Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Èèyàn Aztec Òde Òní Di Kristẹni Tòótọ́

Àwọn Èèyàn Aztec Òde Òní Di Kristẹni Tòótọ́

Àwọn Èèyàn Aztec Òde Òní Di Kristẹni Tòótọ́

“Wọ́n wó àwọn tẹ́ńpìlì wọn, wọ́n sọ wọ́n di ekuru àti eérú, wọ́n pa gbogbo òrìṣà wọn run, wọ́n sì dáná sun àwọn ìwé ẹ̀sìn wọn, síbẹ̀síbẹ̀ àwọn Íńdíà [ti ilẹ̀ Mẹ́síkò] kò gbàgbé àwọn òrìṣà wọn ayé àtijọ́.”—Las antiguas culturas mexicanas (The Ancient Mexican Cultures).

ÀWỌN èèyàn Aztec tó wà ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, kò ju ẹ̀yà kékeré kan lọ nígbà tí wọ́n kó wá síbẹ̀ ní ọgọ́rùn-ún ọdún méje sẹ́yìn. Àmọ́ nígbà tó yá wọ́n di ilẹ̀ ọba kan tó lágbára bíi ti ilẹ̀ ọba àwọn Incas tó wà ní orílẹ̀-èdè Peru. Ilẹ̀ ọba àwọn Aztec ṣubú nígbà tí orílẹ̀-èdè Sípéènì ṣẹ́gun ìlú Tenochtitlán tó jẹ́ olú ìlú ilẹ̀ ọba Aztec lọ́dún 1521, àmọ́ èdè àwọn Aztec, ìyẹn Nahuatl ṣì wà títí dòní. * Ó kéré tán, àádọ́ta ọ̀kẹ́ kan àtààbọ̀ àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Íńdíà wọ̀nyí ló ṣì ń sọ èdè yẹn báyìí ní ìpínlẹ̀ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. Èyí jẹ́ ara ìdí tí díẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ àwọn Aztec àtijọ́ kò fi tíì pa rẹ́, gẹ́gẹ́ bí a ṣe rí i nínú ọ̀rọ̀ tí olùwádìí tó ń jẹ́ Walter Krickeberg sọ ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Ẹ wo díẹ̀ nínú àwọn nǹkan tí wọ́n gbà gbọ́.

Àṣà Tó Ṣeni ní Kàyéfì Àmọ́ Tí Kò Ṣàjèjì

Àṣà tí ọ̀pọ̀ èèyàn fẹ́rẹ̀ẹ́ mọ ẹ̀yà Aztec mọ́ jù ni àṣà fífi èèyàn rúbọ. Wọ́n gbà gbọ́ pé oòrùn yóò kú tí wọn kò bá fún un ní ọkàn èèyàn jẹ kí wọ́n sì fún un ní ẹ̀jẹ̀ èèyàn mu. Ọkùnrin ọmọ ilẹ̀ Sípéènì kan tó jẹ́ ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Diego Duran sọ pé lọ́dún 1487, nígbà tí wọ́n ń ṣe ayẹyẹ ṣíṣí tẹ́ńpìlì ńlá wọn tó jẹ́ aboríṣóńṣó ní ìlú Tenochtitlán, ó lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́rin [80,000] èèyàn tí wọ́n fi rúbọ láàárín ọjọ́ mẹ́rin.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ara àwọn ọmọ ilẹ̀ Sípéènì bù máṣọ nígbà tí wọ́n rí àṣà wọn yìí, ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún wọn nígbà tí wọ́n mọ̀ pé ọ̀pọ̀ nínú ohun tí àwọn Aztec gbà gbọ́ jọ ohun táwọn náà gbà gbọ́ ní Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì. Bí àpẹẹrẹ, àwọn Aztec náà máa ń jẹ oríṣi oúnjẹ ìdàpọ̀ kan bí ẹní gba ara Olúwa, wọ́n á fi àgbàdo ṣu ère tó dà bí àwọn òrìṣà wọn, wọ́n á sì máa jẹ ẹ́. Nígbà míì, wọ́n tiẹ̀ máa ń jẹ ẹran ara èèyàn tí wọ́n bá fi rúbọ. Àwọn Aztec máa ń lo àgbélébùú, wọ́n máa ń ṣe ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, wọ́n sì máa ń ṣe ìtẹ̀bọmi fún ọmọdé. Èyí tó tiẹ̀ pabanbarì jù ni ti òrìṣà Tonantzin tí wọ́n ń bọ, èyí tó jẹ́ wúńdíá “Ìyá Àwọn Ọlọ́run,” tí àwọn ẹ̀yà Aztec fẹ́ràn láti máa pè ní Ìyá Wa Kékeré.

