹ́mù run.

610 Ṣ.S.K. 600 590 580 570 560

607 ← ← Bí ọdún kẹtàdínlógójì [37] ìgbà ìṣàkóso

rẹ̀ bá jẹ́ ọdún 588 ṣáájú Sànmánì Kristẹni,

á jẹ́ pé ó pa Jerúsálẹ́mù run ní ọdún

607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ìyẹn ọdún tí

àwọn ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì fi hàn pé

Jerúsálẹ́mù pa run.

◼ Wàláà VAT 4956 fi ẹ̀rí hàn pé ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni Jerúsálẹ́mù pa run.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 22]

Fọ́tò tá a yà nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda British Museum