Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wíwá Ìṣura Lórí Àwọn Òkè Oníwúrà Lórílẹ̀-èdè Altay

Wíwá Ìṣura Lórí Àwọn Òkè Oníwúrà Lórílẹ̀-èdè Altay

Lẹ́tà Kan Láti Ilẹ̀ Rọ́ṣíà

Wíwá Ìṣura Lórí Àwọn Òkè Oníwúrà Lórílẹ̀-èdè Altay

LỌ́JỌ́ kan tí ojú ọjọ́ mọ́ rekete láàárín oṣù May, a wà ní orílẹ̀-èdè Altay, ìyẹn àgbègbè kan tó fani mọ́ra gan-an ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Sìbéríà. Bí a ṣe wo ìta láti ojú fèrèsé wa, a rí àwọn igbó kéréje-kéréje, a sì tún rí ṣóńṣó orí àwọn òkè tí yìnyín bò lọ́nà tó lẹ́wà lẹ́yìn àwọn igbó yìí, tí wọ́n sì ní àwọ̀ búlúù fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́. Ilẹ̀ olókè págunpàgun tó wà ní àdádó, èyí tí a wà yìí, jẹ́ ilẹ̀ àwọn Altay, ìyẹn àwọn ará Éṣíà kan tí wọ́n ní èdè tiwọn. Àwọn Òkè Ńlá Altai yìí jẹ́ ibi tó bá wọn lára mu gan-an, orúkọ tí wọ́n sì sọ ọ́ wá látinú èdè Turkic-Mogolian tó túmọ̀ sí “oníwúrà.”

Ó ti tó ọdún mélòó kan báyìí tí èmi àti aya mi ti kọ́ èdè adití lọ́nà ti Rọ́ṣíà, tí a sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìbẹ̀wò sí ìjọ àwọn adití tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti sí àwọn àwùjọ wọn kéékèèké tó wà káàkiri. Ní ilẹ̀ Rọ́ṣíà, ó lé ní ọgọ́rùn-ún [100] ẹ̀yà àti onírúurú àṣà ìbílẹ̀ tó lé ní àádọ́rin [70] tí wọ́n jọ ń lo èdè kan ṣoṣo, ìyẹn èdè Rọ́ṣíà. Àwọn odi tó wà láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbẹ̀ náà ní èdè kan tí wọ́n jọ ń sọ, ìyẹn èdè adití lọ́nà ti Rọ́ṣíà. Àwọn odi yìí máa ń ṣe ara wọn lọ́kan, púpọ̀ nínú àwọn tí a sì ń bá pàdé ló máa ń hára gàgà láti sọ nípa ara wọn fún wa àti láti ṣe wá lálejò. Bọ́rọ̀ ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn ní orílẹ̀-èdè Altay.

Ní ìlú kan tó ń jẹ́ Gorno-Altaysk, a gbọ́ pé àwọn odi bí mélòó kan ń gbé ní abúlé kékeré kan tó jìnnà tó nǹkan bí àádọ́talénígba [250] kìlómítà. A mọ̀ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan wà níbẹ̀, àmọ́ wọn kò gbọ́ èdè àwọn adití. A ronú gan-an nípa ọ̀rọ̀ àwọn odi tó wà ní Altay yẹn, a sì pinnu láti lọ síbẹ̀ lọ wá wọn. Ìtara wa wú àwọn odi méjì kan lórí, ìyẹn Yuri àti Tatyana tí wọ́n jẹ́ tọkọtaya, àwọn méjèèjì sì gbà láti bá wa lọ. A kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtẹ̀jáde lédè adití tí wọ́n ṣe sórí àwo DVD àti ẹ̀rọ kan tí wọ́n fi ń wo DVD sínú ọkọ̀ bọ́ọ̀sì kékeré kan. A rọ nǹkan mímu sínú ohun èlò amú-nǹkan-gbóná ńlá kan, a tún gbé oúnjẹ bí búrẹ́dì ẹlẹ́ran àti oúnjẹ ilẹ̀ Rọ́ṣíà míì dání. Lẹ́yìn ìyẹn, a wá fọ́n oògùn tó ń lé eégbọn sára aṣọ àti bàtà wa dáadáa, torí àwọn eégbọn ibẹ̀ sábà máa ń fa àrùn kan tó máa ń mú ọpọlọ wú.

