Mo Fẹ́ Dà Bí Ọmọbìnrin Jẹ́fútà
Mo Fẹ́ Dà Bí Ọmọbìnrin Jẹ́fútà
Gẹ́gẹ́ bí Joanna Soans ṣe sọ ọ́
Nígbà tí mo wà láàárín ọmọ ọdún mẹ́tàlá sí mọ́kàndínlógún, ó wù mí gan-an láti dà bí ọmọbìnrin Jẹ́fútà. Ẹ jẹ́ kí n sọ ohun tí mo ní lọ́kàn àti bí mo ṣe wá dà bí ọmọbìnrin yìí nígbà tó yá.
LỌ́DÚN 1956, mo lọ sí àpéjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún ìgbà àkọ́kọ́ ní ìlú Bombay (tó ń jẹ́ Mumbai nísinsìnyí), lórílẹ̀-èdè Íńdíà, ìyẹn sì yí ìgbésí ayé mi pa dà. Àsọyé kan tí wọ́n sọ nípa ọmọbìnrin Jẹ́fútà wọ̀ mí lọ́kàn gan-an.
Tẹ́ ẹ bá ti kà nípa ọmọbìnrin Jẹ́fútà nínú Bíbélì, ó jọ pé nígbà tí ọmọ yìí kò tíì pé ogún ọdún, ó gbà láti má ṣe lọ́kọ. Èyí mú kó ṣeé ṣe fún bàbá rẹ̀ láti mú ẹ̀jẹ́ kan tó jẹ́ ṣẹ. Nítorí náà, ó ṣiṣẹ́ ìsìn ní ilé Jèhófà tàbí àgọ́ ìjọsìn ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ láìlọ́kọ.—Àwọn Onídàájọ́ 11:28-40.
Ó mà wù mí gan-an láti dà bí ọmọbìnrin yìí! Àmọ́, mo dojú kọ ìṣòro tó lágbára, torí pé nígbà yẹn kò bá àṣà wa mu ní Íńdíà pé kí obìnrin wà láìlọ́kọ.
Ìdílé Tí Mo Ti Wá
Èmi ni ìkarùn-ún nínú àwọn ọmọ mẹ́fà táwọn òbí wa, Benjamin àti Marcelina Soans bí, ìlú Udipi, tó wà ní etíkun ìwọ̀ oòrùn Íńdíà ni wọ́n bí wa sí. Èdè Tulu ni èdè ìbílẹ̀ wa, àwọn èèyàn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù méjì ló sì ń sọ èdè yìí. Àmọ́, èdè Kannada ni wọ́n fi kọ́ wa ní ilé ẹ̀kọ́, bó sì ṣe rí fún ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń gbé ní ìlú Udipi nìyẹn.
Àwọn tó ń gbé ní agbègbè yìí ka ìgbéyàwó àti ọmọ bíbí sí ohun tó ṣe pàtàkì gan-an. Nígbà tí mo wà ní ọmọdé, mi ò rántí bóyá a ní ọ̀rọ̀ tí à ń lò ní èdè Tulu fún “wíwà láìlọ́kọ tàbí wíwà láìláya,” “ìdánìkanwà,” tàbí “àárò ilé.” Ńṣe ló dà bíi pé kò sí ohun tó jọ àwọn nǹkan yìí rárá. Bí àpẹẹrẹ, ìdílé wa, bàbá àti ìyá àwọn òbí mi, àtàwọn ẹbí wọn lọ́kùnrin àti lóbìnrin pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn la jọ ń gbé nínú ilé kan náà!
Nínú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wa, ìdílé ìyá ló máa ń ni ọmọ. Ọ̀dọ̀ ìyá ni wọ́n ti máa ń mọ ìlà ìdílé, àwọn ọmọbìnrin ni wọ́n sì máa ń gba ogún tó pọ̀ jù. Láwọn àgbègbè kan tó jẹ́ ti àwọn tó ń sọ èdè Tulu, ọ̀dọ̀ ìyá ni ọmọbìnrin ṣì máa ń gbé lẹ́yìn tí ó bá ti ṣègbéyàwó, ọkọ rẹ̀ á sì wá máa gbé níbẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀.
