Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“A Ó sì Wàásù Ìhìn Rere Ìjọba Yìí”

“A Ó sì Wàásù Ìhìn Rere Ìjọba Yìí”

“A Ó sì Wàásù Ìhìn Rere Ìjọba Yìí”

“A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.”—MÁTÍÙ 24:14.

Ohun Tí Ọ̀rọ̀ Yìí Túmọ̀ Sí: Lúùkù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ̀wé Ìhìn Rere sọ pé Jésù “ń rin ìrìn àjò lọ láti ìlú ńlá dé ìlú ńlá àti láti abúlé dé abúlé, ó ń wàásù, ó sì ń polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run.” (Lúùkù 8:1) Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé: “Èmi gbọ́dọ̀ polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú ńlá mìíràn pẹ̀lú, nítorí pé tìtorí èyí ni a ṣe rán mi jáde.” (Lúùkù 4:43) Ó rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jáde kí wọ́n máa wàásù ìhìn rere ní àwọn ìlú àti abúlé, lẹ́yìn náà ó pàṣẹ fún wọn pé: “Ẹ óo wá máa ṣe ẹlẹ́rǐ mi . . . títí dé òpin ilẹ̀ ayé.”—Ìṣe 1:8, Ìròhìn Ayọ̀; Lúùkù 10:1.

Ohun Tí Àwọn Kristẹni Àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ Ṣe: Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ tó ní kí wọ́n ṣe láìjáfara. Bíbélì sọ pé: “Ní ojoojúmọ́ nínú tẹ́ńpìlì àti láti ilé dé ilé ni wọ́n sì ń bá a lọ láìdábọ̀ ní kíkọ́ni àti pípolongo ìhìn rere nípa Kristi.” (Ìṣe 5:42) Gbogbo wọn ló ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù, wọn kò fi mọ sí àárín àwùjọ pàtàkì kan. Ohun tí òpìtàn kan tó ń jẹ́ Neander sọ ni pé, ọ̀gbẹ́ni “Celsus tó kọ́kọ́ kọ̀wé láti fi ta ko ìsìn Kristẹni fi àwọn Kristẹni ṣe yẹ̀yẹ́ lórí pé àwọn tó ń rànwú, àwọn tó ń ṣe bàtà, àwọn oníṣẹ́ awọ, àwọn tó ya púrúǹtù jù lọ àtàwọn gbáàtúù nínú ìràn ènìyàn ń fi ìtara wàásù ìhìnrere.” Ọ̀gbẹ́ni Jean Bernardi sọ nínú ìwé rẹ̀ The Early Centuries of the Church pé: “Ṣe ló yẹ káwọn [Kristẹni] máa lọ síbi gbogbo àti sọ́dọ̀ olúkúlùkù èèyàn láti bá wọn sọ̀rọ̀. Lójú pópó àti láwọn ìlú ńlá, ní gbàgede ìlú àti nínú ilé àwọn èèyàn. Yálà àwọn èèyàn tẹ́wọ́ gbà wọ́n tàbí wọn ò tẹ́wọ́ gbà wọ́n. . . . Kí wọ́n dé ìpẹ̀kun ayé.”

Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ohun Tí Jésù Sọ Lónìí? Àlùfáà ìjọ Áńgílíkà kan tó ń jẹ́ David Watson sọ pé: “Bí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì kò ṣe fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó fà á tí àwọn èèyàn òde òní kò fi nífẹ̀ẹ́ sí ìjọsìn Ọlọ́run.” Nínú ìwé tí ọ̀gbẹ́ni José Luis Pérez Guadalupe kọ láti fi sọ ìdí tí àwọn ọmọ ìjọ Kátólíìkì fi ń fi ṣọ́ọ̀ṣì sílẹ̀, ó mẹ́nu kan ìgbòkègbodò àwọn ìjọ Ajíhìnrere, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ Ọjọ́ Ìsinmi (ìyẹn àwọn Adventist) àti àwọn míì, ó sí sọ pé ṣọ́ọ̀ṣì wọ̀nyẹn “kì í lọ láti ilé dé ilé.” Àmọ́ ohun tó kọ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni pé: “Wọ́n máa ń lọ láti ilé dé ilé ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé.”—Why Are the Catholics Leaving.

Àkíyèsí pàtàkì kan tó wúni lórí tí ọ̀gbẹ́ni Jonathan Turley sọ, èyí tó wà nínú ìwé Cato Supreme Court Review, 2001-2002 ni pé: “Kó o máà tíì dárúkọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni ọ̀pọ̀ èèyàn á ti ronú kan àwọn oníwàásù kan tó máa ń wá sílé àwọn láwọn àsìkò tí kò rọgbọ. Lójú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kì í ṣe torí pé wọ́n kàn fẹ́ tan ẹ̀sìn kálẹ̀ ni wọ́n ṣe ń lọ láti ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà láti yíni lọ́kàn pa dà, àmọ́ ṣe ni wọ́n gbà pe iṣẹ́ yẹn jẹ́ ọ̀nà pàtàkì téèyàn gbà ń fi hàn pé òun ní ìgbàgbọ́.”

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 9]

Àwọn Wo Ni Ẹ̀rí Wọ̀nyẹn Fi Hàn Pé Ó Jẹ́ Kristẹni Tòótọ́?

Ní ìbámu pẹ̀lú àwọn kókó pàtàkì látinú Ìwé Mímọ́ tí a gbé yẹ̀ wò nínú àwọn àpilẹ̀kọ yìí, àwọn wo ni ẹ̀rí fi hàn pé ó jẹ́ Kristẹni tòótọ́ lónìí? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀kẹ́ àìmọye ṣọ́ọ̀ṣì àti àwọn ìjọ ló ń sọ pé Kristẹni ni àwọn, rántí ohun tí Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Kì í ṣe olúkúlùkù ẹni tí ń wí fún mi pé, ‘Olúwa, Olúwa,’ ni yóò wọ ìjọba ọ̀run, bí kò ṣe ẹni tí ń ṣe ìfẹ́ Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run ni yóò wọ̀ ọ́.” (Mátíù 7:21) Tó o bá mọ àwọn tó ń ṣe ìfẹ́ Baba, èyí tó jẹ́ ẹ̀rí pé àwọn ni Kristẹni tòótọ́, tó o sì dara pọ̀ mọ́ wọn, ó lè yọrí sí ìbùkún ayérayé fún ọ lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. A rọ̀ ọ́ pé kó o sọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó mú ìwé yìí tọ̀ ọ́ wá pé kí wọ́n túbọ̀ ṣàlàyé fún ọ nípa Ìjọba Ọlọ́run àti bó ṣe máa ṣe wá láǹfààní.—Lúùkù 4:43.