Kí Ni Èrò Rẹ Nípa Jésù?
Kí Ni Èrò Rẹ Nípa Jésù?
Ṣé ìkókó ni? Àbí ẹni tó ń kú lọ? Àbí Ọba tí a gbé ga?
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ní báyìí, Ọba alágbára ni Jésù. Kí ni ìyẹn túmọ̀ sí fún ọ?
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà gbọ́ pé Jésù kú fún àwọn. Àmọ́, báwo ni kíkú tí ọkùnrin kan kú ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì [2,000] sẹ́yìn ṣe lè mú kí àwọn èèyàn ní ìyè lóde òní?
A fi ọ̀yàyà pè ọ́ pé kó o wá gbọ́ ìdáhùn tá a mú látinú Ìwé Mímọ́ sí àwọn ìbéèrè yìí. A máa ṣàlàyé àwọn ìdáhùn náà nígbà tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá pé jọ láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Lọ́dún yìí, ọjọ́ náà bọ́ sí Thursday, April 5, lẹ́yìn tí oòrùn bá ti wọ̀.
Jọ̀wọ́ béèrè ibi tí wọ́n ti fẹ́ ṣe é àti àkókò tí wọ́n máa ṣe é lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ.
Ní òpin ọ̀sẹ̀ ọjọ́ tá a máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún máa sọ àsọyé alárinrin kan tá a mú látinú Bíbélì. Àkòrí àsọyé náà ni “Ǹjẹ́ Òpin Ti Sún Mọ́lé Ju Bó O Ṣe Rò Lọ?” Àsọyé yìí máa jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ìsapá tí à ń ṣe kárí ayé láti ran gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jésù lọ́wọ́. A pè ọ́ pé kó o wá.