Orí òkè tí àwọn ẹ̀yà Aztec ti ń bọ Tonantzin gan-an ni àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì sọ pé Wúńdíá aláwọ̀ dúdú ti Guadalupe, tó ń sọ èdè Nahuatl, ti fara han ọ̀kan lára àwọn Íńdíà tó jẹ́ ẹ̀yà Aztec lọ́dún 1531. Èyí sì jẹ́ kí àwọn èèyàn Aztec tètè di ẹlẹ́sìn Kátólíìkì. Wọ́n wá kọ́ ilé ìjọsìn tí wọ́n fi ṣe ojúbọ wúńdíá ti Guadalupe yìí sórí ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì ti Tonantzin. Ní ọjọ́ kejìlá oṣù December lọ́dọọdún, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn olùfọkànsìn nínú ẹ̀sìn Kátólíìkì nílẹ̀ Mẹ́síkò ló máa ń wá síbi ṣọ́ọ̀ṣì ńlá yìí, tí ọ̀pọ̀ nínú wọn sì jẹ́ àwọn tó ń sọ èdè Nahuatl.

Àwọn tó ń sọ èdè Nahuatl yìí máa ń ṣe onírúurú ọdún tó jẹ́ ti àwọn ẹni mímọ́ tí wọ́n kà sí alátìlẹyìn wọn, ní ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá tí wọ́n ń gbé. Nígbà míì, wọ́n tiẹ̀ máa ń fi ọ̀pọ̀ ọjọ́ tàbí ọ̀sẹ̀ ṣe ọdún wọ̀nyẹn. Ìwé kan tó sọ̀rọ̀ nípa ìgbé ayé àwọn Aztec, sọ pé àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Mẹ́síkò yìí “máa ń wò ó pé bí àwọn ṣe ń jọ́sìn àwọn ẹni mímọ́ nínú ẹ̀sìn Kátólíìkì kò yàtọ̀ sí gbogbo ààtò ìsìn tí àwọn ti ń ṣe ṣáájú ìgbà ayé jagunjagun náà Cortés,” ìyẹn ọ̀gágun ọmọ ilẹ̀ Sípéènì tó ṣẹ́gun wọn láti sọ wọ́n di ẹlẹ́sìn Kátólíìkì. (El universo de los aztecas, ìyẹn The Universe of the Aztecs) Àwọn tó ń sọ èdè Nahuatl yìí máa ń bá ẹ̀mí èṣù lò gan-an. Tí wọ́n bá ṣàìsàn, wọ́n á lọ sọ́dọ̀ àwọn babaláwo tó máa báwọn ṣètùtù ìwẹ̀nùmọ́, tí yóò sì fi ẹran rúbọ. Yàtọ̀ sí èyí, púpọ̀ nínú wọn ni kò kàwé rárá; èyí tó sì pọ̀ jù nínú wọn ni kò lè ka èdè Sípáníìṣì tàbí èdè Nahuatl. Bí wọ́n ṣe ranrí mọ́ àṣà ìbílẹ̀ wọn àti èdè wọn, tí wọ́n sì tún jẹ́ òtòṣì paraku, wọ́n dèrò ẹ̀yìn láwùjọ.

