Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Irú pẹpẹ wo ni pẹpẹ sí “Ọlọ́run Àìmọ̀” tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rí ní ìlú Áténì?—Ìṣe 17:23.

Díẹ̀ nínú àwọn òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì mẹ́nu kan irú àwọn pẹpẹ bẹ́ẹ̀ nínú ìwé wọn láyé àtijọ́. Bí àpẹẹrẹ, òpìtàn kan tó ń jẹ́ Pausanias tó gbé ayé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kejì Sànmánì Kristẹni, tó sì jẹ́ onímọ̀ nípa ilẹ̀ ayé àtàwọn nǹkan tó wà nínú rẹ̀, sọ pé “pẹpẹ kan sí àwọn ọlọ́run Àìmọ̀” wà ní ìlú Olympia. Sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ àti onímọ̀ ọgbọ́n orí kan tó ń jẹ́ Philostratus sọ pé ní Áténì, “wọ́n tiẹ̀ tún ṣe àwọn pẹpẹ láti máa fi júbà àwọn ọlọ́run àìmọ̀.”

Òǹkọ̀wé kan tó gbé ayé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹta Sànmánì Kristẹni, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Diogenes Laertius, sọ ìtàn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ kan tó jẹ́ ká mọ bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í mọ “àwọn pẹpẹ tí kò lórúkọ.” Ìtàn àròsọ yìí tó ti wà láti ọgọ́rùn-ún ọdún kẹfà tàbí ìkeje ṣáájú Sànmánì Kristẹni sọ bí ẹnì kan tó ń jẹ́ Epimenides ṣe ṣètùtù kan tó gba ìlú Áténì lọ́wọ́ àjàkálẹ̀ àrùn kan. Nínú ìwé tí Diogenes kọ, ó sọ pé: “Ó [ìyẹn Epimenides] kó àwọn àgùntàn kan . . . wá sí Áréópágù; ó sì tú wọn sílẹ̀ níbẹ̀ kí wọ́n máa lọ síbi tí wọ́n bá fẹ́, ó wá ní kí àwọn tó ń tẹ̀ lé wọn sàmì síbi tí àgùntàn kọ̀ọ̀kan bá dùbúlẹ̀ sí, kí wọ́n sì rúbọ sí òrìṣà tó wà níbẹ̀. Wọ́n ní bí àjàkálẹ̀ àrùn náà ṣe kásẹ̀ nílẹ̀ nìyẹn. Ìyẹn ló fà á tí àwọn pẹpẹ tí kò lórúkọ fi wà káàkiri ní àgbègbè Attica títí di òní.”

Ìwé The Anchor Bible Dictionary sọ pé ohun tó tún lè jẹ́ ìdí míì tí àwọn kan fi ń mọ pẹpẹ fún ọlọ́run àìmọ̀ ni torí “ìbẹ̀rù kí àwọn má lọ ṣèèṣì gbójú fo àwọn òrìṣà kan tó yẹ kí àwọn máa júbà àmọ́ tí àwọn kò mọ̀ ọ́n, kó sì wá di pé ire tó yẹ kí àwọn gbà lọ́dọ̀ òrìṣà náà fo àwọn ru tàbí kí òrìṣà náà tiẹ̀ bínú sí àwọn.”

Kí nìdí tí àwọn Júù ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní fi kórìíra àwọn agbowó orí?

Àwọn èèyàn kì í fẹ́ràn àwọn agbowó orí rárá. Nílẹ̀ Ísírẹ́lì ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn èèyàn ka àwọn agbowó orí sí èèyànkéèyàn àti aláìṣòótọ́ paraku.

Àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Róòmù máa ń gba owó orí tó pọ̀ gan-an lọ́wọ́ àwọn èèyàn. Àwọn òṣìṣẹ́ ilẹ̀ Róòmù ló máa ń gba owó ilẹ̀ àti owó orí ẹnì kọ̀ọ̀kan, àmọ́ wọ́n máa ń gbé iṣẹ́ gbígba owó ẹrù tó ń wọlé láti ilẹ̀ òkèèrè àti èyí tó ń lọ sílẹ̀ òkèèrè, àti owó ẹrù tí ó ń gba ibodè ìlú kọjá, fún àwọn agbaṣẹ́ṣe tó bá máa pa owó tó pọ̀ jù lọ sápò ìjọba. Nítorí náà, àwọn oníṣòwò máa ń gbàwé àṣẹ láti máa gba owó orí láwọn ibì kan. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan sọ pé àwọn Júù máa ń kórìíra Júù ẹlẹ́gbẹ́ wọn tó bá lọ gba irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn ará ilẹ̀ Róòmù ọ̀tá wọn, torí wọ́n ka irú àwọn Júù bẹ́ẹ̀ sí “ọ̀dàlẹ̀ àti apẹ̀yìndà, tí wọ́n sọ ara wọn di ẹlẹ́gbin nítorí wọléwọ̀de tí wọ́n ń bá àwọn abọ̀rìṣà yẹn ṣe.”—M’Clintock and Strong’s Cyclopædia.

Àwọn agbowó orí máa ń ya aláìṣòótọ́ paraku, wọ́n sì máa ń dìídì fá àwọn Júù ẹlẹ́gbẹ́ wọn lórí láti lè pawó sápò ara wọn. Àwọn míì máa ń bù lé owó tó yẹ́ kí wọ́n gbà lórí ẹrù, wọ́n á sì kó èlé orí rẹ̀ sápò ara wọn, àwọn míì tiẹ̀ máa ń dìídì parọ́ mọ́ àwọn tálákà láti lè gba owó gọbọi lọ́wọ́ wọn. (Lúùkù 3:13; 19:8) Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The Jewish Encyclopedia, sọ pé ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé ojú kan náà ni wọ́n fi ń wo agbowó orí àtàwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, wọn kì í sì í “gbà kí wọ́n jẹ́ adájọ́ tàbí kí wọ́n tilẹ̀ jẹ́ ẹlẹ́rìí pàápàá.”—Mátíù 9:10, 11.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Pẹpẹ kan sí ọlọ́run àìmọ̀, èyí tó wà lára àwókù ìlú Págámù ní orílẹ̀-èdè Tọ́kì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Ère agbowó orí kan tí wọ́n gbẹ́ nílẹ̀ Róòmù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kejì tàbí ìkẹta Sànmánì Kristẹni

[Credit Line]

Erich Lessing/Art Resource, NY