Ábúráhámù Jẹ́ Onígboyà
Ábúráhámù Jẹ́ Onígboyà
Ábúráhámù wo gbogbo ìdílé rẹ̀ àtàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bí wọ́n ṣe fẹ́ gbéra láti máa lọ sí ilẹ̀ Kénáánì. (Jẹ́nẹ́sísì 12:1-5) Bó ṣe ń wo ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn tó jẹ́ pé òun ló ń gbọ́ bùkátà wọn yẹn, yóò túbọ̀ rí i pé ojúṣe ńlá lòun ní. Ó lè máa rò ó pé, báwo lòun yóò ṣe máa gbọ́ bùkátà wọn nílẹ̀ àjèjì? Ǹjẹ́ kò ní rọrùn láti bójú tó ojúṣe yìí ní ìlú Úrì, níbi tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù, tí pápá ìjẹko ti lọ salalu, tó sì jẹ́ ilẹ̀ ọlọ́ràá tí omi pọ̀ sí gan-an? Tóun bá lọ ṣàìsàn tàbí tí òun bá kú ní ilẹ̀ àjèjì yẹn ńkọ́? Ta ló máa bá òun bójú tó ìdílé òun? Bí irú èrò wọ̀nyí bá tiẹ̀ wá sọ́kàn Ábúráhámù rárá, kò jẹ́ kí ìyẹn dẹ́rù ba òun. Ó ti pinnu pé bí iná ń jó bí ìjì ń jà ohun tí Ọlọ́run sọ lòun máa ṣe. Ó ní ìgboyà gan-an ni!
KÍ NI ÌGBOYÀ? Ìgboyà túmọ̀ sí pé kéèyàn láyà, kó jẹ́ ẹni tí kì í ṣojo, kó sì jẹ́ akíkanjú. Ó jẹ́ òdìkejì ẹ̀mí ìbẹ̀rù tàbí ojo. Èyí kò wá túmọ̀ sí pé ẹ̀rù kì í ba ẹni tó bá jẹ́ onígboyà rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni ẹni tó bá nígboyà torí pé ó gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run máa ń ṣe ohun tó yẹ ní ṣíṣe láìka ohun tó lè máa bà á lẹ́rù sí.
BÁWO NI ÁBÚRÁHÁMÙ ṢE LO ÌGBOYÀ? Ábúráhámù ṣe ohun tó yàtọ̀ sí ohun tí gbogbo èèyàn yòókù ń ṣe. Ibi tí wọ́n tí ń bọ onírúurú òrìṣà tó pọ̀ lọ jàra ni Ábúráhámù dàgbà sí. Síbẹ̀, kò jẹ́ kí ìbẹ̀rù ohun táwọn èèyàn máa sọ dá a dúró láti ṣe ohun tó mọ̀ pé ó tọ́. Ó fi ìgboyà ṣe ohun tó yàtọ̀ sí ti gbogbo wọn, ó ń sin Ọlọ́run kan ṣoṣo, ìyẹn Jèhófà, Ọlọ́run “Gíga Jù Lọ.”—Jẹ́nẹ́sísì 14:21, 22.
Ábúráhámù fi ìjọsìn Ọlọ́run tòótọ́ tó ń ṣe ṣáájú àwọn nǹkan ti ara. Ó fínnú fíndọ̀ fi ìgbé ayé ìrọ̀rùn tó ń gbé ní ìlú Úrì sílẹ̀ láti lọ máa gbé nínú aginjù, torí ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé yóò pèsè gbogbo ohun tí òun bá nílò. Lóòótọ́, bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ó ṣeé ṣe kí Ábúráhámù máa rántí àwọn nǹkan kan tó ti ń gbádùn tẹ́lẹ̀ ní Úrì. Àmọ́ ó dá a lójú pé Jèhófà kò ní jẹ́ kí ìyà jẹ òun àti ìdílé òun. Ábúráhámù ka Jèhófà sí ẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ nígbèésí ayé rẹ̀, ó sì rọ̀ mọ́ ọn. Ìyẹn ló jẹ́ kó ní ìgboyà láti máa pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́.
