“Ìgbà Nínífẹ̀ẹ́ àti Ìgbà Kíkórìíra”
“Ìgbà Nínífẹ̀ẹ́ àti Ìgbà Kíkórìíra”
“ỌLỌ́RUN jẹ́ ìfẹ́.” Láwọn ilẹ̀ kan, àwọn èèyàn máa ń kọ ọ̀rọ̀ yìí, tí wọ́n á sì wá gbé e kọ́ sára ògiri ilé wọn. Ká sòótọ́, ọ̀rọ̀ yìí gan-an ló yẹ láti fi ṣàlàyé irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́, torí pé ìfẹ́ ló gba iwájú nínú àwọn ìwà rẹ̀.
Àmọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò mọ̀ pé inú Bíbélì ni ọ̀rọ̀ yìí ti wá. Àpọ́sítélì Jòhánù ló kọ ọ̀rọ̀ yìí pé: “Ẹni tí kò bá nífẹ̀ẹ́ kò tíì mọ Ọlọ́run, nítorí Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Jòhánù tún sọ nípa ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí ìran aráyé tó ṣeé rà pa dà, ó ní: “Nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 3:16.
Èyí lè mú kí àwọn kan máa rò pé, Ọlọ́run ṣe tán láti máa gbójú fo gbogbo nǹkan tí a bá ṣe. Ọ̀nà tí ọ̀pọ̀ gbà ń gbé ìgbé ayé wọn fi èrò ọkàn wọn hàn, èrò náà ni pé Ọlọ́run kò ní sọ pé kí èèyàn wá jíhìn fún ìwà èyíkéyìí tó bá hù. Àmọ́ ṣé òótọ́ ni? Ǹjẹ́ gbogbo èèyàn ni Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́, títí kan ẹni rere àti búburú? Ǹjẹ́ ìgbà kan wà tí Ọlọ́run máa ń kórìíra?
Ìfẹ́ àti Ìkórìíra
Sólómọ́nì ọlọ́gbọ́n Ọba sọ pé: “Ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún, àní ìgbà fún gbogbo àlámọ̀rí lábẹ́ ọ̀run . . . ìgbà nínífẹ̀ẹ́ àti ìgbà kíkórìíra.” (Oníwàásù 3:1, 8) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ní ìfẹ́ gan-an tí ó sì láàánú, àmọ́ gẹ́gẹ́ bí ìlànà yìí ti fi hàn, àwọn àkókò kan wà tó máa ń kórìíra.
Lákọ̀ọ́kọ́, kí ni ọ̀rọ̀ náà, “kíkórìíra” túmọ̀ sí gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe lò ó nínú Bíbélì? Ìwé kan tí a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé: “Nínú Ìwé Mímọ́, ọ̀rọ̀ náà ‘ìkórìíra’ ní oríṣiríṣi ìtumọ̀. Ó túmọ̀ sí kéèyàn máa bínú ẹnì kan ṣáá, kéèyàn sì fẹ́ kí ìyà máa jẹ onítọ̀hún. Ìkórìíra yìí lè lágbára gan-an débi tí á fi mú kí èèyàn fẹ́ ṣe ẹni náà ní jàǹbá.” Irú ìkórìíra yìí ló wọ́pọ̀, a sì ń rí àbájáde rẹ̀ kárí ayé. Àmọ́ ìwé náà ń bá a nìṣó pé: “‘Ìkórìíra’ tún lè túmọ̀ sí kéèyàn má ṣe fẹ́ràn ohun kan rárá, àmọ́ kéèyàn má ṣe ní èrò àtiṣe ìpalára fún nǹkan ọ̀hún.”
