Ǹjẹ́ Bíbélì Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Bí Ọjọ́ Ọ̀la Yóò Ṣe Rí?
Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Ǹjẹ́ Bíbélì Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Bí Ọjọ́ Ọ̀la Yóò Ṣe Rí?
Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìbéèrè tó o ti lè máa béèrè, a sì tún sọ ibi tó o ti lè rí ìdáhùn wọn kà nínú Bíbélì rẹ. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti bá ẹ sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìdáhùn náà.
1. Ǹjẹ́ Bíbélì máa ń sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ṣe pàtó?
Ọlọ́run Olódùmarè nìkan ló lè mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la, títí kan gbogbo bó ṣe máa ṣẹlẹ̀. (Ámósì 3:7) Bí àpẹẹrẹ, láti ìgbà láéláé ló ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ẹnì kan tó ń jẹ́ Mèsáyà tàbí Kristi ń bọ̀. Ó sọ pé Mèsáyà náà yóò jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù ọkùnrin olóòótọ́ náà. Àti pé yóò jẹ́ ọba tó máa mú kí àwọn èèyàn tó bá jẹ́ onígbọràn pa dà di ẹni pípé bí Ọlọ́run ṣe fẹ́, kí wọ́n sì bọ́ pátápátá lọ́wọ́ gbogbo àìsàn. (Jẹ́nẹ́sísì 22:18; Aísáyà 53:4, 5) Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì sì fi hàn pé ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ni Ẹni tí Ọlọ́run ṣèlérí yìí yóò ti wá.—Ka Míkà 5:2.
Ẹ̀rí fi hàn pé Jésù ni Mèsáyà náà. Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ láti èyí tó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún méje ṣáájú kí Mèsáyà tó dé pé wúńdíá lẹni tó máa bí Mèsáyà àti pé àwọn èèyàn yóò tẹ́ńbẹ́lú rẹ̀. Ó tún sọ pé yóò fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn, wọn yóò sì sìnkú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọlọ́rọ̀. (Aísáyà 7:14; 53:3, 9, 12) Bíbélì sì tún sọ ọ́ ní èyí tó lé ní ọgọ́rùn-ún márùn-ún ọdún ṣáájú kí Mèsáyà tó dé, pé yóò gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ Jerúsálẹ́mù àti pé wọn yóò fi lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ fún ọgbọ̀n [30] ẹyọ owó fàdákà. Gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ yìí pátá ló ṣẹ.—Ka Sekaráyà 9:9; 11:12.
2. Ǹjẹ́ Ọlọ́run máa ń sọ àkókò pàtó tí àsọtẹ́lẹ̀ kan máa ṣẹ?
Ọgọ́rùn-ún márùn-ún ọdún ṣáájú kí Mèsáyà tó dé ni Bíbélì ti sọ ọdún pàtó tí Mèsáyà yóò fara hàn. Ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan tó dúró fún ọdún méje-méje ni Bíbélì fi ṣírò iye ọdún tó máa jẹ́ kó tó dé. Iye ọ̀sẹ̀ tí Bíbélì sì sọ pé ó máa jẹ́ ni ọ̀sẹ̀ méje [7], àti ọ̀sẹ̀ méjìlélọ́gọ́ta [62] tí àròpọ̀ rẹ̀ jẹ́ ọ̀sẹ̀ mọ́kàndínláàádọ́rin [69]. Ìṣírò gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ irínwó ọdún ó lé ọgọ́rin àti mẹ́ta [483]. Ìgbà wo wá ni ọdún yẹn bẹ̀rẹ̀? Bíbélì fi hàn pé ó bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà tí Nehemáyà ìránṣẹ́ Ọlọ́run dé Jerúsálẹ́mù tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ odi ìlú náà. Ìtàn àwọn ará Páṣíà sì fi hàn pé ọdún 455 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni. (Nehemáyà 2:1-5) Irínwó ọdún ó lé ọgọ́rin àti mẹ́ta [483] lẹ́yìn náà, ìyẹn ní ọdún 29 Sànmánì Kristẹni, Jésù ṣe ìrìbọmi, ó di Mèsáyà, èyí sì jẹ́ ìgbà tí ìṣírò ọdún yẹn pé gẹ́lẹ́.—Ka Dáníẹ́lì 9:25.
3. Ǹjẹ́ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ń ṣẹ lóde òní?
Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó kàmàmà yóò wáyé lásìkò tiwa yìí. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, ó sọ pé a ó wàásù ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run tó máa mú ìtura bá gbogbo èèyàn tó fẹ́ràn Ọlọ́run ní ayé. Ìjọba yìí yóò fòpin sí gbogbo ètò nǹkan búburú tí à ń gbé nínú rẹ̀ báyìí.—Ka Mátíù 24:14, 21, 22.
Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lásìkò òpin tá a wà yìí. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ohun téèyàn ò rò pé ó yẹ kó tún máa ṣẹlẹ̀ láyé ọ̀làjú yìí ni yóò máa ṣẹlẹ̀, ìyẹn ni pé àwọn èèyàn yóò máa ba ilẹ̀ ayé yìí jẹ́. Ó tún sọ pé ogun, àìtó oúnjẹ, ìmìtìtì ilẹ̀ àti àjàkálẹ̀ àrùn yóò máa fa ìpọ́njú tó lékenkà. (Lúùkù 21:11; Ìṣípayá 11:18) Ìwà ìbàjẹ́ yóò gbilẹ̀. Nínú àkókò tó le koko yìí, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù yóò máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní gbogbo orílẹ̀-èdè.—Ka Mátíù 24:3, 7, 8; 2 Tímótì 3:1-5.
4. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí aráyé lọ́jọ́ iwájú?
Ọlọ́run Olódùmarè ní àwọn ohun rere tó fẹ́ ṣe fún àwọn èèyàn tó bá jẹ́ olóòótọ́. Jésù Kristi tó jẹ́ Mèsáyà àti àwọn tó ti yàn yóò máa ṣàkóso ayé látọ̀run wá. Àwọn ló para pọ̀ jẹ́ Ìjọba Ọlọ́run tí yóò ṣàkóso fún ẹgbẹ̀rún ọdún. A óò jí àwọn tó ti kú dìde, wọn yóò sì lè dẹni tí Ọlọ́run kà yẹ fún ìyè àìnípẹ̀kun. Láfikún sí èyí, Ìjọba Ọlọ́run yóò mú gbogbo èèyàn tó bá wà láyé nígbà yẹn lára dá. Àìsàn àti ikú kì yóò sì sí mọ́.—Ka Ìṣípayá 5:10; 20:6, 12; 21:4, 5.
Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka ojú ìwé 23 sí 25 àti ojú ìwé 197 sí 201 nínú ìwé yìí.