Kí Ló Burú Nínú Bíbá Ẹ̀mí Lò?
Kí Ló Burú Nínú Bíbá Ẹ̀mí Lò?
Láti ìgbà èwe ni Barbara * ti máa ń rí ìran, tó sì ń gbọ́ ohùn àwọn ẹ̀mí àìrí. Ó dáa lójú pé àwọn mọ̀lẹ́bí òun tó ti kú ló máa ń wá bá òun sọ̀rọ̀. Òun àti Joachim ọkọ rẹ̀ ka àwọn ìwé tó dá lórí iṣẹ́ awo, wọ́n sì di ògbóǹkangí nínú fífi àwọn káàdì ìwoṣẹ́ ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀. Káàdì wọn yìí sì fi hàn pé owó ńlá máa wọlé fún wọn, èyí tí wọ́n rí nídìí òwò tí wọ́n ń ṣe. Lọ́jọ́ kan, wọ́n rí ìkìlọ̀ gbà nínú káàdì ìwoṣẹ́ wọn pé àwọn èèyàn burúkú kan máa wá sílé wọn, ó sì tún sọ bí wọ́n ṣe máa dáàbò bo ara wọn.
LÓDE òní, ó lè dà bíi pé ìgbàgbọ́ nínú iṣẹ́ awo kò bóde mu mọ́, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ohun tó jẹ mọ́ nǹkan abàmì. Kárí ayé, ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń lo ìfúnpá, ońdè tàbí tírà, tàbí kí wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn aláwo tàbí adáhunṣe láti woṣẹ́ tàbí láti gba oògùn ààbò. Ìwé ìròyìn ilẹ̀ Jámánì kan tó ń jẹ́ Focus sọ nínú àpilẹ̀kọ kan tó pé àkòrí rẹ̀ ní “Laptop and Lucifer,” pé: “Íńtánẹ́ẹ̀tì ń mú kí àwọn èèyàn túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ohun tó jẹ mọ́ iṣẹ́ oṣó àti àjẹ́.”
Ǹjẹ́ o mọ̀ pé Bíbélì sọ nǹkan kan nípa bíbá ẹ̀mí lò? Ohun tó sọ nípa rẹ̀ lè yà ọ́ lẹ́nu.
Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ìbẹ́mìílò
Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn èèyàn rẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ sọ pé: “Kí a má ṣe rí láàárín rẹ . . . ẹnikẹ́ni tí ń woṣẹ́, pidánpidán kan tàbí ẹnikẹ́ni tí ń wá àwọn àmì ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí oníṣẹ́ oṣó, tàbí ẹni tí ń fi èèdì di àwọn ẹlòmíràn tàbí ẹnikẹ́ni tí ń wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ abẹ́mìílò tàbí olùsàsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí ẹnikẹ́ni tí ń ṣèwádìí lọ́dọ̀ òkú. Nítorí gbogbo àwọn tí ń ṣe nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà.” (Diutarónómì 18:10-12) Kí nìdí tí Jèhófà fi ka bíbá ẹ̀mí lò léèwọ̀ tó bẹ́ẹ̀?
Bí ẹ ṣe rí i nínú ohun tí a sọ nípa Barbara àti Joachim ọkọ rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́ pé alààyè lè bá òkú sọ̀rọ̀ àti pé iṣẹ́ tí àwọn aláwo bá jẹ́ fúnni, àwọn òkú ló fi rán wọn. Ohun tó sì mú kí àwọn èèyàn ní irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀kọ́ tí ọ̀pọ̀ ìsìn fi ń kọ́ni pé téèyàn bá kú, ṣe ló kàn papò dà tó sì ń bá ayé rẹ̀ lọ ní ibòmíì. Ṣùgbọ́n ẹ̀kọ́ tí Bíbélì kọ́ni yàtọ̀ pátápátá sí èyí. Bíbélì sọ ọ́ kedere pé: “Ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá.” (Oníwàásù 9:5) Ó ṣàpèjúwe àwọn òkú bíi pé wọ́n ń sun oorun àsùnwọra, tí wọn kò mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyìíká wọn rárá. * (Mátíù 9:18, 24; Jòhánù 11:11-14) O lè wá máa rò ó pé, tí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn tó wá ń sọ pé àwọn gbọ́ ohùn ẹni tó ti kú, tàbí pé wọ́n rí wọn ńkọ́? Ta ló bá irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀?