Ẹ̀KỌ́ WO LA RÍ KỌ́? Àwa náà lè ṣe bíi ti Ábúráhámù, ká jẹ́ ẹni tí kì í bẹ̀rù láti máa ṣe àwọn ohun tí Jèhófà bá ní ká ṣe, bí àwọn èèyàn yòókù kò bá tiẹ̀ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé àwọn tó bá fẹ́ láti máa fi ohun tí wọ́n ti kọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run ṣèwà hù yóò rí àtakò, èyí sì lè jẹ́ látọ̀dọ̀ àwọn ẹbí tàbí ọ̀rẹ́ tí wọ́n rò pé ire ẹni làwọn ń wá. (Jòhánù 15:20) Ṣùgbọ́n tí ohun tá a ti kọ́ nípa Jèhófà bá dá wa lójú gan-an, a ó máa gbèjà ìgbàgbọ́ wa tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀.—1 Pétérù 3:15.
A sì tún lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé òun yóò bójú tó àwọn tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú òun. Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run pátápátá, a kò ní bẹ̀rù láti máa fi àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run ṣáájú ohun gbogbo dípò ká máa lépa àwọn nǹkan tara. (Mátíù 6:33) Jẹ́ ká wo bí ìdílé kan ṣe ní irú ìgbẹ́kẹ̀lé bẹ́ẹ̀.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Doug àti Becky ti bí ọmọ méjì, wọ́n fẹ́ ṣí lọ sí orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù ìhìn rere púpọ̀ sí i láti lọ máa wàásù níbẹ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n ti fara balẹ̀ ṣèwádìí tí wọ́n sì ti gbàdúrà nípa rẹ̀ dáadáa, wọ́n pinnu pé ohun táwọn máa ṣe náà nìyẹn. Doug sọ pé: “Ó gba ìgboyà láti kó àwọn ọmọ wa ká sì máa lọ láìmọ bí nǹkan ṣe máa rí fún wa lọ́hùn-ún. Àmọ́, a ti gbé àpẹẹrẹ Ábúráhámù àti Sárà yẹ̀ wò nígbà tí a kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í jíròrò ìgbésẹ̀ tá a fẹ́ gbé yìí. Bá a ṣe ronú lórí bí wọ́n ṣe gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà àti bí kò ṣe já wọn kulẹ̀, ràn wá lọ́wọ́ gan-an.”
Báwo wá ni nǹkan ṣe rí fún wọn nílẹ̀ òkèèrè tí wọ́n kó lọ yìí? Doug sọ pé: “A ti jàǹfààní púpọ̀ gan-an.” Ó ṣàlàyé pé: “Torí pé a jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun ìní tara tẹ́ wa lọ́rùn, a ń ráyè lo èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò wa lójúmọ́ láti fi ṣe àwọn nǹkan pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé. Bí àpẹẹrẹ, a jọ máa ń lọ sóde ẹ̀rí pa pọ̀, a jọ máa ń fọ̀rọ̀ wérọ̀, á sì tún máa ń ráyè bá àwọn ọmọ wa ṣeré. A ń gbádùn ara wa gan-an báyìí lọ́nà tó kọjá àfẹnusọ.”
Lóòótọ́, kì í ṣe gbogbo èèyàn ló lè ṣe irú ohun tí Doug àti Becky ṣe yìí. Síbẹ̀ gbogbo wa la lè ṣe bíi ti Ábúráhámù, ká fi ìjọsìn Ọlọ́run ṣáájú ohun gbogbo, ká ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Ọlọ́run kò ní fi wá silẹ̀ láé. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe là ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé ká “jẹ́ onígboyà gidi gan-an, kí a sì sọ pé: ‘Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; èmi kì yóò fòyà.’”—Hébérù 13:5, 6.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 7]
Ẹni tó bá nígboyà torí pé ó gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run máa ń ṣe ohun tó yẹ ní ṣíṣe láìka ohun tó lè máa bà á lẹ́rù sí
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Obìnrin Tó Bẹ̀rù Ọlọ́run Tó sì Jẹ́ Aya Àtàtà
Ọkùnrin tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ ta yọ ni Sárà fẹ́. Àmọ́, Sárà fúnra rẹ̀ jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run àti ẹni àwòfiṣàpẹẹrẹ. Kódà, ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Bíbélì dìídì dárúkọ rẹ̀ pé ó jẹ́ ẹni tó yẹ kí àwọn obìnrin tó bẹ̀rù Ọlọ́run máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. (Aísáyà 51:1, 2; Hébérù 11:11; 1 Pétérù 3:3-6) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ìwé Mímọ́ kò sọ̀rọ̀ púpọ̀ nípa obìnrin àtàtà yìí, síbẹ̀ ohun tó sọ jẹ́ ká mọ̀ pé aya rere ni.