Òtítọ́ Bíbélì Dé Ọ̀dọ̀ Àwọn Aztec Òde Òní

Láti ọ̀pọ̀ ọdún wá ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò ti ń sapá gan-an láti rí i pé àwọn wàásù “ìhìn rere ìjọba” Ọlọ́run fún gbogbo èèyàn. (Mátíù 24:14) Lọ́dún 2000, ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò bẹ̀rẹ̀ ètò pàtàkì kan. Ìyẹn ni pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fi èdè Nahuatl wàásù fún gbogbo àwọn tó bá ń sọ èdè yẹn, wọ́n sì dá ìjọ tó ń sọ èdè Nahuatl sílẹ̀ fún gbogbo àwọn tó bá ń lọ sí ìpàdé ní ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè Sípáníìṣì lára wọn. Wọ́n ṣètò àwùjọ àwọn atúmọ̀ èdè tí wọ́n ń túmọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde tó ń ṣàlàyé Bíbélì sí èdè Nahuatl. Wọ́n ṣe ọ̀pọ̀ akitiyan láti kọ́ àwọn èèyàn tó ń sọ èdè Nahuatl láti mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà lédè wọn. Kí ni ìyẹn ti yọrí sí? Wo àwọn ìrírí tó tẹ̀ lé e yìí.

Nígbà àkọ́kọ́ tí obìnrin kan láti ẹ̀yà Aztec gbọ́ àsọyé Bíbélì kan lédè Nahuatl, ó fìdùnnú sọ pé: “Ọdún kẹwàá rèé tá a ti ń lọ sípàdé, tó sì jẹ́ pé ṣe la kàn ń rún gbogbo ẹ̀ mọ́ ọn tipátipá torí a ò fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ èdè Sípáníìṣì. Àmọ ní báyìí, ó ń ṣe wá bíi pé ńṣe la ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́!” Ọdún mẹ́jọ ni ọ̀gbẹ́ni Juan tó jẹ́ ẹni ọgọ́ta ọdún fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó sì ń wá sí àwọn ìpàdé ní ìjọ tó ń sọ èdè Sípáníìṣì; síbẹ̀, kò ní ìtẹ̀síwájú kankan. Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní èdè Nahuatl. Kí ọdún kan tó pé, ó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ṣe ìrìbọmi!

Látinú àwọn ìrírí yìí, a ti rí i pé ọ̀pọ̀ nínú wọn ló jẹ́ pé èdè Sípáníìṣì ni wọ́n kọ́kọ́ fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ ẹ̀kọ́ náà kò yé wọn tó bó ṣe yẹ. Bí wọ́n ṣe wá ń ṣe ìpàdé ìjọ àti àwọn àpéjọ lédè ìbílẹ̀ wọn tí wọ́n sì tún ní àwọn ìtẹ̀jáde tó dá lórí Bíbélì lédè wọn, wọ́n dẹni tó tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Bíbélì, wọ́n sì mọ àwọn ohun tó jẹ́ ojúṣe wọn gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni dáadáa.

Bí A Ṣe Borí Àwọn Ìṣòro

Ọ̀pọ̀ ìṣòro ló wáyé bí àwọn èèyàn tó ń sọ èdè Nahuatl ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n sábà máa ń fúngun mọ́ wọn pé kí wọ́n kópa nínú àjọ̀dún ìsìn tó lòdì sí Ìwé Mímọ́. Ní ìlú San Agustín Oapan, wọn kò gbà kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa wàásù láti ilé dé ilé. Wọ́n ń bẹ̀rù pé àwọn èèyàn kò ní fẹ́ dá owó àjọ̀dún fún àwọn mọ́. Nígbà tí arákùnrin Florencio àti àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kékeré kan tó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ àwọn tó ń sọ èdè Nahuatl lọ wàásù, ṣe ni wọ́n mú wọn. Láàárín ogún ìṣẹ́jú péré, àwọn èèyàn ti pé jọ láti pinnu irú ìyà tí wọ́n máa fi jẹ wọ́n.