Ọ̀nà tí a gbà lọ sọ́hùn jẹ́ ọ̀nà tó gba ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ òkè ńláńlá tó dùn-ún wò. Ńṣe ni òórùn dídùn láti ara àwọn òdòdó àti ewéko sì kún inú afẹ́fẹ́ ibẹ̀. Ìyẹn sì túbọ̀ mú ara wa yá gágá! Inú wa dùn gan-an bá a ṣe rí agbo àwọn ìgalà ilẹ̀ Sìbéríà tí wọ́n ń rọra ń jẹko. Ilé onípákó tí wọ́n fi páànù bò lórí ni àwọn èèyàn Altay máa ń gbé ní àwọn abúlé wọn, ilé wọn sì máa ń sún mọ́ra. Àwọn ibùgbé tí wọ́n fi igi ṣe tún máa ń wà níbẹ̀, èyí tí wọ́n ń pè ní ayyl, ó sábà máa ń ní orígun mẹ́fà àti òrùlé ṣóńṣó. Àwọn míì nínú wọn máa ń dà bí àgọ́ ṣúúṣùùṣú tí wọ́n fi èèpo igi bò lórí. Ọ̀pọ̀ ìdílé àwọn Altay máa ń gbé nínú ibi tí wọ́n ń pé ní ayyl yìí láti oṣù May sí September, wọ́n á wá pa dà sínú ilé wọn nígbà ìwọ́wé (ìyẹn ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn) àti ìgbà òtútù.

Tẹ̀ríntẹ̀yẹ ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní abúlé yẹn fi kí wa káàbọ̀, tí wọn sì mú wa lọ sí ilé àwọn odi tó jẹ́ tọkọtaya kan níbẹ̀. Inú wọn dùn láti rí wa, wọ́n sì ń fẹ́ láti mọ ibi tí a ti wá àti ohun tí a wá ṣe. Ó ṣẹlẹ̀ pé wọ́n ní ẹ̀rọ̀ kọ̀ǹpútà sílé, torí náà, nígbà tí a mú àwo DVD kan jáde, wọ́n ṣá a fẹ́ ká wò ó lórí rẹ̀. Bí wọ́n ṣe fi àwo DVD yẹn sínú rẹ̀ báyìí, wọn ò tiẹ̀ dá sí wa mọ́, ṣe ni wọ́n gbàgbé wa sórí ìjókòó, bíi pé a ò sí níbẹ̀. Àwọn méjèèjì tẹjú mọ́ fídíò náà, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan wọ́n á fọwọ́ ṣàpèjúwe bíi ti ẹni tí wọ́n ń wò nínú fídíò náà, wọ́n á sì mi orí láti fi hàn pé àwọn rí nǹkan kọ́. A ṣáà wá ọgbọ́n dá láti fi mú kí wọ́n gbọ́ tiwa ká lè dá fídíò náà pa dà sí ìbẹ̀rẹ̀, níbi tí wọ́n ti máa rí àwòrán Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Nígbà tí a dé orí ìran kan, a dá fídíò náà dúró díẹ̀ láti jíròrò nípa àwọn nǹkan tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún aráyé àti irú àwọn èèyàn tí yóò gbé nínú Párádísè tí wọ́n rí àwòrán rẹ̀. Inú wa dùn bí wọ́n ṣe nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́, lẹ́yìn tí a sì parí ìjíròrò wa, wọ́n sọ fún wa pé àwọn tọkọtaya míì tó jẹ́ odi ń gbé ní abúlé kan tó wà nítòsí ọ̀dọ̀ àwọn.