Bíbá Àwọn Ẹ̀mí Àìrí Sọ̀rọ̀
Ìwé ìhìn rere jẹ́ ká mọ̀ pé nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó bá àwọn ẹ̀mí àìrí sọ̀rọ̀. Ìwé Máàkù 1:23, 24 sọ pé “ẹ̀mí àìmọ́” kan sọ fún Jésù pé: “Mo mọ ẹni tí ìwọ jẹ́ gan-an.” Ó dájú pé àwọn ẹ̀mí àìrí mọ ìwọ náà. Ǹjẹ́ ìwọ mọ ẹni tí àwọn náà jẹ́?
Kí Ọlọ́run tó dá àwa èèyàn, ó ti dá ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó dà bí ọmọ fún un, ìyẹn àwọn áńgẹ́lì. (Jóòbù 38:4-7) Àwọn áńgẹ́lì kì í ṣe èèyàn ẹlẹ́ran ara bíi tiwa o. Ẹ̀dá ẹ̀mí ni wọ́n. (Hébérù 2:6, 7) Wọ́n lágbára gan-an, ọgbọ́n wọn sí bùáyà, ńṣe ni Ọlọ́run dá wọn kí wọ́n lè máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ìwé Sáàmù sọ pé: “Ẹ fi ìbùkún fún Jèhófà, ẹ̀yin áńgẹ́lì rẹ̀, tí ẹ tóbi jọjọ nínú agbára, tí ẹ ń pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́.”—Sáàmù 103:20.
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé nígbà tó yá, àwọn áńgẹ́lì kan bẹ̀rẹ̀ sí í kàn sí àwọn èèyàn lọ́nà tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Kí nìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ṣe ni áńgẹ́lì tó kọ́kọ́ ṣe bẹ́ẹ̀ fi ẹ̀tàn mú kí àwọn ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́, ìyẹn Ádámù àti Éfà, kẹ̀yìn sí Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá wọn. Ó wá tipa ohun tó ṣe yìí sọ ara rẹ̀ di Sátánì Èṣù, ìyẹn afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́ àti alátakò.—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6.
Nígbà tó yá, àwọn áńgẹ́lì míì “ṣá ibi gbígbé tiwọn tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu tì” lọ́run, wọ́n gbé ara èèyàn wọ̀, wọ́n wá sí ayé, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn arẹwà obìnrin ṣe aya tí wọ́n ń bá gbé ní ayé. (Júúdà 6; Jẹ́nẹ́sísì 6:1, 2) Àwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ yìí àti àwọn ọmọ wọn tó jẹ́ òmìrán wá bẹ̀rẹ̀ sí í han àwọn èèyàn léèmọ̀ gan-an débi pé ilẹ̀ ayé wá “kún fún ìwà ipá.” Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà mọ ìtàn Bíbélì yẹn, èyí tó sọ nípa bí Ọlọ́run ṣe fi ìkún omi ọjọ́ Nóà pa ìran èèyàn búburú àti oníwà ipá yẹn run.—Jẹ́nẹ́sísì 6:3, 4, 11-13.
Ìkún omi yẹn ló mú kí àwọn áńgẹ́lì yẹn bọ́ ara èèyàn sílẹ̀ tipátipá, tí wọ́n sì para dà di ẹ̀mí àìrí. Ṣùgbọ́n Ẹlẹ́dàá kò gbà kí wọ́n pa dà sí “ibi gbígbé” wọn tí wọ́n ti kúrò tẹ́lẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló fi wọ́n sí ipò ìrẹ̀sílẹ̀, èyí tá a lè fi wé inú “àwọn kòtò òkùnkùn biribiri.” (2 Pétérù 2:4, 5) Bíbélì máa ń pe àwọn ọlọ̀tẹ̀ áńgẹ́lì yẹn ní “àwọn ẹ̀mí èṣù.” (Jákọ́bù 2:19) Àwọn gan-an ló wà nídìí àṣà ìbẹ́mìílò.
Ohun Tí Àwọn Ẹ̀mí Èṣù Ń Fẹ́
Ohun àkọ́kọ́ tí àwọn ẹ̀mí èṣù tó ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ máa ń fẹ́ ṣe ni pé kí wọ́n tan irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kí wọ́n má ṣe jọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́. Agbára tàbí ẹ̀bùn tí àwọn oníṣẹ́ òkùnkùn máa ń sọ pé àwọn ní wulẹ̀ jẹ́ ọ̀nà tí àwọn ẹ̀mí èṣù gbà ń ṣèdíwọ́ fún àwọn èèyàn kí wọ́n má bàa ní ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run kí wọ́n sì wá di ọ̀rẹ́ rẹ̀.
