Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọ̀nà Wo Ni Àwọn Òfin Ọlọ́run Gbà Ń Ṣe Wá Láǹfààní?

Ọ̀nà Wo Ni Àwọn Òfin Ọlọ́run Gbà Ń Ṣe Wá Láǹfààní?

Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Ọ̀nà Wo Ni Àwọn Òfin Ọlọ́run Gbà Ń Ṣe Wá Láǹfààní?

Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a béèrè àwọn ìbéèrè tó o ti lè máa ṣe kàyéfì nípa wọn, a sì tún sọ ibi tó o ti lè rí ìdáhùn wọn kà nínú Bíbélì rẹ. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti bá ẹ sọ̀rọ̀ lórí ohun tí àwọn ìdáhùn náà jẹ́.

1. Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣègbọràn sí Ọlọ́run?

Ohun tó tọ́ ni pé ká ṣègbọràn sí Ọlọ́run, nítorí pé òun ló dá wa. Gbogbo ìgbà ni Jésù pàápàá máa ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run. (Jòhánù 6:38; Ìṣípayá 4:11) Tí a bá ń pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́, èyí máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.—Ka 1 Jòhánù 5:3.

Ire wa ni àwọn òfin Jèhófà Ọlọ́run wà fún. Ní báyìí, wọ́n ń kọ́ wa bí a ṣe lè gbé ìgbésí ayé tó dára jù lọ, wọ́n sì tún ń kọ́ wa bá a ṣe lè gba èrè ayérayé lọ́jọ́ iwájú.—Ka Sáàmù 19:7, 11; Aísáyà 48:17, 18.

2. Àǹfààní wo ni pípa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ ń ṣe fún ara wa?

Òfin Ọlọ́run tó sọ pé ká má ṣe mu ọtí àmujù ń dáàbò boni lọ́wọ́ àìsàn tó ń ṣekú pani àti jàǹbá. Ọtí àmujù máa ń di bárakú, ó sì máa ń mú kéèyàn hùwà òmùgọ̀. (Òwe 23:20, 29, 30) Jèhófà kò sọ pé ká má mu ọtí, àmọ́ ó fẹ́ kó jẹ́ níwọ̀ntúnwọ̀nsì.—Ka Sáàmù 104:15; 1 Kọ́ríńtì 6:10.

Jèhófà tún sọ fún wa pé ká yẹra fún owú, ìbínú fùfù àtàwọn ìwà míì tí kò dára. Bá a bá ṣe ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn rẹ̀ tó ni ìlera wa ṣe máa dára tó.—Ka Òwe 14:30; 22:24, 25.

3. Báwo ni òfin Ọlọ́run ṣe lè dáàbò bò wá?

Òfin Ọlọ́run sọ pé, tọkọtaya kò gbọ́dọ̀ ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹlòmíì. (Hébérù 13:4) Ọkàn tọkọtaya tó bá ń pa òfin yìí mọ́ máa ń balẹ̀, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí ara tu àwọn ọmọ wọn. Àmọ́, ohun tó sábà máa ń gbẹ̀yìn tọkọtaya tí kò pa òfin yìí mọ́ ni, kíkó àrùn, ìkọ̀sílẹ̀, ìjà, ìbànújẹ́ àti dídá tọ́mọ.—Ka Òwe 5:1-9.

Bá a bá ń yẹra fún ìdẹwò tó lè mú ká ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya wa, àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run á túbọ̀ dára sí i. A kò tún ní kó ẹ̀dùn ọkàn bá àwọn ẹlòmíì.—Ka 1 Tẹsalóníkà 4:3-6.

4. Àǹfààní wo la máa rí tí a bá bọ̀wọ̀ fún ìwàláàyè?

Àwọn tó mọrírì ẹ̀bùn ìwàláàyè tí Ọlọ́run fún wa máa ń ní ìlera tó dáa tí wọ́n bá yẹra fún àwọn àṣà bíi, sìgá mímu àtàwọn àṣà míì tó máa ń di bárakú tó lè ṣekú pani. (2 Kọ́ríńtì 7:1) Ojú iyebíye ni Ọlọ́run fi wo ọmọ tó ń dàgbà nínú ìyá rẹ̀. (Ẹ́kísódù 21:22, 23) Nítorí náà, a kò gbọ́dọ̀ mọ̀ọ́mọ̀ pa ọmọ tó ṣì wà nínú ìyá rẹ̀. Bákan náà, àwọn tó mọyì ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìwàláàyè máa ń dènà ewu níbi iṣẹ́, ní ilé àti nínú ọkọ̀. (Diutarónómì 22:8) Yàtọ̀ sí ìyẹn, wọn ò kì í fi ẹ̀mí wọn wewu nítorí eré ìdárayá, nítorí pé ìwàláàyè jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.—Ka Sáàmù 36:9.

5. Ọ̀nà wo ni jíjẹ́ tí ẹ̀jẹ̀ jẹ́ ohun mímọ́ gbà ń ṣe wá láǹfààní?

Ẹ̀jẹ̀ jẹ́ ohun mímọ́ nítorí pé Ọlọ́run sọ pé, ẹ̀jẹ̀ ṣàpẹẹrẹ ìwàláàyè tàbí ọkàn, ohun abẹ̀mí. (Jẹ́nẹ́sísì 9:3, 4) Òfin Ọlọ́run tó sọ pé bí ẹ̀jẹ̀ ṣe ṣeyebíye náà ni ìwàláàyè ṣeyebíye jẹ́ àǹfààní fún wa. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Ó mú kó ṣeé ṣe fún wa láti rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà.—Ka Léfítíkù 17:11-13; Hébérù 9:22.

Ẹ̀jẹ̀ Jésù ṣeyebíye gan-an lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nítorí pé ẹni pípé ni. Jésù gbé ohun tó ṣàpẹẹrẹ ìwàláàyè rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run, ìyẹn ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. (Hébérù 9:12) Ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tó ta sílẹ̀ mú kó ṣeé ṣe fún wa láti ní ìyè àìnípẹ̀kun.—Ka Mátíù 26:28; Jòhánù 3:16.

Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka orí 12 àti 13 nínú ìwé yìí, Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.