Àmọ́, àwọn nǹkan díẹ̀ yàtọ̀ nítorí pé ìdílé wa ti di ẹlẹ́sìn Kristẹni. Ní gbogbo ìrọ̀lẹ́, bàbá-bàbá mi máa ń ṣáájú ìdílé wa nínú ìjọsìn, ó máa ń gbàdúrà, yóò sì wá ka Bíbélì tí wọ́n kọ lédè Tulu sókè. Ìgbàkigbà tó bá ṣí ògbólógbòó Bíbélì rẹ̀ tó fẹ́ kà á fún wa, ńṣe ló máa ń dà bíi pé ó ṣí àpótí tí wọ́n kó ohun ọ̀ṣọ́ iyebíye sí. Ó máa ń gbádùn mọ́ni gan-an! Ohun tó wà nínú Sáàmù 23:1 jọ mí lójú gan-an ni, ó ní: “Jèhófà ni Olùṣọ́ Àgùntàn mi. Èmi kì yóò ṣaláìní nǹkan kan.” Mo máa ń ṣe kàyéfì pé, ‘Ta ni Jèhófà yìí, kí sì nìdí tí wọ́n fi pè é ní olùṣọ́ àgùntàn?’
“Ìpẹ́” Já Bọ́ Lójú Mi
A kó lọ sí ìlú Bombay nítorí ipò ọrọ̀ ajé tí kò fara rọ èyí tí ó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ogún Àgbáyé Kejì, èyí tí ìlú yìí fi jìn síbi tá a wà tẹ́lẹ̀ lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún [900] kìlómítà. Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì wá sọ́dọ̀ bàbá mi lọ́dún 1945 ní ìlú yìí, wọ́n sì fún un ní ìwé kékeré kan tó sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì. Bàbá mi kà á tinútẹ̀yìn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ohun tó wà nínú rẹ̀ fún àwọn èèyàn tó ń sọ èdè Kannada. Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1950, àwùjọ kékeré kan tí wọ́n jọ ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀
Ọlọ́run di ìjọ àkọ́kọ́ ní ìlú Bombay, tí wọ́n ń fi èdè Kannada kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.Bàbá àti Màmá mi kọ́ àwa ọmọ wọn láti máa fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ká sì jẹ́ olùkọ́ tó dáńgájíà. Ojoojúmọ́ ni wọ́n máa ń wá àyè láti gbàdúrà pẹ̀lú wa, tí wọ́n sì máa ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́. (Diutarónómì 6:6, 7; 2 Tímótì 3:14-16) Lọ́jọ́ kan tí mò ń ka Bíbélì, ńṣe ló dà bíi pé ìpẹ́ já bọ́ lójú mi. Mo kẹ́kọ̀ọ́ pé, a fi Jèhófà wé olùṣọ́ àgùntàn nítorí pé, ó ń tọ́ àwọn olùjọsìn rẹ̀ sọ́nà, ó ń bọ́ wọn, ó sì ń dáàbò bò wọ́n.—Sáàmù 23:1-6; 83:18.
Jèhófà Ti Tọ́ Mi Sọ́nà
Mo ṣe ìrìbọmi kété lẹ́yìn àpéjọ àgbègbè mánigbàgbé tó wáyé ní ìlú Bombay lọ́dún 1956. Lóṣù mẹ́fà lẹ́yìn náà, mo tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin tó ń jẹ́ Prabhakar, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi ọ̀pọ̀ wákàtí wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń wù mí láti sọ ohun tó wà nínú Bíbélì fún àwọn èèyàn, síbẹ̀ ẹ̀rù máa ń bà mí tí ara mi á sì máa gbọ̀n. Mo máa ń kólòlò, ohùn mi á sì máa gbọ̀n. Mo sọ fún ara mi pé, ‘Jèhófà nìkan ló lè ràn mí lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ yìí!’
Jèhófà lo Homer àti Ruth McKay tí wọ́n jẹ́ míṣọ́nnárì láti orílẹ̀-èdè Kánádà láti ràn mí lọ́wọ́, ọdún 1947 ni wọ́n lọ sí ilé ẹ̀kọ́ míṣọ́nnárì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Wọ́n ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí mo kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù. Ruth máa ń fi bí a ṣe ń wàásù láti ilé dé ilé dánra wò pẹ̀lú mi. Ó mọ bó ṣe lè mú ara tù mí nígbà tí ẹ̀rù bá ń bà mí. Á di ọwọ́ mi tó ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ mú, á sì wá sọ fún mi pé: “Ọ̀rẹ́, má ṣèyọnu. Jẹ́ ká tún gbìyànjú ẹ̀ wò ní ilé tó kàn.” Ọ̀rọ̀ ìṣírí tí ó máa ń sọ fún mi lókun.
Lọ́jọ́ kan, wọ́n sọ fún mi pé obìnrin àgbàlagbà kan tó ń jẹ́ Elizabeth Chakranarayan, tó mọ bí a ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló máa jẹ́ ẹnì kejì mi nínú iṣẹ́ ìwàásù. Ohun tó kọ́kọ́ wá sí mi lọ́kàn ni pé: ‘Báwo ló ṣe máa rọrùn fún mi láti máa gbé pẹ̀lú irú arábìnrin yìí? Ó dàgbà jù mí lọ gan-an!’ Àmọ́ nígbà tó yá, mo wá rí i pé irú ẹni tí mo nílò láti jọ máa ṣiṣẹ́ gan-an nìyẹn.
