Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bíbélì Dáhùn Ìbéèrè Mẹ́wàá Nípa Ìbálòpọ̀

Bíbélì Dáhùn Ìbéèrè Mẹ́wàá Nípa Ìbálòpọ̀

Bíbélì Dáhùn Ìbéèrè Mẹ́wàá Nípa Ìbálòpọ̀

1 Ṣé ìbálòpọ̀ ni ẹ̀ṣẹ̀ tí Ádámù àti Éfà dá nínú ọgbà Édẹ́nì?

▪ Ìdáhùn: Èrò ọ̀pọ̀ èèyàn ni pé, ìbálòpọ̀ ni èso tí Ọlọ́run sọ pé Ádámù àti Éfà kò gbọ́dọ̀ jẹ. Àmọ́ ṣá o, Bíbélì kò sọ ohun tó jọ bẹ́ẹ̀.

Kíyè sí i pé, kí Ọlọ́run tó dá Éfà ni ó ti pàṣẹ fún Ádámù pé kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú èso “igi ìmọ̀ rere àti búburú.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:15-18) Ádámù nìkan ló wà nínú ọgbà nígbà yẹn, èyí fi hàn pé àṣẹ náà kò lè jẹ́ ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀. Síwájú sí i, Ọlọ́run pàṣẹ tó ṣe kedere fún Ádámù àti Éfà pé, “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Ǹjẹ́ Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ tó pàṣẹ pé kí tọkọtaya àkọ́kọ́ “kún ilẹ̀ ayé,” èyí tó máa gba pé kí wọ́n ní ìbálòpọ̀, yóò tún wá dájọ́ ikú fún wọn nítorí pé wọ́n ṣègbọràn sí àṣẹ rẹ̀?—1 Jòhánù 4:8.

Síwájú sí i, ìgbà tí ọkọ Éfà ò sí nítòsí ni Éfà “mú nínú èso [tí Ọlọ́run sọ pé wọn kò gbọ́dọ̀ jẹ], ó sì jẹ ẹ́. Lẹ́yìn náà, ó fún ọkọ rẹ̀ ní díẹ̀ pẹ̀lú nígbà tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, òun náà sì jẹ ẹ́.”—Jẹ́nẹ́sísì 3:6.

Paríparí rẹ̀, Ọlọ́run kò bá Ádámù àti Éfà wí nígbà tí wọ́n ní ìbálòpọ̀ tí wọ́n sì bí ọmọ. (Jẹ́nẹ́sísì 4:1, 2) Ó ṣe kedere pé, èso tí Ádámù àti Éfà jẹ kì í ṣe ìbálòpọ̀, àmọ́ ó jẹ́ èso igi.

2 Ṣé Bíbélì sọ pé èèyàn kò gbọ́dọ̀ ní ìbálòpọ̀?

▪ Ìdáhùn: Ìwé àkọ́kọ́ nínú Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ló dá èèyàn ní “akọ àti abo.” Ọlọ́run sì sọ pé gbogbo nǹkan tí òun dá ni “ó dára gan-an.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 31) Nígbà tó yá, Ọlọ́run mí sí ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì láti fún àwọn ọkọ ní ìtọ́ni yìí pé: “Máa yọ̀ pẹ̀lú aya ìgbà èwe rẹ . . . Jẹ́ kí ọmú tirẹ̀ máa pa ọ́ bí ọtí ní gbogbo ìgbà.” (Òwe 5:18, 19) Ṣé àwọn ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé Bíbélì sọ pé èèyàn kò gbọ́dọ̀ ní ìbálòpọ̀?

Yàtọ̀ sí pé ìbálòpọ̀ máa jẹ́ kéèyàn lè bímọ, Ọlọ́run tún ṣe ẹ̀yà ara tó wà fún ìbálòpọ̀ lọ́nà tó máa fi ṣeé ṣe fún tọkọtaya láti fi ìfẹ́ hàn sí ara wọn kí wọ́n sì gbádùn ara wọn. Èyí ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn láti tẹ́ ara wọn lọ́rùn.

3 Ǹjẹ́ Bíbélì fọwọ́ sí i kí ọkùnrin àti obìnrin tí kò fẹ́ ara wọn níṣulọ́kà máa gbé pọ̀?

