Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Dúró Nínú Ọ̀rọ̀ Mi”

“Dúró Nínú Ọ̀rọ̀ Mi”

“Dúró Nínú Ọ̀rọ̀ Mi”

“Bí ẹ bá dúró nínú ọ̀rọ̀ mi, ọmọ ẹ̀yìn mi ni ẹ̀yin jẹ́ ní ti tòótọ́, ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.”—JÒHÁNÙ 8:31, 32.

Ohun Tí Ọ̀rọ̀ Yìí Túmọ̀ Sí: Ọ̀rọ̀ tí Jésù ń sọ pé kí wọ́n dúró nínú rẹ̀ ni àwọn ẹ̀kọ́ tó fi kọ́ àwọn èèyàn, ìyẹn àwọn ẹ̀kọ́ tó kọ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Jésù sọ pé: “Baba fúnra rẹ̀ tí ó rán mi ti fún mi ní àṣẹ kan ní ti ohun tí èmi yóò wí àti ohun tí èmi yóò sọ.” (Jòhánù 12:49) Nínú àdúrà tí Jésù gbà sí Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Baba rẹ̀ ọ̀run, ó sọ pé: “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” Jésù máa ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti ẹ̀kọ́ tó ń kọ́ni lẹ́yìn nígbà gbogbo. (Jòhánù 17:17; Mátíù 4:4, 7, 10) Torí náà, àwọn tó jẹ́ Kristẹni tòótọ́ máa ‘dúró nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀,’ ìyẹn ni pé wọ́n á gbà pé ohun tí Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bá sọ ló jẹ́ “òtítọ́,” ohun tó wà nínú Bíbélì sì ni wọ́n máa ń gbé ìgbàgbọ́ wọn àti gbogbo ìṣe wọn kà.

Ohun Tí Àwọn Kristẹni Àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ Ṣe: Bí Jésù ṣe bọ̀wọ̀ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run náà ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe bọ̀wọ̀ fún un. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní.” (2 Tímótì 3:16) Àwọn ọkùnrin tí wọ́n bá yàn pé kí wọ́n máa kọ́ àwọn Kristẹni lẹ́kọ̀ọ́ nínú ìjọ gbọ́dọ̀ “rọ̀ mọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó dájú tó sì ṣeé gbíyè lé.” (Títù 1:7, 9, Bíbélì The Amplified Bible) Bíbélì tún gba àwọn Kristẹni ìjímìjí níyànjú pé kí wọ́n má ṣe gba “ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀tàn òfìfo ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé, tí kò sì sí ní ìbámu pẹ̀lú Kristi.”—Kólósè 2:8.

Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ohun Tí Jésù Sọ Lónìí? Àkójọ òfin tí àwọn aláṣẹ ìjọ Kátólíìkì ṣe, ìyẹn Dogmatic Constitution on Divine Revelation, èyí tí wọ́n tẹ́wọ́ gbà ní ọdún 1965 tí wọ́n sì gbé jáde nínú ìwé katikísìmù ti ìjọ Kátólíìkì, sọ pé: “Kì í ṣe inú Ìwé Mímọ́ nìkan ṣoṣo ni Ṣọ́ọ̀ṣì [Kátólíìkì] ti ń rí ìdánilójú rẹ̀ nípa ohun gbogbo tí a ti fi hàn. Nítorí náà, gbogbo àṣà mímọ́ àti Ìwé Mímọ́ ni a ní láti tẹ́wọ́ gbà kí a sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn pẹ̀lú ẹ̀mí ìjọsìn àti ìtẹríba kan náà.” (Catechism of the Catholic Church) Ìwé ìròyìn Maclean’s sọ pé obìnrin kan tó jẹ́ aṣáájú ìsìn ní ìlú Toronto ní orílẹ̀-èdè Kánádà béèrè pé: “Kí ló dé tó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ẹnì kan tó jẹ́ ajàjàgbara ní ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn la tún ṣì ń tẹ̀ lé lónìí? Ọ̀pọ̀ nǹkan tó dáa gan-an làwa náà máa ń fẹ́ fi ọgbọ́n orí tiwa gbé kalẹ̀, ṣùgbọ́n ohun tó máa ń bà á jẹ́ ni pé a ṣáà máa ń fẹ́ kó bá ọ̀rọ̀ Jésù àti Ìwé Mímọ́ mu.”

Ohun tí Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà New Catholic Encyclopedia sọ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni pé: “Wọ́n ka Bíbélì sí orísun kan ṣoṣo tí wọ́n ní fún ìgbàgbọ́ àti ìlànà ìwà híhù wọn.” Láìpẹ́ yìí, ọkùnrin kan ní orílẹ̀-èdè Kánádà dá ọ̀rọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́nu bí wọ́n ṣe fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn, ó ní: “Mo kúkú mọ̀ yín dáadáa.” Ó wá nawọ́ sí Bíbélì ọwọ́ arábìnrin náà, ó ní, “ohun tí mo fi máa ń dá yín mọ̀ rèé,” ìyẹn ni pé wọ́n lo Bíbélì láti fi bá a sọ̀rọ̀.