Ohun kejì tí àwọn ẹ̀mí èṣù máa ń fẹ́ ni a lè rí látinú ohun tí Sátánì olórí wọn fẹ́ mú kí Jésù ṣe. Sátánì fi “gbogbo ìjọba ayé àti ògo wọn” lọ Jésù. Àmọ́ kí ni Sátánì fẹ́ kí Jésù wá ṣe fún òun? Ó rọ Jésù pé: “Wólẹ̀, [kí] o sì jọ́sìn mi lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.” Àbí ẹ ò rí nǹkan, ohun tí Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ń fẹ́ ni pé kéèyàn máa jọ́sìn wọn. Àmọ́ Jésù kọ̀ jálẹ̀ láti fi Ọlọ́run àti ìjọsìn tòótọ́ sílẹ̀.—Mátíù 4:8-10.
Lónìí, àwọn ẹ̀mí èṣù kì í sábà sọ ohun tí wọ́n ń fẹ́ ní tààràtà fún àwọn èèyàn bí wọ́n ti ṣe nígbà ayé Jésù. Kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ni wọ́n máa
ń fẹ́ láti fi àwọn ohun tí èèyàn kò lè tètè fura sí dẹkùn mú àwọn tí kò kíyè sára. Irú bíi kéèyàn lo awẹ́ obì láti fi woṣẹ́ tàbí èkùrọ́ tàbí àwo ribiti, àti wíwo àtẹ́lẹwọ́, wíwo ìràwọ̀ àti lílo káàdì ìwoṣẹ́. Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fi irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣì ọ́ lọ́nà! Nǹkan wọ̀nyẹn kì í ṣe ọ̀nà téèyàn kàn gbà ń lo agbára àwọn ohun tí Ọlọ́run dá láti fi mọ ohun tó kọjá òye èèyàn o. Àwọn ẹ̀mí burúkú ti mọ̀ pé nǹkan awo sábà máa ń jọni lójú, torí náà wọ́n máa ń dọ́gbọ́n lò ó láti fi dẹkùn mú àwọn èèyàn kí wọ́n má ṣe jọ́sìn Jèhófà. Tí àwọn ẹ̀mí búburú yìí kò bá wá rí ìyẹn ṣe wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í da àwọn tó ti kó sí ọ̀fìn wọn láàmú, wọ́n á fi ayé sú wọn. Tí wọ́n bá ti ń yọ ìwọ lẹ́nu, kí lo lè ṣe láti bọ́ lọ́wọ́ wọn?Bí Ó Ṣe Lè Bọ́ Lọ́wọ́ Ẹ̀mí Èṣù
Mọ̀ dájú pé, àwọn ẹ̀mí àìrí tó máa ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́run, ṣe ni Ọlọ́run sì máa pa wọ́n run. (Júúdà 6) Òpùrọ́ àti ẹlẹ̀tàn tó ń fi ọgbọ́n arúmọjẹ ṣe bíi ẹni tó ti kú ni wọ́n o. Báwo ló ṣe máa rí lára rẹ tó o bá mọ̀ pé ẹnì kan tó o kà sí ọ̀rẹ́ rẹ jẹ́ ẹlẹ̀tàn ẹ̀dá tó kàn ń wá bó ṣe máa dínà ire rẹ? Ká sọ pé o ti bá ẹnì kan da òwò pọ̀ kó o tó wá mọ̀ pé ògbólógbòó olè àti gbájúẹ̀ ni, kí lo máa ṣe? Tó o bá lọ kó sọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù pẹ́nrẹ́n, tiwọn tiẹ̀ tún burú jáì ju àwọn wọ̀nyẹn lọ. Ṣe ni kó o sa gbogbo ipá rẹ láti já ara rẹ gbà kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù. Báwo lo ṣe máa ṣe é?
