Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Wọn Kì Í Ṣe Apá Kan Ayé”

“Wọn Kì Í Ṣe Apá Kan Ayé”

“Wọn Kì Í Ṣe Apá Kan Ayé”

“Ayé ti kórìíra wọn, nítorí pé wọn kì í ṣe apá kan ayé.”—JÒHÁNÙ 17:14.

Ohun Tí Ọ̀rọ̀ Yìí Túmọ̀ Sí: Torí pé Jésù kì í ṣe apá kan ayé, kò dá sí gbogbo rògbòdìyàn tó ń lọ láwùjọ nígbà ayé rẹ̀, kò sì dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú. Ó sọ pé: “Bí ìjọba mi bá jẹ́ apá kan ayé yìí, àwọn ẹmẹ̀wà mi ì bá ti jà kí a má bàa fà mí lé àwọn Júù lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí, ìjọba mi kì í ṣe láti orísun yìí.” (Jòhánù 18:36) Ó tún gba àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n má ṣe fàyè gba ìwà, ọ̀rọ̀ àti àṣà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu.—Mátíù 20:25-27.

Ohun Tí Àwọn Kristẹni Àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ Ṣe: Ohun tí Jonathan Dymond tó jẹ́ òǹkọ̀wé nípa ẹ̀sìn sọ ni pé àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ “kọ̀ láti lọ́wọ́ sí [ogun]; láìka ohun yòówù kó yọrí sí, wọn ì báà pẹ̀gàn wọn, wọn ì báà sọ wọ́n sẹ́wọ̀n, tàbí kí wọ́n tiẹ̀ pa wọ́n.” Wọ́n gbà láti jìyà dípò tí wọ́n fi máa lọ́wọ́ sí ogun. Ìwà àti ìṣe àwọn Kristẹni sì tún mú kí wọ́n dá yàtọ̀ gédégbé. Bíbélì sọ fún àwọn Kristẹni pé: “Nítorí ẹ kò bá a lọ ní sísáré pẹ̀lú wọn ní ipa ọ̀nà yìí sínú kòtò ẹ̀gbin jíjìnwọlẹ̀ kan náà tí ó kún fún ìwà wọ̀bìà, ó rú wọn lójú, wọ́n sì ń bá a lọ ní sísọ̀rọ̀ yín tèébútèébú.” (1 Pétérù 4:4) Òpìtàn náà, Will Durant, sọ pé: ‘Ìwà mímọ́ àti ìwà ọmọlúwàbí àwọn Kristẹni máa ń múnú bí àwọn abọ̀rìṣà ayé ìgbà yẹn tí ayé ìjẹkújẹ ti fọ́ lórí.’

Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ohun Tí Jésù Sọ Lónìí? Lórí ọ̀rọ̀ pé kí Kristẹni kọ̀ láti dá sí ogun jíjà, ohun tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, New Catholic Encyclopedia, sọ ni pé: “Kò tiẹ̀ ṣeé gbọ́ sétí rárá pé kí ẹnì kan sọ pé ẹ̀rí ọkàn òun kò jẹ́ kóun lọ́wọ́ sí ogun jíjà.” Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn Reformierte Presse sọ pé àjọ kan tó ń jà fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn nílẹ̀ Áfíríkà, ìyẹn African Rights, fi ẹ̀rí hàn pé gbogbo àwọn ṣọ́ọ̀ṣì pátá ló lọ́wọ́ nínú ìpẹ̀yàrun tó wáyé ní orílẹ̀-èdè Rùwáńdà lọ́dún 1994, “àyàfi àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ṣoṣo.”

Nígbà tí olùkọ́ nílé ẹ̀kọ́ gíga kan ń sọ̀rọ̀ nípa ìpakúpa rẹpẹtẹ tó wáyé nígbà ìjọba Násì, ó sọ pé ó dun òun pé “kò tiẹ̀ sí ẹgbẹ́ tàbí àjọ kankan tó jẹ́ ti àwọn ará ìlú, tó sọ̀rọ̀ lòdì sí gbogbo irọ́ burúkú, ìwà ìkà àti ìwà búburú jáì tí ìjọba Násì hù.” Lẹ́yìn tí olùkọ́ yìí ṣèwádìí ní ilé àkójọ ohun ìṣẹ̀ǹbáyé kan, ìyẹn United States Holocaust Memorial Museum, ó kọ̀wé pé: “Mo ti wá rí ohun tí mò ń wá báyìí.” Ó rí ẹ̀rí tó fi hàn pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mú ìdúró wọn lòdì sí gbogbo ìwà burúkú yẹn nítorí ìgbàgbọ́ wọn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fìyà jẹ wọ́n gan-an.

Báwo làwọn tó sọ pé Kristẹni ni àwọn ṣe ń ṣe sí ní ti ìwà híhù? Ìwé ìròyìn U.S. Catholic tó sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sìn Kátólíìkì ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ọ̀dọ́ òde òní tó wà nínú ìjọ Kátólíìkì ni kò fara mọ́ ohun tí ṣọ́ọ̀ṣì wọn ń kọ́ni lórí ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó àti bí ọkùnrin àti obìnrin ṣe ń gbé pọ̀ bíi tọkọtaya ṣáájú ìgbéyàwó.” Ìwé ìròyìn yẹn ní díákónì kan nínú ṣọ́ọ̀ṣì yẹn sọ pé: “Èyí tó ju ìdajì nínú àwọn tí mo ń rí pé wọ́n ń wá ṣègbéyàwó wọn nínú ṣọ́ọ̀ṣì ló jẹ́ pé wọ́n ti ń gbé pọ̀ bíi tọkọtaya ṣáájú kí wọ́n tó wá.” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà “gbà pé èèyàn gbọ́dọ̀ máa hùwà mímọ́ nígbà gbogbo.”