Bí àpẹẹrẹ, wo bó ṣe máa rí lára Sárà nígbà tí Ábúráhámù kọ́kọ́ sọ fún un pé Ọlọ́run ní kí àwọn kúrò ní ìlú Úrì. Ǹjẹ́ kò ní máa rò ó pé ibo gan-an làwọn tiẹ̀ ń lọ, kí sì nìdí tí àwọn fi ń lọ? Ǹjẹ́ kò ní máa ronú pé báwo làwọn yóò ṣe máa gbọ́ bùkátà ìdílé àwọn? Ǹjẹ́ kò ní máa dùn ún pé òun máa fi ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ òun sílẹ̀ láìmọ ìgbà tóun tún máa rí wọn, ìyẹn tí àwọn bá tiẹ̀ tún máa ríra mọ́? Ó dájú pé irú èrò bẹ́ẹ̀ yóò wá sí i lọ́kàn. Síbẹ̀, tinútinú ló fi kúrò ní ìlú Úrì, torí ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé yóò san òun lẹ́san bí òun ṣe ṣègbọràn.—Ìṣe 7:2, 3.
Yàtọ̀ sí pé Sárà jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó jẹ́ onígbọràn, ó tún jẹ́ aya rere. Dípò tí yóò fi máa wá bó ṣe máa jọ̀gá lé ọkọ rẹ̀ lórí, ṣe ló bọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún un, ó sì fi tìfẹ́tìfẹ́ tì í lẹ́yìn bó ṣe ń darí ìdílé wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, ó fi ìwà rere ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́.—1 Pétérù 3:1-6.
Lóde òní, ǹjẹ́ àǹfààní kankan wà nínú kí àwọn aya máa hùwà bíi ti Sárà? Obìnrin kan tó ń jẹ́ Jill, tó ti wà nílé ọkọ láti èyí tó lé ní ọgbọ̀n [30] ọdún, tó sì ń gbádùn ilé ọkọ rẹ̀, sọ pé: “Mo ti kẹ́kọ̀ọ́ látinú àpẹẹrẹ Sárà pé, ó dáa kí n máa sọ èrò ọkàn mi jáde fún ọkọ mi fàlàlà. Àmọ́ ọkọ mi, tó jẹ́ olórí ìdílé, ló máa pinnu ohun tí a máa ṣe. Tó bá sì ti ṣe ìpinnu ọ̀hún, ojúṣe tèmi ni pé kí n ṣe gbogbo ohun tó bá yẹ láti ṣe kí ìpinnu náà lè yọrí sí rere.”
Ohun tó jọ pé ó wúni lórí jù nípa Sárà ni pé: Bó tiẹ̀ jẹ́ pé arẹwà obìnrin ni, kò jẹ́ kí ẹwà tó ní kó sí òun lórí. (Jẹ́nẹ́sísì 12:10-13) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi ìrẹ̀lẹ̀ dúró ti ọkọ rẹ̀ gbágbáágbá jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀, yálà nígbà dídùn tàbí nígbà kíkan. Láìsí àní-àní, Ábúráhámù àti Sárà jẹ́ tọkọtaya olóòótọ́ àti onírẹ̀lẹ̀ tó fẹ́ràn ara wọn. Wọ́n fọwọ́ sowọ́ pọ̀ gan-an èyí sì jẹ́ kí ayé àwọn méjèèjì dùn bí oyin.