Bí a ṣe tún gbéra nìyẹn, tí a gba àárín àfonífojì àwọn òkè àpáta ńlá kọjá, á sì gba ọ̀nà kọ́lọkọ̀lọ kan lọ sí abúlé kékeré yẹn. A bá ìdílé kan níbẹ̀ tí gbogbo wọn jẹ́ odi, ìyẹn ọkọ, ìyàwó, ìyá ìyàwó àti ọmọ wọn kékeré. Inú wọn dùn gan-an láti rí àwọn àjèjì tó dédé wá bá wọn lálejò láìròtẹ́lẹ̀. A gba ẹnu ọ̀nà kékeré kan wọ inú ayyl wọn, níbi tí òórùn igi tí wọ́n fi ṣe ilé náà àti òórùn bọ́tà ti ń ta sánsán. Ibùgbé náà ní ihò róbótó kan tí ìmọ́lẹ̀ ń gbà wọlé níbi òrùlé rẹ̀ ṣóńṣó. Ààrò kan tí wọ́n fi bíríkì ṣe àti sítóòfù wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, wọ́n sì lẹ rọ́ọ̀gì aláwọ̀ pupa yíká ara inú ibùgbé náà. Tọkọtaya náà fún wa ní oúnjẹ ilẹ̀ Altay, ìyẹn dónọ́ọ̀tì àti tíì tí wọ́n fi sínú àwọn àwo kékeré tí wọ́n ń lò nílẹ̀ Éṣíà. A béèrè lọ́wọ́ wọn bóyá wọ́n tiẹ̀ ti rò ó rí pé àwọn lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Wọ́n ronú jinlẹ̀ lórí ìbéèrè yẹn. Ìyá ìyàwó yẹn wá sọ pé nígbà tí òun wà lọ́mọdé, òun ti gbé oúnjẹ lọ sórí òkè kan lẹ́ẹ̀kan rí láti fi rúbọ sí àwọn òrìṣà. Ó wá mi èjìká, ó sì rẹ́rìn-ín, ó ní: “Mi ò kúkú mọ ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí. Mo ṣáà mọ̀ pé àṣà ìbílẹ̀ wa ni.”

A wá fi fídíò kan tó sọ̀rọ̀ lórí bí wọ́n ṣe lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run hàn wọ́n, inú wọ́n sì dún gidigidi. Wọn ì bá fẹ́ kí ìjíròrò wa máa bá a lọ, àmọ́, báwo ló ṣe máa ṣeé ṣe? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà tó rọrùn jù láti máa bá àwọn odi sọ̀rọ̀ láti ọ̀nà jíjìn ni pé ká máa fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí wọn lórí fóònù, àmọ́, kò sí ẹ̀rọ alátagbà tó ń gbé ọ̀rọ̀ wá sínú fóònù ládùúgbò yẹn. Torí náà, a ṣèlérí fún wọn pé àá máa kọ lẹ́tà sí wọn.

Nígbà tá a fi máa kúrò lọ́dọ̀ wọn, oòrùn ti ń wọ̀, ó sì ti rẹ̀ wá àmọ́, tayọ̀tayọ̀ la fi ń pa dà bọ̀ láti ọ̀nà jíjìn yẹn wá sí Gorno-Altaysk. Nígbà díẹ̀ lẹ́yìn náà, a béèrè nípa ìdílé yẹn lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀, wọ́n sì sọ fún wa pé ọkùnrin yẹn máa ń lọ sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú ńlá tó wà lágbègbè ibẹ̀ láti lọ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kó sì lọ sí ìpàdé, àti pé arábìnrin kan tó mọ èdè adití ló ń ràn án lọ́wọ́. Inú wa dùn gan-an pé wàhálà wa kò já sí asán!

Ṣe ni bá a ṣe ń wá àwọn odi tó nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ káàkiri dà bí ìgbà tí èèyàn ń wá àwọn ìṣura tó fara sin láàárín àwọn òkè ńláńlá. Inú wa máa ń dùn gan-an tá a bá jàjà bá odi kan tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ pàdé lẹ́yìn ọ̀pọ̀ wákàtí tá a ti ń wá wọn kiri. Bí òkè oníwúrà ni àwọn òkè Altay yóò ṣe máa rí lójú tiwa títí, nítorí ó máa ń jẹ́ ká rántí àwọn olùfẹ́ òtítọ́ tí a rí láàárín àwọn òkè págunpàgun wọ̀nyẹn.