Nǹkan kejì tí ìkórìíra túmọ̀ sí yìí ni à ń jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí. Ó jẹ́ kíkórìíra ohun kan pátápátá, kì í ṣe kéèyàn ní ẹnì kan sínú tàbí kí èèyàn máa wá àtiṣe jàǹbá fún ẹni náà. Ǹjẹ́ Ọlọ́run lè ní irú ìkórìíra yìí? Kíyè sí ohun tó wà nínú ìwé Òwe 6:16-19, ó ní: “Ohun mẹ́fà ní ń bẹ tí Jèhófà kórìíra ní tòótọ́; bẹ́ẹ̀ ni, méje ni ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí fún ọkàn rẹ̀: ojú gíga fíofío, ahọ́n èké, àti ọwọ́ tí ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ sílẹ̀, ọkàn-àyà tí ń fẹ̀tàn hùmọ̀ àwọn ìpètepèrò tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, ẹsẹ̀ tí ń ṣe kánkán láti sáré sínú ìwà búburú, ẹlẹ́rìí èké tí ń gbé irọ́ yọ, àti ẹnikẹ́ni tí ń dá asọ̀ sílẹ̀ láàárín àwọn arákùnrin.”
Jẹ́nẹ́sísì 8:21; Róòmù 5:12) Ẹni tó kọ ìwé Òwe fi àpẹẹrẹ tó dáa yìí ṣàlàyé rẹ̀, ó ní: “Ẹni tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ni ó ń fi ìbáwí tọ́ sọ́nà, àní gẹ́gẹ́ bí baba ti ń tọ́ ọmọ tí ó dunnú sí.” (Òwe 3:12) Òbí máa ń kórìíra ìwà àìgbọràn tí ọmọ kan hù, àmọ́ ó ṣì máa nífẹ̀ẹ́ ọmọ rẹ̀, á sì ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti gba ìwàkiwà lọ́wọ́ rẹ̀ nípa bíbá ọmọ náà wí. Bákan náà, nítorí ìfẹ́ tí Jèhófà ní, òun pẹ̀lú máa ń gbé irú ìgbésẹ̀ yìí láti gba ẹlẹ́ṣẹ̀ kan là, ìyẹn ẹni tí ìrètí wà pé ó ṣì lè ronú pìwà dà.
Gẹ́gẹ́ bá a ṣe rí i, àwọn ìwà kan wà tí Ọlọ́run kórìíra. Àmọ́, kò pọn dandan pé ó máa kórìíra ẹni tó hùwà náà. Ó máa ń wo àwọn nǹkan kan mọ́ wa lára, irú bíi kùdìẹ̀-kudiẹ ara wa, ibi tí a gbé dàgbà, bí wọ́n ṣe tọ́ wa àti àìmọ̀kan wa. (Ìgbà Tí Ó Tọ́ Láti Kórìíra
Tó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹnì kan mọ ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run, àmọ́ tí ó kọ̀ láti ṣe é ńkọ́? Ìbínú Ọlọ́run ni irú ẹni bẹ́ẹ̀ ń wá, kì í ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ńṣe ló máa mú kí Jèhófà kórìíra òun tí ó bá ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣe àwọn nǹkan tí Jèhófà kórìíra. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ ń ṣàyẹ̀wò olódodo àti ẹni burúkú, dájúdájú, ọkàn Rẹ̀ kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.” (Sáàmù 11:5) Irú ẹni tí kò ronú pìwà dà bẹ́ẹ̀ kò lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà, gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ti sọ nínú lẹ́tà tó kọ sí àwọn Hébérù pé: “Bí a bá mọ̀ọ́mọ̀ sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà lẹ́yìn rírí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́ gbà, kò tún sí ẹbọ kankan tí ó ṣẹ́ kù fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, bí kò ṣe ìfojúsọ́nà fún ìdájọ́ akúnfẹ́rù, owú amú-bí-iná sì wà tí yóò jó àwọn tí ń ṣàtakò run.” (Hébérù 10:26, 27) Kí nìdí tí Ọlọ́run ìfẹ́ fi fẹ́ ṣe irú nǹkan yìí?
