Àjálù—Kí Nìdí Tó Fi Pọ̀ Tó Bẹ́ẹ̀?
Àjálù—Kí Nìdí Tó Fi Pọ̀ Tó Bẹ́ẹ̀?
Ó JỌ pé ọ̀rọ̀ nípa àjálù máa ń wọ́pọ̀ nínú ìròyìn. Ọ̀pọ̀ èèyàn tó ju ti tẹ́lẹ̀ lọ ni oríṣiríṣi àjálù ti ṣe lọ́ṣẹ́. Ibùdó Ìṣèwádìí Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Àjálù lórílẹ̀-èdè Belgium ròyìn pé lọ́dún 2010 nìkan, àjálù irínwó ó dín mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [373] ló wáyé, ó kéré tán, èèyàn ẹgbàá méjìdínláàádọ́jọ [296,000] ló kú nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Iye àjálù tí ìròyìn ń gbé jáde ti lọ sókè gan-an láti nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún wá. Bí àpẹẹrẹ, láti ọdún 1975 sí ọdún 1999, nǹkan bí àjálù ọ̀ọ́dúnrún [300] ló ń wáyé lọ́dọọdún. Àmọ́ láti ọdún 2000 sí ọdún 2010, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àjálù irínwó [400] tó ń wáyé lọ́dọọdún. Bóyá ìwọ náà wà lára àwọn tó ń ṣe kàyéfì pé, ‘Kí nìdí tí àjálù fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ nísinsìnyí?’
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn sábà máa ń pe irú àwọn àjálù bẹ́ẹ̀ ni “àmúwá Ọlọ́run,” kì í ṣe bẹ́ẹ̀ rárá. Ọlọ́run kọ́ ló ń fa àwọn àjálù tó ń dé bá àwọn èèyàn lónìí. Àmọ́ ṣá o, Bíbélì sọ pé àjálù yóò wà ní àkókò tiwa yìí. Bí àpẹẹrẹ, ní Mátíù 24:7, 8, Jésù sọ pé: “Àìtó oúnjẹ àti ìsẹ̀lẹ̀ yóò sì wà láti ibì kan dé ibòmíràn. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìroragógó wàhálà.” Kí nìdí tí Jésù fi sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, àmì wo ni wọ́n sì jẹ́ fún wa?
Jésù, Ọmọ Ọlọ́run dáhùn ìbéèrè tí wọ́n bi í pé: “Kí ni yóò sì jẹ́ àmì . . . ìparí ètò àwọn nǹkan?” (Mátíù 24:3) Ó sọ nípa oríṣiríṣi nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ títí kan àjálù bí irú àwọn tá a mẹ́nu kàn ṣáájú. Lẹ́yìn náà, ó sọ ọ̀rọ̀ pàtàkì yìí pé: “Nígbà tí ẹ bá rí nǹkan wọ̀nyí tí ń ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé ìjọba Ọlọ́run sún mọ́lé.” (Lúùkù 21:31) Nítorí náà, àjálù wọ̀nyẹn jẹ́ àmì pàtàkì kan fún wa. Wọ́n ń tọ́ka sí àkókò kan lọ́jọ́ iwájú tí àwọn ìyípadà pàtàkì máa ṣẹlẹ̀.
Àwọn Ohun Tó Ń Fa Àjálù Náà
Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ èèyàn ṣì ń béèrè pé, bí kì í bá ṣe Ọlọ́run ló ń fa àjálù wọ̀nyẹn, ta ló ń fà wọ́n tàbí kí ló ń fà wọ́n? A lè mọ ìdáhùn náà bí a bá mọ òtítọ́ pàtàkì kan tí Bíbélì sọ, ó ní: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú 1 Jòhánù 5:19) Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run kọ́ ló ń fa gbogbo ohun tó ń bani nínú jẹ́ tó wà nínú ayé yìí, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ọ̀tá rẹ̀ ló ń fà á, ìyẹn “ẹni búburú náà” tí Bíbélì pè ní “Èṣù.”—Ìṣípayá 12:9, 12.