▪ Ìdáhùn: Bíbélì sọ ní kedere pé, “Ọlọ́run yóò dá àwọn àgbèrè . . . lẹ́jọ́.” (Hébérù 13:4) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà por·neiʹa, tó túmọ̀ sí àgbèrè ní ìtumọ̀ tó pọ̀, ó kan kí àwọn tí kò tíì ṣe ìgbéyàwó máa lo ẹ̀yà tó wà fún ìbálòpọ̀ lọ́nà tí kò tọ́. * Nítorí náà, ó dájú pé inú Ọlọ́run kò ní dùn sí i pé kí ọkùnrin àti obìnrin tí kò tíì fẹ́ ara wọn níṣulọ́kà máa gbé pa pọ̀, ká tiẹ̀ sọ pé wọ́n ṣì ní i lọ́kàn láti ṣègbéyàwó tó bá yá.

Kódà, bí ọkùnrin àti obìnrin kan bá nífẹ̀ẹ́ ara wọn gan-an, síbẹ̀ Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n ṣe ìgbéyàwó kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìbálòpọ̀. Ọlọ́run ló dá wa bẹ́ẹ̀ pé ká ní ìfẹ́ ara wa. Ìfẹ́ ló gbawájú nínú ìwà Ọlọ́run. Nítorí náà, ohun rere ni Ọlọ́run ní lọ́kàn tó fi fi dandan lé e pé, àwọn tó ti ṣègbéyàwó nìkan ni wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ láti ní ìbálòpọ̀, àpilẹ̀kọ tó kàn máa ṣàlàyé kókó yìí.

4 Ǹjẹ́ Ọlọ́run fọwọ́ sí i pé kéèyàn fẹ́ ju ìyàwó kan lọ?

▪ Ìdáhùn: Láwọn ìgbà kan, Ọlọ́run fàyè gba ọkùnrin kan láti ní ju ìyàwó kan lọ. (Jẹ́nẹ́sísì 4:19; 16:1-4; 29:18–30:24) Àmọ́ Ọlọ́run kọ́ ló dá àṣà kéèyàn máa fẹ́ ju ìyàwó kan lọ sílẹ̀. Ìyàwó kan ṣoṣo ló dá fún Ádámù.

Ọlọ́run ní kí Jésù Kristi fìdí ohun tí òun ní lọ́kàn ní ìbẹ̀rẹ̀ múlẹ̀ pa dà, ohun náà ni pé kí ọkùnrin fẹ́ ìyàwó kan ṣoṣo. (Jòhánù 8:28) Nígbà táwọn èèyàn béèrè ọ̀rọ̀ nípa ìgbéyàwó lọ́wọ́ Jésù, ó ní: “Ẹni tí ó dá wọn láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ṣe wọ́n ní akọ àti abo, ó sì wí pé, ‘Nítorí ìdí yìí ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan.’”—Mátíù 19:4, 5.

Nígbà tó yá, Ọlọ́run mí sí ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù láti sọ pé: “Kí olúkúlùkù ọkùnrin ní aya tirẹ̀, kí olúkúlùkù obìnrin sì ní ọkọ tirẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 7:2) Bíbélì tún sọ pé, Kristẹni ọkùnrin èyíkéyìí tó ti gbéyàwó tí wọ́n bá fún ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn àrà ọ̀tọ̀ nínú ìjọ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ jẹ́ “ọkọ aya kan.”—1 Tímótì 3:2, 12.

5 Ṣé ó burú kí tọkọtaya lo oògùn tí kì í jẹ́ kéèyàn lóyún?

▪ Ìdáhùn: Jésù kò pàṣẹ pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun bímọ. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ náà kò sì sọ ohun tó jọ bẹ́ẹ̀. Kò sí ibì kankan tí Bíbélì ti sọ pé èèyàn kò gbọ́dọ̀ lo oògùn tí kì í jẹ́ kéèyàn lóyún.