Bí ẹnì kan bá ń mọ̀ọ́mọ̀ dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì, ìwà ibi náà lè wá mọ́ onítọ̀hún lára. Ó lè sọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ di oníwà ibi tí kò ní ṣeé yí pa dà. Bíbélì fi irú ẹni náà wé àmọ̀tẹ́kùn tí kò lè yí àmì tó wà ní ara rẹ̀ pa dà. (Jeremáyà 13:23) Àwọn tí kò lè ronú pìwà dà mọ́ yìí ń dá ẹ̀ṣẹ̀ tí Bíbélì pè ní “ẹ̀ṣẹ̀ àìnípẹ̀kun,” èyí tí kò ní ìdáríjì.—Máàkù 3:29.
Bí ọ̀rọ̀ Ádámù àti Éfà àti Júdásì Ísíkáríótù ṣe rí nìyẹn. Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé ẹni pípé ni Ọlọ́run dá Ádámù àti Éfà tó sì fún wọn ní àṣẹ tó ṣe kedere, tó sì yé àwọn méjèèjì, ẹ̀rí fi hàn pé wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ dá ẹ̀ṣẹ̀ náà ni, nítorí náà wọn kò lè sọ pé àwọn kò mọ̀ọ́mọ̀. Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ fún wọn lẹ́yìn náà fi hàn pé wọn kò lè ní àǹfààní láti ronú pìwà dà. (Jẹ́nẹ́sísì 3:16-24) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni Júdásì, ó láǹfààní láti bá Ọmọ Ọlọ́run rìn, àmọ́ ó di ọ̀dàlẹ̀. Jésù pàápàá pe Júdásì ní “ọmọ ìparun.” (Jòhánù 17:12) Bíbélì tún fi hàn pé ó ti pẹ́ tí Èṣù ti ń hùwà ibi, nítorí náà, ìparun ló máa gbẹ̀yìn rẹ̀. (1 Jòhánù 3:8; Ìṣípayá 12:12) Torí bẹ́ẹ̀, àwọn wọ̀nyí ti di ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ Ọlọ́run.
Àmọ́, ó tuni nínú láti mọ̀ pé, kì í ṣe gbogbo ẹni tó ṣẹ̀ ni kò lè ṣàtúnṣe. Jèhófà ní sùúrù gan-an, kì í fẹ́ láti fi ìyà jẹ ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ nítorí àìmọ̀kan. (Ìsíkíẹ́lì 33:11) Ó fẹ́ kí wọ́n ronú pìwà dà kí wọ́n sì rí ìdáríjì gbà. Bíbélì sọ pé: “Kí ènìyàn burúkú fi ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀, kí apanilára sì fi ìrònú rẹ̀ sílẹ̀; kí ó sì padà sọ́dọ̀ Jèhófà, ẹni tí yóò ṣàánú fún un, àti sọ́dọ̀ Ọlọ́run wa, nítorí tí òun yóò dárí jì lọ́nà títóbi.”—Aísáyà 55:7.
Èrò Tó Tọ́ Nípa Ìfẹ́ àti Ìkórìíra
Ó yẹ kí àwọn Kristẹni tòótọ́ tó ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ọlọ́run mọ “ìgbà nínífẹ̀ẹ́” àti “ìgbà kíkórìíra.” Bí ojú àánú bá pọ̀ jù, èyí lè mú kí èèyàn máa fi ìfẹ́ àti àánú hàn lọ́nà tí kò tọ́. Àmọ́ ọ̀rọ̀ tí ọmọ ẹ̀yìn náà Júdà sọ lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ bí a ṣè lè fi àánú tó tọ́ hàn àti bí a ṣe lè kórìíra ẹ̀ṣẹ̀, ó ní: “Ẹ máa bá a lọ ní fífi àánú hàn fún àwọn ẹlòmíràn, ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìbẹ̀rù, ní àkókò kan náà kí ẹ kórìíra ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ tí ara ti kó àbààwọ́n bá.” (Júdà 22, 23) Nítorí náà, ó yẹ ká kórìíra ohun búburú, àmọ́ kò yẹ ká kórìíra ẹni tó hùwà búburú náà.
