Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Àwọn Ohun Àtijọ́ Ni A Kì Yóò Mú Wá sí Ìrántí’

‘Àwọn Ohun Àtijọ́ Ni A Kì Yóò Mú Wá sí Ìrántí’

Sún Mọ́ Ọlọ́run

‘Àwọn Ohun Àtijọ́ Ni A Kì Yóò Mú Wá sí Ìrántí’

TÉÈYÀN bá jẹ́ ẹni tó máa ń rántí nǹkan, ohun tó dáa gan-an ni. Bí àpẹẹrẹ, inú wa máa ń dùn gan-an tí a bá rántí àwọn àkókò alárinrin tí àwa àti àwọn èèyàn wa ti jọ gbádùn. Ṣùgbọ́n nígbà míì, téèyàn bá ń rántí àwọn nǹkan míì, ó máa ń jẹ́ ọgbẹ́ ọkàn fúnni. Ǹjẹ́ o sábà máa ń ro àròdùn lórí àwọn nǹkan ìbànújẹ́ tó ti ṣẹlẹ̀ sí ọ? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, o lè máa rò ó pé, ‘Ọjọ́ wo ni màá bọ́ lọ́wọ́ àwọn àròdùn tó ń bà mí lọ́kàn jẹ́ yìí?’ A rí ìdáhùn tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ gan-an nínú ọ̀rọ̀ wòlíì Aísáyà.—Ka Aísáyà 65:17.

Jèhófà ṣèlérí pé òun yóò mú gbogbo ohun tó ń fa àròdùn kúrò. Lọ́nà wo? Ó máa mú ayé búburú yìí kúrò àti gbogbo ìyà inú rẹ̀, tí yóò sì fi ohun tó dùn tó sì lárinrin gan-an rọ́pò rẹ̀. Jèhófà gbẹnu wòlíì Aísáyà ṣèlérí pé: “Kíyè sí i, èmi yóò dá ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun.” Tá a bá lóye ìlérí yìí, ìyẹn máa jẹ́ ká ní ìrètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.

Kí ni ọ̀run tuntun yìí? A rí ohun méjì nínú Bíbélì tó lè jẹ́ ká mọ ohun tó jẹ́. Àkọ́kọ́, yàtọ̀ sí Aísáyà, òǹkọ̀wé méjì míì nínú Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ọ̀run tuntun. Ohun tí àwọn méjèèjì sì ń ṣàlàyé ni bí àyípadà rere ṣe máa bá ilẹ̀ ayé wa. (2 Pétérù 3:13; Ìṣípayá 21:1-4) Èkejì ni pé, nínú Bíbélì, wọ́n lè fi ọ̀rọ̀ náà “ọ̀run” ṣàpẹẹrẹ ìṣàkóso tàbí ìjọba. (Aísáyà 14:4, 12; Dáníẹ́lì 4:25, 26) Torí náà, ọ̀run tuntun yẹn jẹ́ ìjọba tuntun kan, ìyẹn ìjọba tó lè mú kí àyípadà rere àti òdodo gbilẹ̀ kárí ayé. Ìṣàkóso kan ṣoṣo ló sì lè ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀, ìyẹn Ìjọba Ọlọ́run, èyí tí Jésù kọ́ wa pé ká máa gbàdúrà fún. Ìjọba tó máa ṣàkóso láti ọ̀run wá yìí ni yóò mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run di ṣíṣe kárí ayé.—Mátíù 6:9, 10.

Kí wá ni ilẹ̀ ayé tuntun náà? Jẹ́ ká wo kókó méjì látinú Ìwé Mímọ́ tó máa jẹ́ ká mọ ohun tó jẹ́ gan-an. Àkọ́kọ́, nígbà míì nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà “ilẹ̀ ayé” máa ń túmọ̀ sí àwọn èèyàn, kì í ṣe ilé ayé tá à ń gbé inú rẹ̀ yìí. (Jẹ́nẹ́sísì 11:1; Sáàmù 96:1) Èkejì, Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé lábẹ́ ìjọba Ọlọ́run, àwọn olóòótọ́ èèyàn máa kọ́ òdodo, èyí tí yóò gbilẹ̀ kárí ayé. (Aísáyà 26:9) Torí náà, ayé tuntun túmọ̀ sí àwùjọ èèyàn tó máa fi ara wọn sábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run tí wọ́n á sì máa tẹ̀ lé ìlànà òdodo rẹ̀ ní ìgbésí ayé wọn.

Ṣé ìwọ náà ti wá ń rí bí Jèhófà ṣe máa mú gbogbo ohun tó ń fa àròdùn ọkàn kúrò pátápátá báyìí? Láìpẹ́, Jèhófà máa mú gbogbo ìlérí tó ṣe nípa ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun ṣẹ, yóò sì fìdí ayé tuntun òdodo múlẹ̀. * Nínú ayé tuntun yẹn, gbogbo ohun tó ń fa àròdùn, yálà ìyà tó ń jẹni, èrò tó ń bani nínú jẹ́ tàbí ọgbẹ́ ọkàn, yóò dohun ìgbàgbé. Àwọn olóòótọ́ èèyàn yóò gbádùn ìgbésí ayé wọn dọ́ba, ayọ̀ àti ìdùnnú ni wọ́n á sì máa fi lo ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.

Kí la wá lè ṣe sí ọgbẹ́ ọkàn tó lè máa bá wa fínra lọ́wọ́ báyìí? Ìlérí tí Jèhófà ṣe nípasẹ̀ wòlíì Aísáyà ni pé: “Àwọn ohun àtijọ́ ni a kì yóò sì mú wá sí ìrántí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wá sí ọkàn-àyà.” Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ohun yòówù tí ì báà máa kó ẹ̀dùn ọkàn bá wa nínú ayé burúkú yìí yóò di ohun ìgbàgbé. Ṣé ìlérí yẹn dùn mọ́ ọ nínú? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, o ò ṣe gbìyànjú láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí o ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run tó ṣe ìlérí ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀ yìí?

Bíbélì kíkà tá a dábàá fún March:

Aísáyà 63-66Jeremáyà 1-16

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Fún ìsọfúnni síwájú sí i nípa Ìjọba Ọlọ́run àti ohun tó máa gbé ṣe láìpẹ́, ka orí 3, 8 àti 9 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 19]

Jèhófà ṣèlérí pé òun yóò mú gbogbo ohun tó ń fa àròdùn kúrò