náà.” (Nítorí ìmọtara ẹni nìkan tí ọ̀tá Ọlọ́run yìí ní, kò ka ẹ̀mí àwọn èèyàn sí nǹkan kan. Nítorí pé òun ló ń ṣàkóso gbogbo ayé, ó ti mú kí àwọn èèyàn di onímọtara ẹni nìkan bíi tirẹ̀. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa èyí pé, ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” àwọn ènìyàn yóò jẹ́ “olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera.” (2 Tímótì 3:1, 2) Nítorí náà, kò yani lẹ́nu pé kárí ayé ni Èṣù ti ṣètò àwọn nǹkan tó ń gbé irú àwọn ìwà yìí lárugẹ àtàwọn ìwà míì tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Ọ̀tá yìí máa ń mú kí àwọn èèyàn ní ojú kòkòrò àti ìwọra tó ń ṣàkóbá fún àwọn èèyàn.
Ọ̀nà wo ni ojúkòkòrò àwọn èèyàn gbà ń fa àjálù lóde òní? Àjọ Ìparapọ̀ àwọn Orílẹ̀-èdè sọ̀rọ̀ nípa àjálù kárí ayé, ó ní: “Àgbègbè eléwu làwọn èèyàn sábà máa ń gbé, irú bí àgbègbè tí ìkún omi ti máa ń wáyé. Yàtọ̀ sí ìyẹn, wọ́n ti pa igbó àtàwọn igi run, wọ́n sì ti ba àwọn irà jẹ́, ìyẹn sì ti ṣàkóbá fún àwọn nǹkan tó ń dènà jàǹbá. Èyí tó wá pabanbarì ni ti ojú ọjọ́ tó ń yi pa dà kárí ayé àti omi òkun tó ń pọ̀ sí i nítorí afẹ́fẹ́ olóró tí àwọn ilé iṣẹ́ ń tú jáde.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ iṣẹ́ táwọn èèyàn ń ṣe ni wọ́n sọ pé ó ń mú ìlọsíwájú bá ọrọ̀ ajé, àmọ́, ní tòdodo ìmọtara ẹni nìkan, ìwọra àti ojúkòkòrò ló mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ṣe iṣẹ́ ti wọ́n ń ṣe.
Nítorí náà, ọ̀pọ̀ ọ̀jọ̀gbọ́n ti wá rí i pé ìwà ìmọtara ẹni nìkan tí àwọn èèyàn ń hù ti dá kún àbájáde búburú tí àjálù máa ń fà. Ká sòótọ́, àwọn èèyàn ń ṣe ìfẹ́ Èṣù nípa ṣíṣe àtìlẹ́yìn fún àwọn nǹkan tí Èṣù ń lò láti mú kí ìyà tí àjálù ń fà máa pọ̀ sí i.
Ní báyìí, a ti rí i pé ohun tí kò dáa táwọn èèyàn ń ṣe ló ń fa ọ̀pọ̀ àjálù tó ń wáyé. A sì tún ti rí i pé àwọn àjálù kan ì bá má ṣe ọṣẹ́ tó pọ̀, ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé ló mú kó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀. Ní ọ̀pọ̀ ibi lágbàáyé, ìwà burúkú tí àwọn ọ̀bàyéjẹ́ ń hù ló mú kí àjálù túbọ̀ máa ṣeni lọ́ṣẹ́. Ohun míì tó tún ń mú kí ọṣẹ́ tí àjálù ń fà pọ̀ ni bí ipò òṣì àti ọrọ̀ ajé tó dẹnu kọlẹ̀ tó wà nínú ayé lónìí ṣe mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa gbé níbi eléwu. Àmọ́ ṣá o, àjálù tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn kan kì í ṣe nítorí pé wọn kò bìkítà tàbí pé ó jẹ́ ẹ̀bi ẹnì kan, ohun tó fà á ni “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ [tó] ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.”—Oníwàásù 9:11.
Ohun yòówù kó fa àjálù, kí lo máa ṣe tí àjálù bá ṣẹlẹ̀ tó sì kàn ẹ́? A máa ṣàgbéyẹ̀wò ohun tí o lè ṣe tí àjálù kò fi ní ní ipa tó pọ̀ jù lórí rẹ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Àpọ̀jù èèyàn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Pípa igbó run
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Bíba àyíká jẹ́
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 5]
Òsì: © Mark Henley/Panos Pictures
Àárín: © Jeroen Oerlemans/Panos Pictures