Nítorí náà, tọkọtaya ló máa pinnu bóyá àwọn fẹ́ bímọ tàbí wọn kò fẹ́. Wọ́n tún lè pinnu iye ọmọ tí wọ́n fẹ́ bí àti ìgbà tí wọ́n fẹ́ bí wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé tọkọtaya kan kò gbọ́dọ̀ lo oògùn tó ń ṣẹ́yún, síbẹ̀ wọ́n lè yàn bí wọ́n bá fẹ́ láti lo oògùn tí kì í jẹ́ kéèyàn lóyún. * Ẹnì kankan kò gbọ́dọ̀ dá wọn lẹ́bi lórí èyí.—Róòmù 14:4, 10-13.

6 Ṣé ó burú láti ṣẹ́yún?

▪ Ìdáhùn: Ìwàláàyè jẹ́ ohun mímọ́ lójú Ọlọ́run, ẹ̀dá alààyè ni Ọlọ́run ka ọmọ tó wà nínú ìyá rẹ̀ sí. (Sáàmù 139:16) Ọlọ́run sọ pé, èèyàn tó bá ṣe ọmọ tó wà nínú ikùn léṣe máa jíhìn. Nítorí náà, lójú Ọlọ́run, ìpànìyàn ló jẹ́ téèyàn bá ṣẹ́yún.—Ẹ́kísódù 20:13; 21:22, 23.

Àmọ́, tó bá ṣẹlẹ̀ pé ohun pàjáwìrì kan ṣẹlẹ̀ nígbà tí obìnrin kan fẹ́ bímọ, tí èyí sì mú kó di dandan fún tọkọtaya láti pinnu bóyá ìyá ni wọ́n fẹ́ kó wà láàyè tàbí ọmọ inú rẹ̀ ńkọ́? Tí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, tọkọtaya ló máa pinnu ẹni tí wọ́n fẹ́ kó wà láàyè. *

7 Ǹjẹ́ Bíbélì fọwọ́ sí ìkọ̀sílẹ̀?

▪ Ìdáhùn: Bẹ́ẹ̀ ni, Bíbélì fọwọ́ sí ìkọ̀sílẹ̀. Àmọ́ ṣá o, Jésù sọ ìdí kan ṣoṣo tó ṣe ìtẹ́wọ́gbà tó lè mú kí tọkọtaya kọ ara wọn sílẹ̀, ó ní: “Ẹnì yòówù tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, bí kò ṣe lórí ìpìlẹ̀ àgbèrè, [ìyẹn ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹlòmíì tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya ẹni] tí ó sì gbé òmíràn níyàwó, ṣe panṣágà.”—Mátíù 19:9.

Ọlọ́run kórìíra kí tọkọtaya fi ẹ̀tàn àti àdàkàdekè kọ ara wọn sílẹ̀. Ó máa dá àwọn tó kọ ara wọn sílẹ̀ láìtọ́ lẹ́jọ́, ní pàtàkì tó bá jẹ́ pé torí kí wọ́n lè lọ fẹ́ ẹlòmíì ni wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀.—Málákì 2:13-16; Máàkù 10:9.

8 Ǹjẹ́ Ọlọ́run fọwọ́ sí kí ọkùnrin máa bá ọkùnrin lòpọ̀ àti kí obìnrin máa bá obìnrin lòpọ̀?

▪ Ìdáhùn: Ní kedere Bíbélì dẹ́bi fún àgbèrè, èyí tó kan kí ọkùnrin máa bá ọkùnrin lòpọ̀ àti kí obìnrin máa bá obìnrin lòpọ̀. (Róòmù 1:26, 27; Gálátíà 5:19-21) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì sọ ní kedere pé Ọlọ́run kórìíra àṣà yìí pátápátá, síbẹ̀ a mọ̀ pé “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 3:16.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni tòótọ́ kórìíra àṣà kí ọkùnrin máa bá ọkùnrin lòpọ̀ àti kí obìnrin máa bá obìnrin lòpọ̀, síbẹ̀ wọ́n ń fi inú rere hàn sí gbogbo èèyàn. (Mátíù 7:12) Ọlọ́run fẹ́ ká “bọlá fún onírúurú ènìyàn gbogbo.” Nítorí náà, àwọn Kristẹni tòótọ́ kò kórìíra àwọn ọkùnrin tó ń bá ọkùnrin lòpọ̀ àtàwọn obìnrin tó ń bá obìnrin lòpọ̀.—1 Pétérù 2:17.