Nígbà tí àwọn ará Éfésù ayé àtijọ́ mọ ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa ìbẹ́mìílò, wọ́n rí i pé àwọn gbọ́dọ̀ jó gbogbo ìwé idán pípa tí àwọn ní, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìwé olówó ńlá ni wọ́n. Ṣe ni wọ́n “dáná sun wọ́n níwájú gbogbo ènìyàn.” (Ìṣe 19:19, 20) Lóde òní, kì í ṣe àwọn nǹkan bí ìfúnpá, ońdè, tírà, ìwé idán àti irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ nìkan ni àwọn èèyàn ń lò fún iṣẹ́ awo, wọ́n tún ń lo àwọn nǹkan téèyàn lè rí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì àti nínú àwọn ẹ̀rọ tàbí ohun èlò abánáṣiṣẹ́ míì. Yàgò fún ohunkóhun tó bá lè mú kó o lọ́wọ́ nínú bíbá ẹ̀mí èṣù lò.
Ṣé o rántí tọkọtaya Joachim àti Barbara tí a sọ̀rọ̀ wọn níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí? Ohun tí wọ́n rí nínú káàdì ìwoṣẹ́ wọn mú kí wọ́n gbà pé àwọn èèyàn eléwu kan ń bọ̀ nílé àwọn, pé kò yẹ kí àwọn tẹ́tí sí wọn tàbí kí àwọn gba ohunkóhun lọ́dọ̀ wọn. Àmọ́ nígbà tí àwọn obìnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì, ìyẹn Connie àti Gudrun, wá sí ilé wọn láti wàásù ìhìn rere nípa Ọlọ́run, tọkọtaya náà sọ pé àwọn tiẹ̀ máa gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn. Wọ́n wá jọ sọ̀rọ̀ dé orí ọ̀rọ̀ bíbá ẹ̀mí èṣù lò, arábìnrin Connie àti Gudrun sì fi Ìwé Mímọ́ ṣe àlàyé òtítọ́ nípa rẹ̀ fún wọn. Bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé nìyẹn.
Láìpẹ́, Joachim àti Barbara jáwọ́ pátápátá nínú bíbá ẹ̀mí èṣù lò. Àwọn Ẹlẹ́rìí yẹn ṣàlàyé fún wọn pé inú àwọn ẹ̀mí èṣù náà kò ní dùn bí wọ́n ṣe jáwọ́ o. Láìfọ̀rọ̀ gùn, ojú Joachim àti Barbara rí màbo, àwọn ẹ̀mí èṣù sì tún hàn wọ́n léèmọ̀. Fún ìgbà díẹ̀, alaalẹ́ ni ẹ̀rù máa ń bà wọ́n, àfi ìgbà tí wọ́n kó lọ sí ilé míì ni wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí í bọ́ lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù yẹn. Nínú gbogbo wàhálà wọn yìí, ọ̀rọ̀ inú Fílípì 4:13 ni tọkọtaya yìí fi ń ki ara wọn láyà. Ó sọ pé: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.” Jèhófà sì tì wọ́n lẹ́yìn lóòótọ́ nítorí ìpinnu tí wọ́n ṣe, nígbà tó sì yá àwọn ẹ̀mí èṣù náà kò yọ wọ́n lẹ́nu mọ́. Lónìí, Joachim àti Barbara ti dẹni tó ń jọ́sìn Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ tayọ̀tayọ̀.
Ìwé Mímọ́ rọ gbogbo àwọn tó bá fẹ́ gba ìbùkún Jèhófà pé: “Ẹ fi ara yín sábẹ́ Ọlọ́run; ṣùgbọ́n ẹ kọ ojú ìjà sí Èṣù, yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín. Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” (Jákọ́bù 4:7, 8) Tó o bá fẹ́ bọ́ lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù, Jèhófà lè ràn ọ́ lọ́wọ́, ó sì ṣe tán láti gbà ọ́ sílẹ̀. Bí Joachim àti Barbara ṣe tún ronú nípa bí wọ́n ṣe dòmìnira kúrò nínú bíbá ẹ̀mí èṣù lò, wọ́n gbà tọkàntọkàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ Sáàmù 121:2 tó sọ pé: “Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìrànlọ́wọ́ mi ti wá.”
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ A ti yí orúkọ wọn pa dà.
^ Tó o bá fẹ́ rí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ipò tí àwọn òkú wà, wo orí kẹfà, tí àkòrí rẹ̀ jẹ́, “Ibo Làwọn Òkú Wà?,” nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 21]
Iṣẹ́ awo kì í jẹ́ kí èèyàn ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 22]
“Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.”—JÁKỌ́BÙ 4:8