Bí O Ṣe Lè Fara Da Àjálù
Bí O Ṣe Lè Fara Da Àjálù
Nítorí bí àwọn àjálù ṣe ń wáyé lemọ́lemọ́, tí wọ́n sì máa ń ba nǹkan jẹ́, kí lẹnì kan lè ṣe láti fara da àjálù? Ẹ jẹ́ ká wo àwọn ohun téèyàn lè ṣe.
Yàgò fún àjálù. Bíbélì sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́, ṣùgbọ́n aláìní ìrírí gba ibẹ̀ kọjá, yóò sì jìyà àbájáde rẹ̀.” (Òwe 22:3) Ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n yìí wúlò gan-an tí àjálù bá fẹ́ ṣẹlẹ̀. Nígbà tí wọ́n bá ṣèkìlọ̀ nípa òkè ayọnáyèéfín tó fẹ́ bú gbàù, tí wọ́n sọ nípa ìkún omi tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀ tàbí nípa ìjì líle, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé káwọn èèyàn fi àgbègbè náà sílẹ̀, kí wọ́n sì lọ sí ibi tí kò fi bẹ́ẹ̀ léwu. Ẹ̀mí èèyàn ṣeyebíye ju ilé tàbí ohun ìní lọ.
Ó ṣeé ṣe fún àwọn kan láti má ṣe gbé ní ibi tí ewu pọ̀ sí. Aláṣẹ kan sọ pé: “Àwọn ibì kan wà tí àjálù ti lè tètè wáyé. Àgbègbè kékeré kan wà lórí ilẹ̀ ayé tó jẹ́ pé àjálù lè tètè wáyé níbẹ̀, ọ̀pọ̀ àjálù ńláńlá ló sì tún máa wáyé ní àgbègbè yìí lọ́jọ́ iwájú.” Èyí lè jẹ́ òótọ́, bí àpẹẹrẹ, àjálù lè tètè wáyé ní àwọn etíkun tàbí ní àwọn ibi tí ilẹ̀ ti lè tètè ri. Tí o kò bá gbé ní irú ibi eléwu yìí tàbí tí o bá lè kó lọ sí ibi tí kò fi bẹ́ẹ̀ léwu, ó máa ṣeé ṣe fún ọ láti yẹra fún àjálù dé ìwọ̀n tó pọ̀.
Múra sílẹ̀. Láìka gbogbo ìsapá tí o ṣe sí, àjálù ṣì lè ṣẹlẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀, ó sì lè kàn ẹ́. Á rọrùn fún ọ láti la àjálù já tó o bá ti múra sílẹ̀ kó tó dé. Èyí bá ìmọ̀ràn tó wà nínú ìwé Owe 22:3 tá a sọ níṣàájú mu. Ǹjẹ́ o ní àpò kékeré tí o ti di àwọn nǹkan tí o nílò sí, èyí tí o lè gbé dání nígbà tí nǹkan pàjáwìrì bá ṣẹlẹ̀? Ìwé tó sọ nípa àkókò pàjáwìrì, ìyẹn 1-2-3 of Disaster Education dábàá àwọn nǹkan tí o lè kó sínú àpò náà, àwọn ni: oògùn fún ìtọ́jú pàjáwìrì, omi inú ike, oúnjẹ tí kò lè tètè bà jẹ́ àtàwọn akọsílẹ̀ pàtàkì. Ó tún bọ́gbọ́n mu láti jẹ́ kí àwọn ará ilé rẹ mọ̀ nípa irú àjálù tó lè ṣẹlẹ̀ àtàwọn nǹkan tí wọ́n lè ṣe tí àjálù èyíkéyìí bá ṣẹlẹ̀.
Sún mọ́ Ọlọ́run. Èyí lè ràn ọ́ lọ́wọ́ ní gbogbo ọ̀nà. Bíbélì sọ pé Ọlọ́run jẹ́ “Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo, ẹni tí ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa.” Ẹsẹ míì nínú Bíbélì sọ pé, Ọlọ́run ni “ẹni tí ń tu àwọn tí a rẹ̀ sílẹ̀ nínú.”—2 Kọ́ríńtì 1:3, 4; 7:6.
