Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí O Ṣe Lè Yan Ọ̀rẹ́ Rere

Bí O Ṣe Lè Yan Ọ̀rẹ́ Rere

Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Bí O Ṣe Lè Yan Ọ̀rẹ́ Rere

Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a béèrè àwọn ìbéèrè tó o ti lè máa ṣe kàyéfì nípa wọn, a sì tún sọ ibi tó o ti lè rí ìdáhùn wọn kà nínú Bíbélì rẹ. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti bá ẹ sọ̀rọ̀ lórí ohun tí àwọn ìdáhùn náà jẹ́.

1. Kí nìdí tó fi yẹ ká kíyè sára nígbà tá a bá ń yan ọ̀rẹ́?

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń fẹ́ kí àwọn èèyàn fẹ́ràn àwọn. Èyí sì máa ń mú kí èèyàn fara wé àwọn tó wà láyìíká rẹ̀. Nítorí ìdí yìí, àwọn ọ̀rẹ́ wa máa ń ní ipa lórí àwọn ìwà tí a óò máa hù. Torí bẹ́ẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ tá a bá yàn lè nípa lórí irú ẹni tí a máa jẹ́.—Ka Òwe 4:23; 13:20.

Dáfídì wà lára àwọn tí Ọlọ́run mí sí láti kọ Bíbélì, ọkùnrin yìí sì fọgbọ́n yan àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Àwọn tó ràn án lọ́wọ́ láti máa jẹ́ olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run ló bá ṣọ̀rẹ́. (Sáàmù 26:4, 5, 11, 12) Bí àpẹẹrẹ, Dáfídì gbádùn àjọṣe tó wà láàárín òun àti Jónátánì, nítorí pé Jónátánì gbà á níyànjú láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.—Ka 1 Sámúẹ́lì 23:16-18.

2. Kí lo lè ṣe láti di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run?

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà jẹ́ alágbára gbogbo, síbẹ̀ a ṣì lè di ọ̀rẹ́ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Ábúráhámù di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Ábúráhámù gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó sì ṣègbọràn sí i, nítorí náà Jèhófà kà á sí ọ̀rẹ́ òun. (Jẹ́nẹ́sísì 22:2, 9-12; Jákọ́bù 2:21-23) Tí a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tí a sì ń ṣe ohun tó ní ká ṣe, àwa náà lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.—Ka Sáàmù 15:1, 2.

3. Bí o ṣe lè jàǹfààní látọ̀dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rere

Ọ̀rẹ́ rere máa ń dúró tini, ó sì máa ń ranni lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó tọ́. (Òwe 17:17; 18:24) Bí àpẹẹrẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kí Jónátánì fi ọgbọ̀n [30] ọdún ju Dáfídì lọ, tó sì tún jẹ́ pé òun ló kàn láti gorí ìtẹ́ ọba Ísírẹ́lì, àmọ́ ó dúró ti Dáfídì torí pé Dáfídì ni Ọlọ́run yàn láti jẹ́ ọba, Jónátánì sì tì í lẹ́yìn. Ọ̀rẹ́ rere tún máa ń ní ìgboyà láti tọ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ́nà tó bá rí i pé ó ń ṣe ohun tí kò dára. (Sáàmù 141:5) Ọ̀rẹ́ tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ní ìwà rere.—Ka 1 Kọ́ríńtì 15:33.

O lè rí àwọn èèyàn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ohun rere bíi tìẹ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Níbẹ̀, wàá rí àwọn ọ̀rẹ́ tó máa fún ẹ níṣìírí bí o ṣe ń sapá láti wu Ọlọ́run.—Ka Hébérù 10:24, 25.

Àmọ́ ṣá o, àwọn ọ̀rẹ́ tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run pàápàá lè ṣe ohun tó máa dùn wá nígbà míì. Má ṣe jẹ́ kí àṣìṣe wọn tètè múnú bí ẹ. (Oníwàásù 7:9, 20-22) Rántí pé kò sí ọ̀rẹ́ kan tó jẹ́ ẹni pípé, má sì gbàgbé pé àwọn ọ̀rẹ́ tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ṣeyebíye fún wa. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ̀ wá pé ká máa gbójú fo àṣìṣe àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni.—Ka Kólósè 3:13.

4. Kí lo lè ṣe bí àwọn tí o pè lọ́rẹ̀ẹ́ bá ta kò ẹ́?

Ọ̀pọ̀ èèyàn kíyè sí i pé, nígbà tí àwọn bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àwọn kan lára àwọn ọ̀rẹ́ wọn tẹ́lẹ̀ ta kò wọ́n. Ó lè jẹ́ pé irú àwọn ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ kò rí àǹfààní tó wà nínú ohun tí ò ń kọ́ tàbí kó jẹ́ pé ìrètí tó dájú tí o ti rí nínú Bíbélì kò jẹ́ nǹkan kan lójú wọn. Àmọ́ ṣá o, o lè gbìyànjú láti ràn wọ́n lọ́wọ́.—Ka Kólósè 4:6.

Ìgbà míì sì wà, tí àwọn tó o pè lọ́rẹ̀ẹ́ lè máa fi ìhìn rere tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe yẹ̀yẹ́. (2 Pétérù 3:3, 4) Àwọn kan lè máa fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí pé ò ń sapá láti ṣe ohun tó tọ́. (1 Pétérù 4:4) Bí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ó lè gba pé kí o yan èyí tí o máa ṣe, bóyá kí o fara mọ́ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tàbí kí o di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Tí o bá yàn láti jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, ọ̀rẹ́ tó dára jù lọ lò yàn yẹn.—Ka Jákọ́bù 4:4, 8.

Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka orí 12 àti 19 nínú ìwé yìí, Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.