Bíbélì tún pàṣẹ pé kí àwọn Kristẹni máa fi ìfẹ́ hàn sí àwọn ọ̀tá wọn nípa ṣíṣe ohun tó dara sí wọn. Jésù sọ pé: “Ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín àti láti máa gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín.” (Mátíù 5:44) Ìdí nìyẹn tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń lọ léraléra sọ́dọ̀ àwọn aládùúgbò wọn, tí wọn kò sì dáwọ́ dúró láti máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún wọn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan kò fẹ́ gbọ́ ìwàásù náà. (Mátíù 24:14) Tí a bá fi ojú ohun tí Bíbélì sọ wò ó, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ka gbogbo èèyàn sí ẹni tó lè rí ìfẹ́ àti àánú Jèhófà gbà. Bí àwọn èèyàn kò bá mọyì ìsapá tí wọ́n ń ṣe tàbí tí wọn kò fàyè gbà wọ́n tàbí tí wọ́n ṣe inúnibíni sí wọn, àwọn Ẹlẹ́rìí máa ń fi ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sílò, ó ní: “Ẹ máa bá a nìṣó ní sísúre fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni; ẹ máa súre, ẹ má sì máa gégùn-ún . . . Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan.” (Róòmù 12:14, 17) Wọ́n mọ̀ pé, Jèhófà fúnra rẹ̀ ló máa pinnu ẹni tó máa rí ìfẹ́ rẹ̀ gbà àti ẹni tí ìkórìíra tọ́ sí. Tó bá dọ̀ràn ìyè àti ikú, ohun tí Ọlọ́run bá sọ labẹ́ gé.—Hébérù 10:30.
Òótọ́ ni pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” Ní tiwa, a ní láti mọrírì ìfẹ́ rẹ̀, kí á sì sapá láti mọ àwọn nǹkan tó jẹ́ ìfẹ́ rẹ̀, kí á sì máa ṣe wọ́n. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ yóò dùn láti fi Bíbélì rẹ ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ àti bó o ṣe lè fi í sílò ní ìgbésí ayé rẹ. Tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá di ẹni tí Ọlọ́run fi ìfẹ́ hàn sí, o kò ní di ẹni tí Ọlọ́run kórìíra.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 23]
“Ohun mẹ́fà ní ń bẹ tí Jèhófà kórìíra ní tòótọ́; bẹ́ẹ̀ ni, méje ni ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí fún ọkàn rẹ̀: ojú gíga fíofío, ahọ́n èké, àti ọwọ́ tí ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ sílẹ̀, ọkàn-àyà tí ń fẹ̀tàn hùmọ̀ àwọn ìpètepèrò tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, ẹsẹ̀ tí ń ṣe kánkán láti sáré sínú ìwà búburú, ẹlẹ́rìí èké tí ń gbé irọ́ yọ, àti ẹnikẹ́ni tí ń dá asọ̀ sílẹ̀ láàárín àwọn arákùnrin.”—ÒWE 6:16-19
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 24]
“Bí a bá mọ̀ọ́mọ̀ sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà lẹ́yìn rírí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́ gbà, kò tún sí ẹbọ kankan tí ó ṣẹ́ kù fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, bí kò ṣe ìfojúsọ́nà fún ìdájọ́ akúnfẹ́rù, owú amú-bí-iná sì wà tí yóò jó àwọn tí ń ṣàtakò run.”—HÉBÉRÙ 10:26, 27
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 25]
“Kí ènìyàn burúkú fi ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀, kí apanilára sì fi ìrònú rẹ̀ sílẹ̀; kí ó sì padà sọ́dọ̀ Jèhófà, ẹni tí yóò ṣàánú fún un . . . Òun yóò dárí jì lọ́nà títóbi.”—AÍSÁYÀ 55:7
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Òbí tó nífẹ̀ẹ́ máa ń bá ọmọ rẹ̀ wí torí kó lè ràn án lọ́wọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ọ̀pọ̀ àwọn tó wà lẹ́wọ̀n ni wọ́n ti jàǹfààní ìfẹ́ àti àánú Ọlọ́run