Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ó Yẹ Kí Àwọn Òbí Kọ́ Àwọn Ọmọ Wọn Lẹ́kọ̀ọ́ Nípa Ìbálòpọ̀?

Ṣé Ó Yẹ Kí Àwọn Òbí Kọ́ Àwọn Ọmọ Wọn Lẹ́kọ̀ọ́ Nípa Ìbálòpọ̀?

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . .

Ṣé Ó Yẹ Kí Àwọn Òbí Kọ́ Àwọn Ọmọ Wọn Lẹ́kọ̀ọ́ Nípa Ìbálòpọ̀?

▪ Ọ̀pọ̀ òbí ló ń sa gbogbo ipá wọn láti dáàbò bo àwọn ọmọ wọn kí wọ́n má bàa kó àrùn. Bákan náà, ó yẹ kí àwọn òbí sapá láti dàábò bo àwọn ọmọ wọn kí wọ́n má bàa kó sínú ìwà ìbàjẹ́. Ọ̀kan lára ọ̀nà tí wọ́n lè gbà ṣe é ni pé kí wọ́n kọ́ ọmọ wọn ní ohun tó tọ́ nípa ìbálòpọ̀. (Òwe 5:3-23) Irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ tí àwọn òbí ń kọ́ àwọn ọmọ wọn àti ìtọ́sọ́nà nípa ìwà rere ṣe pàtàkì gan-an nítorí àwọn ọmọdé túbọ̀ ń rí àwọn àwòrán nípa ìbálòpọ̀ èyí tí tẹlifíṣọ̀n, Íńtánẹ́ẹ̀tì, àwọn ìwé àtàwọn eré àwòrẹ́rìn-ín ń gbé jáde.

Obìnrin kan tó ń jẹ́ Diane Levin tó jẹ́ Ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tó sì tún jẹ́ òǹṣèwé sọ pé, “Lóde òní, ọ̀rọ̀ pé àwọn ọmọ wa ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìbálòpọ̀ kọ́ ni ìṣòro. Àmọ́ ìṣòro náà ni ohun tí wọ́n ń kọ́, ọjọ́ orí tí wọ́n ti ń kọ́ ọ àti ẹni tó ń kọ́ wọn. Ohun tí àwọn ọmọdé ń kọ́ nípa ìbálòpọ̀ látinú àṣà tó lòde àti látọ̀dọ̀ àwọn tó ń polówó ọjà burú jáì.”

Àwọn òbí ní láti dáàbò bo àwọn ọmọ wọn kí wọ́n má bàa ní èrò tí kò tọ́ tó gbòde kan nípa ìbálòpọ̀. (Òwe 5:1; Éfésù 6:4) Ó yẹ kí àwọn ọmọdé mọ ohun tí ẹ̀yà ara wọn kọ̀ọ̀kan wà fún, kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè bójú tó ara wọn àti bí wọn kò ṣe ní kó sọ́wọ́ àwọn oníṣekúṣe. Kí ọmọ kan tó wọ ìgbà ìbàlágà, ìyẹn ìgbà tí wọ́n máa ń rí àwọn ìyípadà lára wọn, ní pàtàkì nínú ẹ̀yà ìbímọ wọn, ó yẹ kó mọ àwọn ìyípadà tí á máa wáyé nínú ara rẹ̀. Ó yẹ kí ọmọbìnrin mọ ìdí tí obìnrin fi ń ṣe nǹkan oṣù àti bí ó ṣe máa ń ṣẹlẹ̀. Bákan náà, ó yẹ kí ọmọkùnrin mọ̀ pé àtọ̀ máa ń dà lára ọkùnrin nígbà tó bá ń sùn kí ó tó di pé irú rẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí i. Nígbà tí àwọn ọmọ wà ní kékeré ló yẹ káwọn òbí ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn ní orúkọ tó tọ́ tí ẹ̀yà ara ìbímọ kọ̀ọ̀kan ń jẹ́. Àwọn òbí tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn máa ń kọ́ wọn ní nǹkan pàtàkì mẹ́ta yìí nípa ẹ̀yà ara tó wà fún ìbálópọ̀: (1) Àwọn ẹ̀yà ara náà ṣe pàtàkì gan-an àti pé àwọn ọmọ yẹn nìkan ló wà fún. (2) Wọn kò gbọ́dọ̀ máa fi àwọn ẹ̀yà ara náà ṣe yẹ̀yẹ́. (3) Wọn kò sì gbọ́dọ̀ jẹ́ káwọn èèyàn máa fọwọ́ kàn wọ́n, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò gbọ́dọ̀ máa fi wọ́n han àwọn èèyàn. Bí àwọn ọmọ náà ṣe ń dàgbà, àwọn òbí ní láti mọ ìgbà tó yẹ káwọn ṣàlàyé fún wọn nípa bí obìnrin ṣe ń lóyún. *

Ìgbà wo ló yẹ káwọn òbí bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ yìí? Ìgbà táwọn èèyàn rò pé wọ́n ṣi kéré yẹn gan-an ni. Ọmọbìnrin kan lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe nǹkan oṣù ní ọmọ ọdún mẹ́wàá tàbí kó má tiẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ pàápàá. Ọmọkùnrin kan lè bẹ̀rẹ̀ sí í da àtọ̀ nígbà tó bá ń sùn ní ọmọ ọdún mọ́kànlá tàbí méjìlá. Bí àwọn ọmọ kò bá lóye àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí, àwọn ìyípadà tó wáyé náà lè dẹ́rù bà wọ́n. Ó yẹ káwọn òbí mú un dá wọn lójú ṣáájú àkókò yẹn pé kò sí ìdí láti jáyà tí wọ́n bá rí irú àwọn ìyípadà bẹ́ẹ̀. Àkókò yẹn gan-an ló tún yẹ kéèyàn jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé títẹ̀lé àwọn ìlànà Bíbélì nípa ìbálòpọ̀ ló dára jù, òun ló sì ṣe pàtàkì jù. Yàtọ̀ sí inú Bíbélì, ṣàṣà ni ibi téèyàn ti lè rí irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀.—Òwe 6:27-35.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Àwọn òbí yóò rí ìsọfúnni tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ lórí àwọn kókó ẹ̀kọ́ yìí nínú ìtẹ̀jáde tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe, àwọn nìyí: Jí! October–December 2006, ojú ìwé 10 sí 13 tó ní àpilẹ̀kọ náà, “Bó O Ṣe Lè Ran Ọmọbìnrin Rẹ Lọ́wọ́ Láti Múra Sílẹ̀ De Ìgbà Tó Máa Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Ṣe Nǹkan Oṣù”; Ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì, orí 6 tó sọ pé, “Kí Nìdí Tára Mi Fi Ń Yí Pa Dà?” àti Ilé Ìṣọ́ November 1, 2010, ojú ìwé 12 sí 14 tó ní àpilẹ̀kọ náà, “Ohun Tó Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀—Bá Ọmọ Rẹ Sọ̀rọ̀ Nípa Ìbálòpọ̀.”