Ábúráhámù Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀
Ábúráhámù Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀
Ábúráhámù jókòó, ó ń gba atẹ́gùn nínú àgọ́ rẹ̀ ní ọ̀sán ganrínganrín tí ooru mú gan-an. Bó ṣe wo ọ̀ọ́kán, ó tajú kán rí àwọn ọkùnrin mẹ́ta kan ní ìtòsí ibẹ̀. * Kíá, ó sáré lọ bá wọn, ó sì rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n wá sinmi díẹ̀, kí òun lè ṣe wọ́n lálejò. “Búrẹ́dì díẹ̀” ló ní òun fẹ́ fún wọn, àmọ́ àsè rẹpẹtẹ ló ṣètò fún wọn. Ó pèsè ìṣù búrẹ́dì rìbìtì, bọ́tà, wàrà, àti ẹran tó dára tí wọ́n ti sè. Ábúráhámù sì fúnra rẹ̀ gbé oúnjẹ náà kalẹ̀ fún wọn. Ohun tó ṣe yìí fi hàn pé aájò àlejò nìkan kọ́ ló ní, ó tún lo ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tó kàmàmà, bí a ṣe máa rí i níwájú.—Jẹ́nẹ́sísì 18:1-8.
KÍ NI Ẹ̀MÍ ÌRẸ̀LẸ̀? Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ni pé kéèyàn jẹ́ ẹni tí kì í gbéra ga tàbí ẹni tí kò ní ẹ̀mí ìjọra-ẹni-lójú. Ẹni tó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ máa ń gbà pé àwọn ẹlòmíì ju òun lọ lọ́nà kan tàbí òmíràn. (Fílípì 2:3) Ó máa ń fetí sí ìmọ̀ràn àwọn ẹlòmíràn, kì í sì í kà á sí ìwọ̀sí láti ṣe àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ fún àǹfààní wọn.
BÁWO NI ÁBÚRÁHÁMÙ ṢE LO Ẹ̀MÍ ÌRẸ̀LẸ̀? Ábúráhámù máa ń fi tìdùnnú-tìdùnnú lo ara rẹ̀ fún àwọn ẹlòmíì. Bí a ṣe sọ níṣàájú, gbàrà tí Ábúráhámù ti tajú kán rí àwọn àlejò mẹ́ta yẹn, ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í wá bó ṣe máa ṣe wọ́n lálejò. Kíákíá ni Sárà aya rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í se oúnjẹ tí wọ́n máa jẹ. Àmọ́ kíyè sí i pé Ábúráhámù ló ṣe èyí tó pọ̀ jù nínú iṣẹ́ náà. Òun ló sáré lọ pàdé àwọn àlejò náà, òun ló foúnjẹ lọ̀ wọ́n, òun ló sáré lọ sáàárín agbo ẹran tó sì mú ẹran tí wọ́n máa pa, òun náà ló sì gbé oúnjẹ yẹn fún àwọn àlejò náà. Dípò kí ọkùnrin onírẹ̀lẹ̀ yìí fa iṣẹ́ yẹn lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́, ṣe lòun náà tara bọ àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ yẹn ní pẹrẹu. Kò wò ó pé òun ju ẹni tó lè máa ṣe irú àwọn iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ fún àǹfààní àwọn èèyàn.
Ábúráhámù fetí sí ìmọ̀ràn àwọn tó wà lábẹ́ rẹ̀. Bíbélì ò fi bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ púpọ̀ nípa ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ Jẹ́nẹ́sísì 16:2; 21:8-14) Lákọ̀ọ́kọ́, ọ̀kan lára ìmọ̀ràn náà “kò dùn mọ́ Ábúráhámù nínú rárá.” Ṣùgbọ́n nígbà tí Jèhófà bá Ábúráhámù sọ̀rọ̀, tó jẹ́ kó mọ̀ pé ìmọ̀ràn tó dáa ni Sárà mú wá, Ábúráhámù fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ gbà láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn náà.
láàárín Ábúráhámù àti Sárà. Àmọ́ a rí i kà lẹ́ẹ̀mejì pé Ábúráhámù fetí sí ìmọ̀ràn Sárà, ó sì ṣe ohun tó sọ. (Ẹ̀KỌ́ WO LA RÍ KỌ́? Tá a bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ lóòótọ́, tayọ̀tayọ̀ la ó máa lo ara wa fún àwọn èèyàn. Inú wa yóò máa dùn láti ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti jẹ́ kí ara tu ọmọnìkejì wa.
Ojú tí a fi ń wo ìmọ̀ràn tí ẹlòmíì fún wa tún lè fi hàn bóyá a lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Dípò tí a ó fi kọ ìmọ̀ràn kan kìkì nítorí pé ọkàn tiwa ò lọ síbẹ̀, ó máa bọ́gbọ́n mu pé ká gbọ́ ohun tẹ́lòmíì bá ní láti sọ. (Òwe 15:22) Téèyàn bá nírú ẹ̀mí tó dáa bẹ́ẹ̀, téèyàn jẹ́ ẹni tó ń fi ọgbọ́n ọlọ́gbọ́n ṣọgbọ́n, ó máa ń dáa gan-an, pàápàá fáwọn tó bá jẹ́ aṣáájú. Ọ̀gá ibi iṣẹ́ kan, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ John sọ pé: “Ṣe ni ọ̀gá rere máa ń jẹ́ kí ara tu àwọn èèyàn láti máa sọ èrò ọkàn wọn fàlàlà. Ọ̀gá gbọ́dọ̀ ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, kó tó lè gbà pé ẹni tó wà lábẹ́ òun lè mọ àwọn nǹkan míì ṣe dáadáa ju òun lọ. Ṣùgbọ́n, ká máa rántí pé, yálà a jẹ́ ọ̀gá tàbí ọmọọṣẹ́, kò sẹ́ni tó gbọ́n tán.”
Tá a bá ń ṣe bíi ti Ábúráhámù, tá a máa ń fetí sí ìmọ̀ràn àwọn ẹlòmíì, tá a sì máa ń ṣe àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ fún àǹfààní àwọn èèyàn, a óò rí ojú rere Jèhófà. Ó ṣe tán, “Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn onírera, ṣùgbọ́n ó ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.”—1 Pétérù 5:5.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ Àwọn áńgẹ́lì tí Ọlọ́run rán níṣẹ́ ni àwọn ọkùnrin yìí, àmọ́ Ábúráhámù lè máà kọ́kọ́ mọ pé áńgẹ́lì ni wọ́n.—Hébérù 13:2.