Òótọ́ ni pé Ọlọ́run mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé e. Ọlọ́run ìfẹ́ ni, ó sì ń ṣe ohun tó ń fúnni ní ìṣírí ní onírúurú ọ̀nà. (1 Jòhánù 4:8) Nítorí náà, dípò tí wàá fi máa gbàdúrà fún iṣẹ́ ìyanu, ńṣe ni kó o máa gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ tó lágbára gan-an, tó lè ranni lọ́wọ́ ní ipòkípò tí èèyàn bá wà. Ẹ̀mí mímọ́ lè mú kí àwọn tí àjálù bá rántí àwọn ẹsẹ Bíbélì kan tó lè tù wọ́n nínú, tí ara á sì tù wọ́n. Bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀rọ̀ àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run á dà bíi ti Dáfídì ọba Ísírẹ́lì àtijọ́ tó sọ pé: “Bí mo tilẹ̀ ń rìn ní àfonífojì ibú òjìji, èmi kò bẹ̀rù ohun búburú kankan, nítorí tí ìwọ wà pẹ̀lú mi; ọ̀pá rẹ àti ọ̀pá ìdaran rẹ ni àwọn nǹkan tí ń tù mí nínú.”—Sáàmù 23:4.
Àwọn Kristẹni máa ń ran ara wọn lọ́wọ́. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, wòlíì kan tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Kristẹni tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ágábù sọ pé, “ìyàn ńlá máa tó mú gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá; èyí tí ó ṣẹlẹ̀, ní ti tòótọ́, ní àkókò Kíláúdíù.” Ìyàn náà sì mú ọ̀pọ̀ ọmọ ẹ̀yìn Jésù gan-an ní Jùdíà. Kí làwọn ọmọ ẹ̀yìn tó wà níbòmíràn ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ nípa ìṣòro tí àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni ní? Àkọsílẹ̀ ìròyìn náà sọ pé: “Àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn pinnu, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn gẹ́gẹ́ bí agbára olúkúlùkù ti lè gbé e, láti fi ìpèsè a-dín-ìṣòro-kù ránṣẹ́ sí àwọn ará tí ń gbé ní Jùdíà.” (Ìṣe 11:28, 29) Wọ́n fi ìfẹ́ pèsè àwọn nǹkan tí àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni nílò.
Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní náà máa ń ṣe irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ nígbà tí àjálù tó kàmàmà bá wáyé. Àwọn èèyàn mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dáadáa pé wọ́n máa ń ṣèrànwọ́ fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ìmìtìtì ilẹ̀ ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Chile ní February 27, ọdún 2010, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tètè ṣèrànwọ́ fún àwọn tí àjálù náà bá. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Karla, tí ìkún omi tó ń jẹ́ sùnámì gbé ilé rẹ̀ lọ sọ pé: “Ó tù mí nínú, ó sì mú orí mi wú nígbà tí mo rí i tí [àwọn tá a jọ jẹ́ Ẹlẹ́rìí] dé ní ọjọ́ kejì láti ibòmíràn, tí wọ́n wá ràn wá lọ́wọ́. Kò sí àní-àní pé Jèhófà tù wá nínú nípasẹ̀ inú rere tí àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn náà fi hàn sí wa. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ mi, wọ́n sì dáàbò bò mí.” Bàbá àgbà obìnrin yìí tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà kíyè sí ìrànwọ́ tí wọ́n ṣe náà. Ó ní: “Ohun tí mo rí yìí yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí mo ti rí ní ọ̀pọ̀ ọdún nínú ṣọ́ọ̀ṣì mi.” Ohun tó rí náà mú kó sọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé kí wọ́n máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Bíbá àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run kẹ́gbẹ́ máa jẹ́ ìrànlọ́wọ́ ńlá fún wa ní àkókò àjálù. Yàtọ̀ síyẹn, ǹjẹ́ ìgbà kan máa wà tí kò ní sí àjálù mọ́ ní ayé yìí? Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì sọ lórí kókó yìí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Ǹjẹ́ o ní àpò kékeré tí o ti di àwọn nǹkan tí o nílò sí, èyí tí o lè gbé dání nígbà tí nǹkan pàjáwìrì bá ṣẹlẹ̀?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Nítorí náà, dípò tí wàá fi máa gbàdúrà fún iṣẹ́ ìyanu, ńṣe ni kó o máa gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ tó lágbára gan-an, tó lè ranni lọ́wọ́ ní ipòkípò tí èèyàn bá wà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn Kristẹni máa ń ran ara wọn lọ́wọ́ nígbà àjálù
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
“Wọ́n nífẹ̀ẹ́ mi, wọ́n sì dáàbò bò mí”