Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Máa Ṣe Ìrántí Ikú Jésù?

Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Máa Ṣe Ìrántí Ikú Jésù?

Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Máa Ṣe Ìrántí Ikú Jésù?

Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìbéèrè tó o ti lè máa béèrè, a sì tún sọ ibi tó o ti lè rí ìdáhùn wọn kà nínú Bíbélì rẹ. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti bá ẹ sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìdáhùn náà.

1. Báwo ni ó ṣe yẹ ká máa ṣe Ìrántí Ikú Jésù?

Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa fi oúnjẹ ìṣàpẹẹrẹ kan, ìyẹn búrẹ́dì àti wáìnì, ṣe ìrántí ikú òun. Búrẹ́dì yìí ṣàpẹẹrẹ ara Jésù, wáìnì sì ṣàpẹẹrẹ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.—Ka Lúùkù 22:19, 20.

Búrẹ́dì tí Jésù lò jẹ́ èyí tí kò ní ìwúkàrà, ìyẹn èròjà tó máa ń mú nǹkan wú. Nínú Bíbélì, wọ́n sábà máa ń fi ìwúkàrà ṣàpẹẹrẹ ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí náà, ó bá a mu gan-an láti fi búrẹ́dì tí kò ní ìwúkàrà yìí ṣàpẹẹrẹ ara Jésù tó jẹ́ pípé. Jésù fi ara rẹ̀ rúbọ, ìyẹn sì fi òpin sí fífi ẹran rúbọ, èyí tí Òfin Mósè pa láṣẹ. (Hébérù 10:5, 9, 10) Wáìnì yẹn ṣàpẹẹrẹ ẹ̀jẹ̀ Jésù tó ṣeyebíye, èyí tó ta sílẹ̀ láti fi ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ wa.—Ka 1 Pétérù 1:19; 2:24; 3:18.

2. Ìgbà wo ló yẹ ká máa ṣe Ìrántí Ikú Jésù?

Ọjọ́ Ìrékọjá ni Jésù kú, ìyẹn ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Nísàn. Lọ́dọ̀ àwọn Júù, ọjọ́ kọ̀ọ̀kan máa ń bẹ̀rẹ̀ nígbà tí oòrùn bá wọ̀ ní ìrọ̀lẹ́. Ní ìrọ̀lẹ́ tó bẹ̀rẹ̀ ọjọ́ tí Jésù kú, òun àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ jọ jẹ oúnjẹ Ìrékọjá. Lẹ́yìn náà, ó wá fi oúnjẹ ìrántí míì lọ́lẹ̀ pé ìyẹn ni kí wọ́n máa fi rántí ikú òun.—Ka Lúùkù 22:14, 15.

Lóde òní, bí Ọlọ́run ṣe tipasẹ̀ Jésù dá gbogbo aráyé nídè lóko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú ni àwọn èèyàn Ọlọ́run ń ṣe ìrántí rẹ̀. Àmọ́ bó ṣe jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún ni wọ́n máa ń ṣe Ìrékọjá, ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún náà ni wọ́n máa ń ṣe ìrántí ikú Jésù lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀. Ìyẹn sì jẹ́ lọ́jọ́ kẹrìnlá oṣù Nísàn, nínú kàlẹ́ńdà tí wọ́n ń fi òṣùpá kà, èyí tí àwọn Júù ń lò láyé ìgbà tí wọ́n kọ Bíbélì.—Ẹ́kísódù 12:5-7, 13, 17; ka Jòhánù 1:29.

3. Àwọn wo ló yẹ kó máa jẹ búrẹ́dì ìṣàpẹẹrẹ yẹn kí wọ́n sì máa mu wáìnì ìṣàpẹẹrẹ náà?

Nígbà tí Jésù gbé wáìnì náà fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó ní: “Ife yìí túmọ̀ sí májẹ̀mú tuntun.” (1 Kọ́ríńtì 11:25) Májẹ̀mú tuntun yìí rọ́pò májẹ̀mú Òfin Mósè tí Ọlọ́run fi ṣèlérí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé tí wọ́n bá ṣègbọràn délẹ̀délẹ̀ sí òun, wọn yóò di èèyàn òun. (Ẹ́kísódù 19:5, 6) Àmọ́, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì kò ṣègbọràn sí ohùn Ọlọ́run. Ìyẹn ló fà á tí Jèhófà fi dá májẹ̀mú tuntun míì.—Ka Jeremáyà 31:31.

Jèhófà lo májẹ̀mú tuntun yìí láti fi mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn rí ìbùkún gbà nípasẹ̀ ìwọ̀nba èèyàn kéréje kan. Ìwọ̀nba èèyàn ni Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú tuntun yìí, iye wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] péré. Ipasẹ̀ wọn ni ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn látinú gbogbo orílẹ̀-èdè yóò ti rí ìbùkún ìyè àìnípẹ̀kun gbà nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Àwọn kan lára àwọn tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú tuntun yìí ṣì wà láyé lónìí tí wọ́n ń sin Jèhófà. Àwọn nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti máa jẹ búrẹ́dì ìṣàpẹẹrẹ náà kí wọ́n sì máa mu wáìnì ìṣàpẹẹrẹ náà, torí májẹ̀mú tuntun tí Jèhófà bá wọn dá tó sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Jésù.—Ka Lúùkù 12:32; Ìṣípayá 14:1, 3.

4. Àǹfààní wo la máa rí nínú ṣíṣe Ìrántí Ikú Jésù?

Ìrántí Ikú Jésù tí a máa ń ṣe lọ́dọọdún máa ń jẹ́ ká túbọ̀ mọrírì ìfẹ́ tó bùáyà tí Jèhófà ní sí wa. Ó rán Ọmọ rẹ̀ kí ó wá kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa. Nítorí náà, nígbà tí a bá wà níbi Ìrántí Ikú Jésù, ńṣe ló yẹ ká máa ronú jinlẹ̀ lórí àǹfààní tí ikú rẹ̀ ṣe fún wa. Ó yẹ kí á ronú nípa bí a ṣe lè fi hàn pé a mọrírì ohun tí Jèhófà àti Jésù ṣe fún wa.—Ka Jòhánù 3:16; 2 Kọ́ríńtì 5:14, 15.

Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka ojú ìwé 206 sí 208 nínú ìwé yìí, Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.