“A Ò Dá Nìkan Wà Rí”
Ìlú Aurangabad tó wà ní nǹkan bí irínwó [400] kìlómítà ní ìlà oòrùn ìlú Bombay ni wọ́n kọ́kọ́ rán wa lọ láti wàásù, ìlú yìí lókìkí gan-an nítorí ìtàn rẹ̀. Kò pẹ́ tá a fi mọ̀ pé àwa méjèèjì yìí ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ìlú tí àwọn èèyàn tó ń gbé níbẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù kan. Yàtọ̀ síyẹn, mo ní láti kọ́ èdè Marathi, ìyẹn èdè tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń sọ ní ìlú náà.
Mo máa ń nímọ̀lára pé mo dá nìkan wà nígbà míì, mo sì máa ń sunkún bí ọmọ tí kò ní ìyá. Àmọ́ bí Elizabeth ṣe máa ń bá mi sọ̀rọ̀ bí ìyá máa ń fún mi ní ìṣírí. Ó máa ń sọ pé: “Ó lè ṣe wá bíi pé a dá nìkan wà nígbà míì, àmọ́ a kò dá nìkan wà rí. Òótọ́ ni pé ibi táwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn ìdílé rẹ wà lè jìnnà, àmọ́ gbogbo ìgbà ni Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ. Fi ṣe ọ̀rẹ́ rẹ, tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, o kò ní mọ̀ ọ́n lára pé o dá nìkan wà mọ́.” Ìmọ̀ràn rẹ̀ yẹn ṣì wà lọ́kàn mi títí dòní.
Bí owó ọkọ̀ tó wà lọ́wọ́ wa kò bá tó nǹkan, a máa ń fẹsẹ̀ rin ogún [20] kìlómítà lójoojúmọ́ ní ojú ọ̀nà tó ní eruku àti ẹrẹ̀ àti nínú oòrùn àti nínú òtútù. Nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, ojú ọjọ́ sábà máa ń gbóná gan-an tó nǹkan bí ìwọ̀n ọgọ́rùn-ún ó lé mẹ́rin [104°F]. Tó bá sì di ìgbà òjò, oṣù bíi mélòó kan ni ẹrẹ̀ fi máa ń wà láwọn apá ibì kan ní àgbègbè náà. Àmọ́, a rí i pé ọwọ́ tí àwọn èèyàn ibẹ̀ fi mú àṣà wọn lágbára ju ipò ojú ọjọ́ wọn lọ.
Àwọn obìnrin kì í bá àwọn ọkùnrin sọ̀rọ̀ ní gbangba àyàfi tí wọ́n bá bára tan, àwọn obìnrin kì í sì í sábà kọ́ àwọn ọkùnrin lẹ́kọ̀ọ́. Nítorí náà,
wọ́n máa ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ wọ́n sì máa ń bú wa. Ní oṣù mẹ́fà àkọ́kọ́ tá a lò níbẹ̀, àwa méjèèjì nìkan la máa ń ṣe ìpàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ níbi tá a ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ nígbà tó yá, àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí à ń wàásù dara pọ̀ mọ́ wa. Kò sì pẹ́ tí a fi fẹ́ dá àwùjọ kékeré kan sílẹ̀. Àwọn míì tiẹ̀ máa ń bá wa lọ wàásù.“Máa Mú Kí Iṣẹ́ Rẹ Túbọ̀ Dára Sí I”
Lẹ́yìn ọdún méjì ààbọ̀ ní ìlú yìí, wọ́n tún rán wa pa dà lọ sí ìlú Bombay. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Elizabeth ń bá iṣẹ́ ìwàásù lọ ní tiẹ̀, wọ́n ní kí èmi lọ ran bàbá mi lọ́wọ́ nìdí iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè, nítorí pé òun nìkan ló ń túmọ̀ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí a ń lò sí èdè Kannada. Inú rẹ̀ dùn pé mo wá ràn án lọ́wọ́, torí pé ó ní ọ̀pọ̀ iṣẹ́ tó ń bójú tó nínú ìjọ.
Ní ọdún 1966, àwọn òbí mi pinnu láti pa dà sí Udipi, níbi tí à ń gbé tẹ́lẹ̀. Nígbà tí bàbá mi fẹ́ kúrò ní Bombay, ó sọ fún mi pé: “Ọmọ mi, máa mú kí iṣẹ́ rẹ túbọ̀ dára sí i. Jẹ́ kí ohun tí ò ń túmọ̀ yéni kó sì ṣe kedere. Má ṣe dá ara rẹ lójú, kó o sì máa jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ nìṣó. Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.” Ìmọ̀ràn tó gbà mí kẹ́yìn nìyẹn, torí pé kò pẹ́ tó pa dà sí ìlú Udipi ni ó kú. Títí dòní, mo ṣì ń sapá láti ṣe ohun tó sọ bí mo ti ń ṣe iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè.