Arákùnrin Florencio sọ pé: “Ńṣe ni wọ́n fẹ́ pa wá níbẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Àwọn kan tiẹ̀ dábàá pé kí wọ́n dì wá lókùn kí wọ́n sì jù wá sódò, kí a lé kú sómi! Inú àtìmọ́lé la sùn mọ́jú. Lọ́jọ́ kejì, Ẹlẹ́rìí kan tó jẹ́ agbẹjọ́rò àti àwọn Ẹlẹ́rìí méjì míì wá láti ràn wá lọ́wọ́. Wọ́n tún ju àwọn náà sí àtìmọ́lé. Níkẹyìn, àwọn aláṣẹ tú gbogbo wa sílẹ̀ pé ká máa lọ, tí a bá ti gbà pé a máa kúrò nílùú náà.” Pẹ̀lú gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wa yìí, ọdún kan lẹ́yìn náà ìjọ kan fìdí múlẹ̀ níbẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́tàdínlógún tó ti ṣe ìrìbọmi àti àádọ́ta èèyàn sì ń ṣe ìpàdé níbẹ̀.

Àwọn èèyàn Nahuatl tó wà ní àgbègbè Coapala ní kí Alberto tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wá bá àwọn ṣe ọdún ìbílẹ̀ wọn. Ó kọ̀, wọ́n sì jù ú sí àtìmọ́lé. Wọ́n wá pe ìpàdé lé e lórí, àwọn kan sì bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo pé kí wọ́n yẹgi fún un, kí tiẹ̀ lè jẹ́ àríkọ́gbọ́n fún àwọn míì tó bá fẹ́ ṣe ẹ̀sìn tó ń ṣe, tí wọ́n á wá tìtorí ẹ̀ pa àṣà ìbílẹ̀ tì. Àwọn Ẹlẹ́rìí míì gbìyànjú láti gbà á sílẹ̀, wọ́n bá tún mú àwọn náà. Ìgbà tí wọ́n ṣe ọdún wọn ọlọ́sẹ̀ kan tán ni wọ́n tú gbogbo wọn sílẹ̀. Nígbà tí inúnibíni yẹn kò dáwọ́ dúró, ó di dandan kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fọ̀rọ̀ lọ àwọn aláṣẹ àgbà. Nígbà tí àwọn yẹn sì ti fún wọn ní ìwé àṣẹ, inúnibíni náà dáwọ́ dúró. Ó sì wá dùn mọ́ni pé, olórí àwọn tó ń ṣe inúnibíni bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ṣe ìrìbọmi nígbà tó yá. Ìjọ kan sì ti wà ní ìlú náà báyìí.

Ó Ti Tó Àsìkò Láti Kórè Ibẹ̀

Bí àwọn Ẹlẹ́rìí kan ṣe rí i pé ọ̀pọ̀ àwọn tó ń sọ èdè Nahuatl nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè wọn. Àmọ́ ṣá o, ìyẹn náà ní àwọn ìṣòro tiẹ̀. Àwọn tó ń sọ èdè Nahuatl máa ń tijú, wọ́n sì máa ń lọ́ tìkọ̀ láti sọ èdè wọn torí ohun tí àwọn èèyàn ti fojú wọn rí sẹ́yìn. Èdè ìbílẹ̀ lóríṣiríṣi sì tún wà nínú èdè wọn.

Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Sonia, tó ń fi àkókò tó pọ̀ ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run, sọ ohun tó jẹ́ kó sapá láti kọ́ èdè wọn. Ó ní: “Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] òṣìṣẹ́ tí wọ́n ń sọ èdè Nahuatl, tí wọ́n máa ń kó ṣiṣẹ́ káàkiri, wà níbì kan tí wọ́n kó wọn sí, èyí tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sí ìlú tí mo ń gbé. Wọ́n sì yan ẹ̀ṣọ́ tì wọ́n kí wọ́n máa bàa jáde níbẹ̀. Wọn kò ní olùgbèjà, wọ́n sì ń fìyà jẹ wọ́n gan-an. Ipò tí wọ́n wà dùn mí gan-an torí pé àwọn tó ń sọ èdè Nahuatl yìí jẹ́ ẹni iyì tẹ́lẹ̀ rí, àwọn sì ni orísun àwọn àṣà tí à ń tẹ̀ lé ní ilẹ̀ wa. Ó ti tó ogún ọdún tí a ti ń fi èdè Sípáníìṣì wàásù fún wọn, àmọ́ kò yé wọn dáadáa, wọn kò sì fi bẹ́ẹ̀ kọbi ara sí i. Ṣùgbọ́n, nígbà tí mo wá kọ́ gbólóhùn bíi mélòó kan nínú èdè wọn, ìwàásù mi bẹ̀rẹ̀ sí í wọ̀ wọ́n létí. Ṣe ni wọ́n máa ń pagbo yí mi kà láti gbọ́ ìwàásù mi. Mo sọ fún obìnrin kan lára wọn pé màá kọ́ ọ ní bó ṣe máa mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà tó bá lè kọ́ mi lédè Nahuatl. Ní báyìí, ohun tí wọ́n ń pè mí ní gbogbo ibùdó wọn ni ‘obìnrin tó gbọ́ èdè wa.’ Lóòótọ́ orílẹ̀-èdè mi ni mo wà, àmọ́ ṣe ló ń ṣe mí bíi pé mo ń ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run nílẹ̀ òkèèrè.” Ní báyìí, ìjọ kan tí wọ́n ti ń sọ èdè Nahuatl ti wà ní àgbègbè yẹn.

