Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Ó Ń Bá A Nìṣó Ní Fífà Mọ́ Jèhófà’

‘Ó Ń Bá A Nìṣó Ní Fífà Mọ́ Jèhófà’

Kọ́ Ọmọ Rẹ

‘Ó Ń Bá A Nìṣó Ní Fífà Mọ́ Jèhófà’

JẸ́ o mọ ohun tó túmọ̀ sí pé kéèyàn fà mọ́ ẹnì kan? * Ó túmọ̀ sí pé kéèyàn fẹ́ràn ẹni náà, kéèyàn sún mọ́ ọn tímọ́tímọ́, kéèyàn sì bọ̀wọ̀ fún un. A fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ẹnì kan tí Bíbélì sọ pé ó “ń bá a nìṣó ní fífà mọ́ Jèhófà,” Ọlọ́run òtítọ́. Hesekáyà lorúkọ rẹ̀. Jẹ́ ká wo ẹ̀kọ́ tí a lè rí kọ́ lára rẹ̀.

Nígbà tí Hesekáyà wà lọ́mọdé, àwọn nǹkan tí kò dára ṣẹlẹ̀ sí i. Áhásì bàbá rẹ̀ tó jẹ́ ọba Júdà pa ìjọsìn Jèhófà tì. Ó wá di aṣáájú nínú àwọn tó ń bọ òrìṣà nígbà tí Hesekáyà ṣì wà lọ́mọdé. Ó kéré tán, Áhásì tiẹ̀ mú kí wọ́n pa ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀, tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò Hesekáyà, wọ́n sì fi rúbọ sí òrìṣà!

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Áhásì ń hu ìwà burúkú rẹ̀ lọ, ohun tí Jèhófà sọ ni Hesekáyà ń ṣe ní tirẹ̀. Ǹjẹ́ o rò pé ìyẹn máa rọrùn fún un láti ṣe?— Kò rọrùn rárá o. Síbẹ̀, Hesekáyà kò fi ìjọsìn Jèhófà sílẹ̀! Jẹ́ kí á wá kẹ́kọ̀ọ́ nípa bó ṣe fà mọ́ Jèhófà àti bí àwa náà ṣe lè ṣe bíi tirẹ̀.

Hesekáyà ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn èèyàn kan tí wọ́n fà mọ́ Jèhófà. Dáfídì jẹ́ ọ̀kan lára wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì ti kú tipẹ́tipẹ́ gan-an kí wọ́n tó bí Hesekáyà, ó ṣì lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Dáfídì ṣe nínú Ìwé Mímọ́. Bí àpẹẹrẹ, Dáfídì sọ pé: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé baba mi àti ìyá mi fi mí sílẹ̀, àní Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò tẹ́wọ́ gbà mí.”

Ǹjẹ́ o kíyè sí ohun tó jẹ́ kí Dáfídì lè máa ṣègbọràn sí Jèhófà?— Ìgbàgbọ́ rẹ̀ ni! Dáfídì mọ̀ dáadáa pé tí òun bá jẹ́ onígbọràn, Jèhófà máa ran òun lọ́wọ́. Ìyẹn dá Dáfídì lójú gan-an! Ó dájú pé bí Hesekáyà ṣe ń ronú nípa ohun tí Dáfídì ṣe yìí, ó di ẹni tó fà mọ́ Jèhófà, ìyẹn ni pé ó ń ṣègbọràn sí i. Ìwọ náà lè ní ìdánilójú pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ tí o bá fà mọ́ ọn, ìyẹn ni pé kó o máa ṣe ìgbọràn sí i.

Tó bá jẹ́ pé Bàbá rẹ tàbí ìyá rẹ kì í ṣe ẹni tó ń jọ́sìn Jèhófà ńkọ́?— Ọlọ́run sọ pé àwọn ọmọ gbọ́dọ̀ máa gbọ́ràn sí àwọn òbí wọn lẹ́nu. Nítorí náà, o gbọ́dọ̀ máa gbọ́ràn sí àwọn òbí rẹ lẹ́nu. Ṣùgbọ́n tí àwọn òbí rẹ bá sọ pé kí o ṣe ohun kan tí Ọlọ́run sọ pé o kò gbọ́dọ̀ ṣe, ó máa dáa kí o ṣàlàyé pé o kò ní lè ṣe é. O kò gbọ́dọ̀ purọ́, o kò gbọ́dọ̀ jalè, o kò sì gbọ́dọ̀ ṣe àwọn nǹkan búburú míì tí Ọlọ́run sọ pé kò dára, láìka ẹni yòówù tó bá sọ pé kí o ṣe é. Ohun tí Ọlọ́run sọ ni kó o máa ṣe!

Àwọn èèyàn rere míì wà tí a lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn. Kì í ṣe Dáfídì nìkan ni àpẹẹrẹ rere tí Hesekáyà mọ̀, ó tún rí àpẹẹrẹ rere ti Jótámù Baba ńlá rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jótámù ti kú kí wọ́n tó bí Hesekáyà, àmọ́ ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Jótámù ṣe, àwa náà sì lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ nínú Bíbélì wa lónìí. Ǹjẹ́ o lè rántí àwọn èèyàn míì tó jẹ́ àpẹẹrẹ rere tí àwa náà lè ṣe bíi tiwọn?

Lóòótọ́, wàá rí àwọn àṣìṣe tí Hesekáyà ṣe nínú Bíbélì, wàá tún rí ti Dáfídì àti Jótámù àti ti àwọn èèyàn míì tó jẹ́ aláìpé. Àmọ́ gbogbo wọn ló fẹ́ràn Jèhófà, wọ́n sì gbà pé àwọn ṣe àṣìṣe, wọ́n sì tún gbìyànjú láti máa ṣe dáadáa. Rántí pé Jésù, Ọmọ Ọlọ́run, nìkan ṣoṣo ló jẹ́ ẹni pípé. Jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù dáadáa ká sì gbìyànjú láti ṣe bíi tirẹ̀.

Kà á nínú Bíbélì rẹ

2 Àwọn Ọba 18:6; 2 Kíróníkà 28:1-3;

Sáàmù 27:10; Éfésù 6:1; Kólósè 3:20;

2 Kíróníkà 27:1, 2; 1 Pétérù 2:21

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Tó bá jẹ́ ọmọdé lò ń ka ìwé yìí fún, má gbàgbé láti dánu dúró níbi tó o bá ti rí àmì dáàṣì (—), kó o sì jẹ́ kí ọmọ náà sọ tinú rẹ̀.