9 Ǹjẹ́ ó burú láti máa sọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ lórí tẹlifóònù tàbí fífi ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe ránṣẹ́ lórí tẹlifóònù tàbí Íńtánẹ́ẹ̀tì?

▪ Ìdáhùn: Sísọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ lórí tẹlifóònù tàbí fífi ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe ránṣẹ́ lórí tẹlifóònù tàbí Íńtánẹ́ẹ̀tì wọ́pọ̀ gan-an lóde òní.

Kò sí ibì kankan tí Bíbélì ti sọ̀rọ̀ ní pàtó lórí àwọn àṣà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbòde yìí. Àmọ́ ó sọ pé: “Kí a má tilẹ̀ mẹ́nu kan àgbèrè àti ìwà àìmọ́ onírúurú gbogbo tàbí ìwà ìwọra láàárín yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ àwọn ènìyàn mímọ́; bẹ́ẹ̀ náà ni ìwà tí ń tini lójú tàbí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ tàbí ìṣẹ̀fẹ̀ rírùn, àwọn ohun tí kò yẹ.” (Éfésù 5:3, 4) Sísọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ lórí tẹlifóònù àti fífi ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe ránṣẹ́ lórí tẹlifóònù àti Íńtánẹ́ẹ̀tì ń gbé èrò tí kò tọ́ nípa ìbálòpọ̀ lárugẹ, ó sì ń fún àwọn èèyàn níṣìírí láti máa ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni ti kì í ṣe ọkọ tàbí aya wọn. Kàkà kí àṣà yìí ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ṣàkóso ìfẹ́ ìbálòpọ̀ tó máa ń wà lọ́kàn ẹni, ńṣe ló ń mú kí ìfẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ túbọ̀ lágbára lọ́kàn àwọn èèyàn.

10 Kí ni Bíbélì sọ nípa fífi ọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ara ẹni láti mú ara ẹni gbóná?

▪ Ìdáhùn: Kò sí ibì kankan tí Bíbélì ti sọ̀rọ̀ ní pàtó lórí àṣà fífi ọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ara ẹni láti mára ẹni gbóná. Àmọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pàṣẹ fún àwọn Kristẹni pé: “Ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé di òkú ní ti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn [tí kò tọ́] fún ìbálòpọ̀ takọtabo.”—Kólósè 3:5.

Fífọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ẹni láti mára ẹni gbóná máa ń mú kéèyàn dẹni tí èrò nípa ìbálòpọ̀ gbà lọ́kàn, kò sì ní jẹ́ kéèyàn ní èrò tó tọ́ nípa ìbálòpọ̀. Bíbélì fi dáni lójú pé Ọlọ́run lè fún àwọn tó bá ń fi tọkàntọkàn sapá láti jáwọ́ nínú àṣà yìí ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” láti borí rẹ̀.—2 Kọ́ríńtì 4:7; Fílípì 4:13.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Por·neiʹa tún kan oríṣi àwọn ìbálòpọ̀ míì tí Ọlọ́run kò ní lọ́kàn nígbà tó ṣe ẹ̀yà ara tó wà fún ìbálòpọ̀, irú àwọn ìbálòpọ̀ bíi, panṣágà, kí ọkùnrin máa bá ọkùnrin lòpọ̀ àti kí obìnrin máa bá obìnrin lòpọ̀ àti bíbá ẹranko lòpọ̀.

^ Fún ìsọfúnni síwájú sí i lórí ohun tí Bíbélì sọ nípa iṣẹ́ abẹ tó ń sọni di aláìlèbímọ, jọ̀wọ́ ka Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé, èyí tó wà nínú Ilé Ìṣọ́, June 15, 1999, ojú ìwé 27 sí 28.

^ Fún ìjíròrò lórí bóyá ẹni tí wọ́n fipá bá lòpọ̀ lè ṣẹ́yún, ka ìwé ìròyìn Jí! May 22, 1993, ojú ìwé 10 sí 11. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.