Arábìnrin míì tó ń jẹ́ Maricela, tó ń fi àkókò tó pọ̀ ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run, ń sa gbogbo ipá rẹ̀ láti kọ́ èdè Nahuatl. Lákọ̀ọ́kọ́, èdè Sípáníìṣì ni arábìnrin yìí fi ń kọ́ ọ̀gbẹ́ni Félix tó jẹ́ ẹni àádọ́rin [70] ọdún ní ẹ̀kọ́ Bíbélì. Nígbà tí Maricela wá túbọ̀ kọ́ èdè Nahuatl tó jẹ́ èdè ọkùnrin yìí, ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi èdè náà ṣàlàyé òtítọ́ fún ọkùnrin yìí. Ni ìwàásù rẹ̀ bá bẹ̀rẹ̀ sí í wọ̀ ọ́ lọ́kàn. Inú arábìnrin yìí dùn gan-an ni nígbà tí Félix bi í pé, “Ṣé Jèhófà tiẹ̀ máa ń gbọ́ àdúrà mi ti mò ń gbà sí i lédè Nahuatl?” Inú Félix dùn nígbà tó gbọ́ pé kò sí èdè tí Jèhófà kò gbọ́. Gbogbo ìpàdé ìjọ ni Félix máa ń wá déédéé, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń rin ìrìn wákàtí kan ààbọ̀ kó tó débẹ̀, ó sì ti ṣe ìrìbọmi báyìí. Arábìnrin Maricela sọ pé: “Inú mi dùn gan-an láti máa tẹ̀ lé ìdarí áńgẹ́lì tó ní ìhìn rere àìnípẹ̀kun láti polongo fún gbogbo ènìyàn!”—Ìṣípayá 14:6, 7.

Ní tòótọ́, àwùjọ àwọn tó ń sọ èdè Nahuatl ti dà bí pápá tó “ti funfun fún kíkórè.” (Jòhánù 4:35) Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà Ọlọ́run máa bá a nìṣó láti pe àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè gbogbo wá, títí kan àwọn Aztec tòde oní tí wọ́n jẹ́ ẹni iyì, pé kí wọ́n gòkè wá sí òkè ńlá Jèhófà láti wá gba ìtọ́ni ní àwọn ọ̀nà rẹ̀.—Aísáyà 2:2, 3.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Èdè Nahuatl wá látinú èdè Uto-Aztec tó pín sí oríṣiríṣi tó sì jẹ́ èyí tí àwọn ẹ̀yà bíi Hopi, Shosone àti Comanche tó wà ní Amẹ́ríkà ti Àríwá ń sọ. Inú èdè Nahuatl ni èdè Gẹ̀ẹ́sì ti yá ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń pe èso píà, ìyẹn avocado, àti ṣokoléètì àti tòmátì àti orúkọ ẹranko náà coyote.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 13]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

ÌLÙ MẸ́SÍKÒ

BÍ ÀWỌN AZTEC ṢE PỌ̀ SÍ NÍ ÌPÍNLẸ̀ KỌ̀Ọ̀KAN

150,000

KÒ TÓ 1,000