Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Èmi, Jèhófà Ọlọ́run Rẹ, Yóò Di Ọwọ́ Ọ̀tún Rẹ Mú”

“Èmi, Jèhófà Ọlọ́run Rẹ, Yóò Di Ọwọ́ Ọ̀tún Rẹ Mú”

Sún Mọ́ Ọlọ́run

“Èmi, Jèhófà Ọlọ́run Rẹ, Yóò Di Ọwọ́ Ọ̀tún Rẹ Mú”

BÍ BÀBÁ kan àti ọmọ rẹ̀ ṣe fẹ́ sọdá ọ̀nà tí ohun ìrìnnà àti èrò pọ̀ sí, ó sọ fún ọmọ náà pé “di ọwọ́ mi mú dáadáa.” Nítorí pé bàbá náà fúnra rẹ̀ di ọwọ́ ọmọ náà mú dáadáa, ọmọ yìí kò ní bẹ̀rù, torí yóò ti gbà pé kò séwu fóun rárá. Ǹjẹ́ ó máa ń ṣe ìwọ náà bíi pé kó o rí ẹni tó máa mú ọ la gbogbo wàhálà àti ìdààmú tó wà nínú ayé yìí já? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Aísáyà lè tù ọ́ nínú.—Ka Aísáyà 41:10, 13.

Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ni Aísáyà darí ọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí sí. Ọlọ́run kà wọ́n sí “àkànṣe dúkìá” rẹ̀, àmọ́ àárín ọ̀tá ni wọ́n ń gbé. (Ẹ́kísódù 19:5) Ǹjẹ́ ó yẹ kí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì máa bẹ̀rù? Jèhófà gbẹnu Aísáyà sọ̀rọ̀ kan fún wọn tó fini lọ́kàn balẹ̀. Bí a ó ṣe máa gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò, ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé ọ̀rọ̀ yẹn kan àwa tá à ń sin Ọlọ́run lónìí.—Róòmù 15:4.

Jèhófà sọ fún wọn pé: “Má fòyà.” (Ẹsẹ 10) Èyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ orí ahọ́n lásán o. Jèhófà sọ ìdí tí kò fi yẹ kí àwọn èèyàn rẹ̀ bẹ̀rù, ó ní: “Nítorí mo wà pẹ̀lú rẹ.” Jèhófà kì í ṣe olùrànlọ́wọ́ kan tó wà lọ́nà jíjìn, tó kàn ń ṣèlérí pé òun yóò máa wá láti ṣèrànlọ́wọ́ nígbà tí ìṣòro bá dójú ẹ̀. Ó fẹ́ kí àwọn èèyàn rẹ̀ mọ̀ pé òun wà pẹ̀lú wọn, bíi pé ẹ̀gbẹ́ wọn gan-an lòun wà, láti máa ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà gbogbo. Èyí mà tuni nínú gan-an o!

Jèhófà tún fi àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́kàn balẹ̀ síwájú sí i, ó ní: “Má wò yí ká.” (Ẹsẹ 10) Ọ̀rọ̀ ìṣe tí wọ́n lò nínú ẹsẹ yìí lédè Hébérù sábà máa ń tọ́ka sí àwọn tó “máa ń wò rá-rà-rá torí bóyá ewu ń bọ̀.” Jèhófà sì sọ ìdí tí kò fi yẹ kí àwọn èèyàn rẹ̀ máa wò káàkiri nítorí ìbẹ̀rù, ó ní: “Nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ.” Ẹ ò rí i pé ìyẹn fini lọ́kàn balẹ̀ gan-an! Jèhófà ni “Ẹni Gíga Jù Lọ” àti “Olódùmarè.” (Sáàmù 91:1) Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé Jèhófà, Ọlọ́run Olódùmarè ni Ọlọ́run wọn, kí ló yẹ kó tún dẹ́rù bà wọ́n?

Kí ni Jèhófà yóò wá ṣe fún àwọn olùjọsìn rẹ̀? Ó ṣèlérí fún wọn pé: “Èmi yóò fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi dì ọ́ mú ṣinṣin ní ti tòótọ́.” (Ẹsẹ 10) Ó sì tún sọ pé: “Èmi, Jèhófà Ọlọ́run rẹ, yóò di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú.” (Ẹsẹ 13) Èrò wo ni gbólóhùn méjèèjì yìí gbé wá sí ọ lọ́kàn? Ìwé kan tí a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé: “Téèyàn bá wo ẹsẹ méjèèjì yìí pa pọ̀, ṣe ló ń múni ronú nípa ọ̀rọ̀ òbí kan àti ọmọ rẹ̀. [Bàbá yìí] kò kàn dúró sí ìtòsí ọmọ rẹ̀ láti lè gbà á sílẹ̀ nígbà ewu. Ṣe lòun àti ọmọ náà jọ wà pa pọ̀; kò sì ní jẹ́ kí ohunkóhun pín òun àti ọmọ náà níyà.” Ìwọ rò ó wò ná, Jèhófà kò ní jẹ́ kí ohunkóhun pín òun àti àwọn èèyàn rẹ̀ níyà, kódà láwọn àsìkò tó lè dà bíi pé ìṣòro fẹ́ pin wọ́n lẹ́mìí.—Hébérù 13:5, 6.

Ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Aísáyà yìí jẹ́ ìtùnú gan-an fún àwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà lóde òní. Ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” tá a wà yìí, nígbà míì ó lè máa ṣe wá bíi pé wàhálà àti ìdààmú fẹ́ pọ̀ lápọ̀jù fún wa. (2 Tímótì 3:1) Ṣùgbọ́n Jèhófà kò ní dá wa dá ìṣòro wa. Ó máa nawọ́ rẹ̀ láti dì wá lọ́wọ́ mú. Ó sì yẹ kí àwa náà di ọwọ́ rẹ̀ alágbára mú bí ọmọ tó gbẹ́kẹ̀ lé bàbá rẹ̀ pátápátá ti ń ṣe, pẹ̀lú ìdánilójú pé yóò darí wa gba ọ̀nà tó tọ́, yóò sì ràn wá lọ́wọ́ nígbà ìṣòro.—Sáàmù 63:7, 8.

Bíbélì Kíkà Tá a Dábàá Fún January:

Aísáyà 24-42