Bí A Ṣe Lè Ṣe Ojúṣe Wa Lọ́dọ̀ Ọlọ́run
Sún Mọ́ Ọlọ́run
Bí A Ṣe Lè Ṣe Ojúṣe Wa Lọ́dọ̀ Ọlọ́run
ǸJẸ́ o ti ṣe kàyéfì rí pé, ‘Kí nìdí tá a fi wà láàyè?’ Yàtọ̀ sí pé Jèhófà fún wa ní làákàyè láti béèrè irú ìbéèrè yìí, ó tún mú kí ó wù wá láti mọ ìdáhùn náà. Ó dùn mọ́ wa nínú pé Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ fún wa ní ìdáhùn náà. Ìdáhùn tí à ń wá náà wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀rọ̀ Sólómọ́nì Ọba, èyí tó wà nínú ìwé Oníwàásù 12:13.
Sólómọ́nì ní ọgbọ́n àti ìrírí tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Èyí mú kó lè sọ̀rọ̀ nípa béèyàn ṣe lè gbé ìgbé ayé tó dára kí ó sì ní ayọ̀. Ó ní ọgbọ́n tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ọrọ̀ rẹpẹtẹ, ó sì ní ọlá àṣẹ nítorí pé ọba ni. Ó ṣeé ṣe fún un láti fara balẹ̀ ṣèwádìí nípa ohun táwọn èèyàn ń lépa, títí kan lílépa ọrọ̀ àti òkìkí. (Oníwàásù 2:4-9; 4:4) Nígbà tó yá, Ọlọ́run mí sí Sólómọ́nì, ó sì ṣe àkópọ̀ àwọn àwárí tó ṣe, ó ní: “Òpin ọ̀ràn náà, lẹ́yìn gbígbọ́ gbogbo rẹ̀, ni pé: Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Nítorí èyí ni gbogbo iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ti ènìyàn.” Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn jẹ́ ká mọ ohun tó dára jù téèyàn lè ṣe, tó sì lérè jù lọ.
“Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́.” Èrò náà pé kéèyàn máa bẹ̀rù Ọlọ́run lè kọ́kọ́ jọ ohun tí kò bára dé. Àmọ́ irú ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀ máa ń fi hàn bí ọkàn ẹni ṣe dára tó. Ńṣe ló dà bí ìgbà tí ọmọ kan bá fẹ́ láti wu bàbá rẹ̀ onífẹ̀ẹ́, kì í ṣe bí ìgbà tí ẹrú kan ń fòyà kí ó má bàa ṣẹ ọ̀gá rẹ̀ tó jẹ́ òǹrorò. Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé ìbẹ̀rù Ọlọ́run jẹ́ “ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ gan-an tí àwọn èèyàn Rẹ̀ ń fi hàn sí I nítorí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀, tí wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún agbára àti ìtóbilọ́lá Rẹ̀.” Irú èrò bẹ́ẹ̀ ló ń mú ká máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tá a sì mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Ìbẹ̀rù tó dára yìí jẹ́ èyí tó ń ti ọkàn wá, ó sì máa ń hàn nínú ìwà wa. Lọ́nà wo?
“Pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.” Ìbẹ̀rù tá a ní fún Ọlọ́run ló ń mú ká ṣègbọràn sí i. Ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká máa ṣègbọràn sí Jèhófà. Nítorí pé Òun ló dá wa, ó mọ ọ̀nà tó dára jù lọ tá a lè gbà gbé ìgbé ayé wa, gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ṣe ohun èlò kan ti ṣe mọ ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà lò ó. Yàtọ̀ síyẹn, ohun rere ni Jèhófà fẹ́ fún wa. Ó fẹ́ ká láyọ̀, àǹfààní wa sì làwọn òfin rẹ̀ wà fún. (Aísáyà 48:17) Àpọ́sítélì Jòhánù sọ ọ̀rọ̀ náà báyìí pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira.” (1 Jòhánù 5:3) Tá a bá ń ṣègbọràn, ó ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, àwọn àṣẹ tí Ọlọ́run fún wa sì fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa.
“Èyí ni gbogbo iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ti ènìyàn.” Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ká mọ ìdí pàtàkì tó fi yẹ ká máa bẹ̀rù Ọlọ́run ká sì máa ṣègbọràn sí i. Ohun àìgbọ́dọ̀máṣe ni, ojúṣe wa sì ni. Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá wa, ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìwàláàyè wa ti wá. (Sáàmù 36:9) Òun náà la ní láti máa ṣègbọràn sí. Tá a bá ń gbé ìgbé ayé wa bó ṣe fẹ́, ojúṣe wa là ń ṣe yẹn.
Kí wá nìdí tá a fi wà láàyè? Ní kúkúrú, ìdí náà ni pé: A wà láàyè láti máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Kò sí ọ̀nà míì tó dára ju ìyẹn lọ tó o lè gbà mú kí ìgbésí ayé rẹ dára. O ò ṣe wádìí síwájú sí i nípa ohun tí Jèhófà fẹ́ àti bó o ṣe lè mú kí ìgbésí ayé rẹ bá ìfẹ́ rẹ̀ mu? Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti ràn ẹ́ lọ́wọ́.
Bíbélì kíkà tá a dábàá fún November:
◼ Òwe 22-31; Oníwàásù 1-12–Orin Sólómọ́nì 1-8