Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Ẹ Ní Ìfẹ́ Láàárín Ara Yín’

‘Ẹ Ní Ìfẹ́ Láàárín Ara Yín’

‘Ẹ Ní Ìfẹ́ Láàárín Ara Yín’

“Èmi ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì; gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín, pé kí ẹ̀yin pẹ̀lú nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.”—JÒHÁNÙ 13:34, 35.

Ohun Tí Ọ̀rọ̀ Yìí Túmọ̀ Sí: Kristi sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn gẹ́gẹ́ bí òun ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn. Báwo ni Jésù ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn? Ìfẹ́ tí Jésù ní sí wọn kò dà bíi ti àwọn èèyàn ìgbà ayé rẹ̀ tó ní ẹ̀mí ìran tèmi lọ̀gá. Gbogbo èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló fẹ́ràn ní tiẹ̀. (Jòhánù 4:7-10) Ìfẹ́ ló mú kí Jésù máa lo gbogbo àkókò, okun àti agbára rẹ̀ láti fi ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, títí kan ìgbà tó yẹ kó máa sinmi. (Máàkù 6:30-34) Paríparí rẹ̀, ó fi ìfẹ́ tó ga jù lọ hàn. Abájọ tó fi sọ pé: “Èmi ni olùṣọ́ àgùntàn àtàtà; olùṣọ́ àgùntàn àtàtà fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn.”—Jòhánù 10:11.

Ohun Tí Àwọn Kristẹni Àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ Ṣe: Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn Kristẹni máa ń pe ara wọn ní “arákùnrin” àti “arábìnrin.” (Fílémónì 1, 2) Wọ́n ń gba àwọn èèyàn látinú gbogbo orílẹ̀-èdè tọwọ́-tẹsẹ̀ sínú ìjọ Kristẹni nítorí wọ́n gbà gbọ́ pé “kò sí ìyàtọ̀ láàárín Júù àti Gíríìkì, nítorí Olúwa kan náà ní ń bẹ lórí gbogbo wọn.” (Róòmù 10:11, 12) Lẹ́yìn Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó wà ní Jerúsálẹ́mù “ń ta àwọn ohun ìní àti dúkìá wọn, wọ́n sì ń pín owó ohun tí a tà fún gbogbo wọn, gan-an gẹ́gẹ́ bí àìní olúkúlùkù bá ṣe rí.” Kí nìdí tí wọ́n fi ń pín nǹkan wọ̀nyẹn fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó jẹ́ aláìní? Ìdí ni pé wọ́n ń fẹ́ kí àwọn ẹni tuntun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìrìbọmi wọ̀nyẹn lè dúró ní Jerúsálẹ́mù kí wọ́n máa “bá a lọ ní fífi ara wọn fún ẹ̀kọ́ àwọn àpọ́sítélì.” (Ìṣe 2:41-45) Kí ló mú wọn ṣe bẹ́ẹ̀? Ọ̀gbẹ́ni Tertullian sọ ohun táwọn kan sọ nípa àwọn Kristẹni ní èyí tí kò tíì tó igba ọdún lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì, pé: “Wọ́n mà nífẹ̀ẹ́ ara wọn o . . . kódà wọn ṣe tán láti kú fún ara wọn.”

Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ohun Tí Jésù Sọ Lónìí? Ìwé kan tó sọ ìtàn nípa bí ilẹ̀ ọba Róòmù ṣe ṣubú sọ pé àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní Kristẹni “ń han ara wọn léèmọ̀ lọ́nà tó burú jáì ju èyí tí àwọn aláìgbàgbọ́ pàápàá ń ṣe sí wọn lọ.” (The History of the Decline and Fall of the Roman Empire [1837]) Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà láìpẹ́ yìí fi hàn pé àárín àwọn tó jẹ́ ẹlẹ́sìn ni ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ti wọ́pọ̀ jù, ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ló sì pe ara wọn ní Kristẹni. Bákan náà, ẹ̀mí kóńkó jabele sábà máa ń wà láàárín àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n jọ jẹ́ ọmọ ìjọ kan náà àmọ́ tí wọ́n wà lórílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, torí náà nígbà ìṣòro, wọn kì í lè ṣèrànlọ́wọ́ fún ara wọn, tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ fẹ́ ṣèrànwọ́ rárá.

Lọ́dún 2004, lẹ́yìn tí ìjì líle ńláńlá jà ní ìpínlẹ̀ Florida lẹ́ẹ̀mẹrin láàárín oṣù méjì, alága ìgbìmọ̀ kan tó ń pèsè ìrànwọ́ nígbà àjálù, ìyẹn Florida’s Emergency Operations Committee, ṣe àbẹ̀wò síbẹ̀ láti lè rí i dájú pé àwọn èèyàn ń lo ohun tí àjọ náà ń pèsè bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Alága náà sọ pé kò sí àwùjọ kankan tó wà létòlétò bíi tàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó wá sọ pé òun ṣe tán láti pèsè gbogbo ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí yẹn bá sọ pé àwọn nílò. Ṣáájú ìgbà yẹn, lọ́dún 1997, àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan kó oògùn, oúnjẹ àti aṣọ láti ilẹ̀ Yúróòpù lọ sí orílẹ̀-èdè Kóńgò láti fi ṣèrànwọ́ fún àwọn arákùnrin wọn àti àwọn míì tó nílò ìrànlọ́wọ́. Àwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ wọn ní ilẹ̀ Yúróòpù ló fún wọn ní àwọn ohun èlò náà, èyí tí iye rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọ̀kẹ́ lọ́nà ẹgbẹ̀rún ọ̀kẹ́ lọ́nà àádọ́jọ ó lé mẹ́rin náírà.