Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Mo Ti Sọ Orúkọ Rẹ Di Mímọ̀’

‘Mo Ti Sọ Orúkọ Rẹ Di Mímọ̀’

‘Mo Ti Sọ Orúkọ Rẹ Di Mímọ̀’

“Mo ti fi orúkọ rẹ hàn kedere fún àwọn ènìyàn tí ìwọ fi fún mi láti inú ayé. . . . Mo sì ti sọ orúkọ rẹ di mímọ̀ fún wọn, ṣe ni èmi yóò sì sọ ọ́ di mímọ̀.”—JÒHÁNÙ 17:6, 26.

Ohun Tí Ọ̀rọ̀ Yìí Túmọ̀ Sí: Jésù sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ̀ ní ti pé ó ń lò ó bó ṣe ń wàásù. Jésù sábà máa ń ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ sétí ìgbọ́ àwọn èèyàn, torí náà, láwọn ìgbà tó ń kà á yóò ti pe orúkọ Ọlọ́run níbi tó bá ti rí i nínú Ìwé Mímọ́. (Lúùkù 4:16-21) Ó kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ kí wọ́n máa gbàdúrà pé: “Baba, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.”—Lúùkù 11:2.

Ohun Tí Àwọn Kristẹni Àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ Ṣe: Àpọ́sítélì Pétérù sọ fún àwọn àgbà ọkùnrin tó wà ní Jerúsálẹ́mù pé Ọlọrun ti mú “àwọn ènìyàn kan fún orúkọ rẹ̀” jáde láti inú àwọn orílẹ̀-èdè. (Ìṣe 15:14) Àwọn àpọ́sítélì àti àwọn yòókù sì wàásù pé “olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a ó gbà là.” (Ìṣe 2:21; Róòmù 10:13) Wọ́n tún lo orúkọ Ọlọ́run nínú àwọn ìwé tí wọ́n kọ. Ìwé àkópọ̀ òfin àtẹnudẹ́nu tó ń jẹ́ The Tosefta, tí wọ́n parí kíkọ rẹ̀ ní nǹkan bí ọdún 300 Sànmánì Kristẹni, sọ nípa bí àwọn ọ̀tá ṣe dáná sun ìwé àwọn Kristẹni, ó ní: “Ìwé àwọn Ajíhìnrere àti ìwé àwọn minim [èyí lè túmọ̀ sí àwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù] ni wọn kò yọ nínú iná. Ńṣe ni wọ́n jẹ́ kí iná jó wọn mọ́ ibi tí wọ́n wà, . . . àwọn ìwé náà àti Orúkọ Ọlọ́run tó wà nínú wọn.”

Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ohun Tí Jésù Sọ Lónìí? Bíbélì Revised Standard Version, tí Ìgbìmọ̀ Àpapọ̀ Àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Kristi ní Amẹ́ríkà fàṣẹ sí, sọ nínú ọ̀rọ̀ ìṣáájú rẹ̀ pé: “Lílo orúkọ pàtó kan fún Ọlọ́run kan ṣoṣo náà, bí ẹni pé àwọn ọlọ́run mìíràn wà, tí a ní láti fi Ọlọ́run tòótọ́ hàn yàtọ̀ lára wọn, ni wọ́n ti ṣíwọ́ rẹ̀ nínú ẹ̀sìn àwọn Júù ṣáájú sànmánì àwọn Kristẹni, àti pé kò tiẹ̀ yẹ kó wáyé rárá nínú ìgbàgbọ́ àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹni ní gbogbo gbòò.” Wọ́n wá fi orúkọ oyè náà, “OLÚWA,” rọ́pò orúkọ Ọlọ́run nínú Bíbélì yẹn. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn aláṣẹ ìjọ Kátólíìkì pàṣẹ fún àwọn bíṣọ́ọ̀bù wọn pé: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ lo orúkọ Ọlọ́run, tó jẹ mọ́ lẹ́tà mẹ́rin ti èdè Hébérù náà YHWH * yálà nínú orin tàbí nínú àdúrà, ẹ má sì pè é rárá.”

Lóde òní, àwọn wo ló ń lo orúkọ Ọlọ́run tí wọ́n sì ń sọ ọ́ di mímọ̀ fún àwọn èèyàn? Nígbà tí ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Sergey ṣì wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lórílẹ̀-èdè Kyrgyzstan, ó wo fíìmù kan tí wọ́n ti sọ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. Odindi ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn náà, kò gbọ́ nǹkan kan nípa orúkọ yẹn mọ́. Lẹ́yìn tí Sergey wá kó lọ sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì wàásù fún un nílé rẹ̀, wọ́n sì fi orúkọ Ọlọ́run hàn án nínú Bíbélì. Inú rẹ̀ dùn gan-an pé òun rí àwọn èèyàn tó ń lo orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà. Ó sì dùn mọ́ni pé ìwé atúmọ̀ èdè náà, Webster’s Third New International Dictionary, sọ pé Jèhófà Ọlọ́run ni “Ọlọ́run gíga jù lọ, òun sì ni Ọlọ́run kan ṣoṣo tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ tí wọ́n sì ń jọ́sìn.”

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ “Jèhófà” ni wọ́n sábà máa ń pe orúkọ Ọlọ́run lédè Yorùbá.