Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Gbé Ìgbé Ayé Wa Ní Ìbámu Pẹ̀lú Àwọn Ìlànà Bíbélì?
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Gbé Ìgbé Ayé Wa Ní Ìbámu Pẹ̀lú Àwọn Ìlànà Bíbélì?
ṢÉ ÒÓTỌ́ ni pé ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbálòpọ̀ kò bóde mu mọ́ àti pé ó ti le jù? Rárá. Dípò ìyẹn, ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbálòpọ̀ lè ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún:
▪ Àwọn àrùn téèyàn ń kó nípasẹ̀ ìbálòpọ̀
▪ Oyún ẹ̀sín
▪ Ìbànújẹ́ tí ìgbéyàwó tó túká máa ń fà
▪ Ẹ̀rí ọkàn tó ń dáni lẹ́bi
▪ Ìtìjú
Jèhófà Ọlọ́run * tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá wa fẹ́ kó o gbádùn lílo àwọn ẹ̀bùn tó fún wa, ó sì fẹ́ kó o jàǹfààní wọn. Ọlọ́run ni “Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní.” (Aísáyà 48:17) Ẹni tó ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì nípa ìbálòpọ̀ nínú ìgbésí ayé rẹ̀ máa jèrè:
▪ Ojú rere Ọlọ́run
▪ Ìbàlẹ̀ ọkàn
▪ Ìdílé tó wà ní ìṣọ̀kan
▪ Orúkọ rere
▪ Ọ̀wọ̀ ara ẹni
Àmọ́ tó bá ṣẹlẹ̀ pé ní báyìí, o kò tíì máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì nínú ìgbésí ayé rẹ ńkọ́? Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe pé kó o yí bó o ṣe ń gbé ìgbé ayé rẹ pa dà? Ǹjẹ́ Ọlọ́run máa ka ohun tó o ti ṣe sẹ́yìn sí ẹ lọ́rùn?
Gbé èyí yẹ̀ wò: Àwọn kan lára àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ti fìgbà kan rí jẹ́, alágbèrè, onípanṣágà àti ọkùnrin tí ń bá ọkùnrin lòpọ̀ àti obìnrin tí ń bá obìnrin lòpọ̀. Wọ́n pinnu láti yí ìgbésí ayé wọn pa dà, wọ́n sì jàǹfààní tó pọ̀. 1 Kọ́ríńtì 6:9-11) Lóde òní, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn kárí ayé ló ti ṣe irú ìpinnu yìí. Wọ́n ti jáwọ́ nínú níní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ èèyàn, wọ́n sì ti jàǹfààní nínú títẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì nínú ìgbésí ayé wọn. Bí àpẹẹrẹ, kíyè sí àpẹẹrẹ Sarah tá a sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.
(“Kò Pẹ́ Rárá Tí Ara Fi Tù Mí”
Sarah rí i pé ìgbésí ayé jákujàku tí òun ń gbé kò fún òun ní òmìnira àti ìtẹ́lọ́rùn tí òun ń fẹ́. Ó sọ pé, “Mo kíyè sí i pé, ẹ̀rí ọkàn mi ti kú. Ìtìjú bá mi, ẹ̀rù sì ń bà mí pé mo lè lóyún tàbí kí n kó àrùn burúkú. Àmọ́ ṣá o, mo ṣì gbà gbọ́ pé Ọlọ́run wà àti pé ọ̀nà tí mo gbà ń gbé ìgbé ayé mi kò múnú rẹ̀ dùn. Mo rí i pé mo ti di aláìmọ́, mo sì ti lo ara mi nílòkulò.”
Nígbà tó yá, Sarah ní okun láti yí bó ṣe ń gbé ìgbé ayé rẹ̀ pa dà. Ó ní kí àwọn òbí òun tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ran òun lọ́wọ́. Ó tún ní kí àwọn alàgbà tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn tí wọ́n wà nínú ìjọ Kristẹni ran òun lọ́wọ́. Sarah sọ pé, “Ìyàlẹ́nu pátápátá ló jẹ́ fún mi láti rí bí àwọn òbí mi àtàwọn alàgbà ìjọ ṣe fi ìfẹ́ àti inú rere hàn sí mi. Kò pẹ́ rárá tí ara fi tù mí.”
Ní báyìí, Sarah ń tọ́ ọmọ rẹ̀ méjì. Sarah sọ pé, “Mi ò fi nǹkan kan pa mọ́ fún àwọn ọmọ mi nípa ìgbésí ayé tí mo gbé sẹ́yìn. Mo fẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí ojú mi rí nítorí pé mi ò tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run. Ohun tó wù mí ni pé, mò fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọyì àǹfààní tó máa ń ṣe fún ara àti èrò ẹni téèyàn bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run nípa ìbálòpọ̀. Mo gbà pé, ìdí tí Ọlọ́run fi fún wa láwọn ìlànà lórí ìwà híhù ni pé, kò fẹ́ ká ṣe ohun tó máa pa wá lára.”
Ìwọ náà lè jàǹfààní tó wà nínú títẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run. Bíbélì ṣèlérí yìí pé: “Àwọn àṣẹ ìtọ́ni láti ọ̀dọ̀ Jèhófà dúró ṣánṣán, wọ́n ń mú ọkàn-àyà yọ̀; àṣẹ Jèhófà mọ́, ó ń mú kí ojú mọ́lẹ̀. . . . Èrè ńlá wà nínú pípa wọ́n mọ́.”—Sáàmù 19:8, 11. *
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ.
^ Tó o bá fẹ́ mọ̀ síwájú sí i nípa àwọn ìmọ̀ràn tó gbéṣẹ́ tó wà nínú Bíbélì, wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kàn ládùúgbò rẹ. Tàbí kó o kọ̀wé sí àwọn tó ṣe ìwé yìí, wàá rí àdírẹ́sì tó o lè lò nínú èyí tó wà lójú ìwé 4 ìwé ìròyìn yìí tàbí kó o lọ sórí ìkànnì wa www.watchtower.org.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 8]
Àwọn tí kì í tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì sábà máa ń fa ìrora ọkàn fún àwọn èèyàn
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 9]
Àwọn tó ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì nínú ìgbésí ayé wọn máa ń ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, ìdílé wọn sì máa ń wà ní ìṣọ̀kan