“Ṣé Ìwọ Ò Ní Lọ́kọ Kó O sì Bímọ Ni?”
Nínú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn Íńdíà, àwọn òbí máa ń ṣètò pé kí àwọn ọmọkùnrin àtàwọn ọmọbìnrin wọn ṣègbéyàwó nígbà tí wọ́n ṣì kéré, kí wọ́n lè tètè bẹ̀rẹ̀ sí í bímọ. Nítorí náà, wọ́n sábà máa ń bi mí pé: “Ṣé ìwọ ò ní lọ́kọ kó o sì bímọ ni? Ta ló máa tọ́jú rẹ tó o bá dàgbà? Ṣé o kò ní dá nìkan wà báyìí tó o bá ti darúgbó?”
Nígbà míì, irú àwọn ọ̀rọ̀ tó ń wá lemọ́lemọ́ yìí máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo máa ń mú un mọ́ra ní gbangba, àmọ́ mo máa ń sọ èrò ọkàn mi fún Jèhófà nígbà tí mo bá dá wà. Mo rí ìtùnú gbà torí mo mọ̀ pé Jèhófà kò kà mí sí ẹni tó ti pàdánù ohun kan nítorí pé mi ò lọ́kọ. Kí n lè gbájú mọ́ ìpinnu mi láti sin Ọlọ́run láìsí ìpínyà ọkàn, mo ronú lórí àpẹẹrẹ ọmọbìnrin Jẹ́fútà àti ti Jésù, àwọn méjèèjì kò ṣègbéyàwó, wọ́n sì gbájú mọ́ ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.—Jòhánù 4:34.
Ẹ̀bùn Látọ̀dọ̀ Jèhófà
Èmi àti Elizabeth jọ jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ fún ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́ta [50] ọdún. Obìnrin yìí kú lọ́dún 2005, lẹ́ni ọdún méjì dín lọ́gọ́rùn-ún [98]. Nígbà tí ọjọ́ ogbó kò jẹ́ kó lè ka Bíbélì mọ́, torí ojú rẹ̀ tó ti di bàìbàì, ńṣe ló máa ń lo èyí tó pọ̀ nínú ọjọ́ kọ̀ọ̀kan láti gbàdúrà gígùn sí Ọlọ́run. Nígbà míì, ńṣe ni mo máa ń rò pé ó ń jíròrò Ìwé Mímọ́ pẹ̀lú ẹnì kan nínú yàrá rẹ̀, àmọ́ nígbà tó yá ni mo wá rí i pé Jèhófà ló ń bá sọ̀rọ̀. Jèhófà jẹ́ Ẹni gidi sí obìnrin yìí, ńṣe ló sì máa ń gbé ìgbé ayé rẹ̀ bíi pé iwájú Jèhófà ló wà. Mo ti kẹ́kọ̀ọ́ pé, èyí gan-an ni ohun tí èèyàn lè ṣe láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run nìṣó láìyẹsẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọmọbìnrin Jẹ́fútà ti ṣe. Mo dúpẹ́ mo tún ọpẹ́ dá lọ́wọ́ Jèhófà tó fún mi ní obìnrin àgbàlagbà yìí, ìyẹn ẹni tó kọ́ mi tó sì tún fún mi ní ìṣírí nígbà tí mo wà ní ọ̀dọ́ lákòókò tí nǹkan kò rọrùn fún mi.—Oníwàásù 4:9, 10.
Ẹ ò rí bí àǹfààní tí mo ní ti pọ̀ tó torí pé mo ṣiṣẹ́ sin Jèhófà bíi ti ọmọbìnrin Jẹ́fútà! Wíwà láìlọ́kọ àti títẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì ti mú kí ìgbésí ayé mi dára kí ó sì lérè, bí mo ṣe ń bá a nìṣó ní “ṣíṣiṣẹ́sin Olúwa nígbà gbogbo láìsí ìpínyà-ọkàn.”—1 Kọ́ríńtì 7:35.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Bàbá mi rèé tó ń sọ àsọyé fún gbogbo èèyàn ní ìlú Bombay láwọn ọdún 1950 sí 1959
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Èmi àti arábìnrin Elizabeth kí ó tó kú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
À ń kéde àsọyé Bíbélì ní ìlú Bombay lọ́dún 1960
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Èmi àti àwọn tí a jọ ń ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì ìtumọ̀ èdè